ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 51
Ṣé Ó Dá Ẹ Lójú Pé O Mọ Jèhófà?
“Àwọn tó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀ lé ọ; Jèhófà, ìwọ kì yóò pa àwọn tó ń wá ọ tì láé.”—SM. 9:10.
ORIN 56 Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Arákùnrin Angelito?
ṢÉ Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó dáa. Àmọ́ fi sọ́kàn pé ìgbàgbọ́ kì í ṣe ogún ìdílé, ti pé àwọn òbí rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà kò sọ ìwọ náà di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Yálà Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí wa tàbí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, oníkálukú wa ló gbọ́dọ̀ ṣe ohun táá mú kó di ọ̀rẹ́ Jèhófà.
2 Ẹ jẹ́ ká fi ìrírí arákùnrin kan ṣàpẹẹrẹ ohun tá à ń sọ yìí. Angelito lorúkọ ẹ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì làwọn òbí ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó gbà pé òun ò fi bẹ́ẹ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó ní: “Mò ń sin Jèhófà torí pé mi ò fẹ́ ṣe ohun tó yàtọ̀ sóhun táwọn òbí mi ń ṣe.” Bó ti wù kó rí, Arákùnrin Angelito ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ kó sọ òtítọ́ di tiẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ó ń ṣàṣàrò lórí ohun tó ń kà, ó sì ń gbàdúrà déédéé. Àǹfààní wo nìyẹn ṣe é? Angelito sọ pé: “Ó wá yé mi pé kò sí àbùjá lọ́rùn ọ̀pẹ, tí mo bá máa di ọ̀rẹ́ Jèhófà Baba mi ọ̀run, àfi kí n fúnra mi mọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Angelito yìí máa mú ká béèrè àwọn ìbéèrè kan. Àkọ́kọ́: Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú kéèyàn kàn mọ Jèhófà àti kéèyàn mọ̀ ọ́n dunjú? Ìkejì: Báwo la ṣe lè mọ Jèhófà dunjú?
3. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú kéèyàn kàn mọ Jèhófà àti kéèyàn mọ̀ ọ́n ní àmọ̀dunjú?
3 Ẹni tó mọ orúkọ Ọlọ́run, tó sì mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣe àtohun tó sọ lè ronú pé òun mọ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ló mọ Jèhófà? Kí lẹni tó mọ Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe? Ó gbọ́dọ̀ wáyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, àwọn
ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Ìgbà yẹn lá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye ìdí tí Jèhófà fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan àti ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Èyí á mú kó mọ̀ bóyá èrò òun, ọ̀rọ̀ òun àti ìṣe òun bá ti Jèhófà mu. Téèyàn bá sì ti mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe, ohun tó kù ni pé kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.4. Kí ló máa dá wa lójú tá a bá wo àpẹẹrẹ àwọn èèyàn bíi tiwa tó wà nínú Bíbélì?
4 Àwọn èèyàn lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tá a bá pinnu pé Jèhófà la máa sìn, kódà wọ́n lè ta kò wá tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà. Àmọ́ tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò ní fi wá sílẹ̀ láé. Tá a bá dúró lórí ìpinnu wa, àá di ọ̀rẹ́ Jèhófà, okùn ọ̀rẹ́ wa ò sì ní já. Ṣó ṣeé ṣe kéèyàn mọ Jèhófà débi téèyàn á fi di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Ó ṣeé ṣe dáadáa! Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn bíi tiwa ló wà nínú Bíbélì tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, lára wọn ni Mósè àti Ọba Dáfídì. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí wọ́n ṣe ká sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Báwo ni wọ́n ṣe dẹni tó mọ Jèhófà? Kí la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ wọn?
MÓSÈ DI OJÚLÙMỌ̀ “ẸNI TÍ A KÒ LÈ RÍ”
5. Kí ni Mósè pinnu pé òun máa ṣe?
5 Mósè pinnu pé Jèhófà lòun máa sìn. Nígbà tí Mósè wà lẹ́ni ogójì (40) ọdún, ó yàn láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà, ìyẹn àwọn Hébérù dípò táwọn èèyàn á fi mọ̀ ọ́n sí “ọmọ ọmọbìnrin Fáráò.” (Héb. 11:24) Ipò pàtàkì ni Mósè wà tẹ́lẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì, àmọ́ ó pa ìyẹn tì, ó sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú. Ó mọ̀ pé ohun tóun ṣe yẹn máa bí Ọba Fáráò nínú, bẹ́ẹ̀ sì rèé òrìṣà àkúnlẹ̀bọ làwọn ará Íjíbítì ka Fáráò sí. Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ tó lágbára ni Mósè ní! Kò sí àní-àní pé Mósè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ìyẹn ló sì mú kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀.—Òwe 3:5.
6. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Mósè?
6 Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Mósè? Bíi ti Mósè, ohun pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣèpinnu lé lórí, ohun náà ni pé: Ṣé Jèhófà la máa sìn, ṣé a sì máa dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀? Ká tó lè sin Jèhófà, ó lè gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan, ó sì ṣeé ṣe káwọn tí ò mọ Jèhófà kórìíra wa. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run, kò ní fi wá sílẹ̀ láé!
7-8. Kí ni Mósè túbọ̀ ń mọ̀ nípa Jèhófà?
7 Mósè túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, ó sì ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà yan Mósè pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, kò gbà pé òun á lè ṣe iṣẹ́ náà, kódà léraléra ló sọ fún Jèhófà pé ẹ̀mí òun ò gbé e. Ọlọ́run fi àánú hàn sí Mósè, ó sì ràn án lọ́wọ́. (Ẹ́kís. 4:10-16) Ohun tí Jèhófà ṣe yẹn mú kí Mósè nígboyà láti kéde ìdájọ́ Jèhófà fún Fáráò. Mósè wá rí bí Jèhófà ṣe lo agbára rẹ̀ láti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè tó sì pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú Òkun Pupa.—Ẹ́kís. 14:26-31; Sm. 136:15.
8 Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ráhùn. Dípò kí Jèhófà bínú, Mósè rí i pé ṣe ni Jèhófà mú sùúrù fáwọn èèyàn rẹ̀ tó dá nídè. (Sm. 78:40-43) Yàtọ̀ síyẹn, Mósè kíyè sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí kò láfiwé tí Jèhófà lò nígbà tó gbà láti ṣe ohun tí Mósè rọ̀ ọ́ pé kó ṣe.—Ẹ́kís. 32:9-14.
9. Bó ṣe wà nínú Hébérù 11:27, báwo ni àárín Mósè àti Jèhófà ṣe rí?
9 Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ó ṣe kedere pé àárín Mósè àti Jèhófà wọ̀ gan-an débi tó fi dà bíi pé Mósè ń rí Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run lójúkojú. (Ka Hébérù 11:27.) Nígbà tí Bíbélì ń sọ bí àjọṣe tó wà láàárín wọn ṣe rí, ó ní: “Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ojúkojú, bí ìgbà téèyàn méjì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.”—Ẹ́kís. 33:11.
10. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ mọ Jèhófà dunjú?
10 Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Tá a bá máa mọ Jèhófà dunjú, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó. A tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fẹ́. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe lónìí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ìfẹ́ Jèhófà ni pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:3, 4) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká máa kọ́ àwọn míì nípa Jèhófà.
11. Bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ ọ́n?
11 Lọ́pọ̀ ìgbà, bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làwa náà á túbọ̀ máa mọ̀ ọ́n. Bí àpẹẹrẹ, àánú Jèhófà túbọ̀ ń ṣe kedere sí wa bó ṣe ń darí wa sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tí wọ́n sì fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòh. 6:44; Ìṣe 13:48) À ń rí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní bá a ṣe ń kíyè sí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n ń jáwọ́ nínú àwọn ìwà wọn àtijọ́ tí wọ́n sì ń hùwà tó yẹ Kristẹni. (Kól. 3:9, 10) Bákan náà, à ń rí bí Ọlọ́run ṣe ń mú sùúrù fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa nítorí pé léraléra ló ń rán wa lọ sọ́dọ̀ wọn ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n bàa lè rí ìgbàlà.—Róòmù 10:13-15.
12. Bó ṣe wà nínú Ẹ́kísódù 33:13, kí ni Mósè béèrè lọ́wọ́ Jèhófà, kí sì nìdí?
12 Mósè mọyì àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà. Kódà lẹ́yìn tí Jèhófà lo Mósè láti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, ó bẹ Jèhófà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé kó jẹ́ kóun túbọ̀ mọ̀ ọ́n. (Ka Ẹ́kísódù 33:13.) Mósè ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún nígbà tá à ń sọ yìí, síbẹ̀ ó gbà pé ọ̀pọ̀ nǹkan lòun ò tíì mọ̀ nípa Jèhófà Baba rẹ̀ ọ̀run.
13. Sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run.
13 Kí lèyí kọ́ wa? Yálà ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí kò tíì pẹ́, ẹ má ṣe jẹ́ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà fi hàn pé a mọyì àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà ni pé ká máa gbàdúrà sí i.
14. Báwo ni àdúrà ṣe ń mú ká túbọ̀ mọ Jèhófà?
14 Àárín àwọn ọ̀rẹ́ méjì máa túbọ̀ gún régé tí wọ́n bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ déédéé. Torí náà, máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé, máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún un láìbẹ̀rù. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àárín ìwọ àtiẹ̀ á túbọ̀ gún régé. (Éfé. 6:18) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Krista tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Tọ́kì sọ pé: “Kò sígbà tí mo gbàdúrà sí Jèhófà tí mo sì rí bó ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ tí inú mi kì í dùn, ó ń jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn kí ìgbàgbọ́ mi sì lágbára sí i. Bí Jèhófà ṣe ń dáhùn àdúrà mi ti mú kí àárín èmi àtiẹ̀ túbọ̀ gún régé. Ó wá ṣe kedere sí mi pé Jèhófà jẹ́ Baba àti Ọ̀rẹ́ mi.”
ẸNI TÍ ỌKÀN JÈHÓFÀ FẸ́
15. Kí ni Jèhófà sọ nípa Ọba Dáfídì?
15 Inú orílẹ̀-èdè tí Jèhófà yà sí mímọ́ fún ara rẹ̀ ni wọ́n bí Ọba Dáfídì sí. Síbẹ̀ kì í ṣe torí pé àwọn òbí Dáfídì ń jọ́sìn Jèhófà lòun náà fi ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun alára ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà, Jèhófà náà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kódà, Jèhófà pe Dáfídì ní “ẹni tí ọkàn [òun] fẹ́.” (Ìṣe 13:22) Kí ni Dáfídì ṣe tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?
16. Kí ni Dáfídì mọ̀ nípa Jèhófà bó ṣe ń wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?
16 Dáfídì túbọ̀ mọ Jèhófà bó ṣe ń wo ohun tí Jèhófà dá. Nígbà tí Dáfídì wà lọ́mọdé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń wà níta bó ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àsìkò yẹn ló fi máa ń ṣàṣàrò nípa àwọn Sm. 19:1, 2) Nígbà tí Dáfídì ronú nípa ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà dá àwa èèyàn, ó rí i pé ọgbọ́n Jèhófà kò láfiwé. (Sm. 139:14) Ní gbogbo ìgbà tí Dáfídì bá ń ronú àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà dá, ó máa ń rí i pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Sm. 139:6.
nǹkan tí Jèhófà dá. Bí àpẹẹrẹ, bí Dáfídì ṣe ń wòkè lálẹ́, ó dájú pé ó máa rí i tí ojú ọ̀run tẹ́ rẹrẹ tó sì kún fún àìmọye ìràwọ̀. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́, àwọn ohun tó rí máa jẹ́ kó túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá àtàwọn ànímọ́ rẹ̀. Ohun tí Dáfídì rí wú u lórí débi tó fi sọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; ojú ọ̀run sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” (17. Kí la máa rí kọ́ tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá?
17 Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì? Ó yẹ káwa náà máa kíyè sáwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ dí jù débi tí o ò fi ní ráyè kíyè sáwọn nǹkan mèremère tó yí ẹ ká. Jẹ́ kí wọ́n máa mú inú rẹ dùn, kí orí rẹ sì máa wú bó o ṣe ń kíyè sí wọn. Bó o ṣe ń sùn tó ò ń jí lójoojúmọ́, máa ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá, ìyẹn àwọn ewéko àtàwọn ẹranko títí kan ọ̀nà àrà tó gbà dá àwa èèyàn. Ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́, ṣe ni wàá túbọ̀ máa mọ Baba rẹ ọ̀run. (Róòmù 1:20) Nípa bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó o ní fún un á máa jinlẹ̀ sí i lójoojúmọ́.
18. Bó ṣe wà nínú Sáàmù 18, kí ló dá Dáfídì lójú?
18 Dáfídì gbà pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì gba àgùntàn bàbá rẹ̀ lẹ́nu kìnnìún àti bíárì, ó dá a lójú pé Jèhófà ló ran òun lọ́wọ́ tí òun fi lè mú àwọn ẹranko ìgbẹ́ yẹn balẹ̀. Nígbà tó ṣẹ́gun Gòláyátì tó jẹ́ akínkanjú ọmọ ogun, ó dá Dáfídì lójú pé kì í ṣe agbára òun ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe bí kò ṣe Jèhófà tó wà pẹ̀lú òun. (1 Sám. 17:37) Nígbà tó bọ́ lọ́wọ́ Ọba Sọ́ọ̀lù tó ń ṣe ìlara rẹ̀, Dáfídì sọ gbangba-gbàǹgbà pé ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà ló jẹ́ kóun wà láàyè. (Sm. 18, àkọlé) Agbéraga èèyàn ò ní sọ ohun tí Dáfídì sọ yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ á sọ pé agbára òun ló jẹ́ kó ṣeé ṣe. Àmọ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Dáfídì, ìyẹn ló jẹ́ kó rọ́wọ́ Jèhófà láyé rẹ̀.—Sm. 138:6.
19. Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Dáfídì?
19 Kí la rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ yìí? Kò yẹ ká kàn máa bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Ó tún yẹ ká máa kíyè sí ìgbà tó ń ràn wá lọ́wọ́ àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀. Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, á rọrùn fún wa láti rí bí Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá sì ń fara balẹ̀ kíyè sí bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́, àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ á túbọ̀ gún régé. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn fún arákùnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Fíjì. Isaac lorúkọ ẹ̀, ó sì ti pẹ́ tó ti wà nínú òtítọ́. Ó sọ pé: “Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn, tí mo sì rántí ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, mo máa ń rí i pé Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an títí dòní olónìí. Ìyẹn sì mú kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà wà àti pé ó nífẹ̀ẹ́ mi.”
20. Àwọn nǹkan wo ni Dáfídì ṣe tó mú kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí nìyẹn sì kọ́ wa?
20 Dáfídì fìwà jọ Jèhófà. Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè gbé àwọn ànímọ́ rẹ̀ yọ ká sì fìwà jọ ọ́. (Jẹ́n. 1:26) Torí náà, bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá ṣe rọrùn fún wa láti fìwà jọ ọ́. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé: “Ẹní bíni làá jọ.” Dáfídì mọ Baba rẹ̀ ọ̀run gan-an, ó sì fìwà jọ ọ́, kódà ó hàn nínú bó ṣe bá àwọn míì lò. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Ẹ rántí pé Dáfídì dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà nígbà tó bá Bátí-ṣébà, ìyàwó oníyàwó sùn tó sì tún pa ọkọ rẹ̀. (2 Sám. 11:1-4, 15) Síbẹ̀, Jèhófà ṣàánú Dáfídì, ó sì dárí jì í torí pé òun náà máa ń ṣàánú àwọn èèyàn. Dáfídì ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kódà, òun ni Jèhófà sábà máa ń tọ́ka sí láti fi díwọ̀n bóyá ọba kan ṣe dáadáa tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀.—1 Ọba 15:11; 2 Ọba 14:1-3.
21. Bó ṣe wà nínú Éfésù 4:24 àti 5:1, àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń “fara wé Ọlọ́run”?
21 Kí lèyí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé ká máa “fara wé Ọlọ́run.” Yàtọ̀ sí pé a máa jàǹfààní tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ ọ́n. Tá a bá fìwà jọ Jèhófà nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, ńṣe là ń fi hàn pé ọmọ rẹ̀ ni wá.—Ka Éfésù 4:24; 5:1.
TÚBỌ̀ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA JÈHÓFÀ
22-23. Èrè wo la máa rí tá a bá ń fi ohun tá à ń kọ́ nípa Jèhófà sílò?
22 Bá a ṣe jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó ṣe kedere pé a lè túbọ̀ mọ Jèhófà tá a bá ń kíyè sáwọn nǹkan tó dá, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́kùnrin àti lóbìnrin tá a lè fara wé wà nínú ọba ìwé yìí, títí kan Mósè àti Dáfídì. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ti ṣe ipa tiẹ̀, ọwọ́ wa ló kù sí báyìí. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wo àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, ká dẹ etí wa sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì jẹ́ káwọn ìtọ́ni rẹ̀ máa wọnú ọkàn wa.
23 Títí ayé làá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Oníw. 3:11) Àmọ́, kéèyàn kó ìmọ̀ jọ tàbí kéèyàn rọ́ ìmọ̀ ságbárí kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe ohun téèyàn fi ìmọ̀ náà ṣe. Ohun tó dáa jù lọ ni pé ká máa fi ohun tà à ń kọ́ ṣèwàhù, ká máa sapá láti fìwà jọ Jèhófà Baba wa onífẹ̀ẹ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà á túbọ̀ sún mọ́ wa, àárín àwa àtiẹ̀ á sì túbọ̀ gún régé. (Jém. 4:8) Ó fi dá wa lójú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun ò ní fàwọn tó mọ òun sílẹ̀ láé.
ORIN 80 ‘Tọ́ Ọ Wò, Kó O sì Rí I Pé Ẹni Rere Ni Jèhófà’
^ ìpínrọ̀ 5 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ wọn ò mọ̀ ọ́n dunjú. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan mọ Jèhófà? Kí la lè rí kọ́ nínú bí Mósè àti Ọba Dáfídì ṣe mọ Jèhófà dunjú tí wọ́n sì tún jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ yìí.