ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43
Jèhófà Ló Ń Darí Ètò Rẹ̀
“‘Kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn ọmọ ogun tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”—SEK. 4:6.
ORIN 40 Ti Ta Ni A Jẹ́?
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ló yẹ kí Kristẹni kan máa ṣe kódà lẹ́yìn tó ti ṣèrìbọmi?
ṢÉ O ti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti sọ lójú gbogbo èèyàn pé o nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, o sì ti ṣe tán láti máa jọ́sìn pẹ̀lú ètò tó ń darí. * Síbẹ̀, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú Jèhófà máa lágbára sí i. Ó tún yẹ kó o máa ṣe ohun táá jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀ lónìí.
2-3. Báwo ni Jèhófà ṣe ń darí ètò rẹ̀ lónìí? Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.
2 Lónìí, Jèhófà ń darí ètò rẹ̀ lọ́nà tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́, àwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àtàwọn ìlànà rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká jíròrò mẹ́ta lára ohun tó jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti bó ṣe hàn nínú ètò rẹ̀.
3 Àkọ́kọ́, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa ní Ọmọ rẹ̀ láti ṣe ‘ìràpadà fún gbogbo èèyàn.’ (1 Tím. 2:6; Jòh. 3:16) Jèhófà ń mú káwọn èèyàn rẹ̀ wàásù fún gbogbo ẹni tó ṣe tán láti gbọ́, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ìràpadà náà. Ìkejì, Ọlọ́run ètò àti àlàáfíà ni Jèhófà. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Torí náà, ó yẹ káwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀ wà létòlétò, kí àlàáfíà sì wà láàárín wa. Ìkẹta, Jèhófà ni “Olùkọ́ [wa] Atóbilọ́lá.” (Àìsá. 30:20, 21) Ìdí nìyẹn tí ètò rẹ̀ fi ń sapá gan-an láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn nínú ìjọ àti lóde ẹ̀rí. Báwo ni irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ ṣe hàn nínú bó ṣe darí ìjọ Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní? Báwo ló ṣe hàn nínú bó ṣe ń darí ìjọ rẹ̀ lónìí? Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bíwọ náà ṣe ń jọ́sìn nínú ètò Jèhófà lónìí?
ỌLỌ́RUN KÌ Í ṢE OJÚSÀÁJÚ
4. Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nínú Ìṣe 1:8, kí ló sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́?
4 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ìhìn rere tí Jésù wàásù rẹ̀ mú kí gbogbo èèyàn nírètí. (Lúùkù 4:43) Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá iṣẹ́ tóun bẹ̀rẹ̀ lọ, kí wọ́n sì wàásù “títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.” (Ka Ìṣe 1:8.) Àmọ́ wọn ò lè dá ṣiṣẹ́ náà. Torí náà, wọ́n nílò ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn “olùrànlọ́wọ́” tí Jésù ṣèlérí pé òun máa fún wọn.—Jòh. 14:26; Sek. 4:6.
5-6. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lọ́wọ́?
5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 S.K. Kété lẹ́yìn tí wọ́n rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, kò sì pẹ́ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn fi di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Ìṣe 2:41; 4:4) Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí wọn, dípò káwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bẹ̀rù, ṣe ni wọ́n bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Wọ́n gbàdúrà pé: “Jẹ́ kí àwa ẹrú rẹ máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó pẹ̀lú ìgboyà.” Ẹ̀yìn náà ni ẹ̀mí mímọ́ bà lé wọn, wọ́n sì ń “fi ìgboyà sọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—Ìṣe 4:18-20, 29, 31.
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tún kojú àwọn ìṣòro míì. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ̀nba ni ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ní, wọn ò sì ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe ní in lónìí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ní láti wàásù fún àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè. Láìka gbogbo ìyẹn sí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn lo ìtara, wọ́n sì ṣe àṣeyọrí tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún péré, wọ́n ti wàásù ìhìn rere “láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:6, 23.
7. Báwo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe lóhun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, kí ni wọ́n sì ṣe?
7 Lóde òní. Jèhófà ṣì ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń fún wọn lágbára láti ṣe ohun tó fẹ́. Ó sábà máa ń darí wọn nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣe tán ẹ̀mí mímọ́ ló fi darí àwọn tó kọ ọ́. Inú Bíbélì la ti rí bí Jésù ṣe wàásù àti àṣẹ tó pa pé ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà lọ. (Mát. 28:19, 20) Abájọ tí Ilé Ìṣọ́ July 1881 fi sọ pé: “A kò pè wá tàbí fi òróró yàn wá ká lè gba ọlá tàbí ká lè kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n láti ná ohun ìní wa, ká sì ná ara wa láti wàásù ìhìn rere.” Ìwé To Whom the Work Is Entrusted, tá a tẹ̀ ní 1919 sọ pé: “Iṣẹ́ náà lè dà bí èyí tó ń kani láyà lóòótọ́, àmọ́ iṣẹ́ Olúwa ni, òun ló sì máa fún wa lókun láti ṣe é.” Bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn arákùnrin yẹn lo ìgboyà, wọ́n lo ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà, ó sì dá wọn lójú pé ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ káwọn wàásù fún onírúurú èèyàn. Ó dá àwa náà lójú pé ẹ̀mí mímọ́ máa ràn wá lọ́wọ́.
8-9. Àwọn ọ̀nà wo ni ètò Jèhófà ń lò láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i?
8 Àwọn ọ̀nà tó dáa jù ni ètò Jèhófà ń gbà mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà gbòòrò sí i. Lára àwọn nǹkan tí wọ́n lò láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i làwọn ìwé tá à ń tẹ̀, fíìmù “Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá,” ẹ̀rọ giramafóònù, mọ́tò tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́, rédíò àti Íńtánẹ́ẹ̀tì tá à ń lò lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Yàtọ̀ síyẹn, àsìkò yìí ni ètò Jèhófà ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sáwọn èdè tó pọ̀ jù! Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a fẹ́ kí onírúurú èèyàn gbọ́ ìhìn rere ní èdè wọn. Ó ṣe tán, Jèhófà Ọlọ́run wa kì í ṣe ojúsàájú, ó sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé a máa wàásù ìhìn rere yìí “fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.” (Ìfi. 14:6, 7) Ó dájú pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà fẹ́ kó gbọ́ ìhìn rere.
9 Kí là ń ṣe láti mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ àwọn
tí a kì í lè dé ọ̀dọ̀ wọn torí pé ilé onígéètì tí kò rọrùn láti wọ̀ ni wọ́n ń gbé? Kó lè ṣeé ṣe fún wa láti wàásù fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, ètò Jèhófà ní ká lọ máa wàásù níbi táwọn èrò pọ̀ sí. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2001, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé káwọn ará máa lo àwọn kẹ̀kẹ́ tá a fi ń pàtẹ ìwé wa lórílẹ̀-èdè Faransé, nígbà tó sì yá, wọ́n ní káwa yòókù máa lò ó. Ìṣètò yẹn méso jáde gan-an. Lọ́dún 2011, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìṣètò kan ní ọ̀kan lára ibi térò máa ń pọ̀ sí jù nílùú New York City, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Láàárín ọdún kan péré, àwọn ará fi ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ùn kan àti méjì (102,129) ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde, títí kan ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádọ́rin (68,911) ìwé ìròyìn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọgọ́rùn-ún méje ó lé ẹyọ kan (4,701) ló ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìyẹn mú kó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí iṣẹ́ yìí. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí gbogbo wa máa lo àwọn kẹ̀kẹ́ tá a fi ń pàtẹ ìwé wa kárí ayé.10. Báwo la ṣe lè sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni?
10 Ohun tó o lè ṣe. Máa fi àwọn àbá àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń fún wa nípàdé sílò. Máa lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwùjọ rẹ déédéé. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tó nírìírí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè sunwọ̀n sí i, wọ́n á sì fún ẹ níṣìírí. Máa wàásù nìṣó láìka ìṣòro tàbí àtakò sí. Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà ṣe sọ, ẹ̀mí mímọ́ ló ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí, kì í ṣe agbára wa. (Sek. 4:6) Ó ṣe tán, iṣẹ́ Ọlọ́run là ń ṣe.
ỌLỌ́RUN ÈTÒ ÀTI ÀLÀÁFÍÀ NI JÈHÓFÀ
11. Kí ni ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe tí ìṣọ̀kan fi wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n sì ń ṣe nǹkan létòlétò?
11 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Ìṣe 2:42) Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn kan ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ ní nǹkan bí ọdún 49 S.K., ẹ̀mí mímọ́ darí ìgbìmọ̀ olùdarí láti dórí ìpinnu tó ṣe gbogbo ìjọ láǹfààní. Ká sọ pé wọ́n jẹ́ kọ́rọ̀ yìí dá ìyapa sílẹ̀ láàárín àwọn ará ni, iṣẹ́ ìwàásù náà ì bá ti dúró. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Júù làwọn àpọ́sítélì àtàwọn alàgbà tó wà nínú ìgbìmọ̀ náà, wọn ò jẹ́ kí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù ràn wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fàyè gba èrò àwọn tó ń gbé àṣà náà lárugẹ. Dípò bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ ni wọ́n gbára lé láti tọ́ wọn sọ́nà. (Ìṣe 15:1, 2, 5-20, 28) Kí nìyẹn wá yọrí sí? Jèhófà bù kún ìpinnu tí wọ́n ṣe, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ, iṣẹ́ ìwàásù náà sì tẹ̀ síwájú.—Ìṣe 15:30, 31; 16:4, 5.
12. Àwọn nǹkan wo ló fi hàn pé àlàáfíà wà nínú ètò Jèhófà lónìí àti pé nǹkan ń lọ létòlétò?
12 Lóde òní. Ètò Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 1895, wọ́n gbé àpilẹ̀kọ kan jáde tí wọ́n pè ní “Decently and in Order” nínú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence ti November 15. 1 Kọ́ríńtì 14:40 ni wọ́n gbé àpilẹ̀kọ náà kà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn àpọ́sítélì sọ fún àwọn tó wà nínú ìjọ ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní nípa bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ létòlétò . . . Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ‘gbogbo ohun tí a kọ ní ìṣáájú fún wa láti gba ẹ̀kọ́.’” (Róòmù 15:4) Lónìí, ètò Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà, kí ohun gbogbo sì máa lọ létòlétò bíi ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé o rìnrìn àjò, o sì lọ sípàdé níbẹ̀, ó dájú pé o mọ bí wọ́n ṣe máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, o sì mọ àpilẹ̀kọ tí wọ́n máa jíròrò lọ́jọ́ náà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lara ẹ máa silé, o ò sì ní dà bí àjèjì láàárín wọn. Kò sí nǹkan míì tó lè mú kírú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ wà bí kò ṣe ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.—Sef. 3:9.
13. Tá a bá fi ohun tó wà nínú Jémíìsì 3:17 sọ́kàn, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
13 Ohun tó o lè ṣe. Jèhófà fẹ́ káwa èèyàn rẹ̀ máa “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) Torí náà, bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mò ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ? Ṣé mo máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn tó ń múpò iwájú? Ṣé àwọn míì lè fọkàn tán mi, pàápàá tí mo bá ní àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ? Ṣé mi ò kì í pẹ́ lẹ́yìn, ṣé ó sì máa ń yá mi lára láti ṣiṣẹ́ sin àwọn míì?’ (Ka Jémíìsì 3:17.) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Bó o ṣe ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí èrò àti ìwà ẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ, wọ́n á sì mọyì rẹ nínú ìjọ.
JÈHÓFÀ Ń KỌ́ WA, Ó SÌ Ń FÚN WA LÓHUN TÁ A NÍLÒ
14. Bó ṣe wà nínú Kólósè 1:9, 10, báwo ni Jèhófà ṣe dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?
14 Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Tayọ̀tayọ̀ ni Jèhófà fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (Sm. 32:8) Ó fẹ́ kí gbogbo wọn mọ òun, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Àmọ́, àwọn nǹkan yìí kò ní ṣeé ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Jòh. 17:3) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ìjọ Kristẹni ni Jèhófà lò láti dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. (Ka Kólósè 1:9, 10.) Ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn “olùrànlọ́wọ́” tí Jésù ṣèlérí ló jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. (Jòh. 14:16) Ó jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ kí wọ́n rántí ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù kọ́ wọn àtàwọn nǹkan tó ṣe, èyí tó wà lákọsílẹ̀ nígbà tó yá nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere. Ohun tí wọ́n mọ̀ yìí mú kí ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni yẹn túbọ̀ lágbára, ó sì mú kí wọ́n túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jésù, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì.
15. Àwọn nǹkan wo ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ń mú ìlérí tó ṣe nínú Àìsáyà 2:2, 3 ṣẹ?
15 Lóde òní. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,” àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè máa wá sí òkè mímọ́ òun kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun. (Ka Àìsáyà 2:2, 3.) À ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lónìí. Jèhófà ti gbé ìjọsìn tòótọ́ ga ju gbogbo ìsìn èké lọ. Ó sì tún ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ fáwa èèyàn rẹ̀. (Àìsá. 25:6) Kì í ṣe pé ó ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ nìkan, ó tún ń pèsè ẹ̀ lóríṣiríṣi. Oríṣiríṣi làwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn àsọyé tá à ń gbádùn, títí kan àwọn eré bèbí àtàwọn fídíò. (Mát. 24:45) Bó ṣe rí lára Élíhù ọ̀rẹ́ Jóòbù náà ló rí lára wa nígbà tó sọ pé: “Olùkọ́ wo ló dà bí [Ọlọ́run]?”—Jóòbù 36:22.
16. Kí lo lè ṣe láti túbọ̀ jẹ́ ẹni tẹ̀mí?
16 Ohun tó o lè ṣe. Ẹ̀mí Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi ohun tó ò ń kà àtohun tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Máa gbàdúrà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Jèhófà, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ. Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ. Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” (Sm. 86:11) Torí náà, máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀. Àmọ́ o, kì í ṣe torí kó o lè ní ìmọ̀ nìkan lo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó o fẹ́ ni pé kí òtítọ́ wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, kó o sì máa fi í sílò láyé rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kó o tún máa fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin níṣìírí. (Héb. 10:24, 25) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọmọ ìyá ni gbogbo wa nínú ìdílé Jèhófà. Bákan náà, máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dáhùn látọkàn wá nípàdé kó o sì máa ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún ẹ dáadáa. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù, o sì nífẹ̀ẹ́ àwọn “àgùntàn” wọn.—Jòh. 21:15-17.
17. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fi hàn pé ò ń ti ètò Jèhófà lẹ́yìn, o sì jẹ́ adúróṣinṣin?
17 Láìpẹ́, ètò tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí nìkan ló máa kù láyé. Torí náà, máa ti ètò Jèhófà lẹ́yìn kó o sì máa lo ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bíi ti Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, kó o sì máa wàásù ìhìn rere fún gbogbo àwọn tó o bá rí. Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Máa fetí sí Olùkọ́ rẹ Atóbilọ́lá, kó o sì máa jẹ onírúurú oúnjẹ tẹ̀mí tó ń pèsè. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní bẹ̀rù bí ayé Sátánì yìí ṣe ń lọ sópin. Dípò bẹ́ẹ̀, ọkàn ẹ á balẹ̀ pé o wà pẹ̀lú àwọn tó ń fi òótọ́ inú sin Jèhófà nínú ètò rẹ̀.
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
^ ìpínrọ̀ 5 Ṣé ó dá ẹ lójú pé Jèhófà ló ń darí ètò rẹ̀ lónìí? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe darí ìjọ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní àti bó ṣe ń darí àwọn èèyàn ẹ̀ lónìí.
^ ìpínrọ̀ 1 ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Ètò Jèhófà ní apá ti ọ̀run àti apá ti ayé. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀rọ̀ náà “ètò” tọ́ka sí apá ti ayé nínú ètò Ọlọ́run.
^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Lẹ́yìn tí arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan wo fídíò àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ tó sì tún rí àwọn kan tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó wù ú pé kóun náà ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, ó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀.