1920—Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn
BẸ̀RẸ̀ látọdún 1920, àwọn èèyàn Jèhófà tún bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù. Kódà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n yàn fún ọdún 1920 sọ pé: “OLUWA li agbara ati orin mi.”—Sm. 118:14, Bibeli Mimọ.
Jèhófà fún àwọn tó ń fìtara wàásù yìí lágbára lóòótọ́. Lọ́dún yẹn, àwọn apínwèé-ìsìn-kiri tàbí àwọn tá à ń pè ní aṣáájú-ọ̀nà pọ̀ sí i láti igba ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (225), wọ́n di ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ààbọ̀ (350). Ìgbà àkọ́kọ́ sì nìyẹn tí àwọn òṣìṣẹ́ inú ìjọ (àwọn akéde) tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ (8,000) lọ fi ìròyìn wọn ránṣẹ́ sí oríléeṣẹ́. Ó hàn pé Jèhófà bù kún ìtara wọn gan-an.
WỌ́N LO ÌTARA TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
Ní March 21, 1920, Arákùnrin Joseph F. Rutherford tó ń múpò iwájú láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Gbogbo ohun tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn lè ṣe ni wọ́n ṣe láti pe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ wá síbi àsọyé náà. Ọ̀kan lára àwọn ilé ìwòran tó tóbi jù ní New York City ni wọ́n háyà, wọ́n sì pín ìwé ìkésíni tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320,000).
Iye àwọn èèyàn tó wá síbẹ̀ kọjá ohun tí wọ́n retí. Àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) kún ilé ìwòran náà bámúbámú, kódà wọ́n ní láti dá àwọn bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) pa dà torí pé kò síbi tí wọ́n lè jókòó sí. Ìwé ìròyìn The Watch Tower sọ pé àpéjọ yìí jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn àpéjọ tó fakíki jù tí Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé ṣe.”
Ibi gbogbo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń kéde pé “àràádọ́ta ọ̀kẹ́ [èèyàn] tó wà láàyè nísinsìnyí kò ní kú láé.” Nígbà yẹn, wọn ò mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù máa gbòòrò tó bó ṣe rí lónìí. Síbẹ̀, wọ́n lo ìtara tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Ida Olmstead tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé lọ́dún 1902 sọ pé: “A mọ̀ pé Ọlọ́run máa rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé, a ò sì yéé sọ ìhìn rere yìí fún gbogbo àwọn tá à ń bá pàdé.”
A BẸ̀RẸ̀ SÍ Í TẸ ÌWÉ WA FÚNRA WA
Kí àwọn ará lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà déédéé, àwọn arákùnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé wa kan jáde fúnra wọn. Torí náà wọ́n ra ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, wọ́n sì gbé e sí ilé kan tí wọ́n rẹ́ǹtì ní 35 Myrtle Avenue, Brooklyn tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí Bẹ́tẹ́lì.
January 1920 ni Arákùnrin Leo Pelle àti Walter Kessler dé sí Bẹ́tẹ́lì. Arákùnrin Walter sọ pé: “Nígbà tá a dé Bẹ́tẹ́lì, arákùnrin tó ń bójú tó ẹ̀ka ìtẹ̀wé sọ fún wa pé ‘Ó ṣì ku wákàtí kan ààbọ̀ ká tó lọ jẹun ọ̀sán.’ Torí náà, ó ní ká lọ máa kó àwọn páálí ìwé tó wà ní àjà ilẹ̀ ilé náà.”
Arákùnrin Leo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kejì, ó ní: “Wọ́n ní ká lọ sílé tó wà ní 35 Myrtle Avenue, ká sì fọ ògiri inú ilé tó wà nísàlẹ̀ rẹ̀. Iṣẹ́ tó dọ̀tí jù tí mo tíì ṣe láyé mi nìyẹn. Àmọ́ iṣẹ́ Olúwa ni, torí náà
gbogbo okun mi ni mo fi ṣe é torí mo gbà pé ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”Láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀, àwọn arákùnrin onítara bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn The Watch Tower jáde. Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta (60,000) ni ẹ̀dà The Watch Tower February 1, 1920 tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó wà ní àjà kejì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn arákùnrin tún gbé ẹ̀rọ ìtẹ̀wé míì tí wọ́n pè ní Battleship sí àjà ilẹ̀ ilé náà. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age jáde bẹ̀rẹ̀ láti ẹ̀dà April 14, 1920. Kò sí àní-àní pé Jèhófà bù kún ìsapá àwọn arákùnrin yẹn gan-an.
“Iṣẹ́ Olúwa ni, torí náà gbogbo okun mi ni mo fi ṣe é torí mo gbà pé ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ”
“Ẹ JẸ́ KÁ JỌ WÀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ”
Àwọn èèyàn Jèhófà tó jẹ́ adúróṣinṣin ń gbádùn àlàáfíà, wọ́n sì ń jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́. Àmọ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ti fi ètò Ọlọ́run sílẹ̀ láàárín ọdún 1917 sí 1919 nígbà tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Kí ni ètò Ọlọ́run ṣe láti mú kí wọ́n pa dà?
Wọ́n gbé àpilẹ̀kọ kan jáde nínú The Watch Tower ti April 1, 1920, àkòrí ẹ̀ ni “Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Wà ní Àlàáfíà.” Àpilẹ̀kọ náà rọ̀ wọ́n pé: ‘A mọ̀ pé gbogbo àwọn tó ní ẹ̀mí Olúwa ló máa gbàgbé àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, tí wọ́n á sì wà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará yòókù, gbogbo wa á sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara kan.’
Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló mọyì àpilẹ̀kọ yìí tí wọ́n sì ṣẹ́rí pa dà. Tọkọtaya kan sọ pé: “Ó dá wa lójú pé àṣìṣe ńlá gbáà la ṣe láwọn ọdún tó kọjá bá ò ṣe lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù nígbà táwọn míì ń bá iṣẹ́ náà lọ. . . . Torí náà, a pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun tún mú ká ṣíwọ́ àtimáa wàásù.” Àwọn tó pa dà sínú ètò wá rí i pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló wà láti ṣe.
WỌ́N PÍN ÌWÉ “ZG”
Ní June 21, 1920, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara pín ìwé tí wọ́n pè ní “ZG,” ìyẹn ìwé The Finished Mystery * tó ní èèpo ẹ̀yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́. Wọ́n ti tọ́jú ẹ̀dà rẹpẹtẹ ìwé yìí pa mọ́ nígbà tí wọ́n fòfin dè é lọ́dún 1918.
Kì í ṣe àwọn apínwèé-ìsìn-kiri nìkan ni wọ́n rọ̀ láti pín ìwé yìí, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ inú ìjọ ló lọ́wọ́
nínú ẹ̀. Ìwé ìròyìn ZG sọ pé: “Kí gbogbo àwọn tó ti ṣèrìbọmi tó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ fayọ̀ lọ́wọ́ nínú pínpín ìwé náà. Ọ̀rọ̀ tó yẹ kí gbogbo wa máa sọ fún ara wa ni pé: ‘Màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe kí n lè fi ìwé ZG sóde.’ ” Arákùnrin Edmund Hooper sọ pé ìyẹn nìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ máa wàásù láti ilé dé ilé. Ó fi kún un pé, “Ìgbà yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í lóye bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe máa gbòòrò tó.”WỌ́N TÚN ṢÈTÒ IṢẸ́ NÁÀ LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I NÍ YÚRÓÒPÙ
Torí pé kò rọrùn fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè yòókù láti kàn sí oríléeṣẹ́ lásìkò Ogun Àgbáyé Kìíní, Arákùnrin Rutherford fún àwọn ará yẹn níṣìírí, ó sì tún ṣètò bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe máa pa dà bẹ̀rẹ̀. Torí náà ní August 12, 1920, òun àtàwọn arákùnrin mẹ́rin míì lọ ṣèbẹ̀wò sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Yúróòpù àti Middle East.
Nígbà tí Arákùnrin Rutherford dé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ agbègbè mẹ́ta, wọ́n sì ṣe àwọn ìpàdé méjìlá (12) míì tí wọ́n pe àwọn èèyàn sí. Àròpọ̀ àwọn tó wá síbẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000). Nígbà tí ìwé ìròyìn The Watch Tower ń sọ bí ìbẹ̀wò náà ṣe lọ, ó ní: “Inú àwọn ará náà dùn, orí wọn sì wú. Ṣe ni ìfẹ́ tó wà láàárín wọn túbọ̀ lágbára, wọ́n túbọ̀ pinnu pé àwọn á fọwọ́sowọ́pọ̀ láti ṣiṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn sì mú káwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́.” Nígbà tí Arákùnrin Rutherford dé Paris, ó tún sọ àsọyé náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé.” Nígbà tó fi máa bẹ̀rẹ̀ àsọyé yẹn, èrò ti kún inú gbọ̀ngàn náà fọ́fọ́. Kódà, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) èèyàn ló sọ pé àwọn fẹ́ mọ̀ sí i.
Láwọn ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, àwọn arákùnrin kan ṣèbẹ̀wò sí ìlú Áténì, Cairo àti Jerúsálẹ́mù. Kí ìfẹ́ táwọn ará tó wà láwọn ìlú yẹn ní má bàa di tútù, Arákùnrin Rutherford ṣètò ibì kan tí wọ́n á máa já àwọn ìwé wa sí nílùú Ramallah, nítòsí Jerúsálẹ́mù. Lẹ́yìn náà ó pa dà sí Yúróòpù, ó dá ẹ̀ka ọ́fíìsì kan sílẹ̀ ní Central Europe, ó sì ṣètò pé kí wọ́n máa tẹ àwọn ìwé wa níbẹ̀.
WỌ́N TÚ ÀṢÍRÍ ÀÌṢÈDÁJỌ́ ÒDODO
Ní September 1920, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú ìwé ìròyìn The Golden Age No. 27 jáde, inú ẹ̀ sì ni wọ́n ti tú àṣírí inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dún 1918. Tọ̀sántòru ni ẹ̀rọ ìtẹ̀wé Battleship tá a sọ lẹ́ẹ̀kan ń ṣiṣẹ́, ó sì tẹ ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin ìwé ìròyìn náà jáde.
Àwọn tó ka ìwé ìròyìn náà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Emma Martin. Apínwèé-ìsìn-kiri ni Arábìnrin Martin, San Bernardino ní California ló sì ń gbé. Ní March 17, 1918, òun àtàwọn
arákùnrin mẹ́ta kan lọ sípàdé. Àwọn arákùnrin mẹ́ta náà ni E. Hamm, E. J. Sonnenburg àti E. A. Stevens.Ọkùnrin kan wá sípàdé yẹn, àmọ́ kì í ṣe torí kó lè kẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ nílé ẹjọ́ nígbà tó yá pé: “Ọ́fíìsì ìjọba tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹjọ́ ló rán mi lọ sípàdé yẹn. Ìdí sì ni pé wọ́n fẹ́ kí n rí nǹkan tí ìjọba á fi fẹ̀sùn kàn wọ́n.” Ó sì rí nǹkan tó ń wá, ìyẹn ẹ̀dà kan ìwé The Finished Mystery. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, wọ́n mú Arábìnrin Martin àtàwọn arákùnrin mẹ́ta náà. Wọ́n gbé wọn lọ sílé ẹjọ́, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń pín ìwé tí ìjọba ti fòfin dè.
Ilé ẹjọ́ dá Arábìnrin Emma àtàwọn arákùnrin yẹn lẹ́bi, wọ́n sì rán wọn lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta. Wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ ibì kan náà ló já sí. Torí náà ní May 17, 1920 wọ́n ní kí wọ́n lọ ṣẹ̀wọ̀n wọn. Àmọ́ kò pẹ́ tí nǹkan fi yí pa dà sí rere.
Ní àpéjọ agbègbè tí wọ́n ṣe ní June 20, 1920 nílùú San Francisco lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, Arákùnrin Rutherford sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará yẹn. Inú àwọn tó péjọ yẹn ò dùn, wọ́n sì tẹ wáyà ránṣẹ́ sí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ohun tí wọ́n kọ ránṣẹ́ ni: ‘A gbà pé òfin tí wọ́n fi mú Arábìnrin Martin kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kò sì tọ́. Bákan náà, bí ìjọba ṣe rán aṣojú wọn lọ sípàdé yẹn láti lọ fimú fínlẹ̀ kí wọ́n lè fẹ̀sùn kan Arábìnrin Martin, kí wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n kò bójú mu rárá.’
Lọ́jọ́ kejì, bí Ààrẹ Woodrow Wilson ṣe gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló fagi lé ìdájọ́ tí wọ́n dá fún Arábìnrin Martin, títí kan tàwọn Arákùnrin Hamm, Sonnenburg àti Stevens. Bó ṣe di pé wọ́n dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nìyẹn o.
Nígbà tí ọdún 1920 fi máa parí, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ti gbé ṣe, inú wọn sì dùn gan-an. Iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní oríléeṣẹ́ ń gbòòrò sí i. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń fìtara kéde pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ni ojútùú sí gbogbo ìṣòro aráyé. (Mát. 24:14) Lọ́dún 1921 tó tẹ̀ lé e, iṣẹ́ ńlá làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ṣe láti polongo ìhìn rere Ìjọba náà.
^ ìpínrọ̀ 18 Ìwé The Finished Mystery ni apá keje ìwé Studies in the Scriptures. “ZG” ni ẹ̀dà ẹ̀ tó ní èèpo ẹ̀yìn fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n tẹ̀, tí wọ́n sì pè ní The Watch Tower ti March 1, 1918. “Z” yẹn dúró fún Zion’s Watch Tower, nígbà tí “G” dúró fún lẹ́tà keje nínú a,b,d torí pé ìwé yẹn ni apá keje.