ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45
Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Láti Máa Pa Àṣẹ Kristi Mọ́
‘Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.’—MÁT. 28:19, 20.
ORIN 89 Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nínú Mátíù 28:18-20?
LẸ́YÌN tí Ọlọ́run jí Jésù dìde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó kóra jọ ní Gálílì. Ohun pàtàkì kan wà tó fẹ́ bá wọn sọ. Kí lohun náà? Ohun tó bá wọn sọ wà nínú Mátíù 28:18-20.—Kà á.
2. Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn kan àwa náà lónìí. Ká lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ìbéèrè mẹ́ta. Àkọ́kọ́, kí lohun míì tó tún yẹ ká ṣe láfikún sí kíkọ́ àwọn ẹni tuntun láwọn ìlànà Ọlọ́run? Ìkejì, kí ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lè ṣe káwọn ẹni tuntun yìí lè túbọ̀ tẹ̀ síwájú? Ìkẹta, báwo la ṣe lè ran àwọn ará wa tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa dà máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn?
KỌ́ WỌN LÁTI MÁA PA ÀWỌN ÀṢẸ JÉSÙ MỌ́
3. Àwọn nǹkan pàtó wo ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe?
3 Àwọn ìtọ́ni tí Jésù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ṣe kedere. A gbọ́dọ̀ kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó pa láṣẹ. Àmọ́, kókó pàtàkì kan wà tá ò gbọ́dọ̀ gbójú fò nínú ìtọ́ni yẹn. Jésù ò sọ pé: ‘Ẹ máa kọ́ wọn ní gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín.’ Kàkà bẹ́ẹ̀ ó sọ pé, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n “máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” Tá a bá máa fi ìtọ́ni pàtó yìí sílò, kì í ṣe pé ká kàn máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nìkan, ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa tọ́ wọn sọ́nà. (Ìṣe 8:31) Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?
4. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ní ká pa àṣẹ òun mọ́? Ṣàpèjúwe.
4 Nígbà tí Jésù sọ pé ká “pa” àṣẹ òun mọ́, ohun tó ń sọ ni pé ká máa ṣègbọràn sí òun. Ẹ jẹ́ ká ṣàpèjúwe bá a ṣe lè kọ́ ẹnì kan láti máa pa àṣẹ Jésù mọ́ tàbí láti máa ṣègbọràn sí i. Báwo lẹni tó ń kọ́ni lọ́kọ̀ wíwà ṣe máa kọ́ ẹnì kan láti máa pa àwọn òfin ìrìnnà mọ́? Lákọ̀ọ́kọ́, olùkọ́ náà á kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà láwọn òfin ìrìnnà kí wọ́n tó kúrò nílé. Àmọ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà tó mọ bóun á ṣe máa pa òfin ìrìnnà yẹn mọ́, ohun pàtàkì míì wà tí olùkọ́ náà gbọ́dọ̀ ṣe. Ó gbọ́dọ̀ wà pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ náà nínú ọkọ̀ kó sì máa tọ́ ọ sọ́nà bí akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe ń wakọ̀, tó sì ń gbìyànjú láti fi ìtọ́ni tó gbà sílò. Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe yìí?
5. (a) Kí ló yẹ ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pé kí wọ́n máa ṣe bó ṣe wà nínú Jòhánù 14:15 àti 1 Jòhánù 2:3? (b) Sọ àpẹẹrẹ bá a ṣe lè tọ́ wọn sọ́nà.
5 Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe là ń kọ́ wọn láwọn ìlànà Ọlọ́run. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi àwọn ìlànà yẹn sílò nígbèésí ayé wọn lójoojúmọ́. (Ka Jòhánù 14:15; 1 Jòhánù 2:3.) A lè lo àpẹẹrẹ tiwa láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nílé ìwé, níbi iṣẹ́ tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ìnàjú. O lè sọ fún wọn nípa ìgbà kan tó o fi ìlànà Bíbélì sílò, tíyẹn sì dáàbò bò ẹ́ kúrò lọ́wọ́ ewu tàbí tó mú kó o ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Tá a bá wà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, a lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó máa fi ẹ̀mí ẹ̀ tọ́ wọn sọ́nà.—Jòh. 16:13.
6. Kí ló tún yẹ ká ṣe tá a bá ń kọ́ àwọn míì pé kí wọ́n máa pa àṣẹ Jésù mọ́?
6 Kí làwọn nǹkan míì tó yẹ ká ṣe tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n pa àṣẹ Jésù mọ́? A gbọ́dọ̀ ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè máa wù wọ́n láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ẹ̀rù lè máa ba àwọn kan láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. A gbọ́dọ̀ mú sùúrù fún wọn títí wọ́n á fi lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́, tí ìgbàgbọ́ wọn á sì lágbára. Tí ìgbàgbọ́ wọn bá lágbára, ìyẹn á mú kó wù wọ́n láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kó máa wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti máa wàásù?
7. Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ táá fi máa wù ú láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù?
7 A lè béèrè lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pé: “Báwo làwọn ìlànà Bíbélì tó ò ń fi sílò ṣe mú kí ìgbésí ayé rẹ sunwọ̀n sí i? Ǹjẹ́ o mọ àwọn míì tí ìlànà yìí máa ṣe láǹfààní? Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?” (Òwe 3:27; Mát. 9:37, 38) Fi àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa han akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kó o sì jẹ́ kó yan èyí tó rò pé ó máa ṣàǹfààní fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Kẹ́ ẹ sì jọ múra bó ṣe lè mú káwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Bó ti wù kó rí, bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó ṣe pàtàkì ká bá a ṣiṣẹ́ ká lè máa tọ́ ọ sọ́nà.—Oníw. 4:9, 10; Lúùkù 6:40.
OHUN TÁWỌN ARÁ ÌJỌ LÈ ṢE LÁTI MÚ KÁWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TẸ̀ SÍWÁJÚ
8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò wọn? (Tún wo àpótí náà “ Bá A Ṣe Lè Mú Káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Túbọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.”)
8 Ó yẹ ká máa rántí ìtọ́ni tí Jésù fún wa pé ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti máa “pa gbogbo ohun” tí Jésù pa láṣẹ fún wa mọ́. Èyí kan àṣẹ méjì tó tóbi jù lọ náà tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa. Mát. 22:37-39) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àti fún àwọn aládùúgbò wa ló ń mú ká máa wàásù. Ká sòótọ́, ẹ̀rù lè máa ba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa láti lọ wàásù. Àmọ́ a lè fi dá wọn lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù yìí bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. (Sm. 18:1-3; Òwe 29:25) Àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, kí làwọn tó wà nínú ìjọ lè ṣe láti ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn?
Ìfẹ́ yìí ló ń mú ká máa wàásù ká sì máa sọni dọmọ ẹ̀yìn. (9. Nínú àpèjúwe ẹni tó ń kọ́ béèyàn ṣe ń wakọ̀, àwọn ọ̀nà míì wo ni akẹ́kọ̀ọ́ náà tún máa gbà kẹ́kọ̀ọ́?
9 Ẹ jẹ́ ká pa dà sí àpèjúwe ẹni tó ń kọ́ béèyàn ṣe ń wakọ̀. Tí akẹ́kọ̀ọ́ náà bá ń wakọ̀ lójú pópó, tí olùkọ́ rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wo ló tún máa gbà kẹ́kọ̀ọ́? Ó tún lè kẹ́kọ̀ọ́ tó bá ń fetí sí olùkọ́ rẹ̀, tó sì ń kíyè sí àwọn tó ń fara balẹ̀ wakọ̀ lójú pópó. Bí àpẹẹrẹ, olùkọ́ náà lè tọ́ka sí awakọ̀ kan tó fún ọlọ́kọ̀ míì láyè láti wọlé síwájú òun. Tàbí awakọ̀ míì tó lo ìgbatẹnirò, tó sì dín iná iwájú ọkọ̀ rẹ̀ kù kó má bàa wọ ojú àwọn awakọ̀ tó ń bọ̀ níwájú. Àwọn àpẹẹrẹ yìí máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ ohun tó yẹ kó ṣe tóun náà bá ń wakọ̀.
10. Kí ló máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
10 Lọ́nà kan náà, bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe ń rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, kì í ṣe ara ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nìkan lá ti máa kẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n á tún máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn míì tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà. Torí náà, kí ló máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí? Ohun kan ni pé kó máa wá sípàdé déédéé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó ń gbọ́ nípàdé á mú kó túbọ̀ lóye òtítọ́, kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára, kó sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. (Ìṣe 15:30-32) Yàtọ̀ síyẹn, tó bá wá sípàdé, olùkọ́ rẹ̀ lè fojú rẹ̀ mọ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí ipò wọn jọ tiẹ̀. Bákan náà, ó máa kẹ́kọ̀ọ́ bó ṣe ń rí i tí àwọn ará ń fìfẹ́ hàn síra wọn lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìjọ. Ẹ kíyè sí àwọn àpẹẹrẹ yìí.
11. Àwọn wo ni akẹ́kọ̀ọ́ kan máa kíyè sí nínú ìjọ, ẹ̀kọ́ wo ló sì lè rí kọ́ lára wọn?
11 Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń dá tọ́mọ lè kíyè sí arábìnrin kan nínú ìjọ tóun náà ń dá tọ́mọ. Ó wú akẹ́kọ̀ọ́ náà lórí bó ṣe ń rí i tí arábìnrin náà ń sapá láti máa kó àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké wá sípàdé. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń sapá láti jáwọ́ nínú sìgá mímú lè bá arákùnrin kan pàdé tó ti nírú ìṣòro yìí rí, àmọ́ tó ti borí ẹ̀. Arákùnrin náà lè ṣàlàyé fún akẹ́kọ̀ọ́ yẹn pé ìfẹ́ tóun ní fún Jèhófà ló mú kóun jáwọ́ nínú àṣà burúkú náà. (2 Kọ́r. 7:1; Fílí. 4:13) Ó lè wá sọ ìrírí ara ẹ̀ fún akẹ́kọ̀ọ́ náà, kó sì fi dáa lójú pé “Ìwọ náà lè jáwọ́.” Èyí á fún akẹ́kọ̀ọ́ náà níṣìírí, á sì jẹ́ kó dáa lójú pé lóòótọ́ lòun lè jáwọ́ nínú àṣà burúkú náà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ kíyè sí arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́, ó sì rí i pé ó ń láyọ̀ torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Torí náà, ó sún mọ́ arábìnrin yẹn kó lè mọ ohun tó ń fún un láyọ̀.
12. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí?
12 Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ará tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn Jòh. 13:35; 1 Tím. 4:12) Bá a ṣe sọ ṣáájú, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ará tó ti dojú kọ irú àwọn ìṣòro tóun náà ní báyìí. Àpẹẹrẹ àwọn ará yẹn máa jẹ́ kóun náà mọ̀ pé òun á lè ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ láti di ọmọlẹ́yìn Kristi. (Diu. 30:11) Ó ṣe kedere nígbà náà pé gbogbo wa pátá la lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Mát. 5:16) Ìbéèrè náà ni pé kí ni ìwọ ń ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?
nípa bá a ṣe lè pa àṣẹ Jésù mọ́ tó ní ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. (RAN ÀWỌN ALÁÌṢIṢẸ́MỌ́ LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ PA DÀ MÁA WÀÁSÙ
13-14. Kí ni Jésù ṣe fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì?
13 Ó yẹ ká ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ kí wọ́n lè pa dà máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn bí Jésù ṣe pa láṣẹ. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí Jésù ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ nígbà tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì.
14 Nígbà tí Jésù ń parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tó sì kù díẹ̀ kí wọ́n pa á, “gbogbo [àwọn àpọ́sítélì rẹ̀] fi í sílẹ̀, wọ́n sì sá lọ.” (Máàkù 14:50; Jòh. 16:32) Kí ni Jésù ṣe fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lásìkò tí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì? Kété lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó sọ fún àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi [pé mo ti jíǹde].” (Mát. 28:10a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àpọ́sítélì náà fi Jésù sílẹ̀, Jésù ò pa wọ́n tì. Kódà, ó pè wọ́n ní “awọn arákùnrin mi.” Bíi ti Jèhófà, aláàánú ni Jésù, ó sì máa ń dárí jini.—2 Ọba 13:23.
15. Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ ṣe máa ń rí lára wa?
15 Bíi ti Jésù, ọ̀rọ̀ àwon tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́ máa ń jẹ wá lọ́kàn. Ó ṣe tán, arákùnrin àti arábìnrin wa ni wọ́n, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an. A ṣì ń rántí iṣẹ́ takuntakun táwọn ará wa ọ̀wọ́n yìí ti ṣe sẹ́yìn fún Jèhófà. Kódà, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn kan fi ṣe bẹ́ẹ̀. (Héb. 6:10) Àárò wọn ń sọ wá gan-an! (Lúùkù 15:4-7) Bíi ti Jésù, kí la lè ṣe láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an?
16. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó ti di aláìṣisẹ́mọ́?
16 Gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n wá sípàdé. Ọ̀nà kan tí Jésù gbà fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tó rẹ̀wẹ̀sì níṣìírí ni pé ó pè wọ́n wá sí ìpàdé kan. (Mát. 28:10b; 1 Kọ́r. 15:6) Lọ́nà kan náà, a lè gba ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ níyànjú pé kó máa wá sípàdé, ìyẹn tí kò bá tíì máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ká fi sọ́kàn pé ó lè ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tá a máa kàn sí wọn kó tó di pé wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Kò sí àní-àní pé inú Jésù dùn gan-an nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wá sí ìpàdé tó pè.—Fi wé Mátíù 28:16 àti Lúùkù 15:6.
17. Kí la máa ṣe tí ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ bá wá sípàdé?
17 Kí wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Jésù mára tu àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tí wọ́n dé, kódà, òun ló kọ́kọ́ bá wọn sọ̀rọ̀. (Mát. 28:18) Kí làwa náà máa ṣe tí ẹnì kan tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ bá wá sípàdé? Ṣe ló yẹ ká lọ bá a ká sì fi ọ̀yàyà kí i káàbọ̀. Ó lè kọ́kọ́ ṣe wá bíi pé a ò mọ ohun tá a máa sọ. Dípò tá a máa fi ṣe ohun to máa kó ìtìjú bá a, á dáa ká jẹ́ kó mọ̀ pé inú wa dùn láti rí i.
18. Kí la lè ṣe láti fi àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ lọ́kàn balẹ̀?
18 Ṣe ohun táá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ronú pé àwọn ò ní lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fáwọn pé káwọn wàásù dé gbogbo ayé. Àmọ́ Jésù fi wọ́n Mát. 28:20) Ṣé ohun tí Jésù sọ fún wọn yẹn fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Kò pẹ́ sígbà yẹn, Bíbélì ròyìn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń “kọ́ni láìdabọ̀, wọ́n sì ń kéde ìhin rere.” (Ìṣe 5:42) Àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ náà nílò ìṣírí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀rù lè máa bà wọ́n láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pa dà. A lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìgbàkigbà tí wọ́n bá ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pa dà, a máa bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Ó dájú pé wọ́n máa mọyì ìtìlẹ́yìn wa nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pa dà. Tá a bá fi hàn lọ́rọ̀ àti níṣe pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́, èyí lè mú kí wọ́n pa dà sí í lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, inú gbogbo ìjọ á sì dùn.
lọ́kàn balẹ̀ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́.” (Ó YẸ KÁ PARÍ IṢẸ́ TÍ JÉSÙ GBÉ FÚN WA
19. Kí la pinnu pé a máa ṣe, kí sì nìdí?
19 Títí dìgbà wo la fi máa ṣe iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn? Títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan. (Mát. 28:20; wo Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, “Ìparí ètò àwọn nǹkan.”) Ṣé àá lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó títí dìgbà yẹn? Ohun tá a pinnu láti ṣe nìyẹn! Tayọ̀tayọ̀ la fi ń lo àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa láti wá “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni pé kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tó rán mi, kí n sì parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:34; 17:4) Ohun tí àwa náà pinnu láti ṣe nìyẹn. A ti pinnu láti parí iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa. (Jòh. 20:21) A sì fẹ́ kí àwọn míì dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ yìí títí kan àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́, ká sì jọ fara dà á títí dópin.—Mát. 24:13.
20. Kí ni Fílípì 4:13 sọ tó fi hàn pé a lè parí iṣẹ́ tí Jésù pa láṣẹ fún wa?
20 Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún wa yìí, àmọ́ àwa nìkan kọ́ la máa ṣiṣẹ́ náà. Jésù ṣèlérí pé òun máa wà pẹ̀lú wa. Bíbélì sọ pé a jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run,” a sì ń bá Kristi ṣiṣẹ́ bá a ṣe ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. (1 Kọ́r. 3:9; 2 Kọ́r. 2:17) Torí náà, a lè ṣe iṣẹ́ yìí ní àṣeyọrí. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún wa ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ yìí, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!—Ka Fílípì 4:13.
ORIN 79 Kọ́ Wọn Kí Wọ́n Lè Dúró Gbọn-in
^ ìpínrọ̀ 5 Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì kọ́ wọn láti máa pa gbogbo àṣẹ òun mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù. Inú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2004, ojú ìwé 14-19 la ti mú díẹ̀ lára àwọn àlàyé tá a ṣe nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 66 ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń ṣàlàyé ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ lè ṣe kó lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Nígbà tó yá, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà fi àwọn àbá mẹ́ta tí arábìnrin náà fún un sílò.