ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31
“A Kò Juwọ́ Sílẹ̀”!
“Nítorí náà, a kò juwọ́ sílẹ̀.”—2 KỌ́R. 4:16.
ORIN 128 Bí A Ṣe Lè Fara Dà Á Dópin
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè sá eré ìje ìyè náà dópin?
GBOGBO àwa Kristẹni là ń sá eré ìje ìyè. Yálà ọjọ́ pẹ́ tá a ti wà lẹ́nu ẹ̀ tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó ṣe pàtàkì ká má bọ́hùn títí tá a fi máa sá eré náà dópin. Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Fílípì máa fún wa níṣìírí láti máa bá eré ìje ìyè náà lọ. Àwọn kan nínú ìjọ yẹn ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí wọn. Wọ́n ń ṣe dáadáa nínú òtítọ́, àmọ́ Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé wọ́n gbọ́dọ̀ fara dà á dópin. Ó fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun, kí wọ́n sì máa ‘sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ èrè náà.’—Fílí. 3:14.
2. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn ará Fílípì fi bọ́ sákòókò?
2 Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fáwọn ará Fílípì bọ́ sákòókò gan-an. Ìdí ni pé nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ará ìjọ yẹn látìgbà tí wọ́n ti dá ìjọ náà sílẹ̀. Báwo ni ìjọ náà ṣe bẹ̀rẹ̀? Nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí Fílípì lẹ́yìn tí ẹ̀mí mímọ́ ní kí wọ́n “sọdá wá sí Makedóníà.” (Ìṣe 16:9) Níbẹ̀, wọ́n pàdé obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà. Obìnrin yìí ń “fetí sílẹ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀” láti gbọ́ ìhìn rere. (Ìṣe 16:14) Kò pẹ́ lẹ́yìn náà lòun àtàwọn ará ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi. Àmọ́ Èṣù tún gbé ìṣe ẹ̀ dé, ṣe làwọn ọkùnrin ìlú yẹn wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́, wọ́n sì parọ́ mọ́ wọn pé wọ́n ń da ìlú rú. Torí náà, wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọ́n sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì ní kí wọ́n fi ìlú àwọn sílẹ̀. (Ìṣe 16:16-40) Ṣé wọ́n wá tìtorí ìyẹn sọ pé àwọn ò ní wàásù mọ́? Ká má rí i! Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà níjọ tuntun yìí ńkọ́, kí làwọn ṣe? Inú wa dùn pé wọ́n fara dà á! Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ àtàtà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi lélẹ̀ ló mú káwọn náà lè fara dà á.
3. Kí ni Pọ́ọ̀lù rí i pé òun gbọ́dọ̀ ṣe, àwọn ìbéèrè wo la sì máa dáhùn?
3 Pọ́ọ̀lù ti pinnu pé òun ò ní juwọ́ sílẹ̀ láìka ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí. (2 Kọ́r. 4:16) Ó rí i pé tóun bá máa sá eré ìje náà dópin, òun gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ èrè tóun máa gbà. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù? Àwọn àpẹẹrẹ òde òní wo ló jẹ́ ká rí i pé a lè fara da ìṣòro yòówù ká kojú lẹ́nu eré ìje yìí? Báwo ni ìrètí ọjọ́ iwájú ṣe lè mú káwa náà túbọ̀ pinnu pé a ò ní juwọ́ sílẹ̀?
OHUN TÁ A RÍ KỌ́ LÁTINÚ ÀPẸẸRẸ PỌ́Ọ̀LÙ
4. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láìka bí nǹkan ṣe nira fún un tó?
4 Báwo ni nǹkan ṣe rí fún Pọ́ọ̀lù lásìkò tó kọ̀wé sí àwọn ará Fílípì? Àtìmọ́lé ló wà nílùú Róòmù, kò sì láǹfààní láti jáde lọ wàásù. Àmọ́, ó máa ń wàásù fáwọn tó bá wá kí i, ó sì ń kọ lẹ́tà sáwọn ìjọ tó wà káàkiri. Lónìí bíi ti Pọ́ọ̀lù, ọ̀pọ̀ Kristẹni ni ò lè jáde nílé mọ́, àmọ́ wọ́n máa ń lo àǹfààní èyíkéyìí tí wọ́n bá ní láti wàásù fáwọn tó bá wá kí wọn nílé. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń kọ lẹ́tà sáwọn tí a kì í sábà bá nílé.
5. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú Fílípì 3:12-14, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti gbájú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú?
5 Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kí àwọn àṣeyọrí tàbí àwọn àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn pín ọkàn rẹ̀ níyà. Kódà, ó sọ pé òun ní láti ‘gbàgbé àwọn ohun tóun ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ kóun tó lè “nàgà sí àwọn ohun tó wà níwájú,” ìyẹn kọ́wọ́ òun tó lè tẹ èrè náà. (Ka Fílípì 3:12-14.) Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó pín ọkàn òun níyà? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tó ṣe nínú ẹ̀sìn àwọn Júù kó sí i lórí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ka gbogbo ẹ̀ sí “ọ̀pọ̀ pàǹtírí.” (Fílí. 3:3-8) Ìkejì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń banú jẹ́ torí inúnibíni tó ṣe sáwọn Kristẹni, kò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun. Ìkẹta, kò ronú pé ohun tóun ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti tó. Ká sòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù méso jáde láìka gbogbo ohun tójú ẹ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, wọ́n lù ú, wọ́n sọ ọ́ lókùúta, ọkọ̀ ojú omi tó wọ̀ rì, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ìgbà míì wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní oúnjẹ àti aṣọ. (2 Kọ́r. 11:23-27) Pẹ̀lú gbogbo ohun tó gbé ṣe àtohun tójú ẹ̀ rí, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé òun ṣì gbọ́dọ̀ máa bá eré ìje náà lọ. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí fáwa náà nìyẹn.
6. Kí ni díẹ̀ lára ‘àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ tó yẹ ká gbàgbé?
6 Báwo la ṣe lè fara wé Pọ́ọ̀lù tó bá di pé ká ‘gbàgbé àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’? Àwọn kan ṣì máa ń dá ara wọn lẹ́bi torí àwọn àṣìṣe tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, ìyẹn sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí, o ò ṣe dìídì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìràpadà Jésù? Tá a bá ṣèwádìí nípa ìràpadà náà, tá a ronú jinlẹ̀, tá a sì gbàdúrà nípa ẹ̀, ó ṣeé ṣe kọ́kàn wa balẹ̀. Ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká máa dá ara wa lẹ́bi ṣáá fún ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ti dárí ẹ̀ jì wá. Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun míì tá a kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan lè ti fiṣẹ́ olówó ńlá sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé a lè gbàgbé àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ká má sì máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ṣeé ṣe ká kó jọ ká sọ pé a ò fiṣẹ́ náà sílẹ̀? (Nọ́ń. 11:4-6; Oníw. 7:10) Lára ‘àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn’ ni àwọn àṣeyọrí tàbí àwọn àdánwò tá a ti fara dà sẹ́yìn. Òótọ́ ni pé tá a bá ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà bù kún wa àti bó ṣe ràn wá lọ́wọ́, àá túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run. Àmọ́, kò yẹ ká ronú pé èyí tá a ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà náà ti tó.—1 Kọ́r. 15:58.
7. Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 9:24-27, kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè sá eré ìje ìyè náà dópin? Ṣàpèjúwe.
7 Jésù sọ pé: “Ẹ sa gbogbo ipá yín.” (Lúùkù 13:23, 24) Pọ́ọ̀lù lóye ọ̀rọ̀ yìí dáadáa, ó sì mọ̀ pé bíi ti Kristi, òun gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá òun títí dópin. Ìdí nìyẹn tó fi fi àwa Kristẹni wé àwọn tó ń sá eré ìje. (Ka 1 Kọ́ríńtì 9:24-27.) Kí sárésáré kan tó lè sáré dópin, ó gbọ́dọ̀ gbájú mọ́ ibi tó ń lọ, kí ohunkóhun má sì pín ọkàn rẹ̀ níyà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń sáré lónìí lè gba ojú ọ̀nà táwọn èèyàn ti ń tajà tàbí tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan míì tó ń gbàfiyèsí. Ǹjẹ́ ẹ ronú pé sárésáré kan máa dúró, á sì máa yẹ àwọn ọjà tí wọ́n ń tà ní ṣọ́ọ̀bù kan wò? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá fẹ́ gbégbá orókè! Bákan náà, nínú eré ìje ìyè, a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbogbo nǹkan tó lè pín ọkàn wa níyà. Tá a bá gbájú mọ́ èrè tó wà níwájú wa, tá a sì ń sapá gan-an bíi ti Pọ́ọ̀lù, a máa gba èrè náà!
BÁ A ṢE LÈ BORÍ ÀWỌN ÌṢÒRO TÓ Ń DÁN ÌGBÀGBỌ́ ẸNI WÒ
8. Ìṣòro mẹ́ta wo la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?
8 Ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro mẹ́ta tó lè mú ká dẹwọ́ lẹ́nu eré ìje yìí. Àwọn nǹkan náà ni (1) tí ohun tá à ń retí ò bá dé lásìkò tá a fẹ́, (2) ara tó ń dara àgbà àti (3) àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó ti fara da àwọn ìṣòro yìí láìbọ́hùn.—Fílí. 3:17.
9. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ohun tá à ń retí ò bá dé lásìkò tá a fẹ́?
9 Tí ohun tá à ń retí ò bá dé lásìkò tá a fẹ́. Ó máa ń wù wá pé káwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣèlérí ti ṣẹ. Kódà nígbà tó ń ṣe Hábákúkù bíi kí Jèhófà ti fòpin sí gbogbo ìwà burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ ní Júdà, Jèhófà sọ fún un pé kó “ṣáà máa retí.” (Háb. 2:3) Àmọ́, tó bá dà bíi pé àwọn nǹkan tá à ń retí ò dé lásìkò tá a fẹ́, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì, kí iná ìtara wa sì kú. (Òwe ) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1914. Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ronú pé ọdún 1914 làwọn máa lọ sọ́run. Àmọ́ ìyẹn ò ṣẹlẹ̀. Kí wá làwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe? 13:12
10. Kí ni tọkọtaya kan ṣe nígbà tí ohun tí wọ́n ń retí ò dé lásìkò tí wọ́n fẹ́?
10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí tọkọtaya kan ṣe lásìkò yẹn. Arákùnrin Royal Spatz ṣèrìbọmi lọ́dún 1908 nígbà tó wà lọ́mọ ogún (20) ọdún. Ó dá a lójú pé òun máa tó lọ sọ́run. Kódà nígbà tó dẹnu ìfẹ́ kọ Pearl lọ́dún 1911, ó sọ fún un pé: “O ṣáà mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914. Torí náà, tá a bá máa fẹ́ra wa, àfi ká tètè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí torí a ò ní pẹ́ lọ sọ́run!” Ṣé tọkọtaya náà wá juwọ́ sílẹ̀ nígbà tí wọn ò lọ sọ́run lọ́dún 1914? Rárá o, torí pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún, kì í ṣe èrè tí wọ́n fẹ́ gbà. Wọ́n pinnu pé àwọn á fi ìfaradà sá eré ìje náà dópin. Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn, torí pé àwọn méjèèjì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí wọ́n fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Kò sí àní-àní pé ó wu ìwọ náà pé kí Jèhófà mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ, kó dá orúkọ mímọ́ rẹ̀ láre, kó sì mú káwọn èèyàn gbà pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé gbogbo nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Jèhófà yàn. Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, ká má sì rẹ̀wẹ̀sì kódà táwọn nǹkan tá à ń retí ò bá tíì tẹ̀ wá lọ́wọ́.
11-12. Ṣé ó dìgbà tára wa bá gbé kánkán ká tó lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
11 Ara tó ń dara àgbà. Ó ṣe pàtàkì kí ara sárésáré kan le dáadáa kó tó lè sáré, àmọ́ kò dìgbà tára wa bá ń ta kébékébé ká tó lè tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kódà, àwọn tára wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán mọ́ ṣì máa ń nítara, wọ́n sì máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (2 Kọ́r. 4:16) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Arthur Secord * ti pé ẹni ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún (88), ó sì ti lo ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55) lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, ṣùgbọ́n ní báyìí ara ẹ̀ ò gbé kánkán mọ́. Lọ́jọ́ kan tí nọ́ọ̀sì kan wá tọ́jú rẹ̀, ó wò ó lórí bẹ́ẹ̀dì, ó sì sọ fún un pé: “Arákùnrin Secord, ẹ ti fara ṣiṣẹ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà.” Bó ti wù kó rí, kì í ṣe ohun tí Arákùnrin Secord ti ṣe sẹ́yìn ló gbájú mọ́. Ó wojú nọ́ọ̀sì náà, ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ fún un pé: “Òótọ́ lo sọ. Àmọ́ kì í ṣe ohun tá a ṣe sẹ́yìn ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe ohun tá a bá ṣe láti ìsinsìnyí lọ.”
12 Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti fòótọ́ ọkàn sin Héb. 6:10) Torí náà, fi sọ́kàn pé kò dìgbà tó o bá ṣe ohun tó pọ̀ kó o tó lè fi hàn pé tọkàntọkàn lo fi ń sin Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, tó o bá ṣe gbogbo ohun tágbára ẹ gbé, tó o sì lẹ́mìí tó dáa, ìyẹn á fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Kól. 3:23) Jèhófà mọ ohun tágbára wa gbé, kì í sì í béèrè ohun tó ju agbára wa lọ.—Máàkù 12:43, 44.
Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n ní báyìí, àìlera ò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, má banú jẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (13. Báwo ni ìrírí Anatoly àti Lidiya ṣe lè mú káwa náà máa fara dà á nìṣó?
13 Àwọn àdánwò ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an. Àwọn kan lára wa ti fara da onírúurú àdánwò àti inúnibíni fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún méjìlá (12) ni Arákùnrin Anatoly Melnik * nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú bàbá rẹ̀, wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n, lẹ́yìn náà wọ́n rán an lọ sígbèkùn ní Siberia. Ibẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) máìlì síbi tí ìdílé ẹ̀ ń gbé ní Moldova. Ọdún kan lẹ́yìn náà, wọ́n mú Anatoly, ìyá rẹ̀ àtàwọn òbí rẹ̀ àgbà, wọ́n sì rán gbogbo wọn lọ sígbèkùn ní Siberia. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n wọ́nà àtimáa lọ sípàdé ní abúlé míì, àmọ́ ìyẹn gba pé kí wọ́n rin ìrìn ogún (20) máìlì nínú òtútù, tí gbogbo ilẹ̀ sì kún fún yìnyín. Nígbà tó yá, wọ́n rán Arákùnrin Anatoly lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta, ó sì fi ìyàwó àti ọmọbìnrin wọn tó jẹ́ ọmọ ọdún kan sílẹ̀ nílé. Láìka gbogbo àdánwò yìí sí, Anatoly àti ìdílé rẹ̀ ò dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà. Ní báyìí, Arákùnrin Anatoly ti pé ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́rin (82), ó sì wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Central Asia. Bíi ti Anatoly àti Lidiya, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ká sì máa fara dà á nìṣó bá a ti ń ṣe bọ̀ látẹ̀yìn.—Gál. 6:9.
ÌRÈTÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Ń MÚ KÁ LÈ FARA DÀ Á
14. Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ pé òun gbọ́dọ̀ ṣe kọ́wọ́ òun lè tẹ èrè ọjọ́ iwájú?
14 Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun máa sá eré ìje ìyè náà dópin, òun sì máa gba èrè ọjọ́ iwájú. Torí pé Kristẹni ẹni àmì òróró ni, ó ń fojú sọ́nà láti gba “èrè ìpè Ọlọ́run sí òkè.” Síbẹ̀, ó mọ̀ pé òun gbọ́dọ̀ máa “sapá” nìṣó kí ọwọ́ òun tó lè tẹ èrè náà. (Fílí. 3:14) Pọ́ọ̀lù wá lo àfiwé kan káwọn ará Fílípì lè rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbájú mọ́ èrè ọjọ́ iwájú yẹn.
15. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo ọ̀rọ̀ jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ láti gba àwọn ará Fílípì níyànjú pé kí wọ́n máa “sapá” nìṣó?
Fílí. 3:20) Kí nìdí tó fi lo àfiwé yìí? Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ohun iyì ni téèyàn bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù. * Àmọ́ àǹfààní táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yẹn ní kò láfiwé torí pé ọ̀run ni ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ó ṣe kedere pé jíjẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní ńlá táwọn Kristẹni yìí ní! Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi gba àwọn ará Fílípì níyànjú pé kí wọ́n “máa ṣe ohun tó fi hàn pé [wọ́n] jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ́nà tó yẹ ìhìn rere nípa Kristi.” (Fílí. 1:27, àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lónìí náà ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ bí wọ́n ṣe ń sapá kí wọ́n lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run.
15 Pọ́ọ̀lù rán àwọn ará yẹn létí pé ọ̀run ni ìlú ìbílẹ̀ wọn. (16. Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé yìí la máa wà, kí ni Fílípì 4:6, 7 rọ̀ wá pé ká máa ṣe?
16 Yálà ọ̀run là ń lọ tàbí ayé yìí la máa wà, ẹ jẹ́ ká sapá kọ́wọ́ wa lè tẹ èrè náà. Ìṣòro yòówù kó máa bá wa fínra, ẹ má ṣe jẹ́ ká wo àwọn ohun tá a ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn, ká má sì jẹ́ kí ohunkóhun mú ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. (Fílí. 3:16) Àwọn ohun tá à ń retí lè má dé lásìkò tá a fẹ́, ara tó ń dara àgbà sì lè mú kí nǹkan nira fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, a lè ti fara da ọ̀pọ̀ àdánwò àti inúnibíni látọdún yìí wá. Èyí ó wù kó jẹ́, “ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á fún wa ní àlàáfíà tó kọjá gbogbo òye wa.—Ka Fílípì 4:6, 7.
17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Bíi ti sárésáré kan tó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ bó ṣe ń sún mọ́ ìparí, ẹ jẹ́ káwa náà sa gbogbo ipá wa, ká sì gbájú mọ́ ìrètí ọjọ́ iwájú bá a ti ń sún mọ́ òpin eré ìje ìyè náà. Láìka bí ipò wa ṣe rí, ẹ jẹ́ ká máa ṣe gbogbo ohun tágbára wa gbé lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kí ló yẹ ká ṣe ká lè máa bá eré ìje náà nìṣó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ká sì fara dà á láìbọ́hùn? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa jẹ́ ká mọ “àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” tó yẹ kó gbawájú láyé wa.—Fílí. 1:9, 10.
ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-In
^ ìpínrọ̀ 5 Láìka bó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Jèhófà, ó ṣe pàtàkì ká máa tẹ̀ síwájú, ká sì máa sunwọ̀n sí i nínú ìjọsìn wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe juwọ́ sílẹ̀ láé. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Fílípì, ó sọ àwọn nǹkan táá jẹ́ ká lè fara dà á nínú eré ìje ìyè tá à ń sá. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò.
^ ìpínrọ̀ 11 Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Secord wà nínú Ile-Iṣọ Na, February 1, 1967, ojú ìwé 60. Àkòrí ẹ̀ ni, “Ipa Temi Ni Mimu Ijọsin Tootọ Tẹ Siwaju.”
^ ìpínrọ̀ 13 Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Anatoly Melnik wà nínú Jí!, November 8, 2004. Àkòrí ẹ̀ ni, “Àtikékeré Ni Wọ́n Ti Kọ́ Mi Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.”
^ ìpínrọ̀ 15 Torí pé abẹ́ àkóso Róòmù ni ìlú Fílípì wà, àwọn aráàlú yẹn náà láwọn ẹ̀tọ́ kan táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní. Torí náà, àfiwé tí Pọ́ọ̀lù lò máa yé wọn dáadáa.