ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39
ORIN 125 “Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú!”
Wàá Túbọ̀ Láyọ̀ Tó O Bá Ń Fún Àwọn Èèyàn Ní Nǹkan
“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa túbọ̀ láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan.
1-2. Kí nìdí tá a fi máa ń láyọ̀ tá a bá fún àwọn èèyàn ní nǹkan ju ìgbà tí wọ́n bá fún wa ní nǹkan?
JÈHÓFÀ dá a mọ́ wa pé ká máa láyọ̀ tá a bá fún àwọn èèyàn ní nǹkan ju ìgbà tí wọ́n bá fún wa ní nǹkan. (Ìṣe 20:35) Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé a ò ní láyọ̀ táwọn èèyàn bá fún wa ní nǹkan? Rárá o. A mọ̀ pé inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá fún wa lẹ́bùn. Àmọ́, inú wa máa dùn gan-an tó bá jẹ́ pé àwa la fún àwọn èèyàn lẹ́bùn! Bí Jèhófà sì ṣe dá wa yìí máa ń ṣe wá láǹfààní gan-an. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
2 Bí Jèhófà ṣe dá wa yẹn ló jẹ́ káwa náà lè túbọ̀ máa láyọ̀. A lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i tá a bá ń wá bá a ṣe máa ṣe nǹkan fáwọn èèyàn. Ẹ ò rí i pé Jèhófà dá wa lọ́nà àgbàyanu!—Sm. 139:14.
3. Kí nìdí tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀”?
3 Bíbélì fi dá wa lójú pé a máa láyọ̀ tá a bá ń fáwọn èèyàn ní nǹkan. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Jèhófà lẹni tó kọ́kọ́ fúnni ní nǹkan, kò sì sẹ́ni tó lè fúnni ní nǹkan bíi tiẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìpasẹ̀ rẹ̀ “ni a fi ní ìyè, tí à ń rìn, tí a sì wà.” (Ìṣe 17:28) Ká sòótọ́, ọ̀dọ̀ Jèhófà ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti ń wá.—Jém. 1:17.
4. Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀?
4 Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká fún àwọn èèyàn ní nǹkan torí a mọ̀ pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa túbọ̀ láyọ̀ . A lè nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ tá a bá ń fara wé Jèhófà bó ṣe ń fún wa ní nǹkan. (Éfé. 5:1) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tá a bá rí i pé àwọn èèyàn ò mọyì nǹkan tá a ṣe fún wọn. Ohun tá a máa kọ́ á jẹ́ ká lè túbọ̀ máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan, ká sì túbọ̀ máa láyọ̀.
MÁA FÚN ÀWỌN ÈÈYÀN NÍ NǸKAN BÍI TI JÈHÓFÀ
5. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún wa?
5 Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà fún wa? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn. Jèhófà fún wa lóhun tá a nílò. A lè má ní nǹkan rẹpẹtẹ, àmọ́ a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún wa lóhun tá a nílò. Bí àpẹẹrẹ, ó fún wa lóúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé. (Sm. 4:8; Mát. 6:31-33; 1 Tím. 6:6-8) Ṣé torí pé a fipá mú Jèhófà ló ṣe fún wa láwọn nǹkan yìí ni? Rárá o! Kí wá nìdí tí Jèhófà fi fún wa láwọn nǹkan yìí?
6. Kí la rí kọ́ nínú Mátíù 6:25, 26?
6 Jèhófà pèsè ohun tá a nílò torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:25, 26. (Kà á.) Nínú àwọn ẹsẹ yẹn, Jésù fi àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe àpẹẹrẹ. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹyẹ, ó ní: “Wọn kì í fúnrúgbìn tàbí kárúgbìn tàbí kí wọ́n kó nǹkan jọ sínú ilé ìkẹ́rùsí.” Àmọ́, ẹ wo ohun tó wá sọ tẹ̀ lé e, ó ní: “Baba yín ọ̀run ń bọ́ wọn.” Lẹ́yìn náà, Jésù béèrè pé: “Ṣé ẹ ò wá níye lórí jù wọ́n lọ ni?” Kí la rí kọ́? Àwa èèyàn Jèhófà ṣeyebíye lójú ẹ̀ ju àwọn ẹranko lọ. Tí Jèhófà bá lè bójú tó àwọn ẹranko, ó dájú pé ó máa bójú tó àwa náà! Bí bàbá tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀ ṣe máa ń bójú tó wọn, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fìfẹ́ bójú tó àwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀.—Sm. 145:16; Mát. 6:32.
7. Báwo la ṣe lè máa fún àwọn èèyàn ní nǹkan bíi ti Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan, Jèhófà là ń fara wé, ìyẹn sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà tó nílò oúnjẹ tàbí aṣọ? Jèhófà lè lò ẹ́ láti fún ẹni náà lóhun tó nílò. Àwa èèyàn Jèhófà máa ń ran ara wa lọ́wọ́ nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fún àwọn ará lóúnjẹ, aṣọ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n nílò. Ọ̀pọ̀ àwọn ará tún fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé. Ìyẹn jẹ́ ká rówó ṣèrànwọ́ fáwọn ará tí àjálù dé bá. Torí náà, wọ́n ṣe ohun tó wà ní Hébérù 13:16 tó sọ pé: “Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa pín ohun tí ẹ ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, torí inú Ọlọ́run máa ń dùn gan-an sí irú àwọn ẹbọ bẹ́ẹ̀.”
8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fún wa lágbára? (Fílípì 2:13)
8 Jèhófà ń fún wa lágbára. Agbára Jèhófà ò ní ààlà, inú ẹ̀ sì máa ń dùn láti fún àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn ẹ̀ lágbára. (Ka Fílípì 2:13.) Ṣé o ti gbàdúrà rí pé kí Jèhófà fún ẹ lágbára kó o lè kojú ìdẹwò tàbí kó o lè fara da ìṣòro tó le gan-an? Ó tún ṣeé ṣe kó o ti gbàdúrà pé kó fún ẹ lókun tó o nílò lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí Jèhófà dáhùn àdúrà ẹ, ó dájú pé o gbà pé òótọ́ lohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílí. 4:13.
9. Báwo la ṣe lè fi agbára wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi ti Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò ní agbára tó pọ̀ gan-an bíi ti Jèhófà, a ò sì lè fún èèyàn lágbára bí Jèhófà ṣe ń fúnni, a lè fi agbára wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a lè lọ bá àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn tára wọn ò yá ra nǹkan, a sì lè bá wọn ṣiṣẹ́ ilé. Yàtọ̀ síyẹn, tó bá ṣeé ṣe, a lè lọ ṣe ìmọ́tótó Ilé Ìpàdé tàbí ká tún un ṣe. Tá a bá ń lo agbára àti okun wa láti ṣe irú àwọn nǹkan yìí, ńṣe là ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́, ó sì máa ṣe wọ́n láǹfààní gan-an.
10. Báwo la ṣe lè sọ̀rọ̀ tó máa fún àwọn èèyàn níṣìírí?
10 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé a lè sọ̀rọ̀ tó máa fún àwọn èèyàn níṣìírí. Ṣé o mọ ẹnì kan tó máa jàǹfààní gan-an tó o bá gbóríyìn fún un látọkàn wá àbí ẹnì kan tó yẹ kó o tù nínú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é? O lè wá ẹni náà lọ tàbí kó o pè é lórí fóònù, o sì lè fi káàdì tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí i. Má da ara ẹ láàmú jù nípa ohun tó o fẹ́ sọ. Ọ̀rọ̀ díẹ̀ tó o bá sọ látọkàn wá lè fún ẹni náà lókun, á sì jẹ́ kó máa sin Jèhófà nìṣó.—Òwe 12:25; Éfé. 4:29.
11. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo ọgbọ́n ẹ̀?
11 Jèhófà ń fúnni ní ọgbọ́n. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jémíìsì sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni nínú yín ò bá ní ọgbọ́n, kó máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì máa fún un, torí ó lawọ́ sí gbogbo èèyàn, kì í sì í dáni lẹ́bi.” (Jém. 1:5; àlàyé ìsàlẹ̀) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà ò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó máa ń fi ọgbọ́n ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́. Ẹ tún kíyè sí i pé tí Jèhófà bá fún wa ní ọgbọ́n, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ láì “pẹ̀gàn,” “kì í sì í dáni lẹ́bi.” Kò fẹ́ ká máa rò pé a ò gbọ́n tá a bá ní kó tọ́ wa sọ́nà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ó fẹ́ ká máa béèrè ọgbọ́n lọ́wọ́ òun.—Òwe 2:1-6.
12. Báwo la ṣe ń fi ọgbọ́n wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́?
12 Àwa náà ńkọ́? Ṣé a lè máa fi ọgbọ́n wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bíi ti Jèhófà? (Sm. 32:8) Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwa èèyàn Jèhófà ní láti máa fi ohun tá a mọ̀ kọ́ àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, àwọn alàgbà máa ń fi sùúrù ran àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàwọn arákùnrin míì tó ti ṣèrìbọmi lọ́wọ́, kí wọ́n lè bójú tó ojúṣe wọn dáadáa nínú ìjọ. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó mọṣẹ́ ìkọ́lé àti bí wọ́n ṣe ń ṣàtúnṣe ilé máa ń dá àwọn tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọṣẹ́ náà lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ilé ètò Ọlọ́run dáadáa.
13. Báwo la ṣe lè fi ọgbọ́n tá a ní ran àwọn tá à ń dá lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ bíi ti Jèhófà?
13 Ó yẹ káwọn tó ń dáni lẹ́kọ̀ọ́ máa fi ọgbọ́n tí wọ́n ní ran àwọn tí wọ́n ń dá lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ bíi ti Jèhófà. Ẹ má gbàgbé pé Jèhófà ò mọ tara ẹ̀ nìkan, ó máa ń fún wa lọ́gbọ́n tá a nílò. Lọ́nà kan náà, ó yẹ káwa náà máa kọ́ àwọn èèyàn lóhun tá a mọ̀ láì fi nǹkan kan pa mọ́. Kò yẹ ká máa fi ohun tá a mọ̀ pa mọ́ torí à ń bẹ̀rù pé wọ́n lè gbaṣẹ́ yẹn mọ́ wa lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa ronú pé: ‘Kò sẹ́ni tó kọ́ èmi náà! Kóun náà lọ kọ́ ọ fúnra ẹ̀.’ Kò yẹ kí àwa èèyàn Jèhófà nírú èrò yìí rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kínú wa máa dùn pé a fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn lóhun tá a mọ̀, a sì tún fẹ́ lo “ara wa” fún wọn. (1 Tẹs. 2:8) Ó dá wa lójú pé àwọn náà á “wá kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti kọ́ àwọn ẹlòmíì.” (2 Tím. 2:1, 2) Torí náà, tá a bá ń fi ọgbọ́n wa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, gbogbo wa làá máa gbọ́n sí i, àá sì túbọ̀ máa láyọ̀.
TÁWỌN ÈÈYÀN Ò BÁ MỌYÌ OHUN TÁ A ṢE
14. Tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kí ni wọ́n máa ń ṣe?
14 Tá a bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, pàápàá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, wọ́n máa ń mọyì ẹ̀ gan-an. Wọ́n lè fi káàdì ìdúpẹ́ ránṣẹ́ sí wa tàbí kí wọ́n fi hàn láwọn ọ̀nà míì pé àwọn mọrírì ohun tá a ṣe fún wọn. (Kól. 3:15) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yẹn máa ń jẹ́ ká túbọ̀ láyọ̀.
15. Kí ló yẹ ká máa rántí táwọn kan ò bá dúpẹ́ lọ́wọ́ wa?
15 Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa tá a bá ṣoore fún wọn. Nígbà míì, a lè lo àkókò wa, okun wa àtohun tá a ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ ó lè yà wá lẹ́nu pé wọn ò mọyì ohun tá a ṣe fún wọn. Tírú nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, kí la lè ṣe tá ò fi ní pàdánù ayọ̀ wa? Rántí ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé, ìyẹn Ìṣe 20:35. Kò dìgbà táwọn èèyàn bá mọyì ohun tá a ṣe ká tó lè rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn máa ṣoore. A lè pinnu pé àá máa láyọ̀ bá a ṣe ń ṣoore kódà táwọn kan ò bá mọyì ohun tá a ṣe fún wọn. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára nǹkan tá a lè ṣe.
16. Kí ni ò yẹ ká máa retí tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan?
16 Máa fara wé Jèhófà. Gbogbo èèyàn ni Jèhófà ń ṣoore fún bóyá wọ́n mọyì ẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. (Mát. 5:43-48) Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá fara wé òun, tá à ń fáwọn èèyàn ní nǹkan “láìretí ohunkóhun pa dà,” ‘èrè wa máa pọ̀.’ (Lúùkù 6:35) Ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ wà lára “ohunkóhun” tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. Torí náà, bóyá àwọn èèyàn dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn tàbí wọn ò dúpẹ́, Jèhófà máa san èrè fún wa torí ó nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń “fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”—Òwe 19:17; 2 Kọ́r. 9:7.
17. Kí lá jẹ́ ká máa ṣoore fáwọn èèyàn nìṣó? (Lúùkù 14:12-14)
17 Tá a bá fẹ́ máa ṣoore fáwọn èèyàn nìṣó, bóyá wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ wa tàbí wọn ò dúpẹ́, ìlànà tó máa ràn wá lọ́wọ́ wà nínú Lúùkù 14:12-14. (Kà á.) Kò burú tá a bá ṣoore fáwọn èèyàn, kódà tá a bá mọ̀ pé wọ́n lè san án pa dà fún wa. Àmọ́, tá a bá rí i pé torí ká lè rí nǹkan gbà pa dà lọ́wọ́ àwọn èèyàn la ṣe ń ṣoore fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà ńkọ́? Á dáa ká ṣe ohun tí Jésù sọ. Ó yẹ ká máa ṣoore fáwọn tá a mọ̀ pé wọn ò lè san án pa dà fún wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa láyọ̀ torí a mọ̀ pé à ń fara wé Jèhófà. Bákan náà, kò ní jẹ́ ká pàdánù ayọ̀ wa táwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ mọyì ohun tá a ṣe fún wọn.
18. Kí la ò gbọ́dọ̀ ṣe, kí sì nìdí?
18 Má ṣe rò pé aláìmoore lẹnì kan. (1 Kọ́r. 13:7) Táwọn èèyàn ò bá dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé aláìmoore ni wọ́n lóòótọ́ àbí wọ́n gbàgbé láti dúpẹ́?’ Ó sì lè jẹ́ pé àwọn nǹkan míì ni ò jẹ́ kí wọ́n dúpẹ́ bó ṣe yẹ. Àwọn kan lè mọyì ohun tá a ṣe fún wọn gan-an, àmọ́ kí wọ́n má mọ bí wọ́n ṣe máa dúpẹ́. Ojú lè máa tì wọ́n torí pé tẹ́lẹ̀ àwọn ló máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àmọ́ ní báyìí, àwọn èèyàn ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí ó wù kó jẹ́, tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dénú, a ò ní máa rò pé aláìmoore ni wọ́n, àá sì máa láyọ̀ nìṣó bá a ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́.—Éfé. 4:2.
19-20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní sùúrù tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
19 Máa ní sùúrù. Nígbà tí ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ń sọ nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa ṣoore, ó sọ pé: “Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, torí pé lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, wàá tún rí i.” (Oníw. 11:1) Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó lè pẹ́ káwọn kan tó mọyì ohun tá a ṣe fún wọn, ó tiẹ̀ lè jẹ́ “lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀” pàápàá. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan.
20 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìyàwó alábòójútó àyíká kan kọ lẹ́tà sí arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi láti fún un níṣìírí pé kó máa sin Jèhófà tọkàntọkàn. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, arábìnrin náà kọ lẹ́tà sí ìyàwó alábòójútó àyíká yẹn, ó sọ pé: “Mo rí i pé ó yẹ kí n kọ lẹ́tà yìí sí yín torí pé ẹ ò mọ bí lẹ́tà tẹ́ ẹ kọ sí mi nígbà yẹn ṣe ràn mí lọ́wọ́ tó.” Ó fi kún un pé: “[Lẹ́tà yẹn] mára tù mí, àmọ́ ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ ló wọ̀ mí lọ́kàn jù, mi ò sì ní gbàgbé ẹ̀ láé.” a Lẹ́yìn tó sọ àwọn ìṣòro tó ti ní, ó sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n fi Jèhófà sílẹ̀, kí n má sì sìn ín mọ́. Àmọ́ ẹsẹ Bíbélì yẹn máa ń fún mi lókun, ó sì ń jẹ́ kí n máa sin Jèhófà nìṣó.” Ó tún sọ pé: “Ní gbogbo ọdún mẹ́jọ yẹn, lẹ́tà yín àti ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ gan-an.” Ẹ wo bí inú ìyàwó alábòójútó àyíká yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tó gba lẹ́tà náà ‘lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún!’ Ọ̀rọ̀ tiwa náà lè rí bẹ́ẹ̀ torí ó lè pẹ́ káwọn kan tó wá dúpẹ́ oore tá a ṣe fún wọn.
21. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá máa ṣoore fáwọn èèyàn bíi ti Jèhófà?
21 Bá a ṣe sọ níṣàájú, Jèhófà ti dá ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ mọ́ wa. Ká sòótọ́, inú wa máa ń dùn táwọn èèyàn bá fún wa ní nǹkan, àmọ́ ìgbà tínú wa máa ń dùn jù lọ nìgbà tá a fún àwọn èèyàn ní nǹkan. Inú wa tún máa ń dùn tá a bá ran àwọn ará wa lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, tá a sì rí i pé wọ́n mọyì ohun tá a ṣe fún wọn. Bóyá ẹni yẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ wa tàbí kò dúpẹ́, inú wa máa dùn pé a ti ṣe ohun tó tọ́. Máa rántí pé tó o bá ń ṣoore fáwọn èèyàn, “Jèhófà mọ bó ṣe máa fi èyí tó pọ̀ ju bẹ́ẹ̀ san án fún ọ.” (2 Kíró. 25:9) Torí náà, ohun tí Jèhófà máa fi san án pa dà fún wa máa pọ̀ ju ohun tá a fún àwọn èèyàn lọ! Ká sòótọ́, kò sí ayọ̀ tó jùyẹn lọ torí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló san èrè fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé àá máa fara wé Jèhófà Baba wa ọ̀run tó máa ń ṣoore fáwọn èèyàn.
ORIN 17 “Mo Fẹ́ Bẹ́ẹ̀”
a Ẹsẹ Bíbélì tó fi ran arábìnrin yẹn lọ́wọ́ ni 2 Jòhánù 8, ó sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra, kí ẹ má bàa mú kí iṣẹ́ wa já sí asán, ṣùgbọ́n kí ẹ lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.”
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwòrán yìí ń sọ nípa ìgbà tí ìyàwó alábòójútó àyíká kan kọ lẹ́tà sí arábìnrin kan láti fún un níṣìírí. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, arábìnrin yẹn kọ lẹ́tà sí ìyàwó alábòójútó àyíká yẹn láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀.