Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Mú Ká Wà Létòletò
“Ọgbọ́n ni Jèhófà fúnra rẹ̀ fi fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ìfòyemọ̀ ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—ÒWE 3:19.
ORIN: 105, 107
1, 2. (a) Kí làwọn kan máa ń sọ tá a bá sọ pé Ọlọ́run ní ètò tó fi ń darí wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ṢÉ Ọlọ́run ní ètò kan tó fi ń darí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? Àwọn kan máa ń sọ pé: “Ẹ ò nílò ètò kankan táá máa darí yín. Téèyàn bá ṣáà ti mọ Ọlọ́run, kí ló tún kù.” Ṣé èrò yìí tọ̀nà? Kí la lè rí kọ́ látinú ìṣẹ̀dá àtàwọn nǹkan míì tí Ọlọ́run ṣe?
2 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Olùṣètò tí kò láfiwé ni Jèhófà. A tún máa jíròrò ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá rí ìtọ́ni gbà látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 14:33, 40) Torí pé àwọn Kristẹni ayé ọjọ́hun àtàwa tòde òní ń tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti wàásù ìhìn rere kárí ayé. Yàtọ̀ síyẹn, à ń gbádùn àlááfíà àti ìṣọ̀kan, ìjọ sì wà ní mímọ́ torí pé a rọ̀ mọ́ ìlànà Bíbélì, à sì ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa.
OLÙṢÈTÒ TÍ KÒ LÁFIWÉ NI JÈHÓFÀ
3. Kí ló mú kó o gbà pé Olùṣètò tí kò láfiwé ni Jèhófà?
3 Àwọn nǹkan tí Jèhófà Ọlọ́run dá jẹ́ ká mọ̀ pé Olùṣètò tí kò láfiwé ni. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n ni Jèhófà fúnra rẹ̀ fi fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀. Ìfòyemọ̀ ni ó fi fìdí ọ̀run múlẹ̀ gbọn-in Òwe 3:19) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, bíńtín la tíì mọ̀ nípa Ọlọ́run, kódà ‘àhegbọ́ lásán ṣì ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’ (Jóòbù 26:14) Síbẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ tá a mọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀, àwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì jẹ́ ká rí i pé àwọn nǹkan yìí wà létòletò. (Sm. 8:3, 4) Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, gbogbo wọn ń yípo lọ́nà tó wà létòletò, láìgbún ara wọn. Bákan náà, ayé yìí àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì míì ń yípo oòrùn lọ́nà tó wà létòletò. Gbogbo nǹkan àgbàyanu yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà “fi òye ṣẹ̀dá ọ̀run,” torí náà òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn ká sì máa yìn.—Sm. 136:1, 5-9.
gbọn-in.” (4. Kí nìdí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò fi lè dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ṣe pàtàkì?
4 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti jẹ́ ká mọ̀ nípa àgbáálá ayé wa, àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàwárí sì ti ṣe wá láǹfààní gan-an. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìbéèrè làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò lè dáhùn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn onímọ̀ nípa sánmà ò lè sọ bí àgbáálá ayé yìí ṣe wà tàbí ìdí tó fi jẹ́ pé orí ilẹ̀ ayé là ń gbé tí kì í ṣe ibòmíì. Bákan náà, àwọn èèyàn kárí ayé ò lè sọ ìdí tó fi máa ń wù wá pé ká máa wà láàyè nìṣó. (Oníw. 3:11) Àmọ́, kí nìdí tí wọn ò fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì yìí? Ọ̀kan lára ohun tó fà á ni pé ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì kò fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Ọlọ́run wà, ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ni wọ́n ń gbé lárugẹ. Àmọ́, Jèhófà ti fi Bíbélì dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn níbi gbogbo.
5. Báwo làwọn òfin ìṣẹ̀dá ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
5 Gbogbo wa là ń jàǹfààní àwọn òfin ìṣẹ̀dá tí kì í yí pa dà tí Jèhófà gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná, àwọn awakọ̀ òfuurufú, àwọn púlọ́ńbà, àwọn ẹnjiníà àtàwọn dókítà máa ń jàǹfààní àwọn òfin yìí kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ táwọn dókítà bá fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún ẹnì kan, wọn ò ní ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá ibi tí ọkàn onítọ̀hún wà kí wọ́n tó ṣiṣẹ́ torí wọ́n mọ̀ pé ibì kan náà ni ọkàn gbogbo èèyàn máa ń wà. Bákan náà, a kì í fojú di àwọn òfin ìṣẹ̀dá. Bí àpẹẹrẹ tẹ́nì kan bá fojú di òfin òòfà, tó wá lọ bẹ́ látorí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan, ó lè gbabẹ̀ kú.
ÀWỌN NǸKAN TÍ ỌLỌ́RUN ṢÈTÒ
6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ wà létòletò?
6 Gbogbo ohun tí Jèhófà dá ló wà létòletò. Torí náà, ó dájú pé Jèhófà máa fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ náà wà létòletò. Ìdí nìyẹn tó fi fún wa ní Bíbélì kó lè máa tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, tá a sì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa, a máa láyọ̀, ìgbésí ayé wa á sì nítumọ̀.
7. Kí ló fi hàn pé ìwé tó wà létòletò ni Bíbélì?
7 Ìwé tó wà létòletò ni Bíbélì, ó sì dájú pé ó ní ìmísí Ọlọ́run. Kì í kàn ṣe ìwé táwọn Júù àtàwọn Kristẹni kó jọ. Gbogbo ìwé tó wà nínú Bíbélì pátápátá ló so kọ́ra. Ohun kan náà ni gbogbo ẹ̀ dá lé láti Jẹ́nẹ́sísì dé Ìṣípayá. Ohun tó dá lé ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Bákan náà, ó tún sọ bí Jèhófà ṣe máa lo Ìjọba rẹ̀ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. Jésù Kristi tó jẹ́ “irú-ọmọ” tá a ṣèlérí ló sì máa jẹ́ ọba Ìjọba náà.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:15; Mátíù 6:10; Ìṣípayá 11:15.
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà létòletò?
8 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà wà létòletò. Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ìránṣẹ́bìnrin kan wà “tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn àfètòṣe ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” (Ẹ́kís. 38:8) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fẹ́ ṣí kúrò níbi tí wọ́n pàgọ́ sí lọ sí ibòmíì, tàbí tí wọ́n bá fẹ́ gbé àgọ́ ìjọsìn, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó wà létòletò. Nígbà tó yá, Dáfídì Ọba ṣètò àwọn ọmọ Léfì àtàwọn àlùfáà sí àwùjọ àwùjọ kí iṣẹ́ wọn lè máa wà létòletò. (1 Kíró. 23:1-6; 24:1-3) Gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ṣègbọràn, Jèhófà máa ń mú kí wọ́n wà létòletò, kí àlááfíà jọba láàárín wọn, kí wọ́n sì tún wà níṣọ̀kan.—Diu. 11:26, 27; 28:1-14.
9. Kí ló fi hàn pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní wà létòletò?
9 Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà wà létòletò, wọ́n sì jàǹfààní látinú àwọn ìtọ́ni tí ìgbìmọ̀ olùdarí ń fún wọn. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn àpọ́sítélì nìkan ló para pọ̀ jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí. (Ìṣe 6:1-6) Nígbà tó yá, wọ́n fi àwọn arákùnrin míì kún ìgbìmọ̀ olùdarí náà. (Ìṣe 15:6) Nígbà yẹn, ìgbìmọ̀ olùdarí tàbí àwọn míì tó bá wọn ṣiṣẹ́ máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn ìjọ kí wọ́n lè fún àwọn ará láwọn ìtọ́ni tí wọ́n nílò. (1 Tím. 3: 1-13; Títù 1:5-9) Àǹfààní wo ni ìjọ rí nígbà tí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí?
10. Àǹfààní wo ni àwọn Kristẹni ìgbàanì rí nígbà tí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ olùdarí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
10 Ka Ìṣe 16:4, 5. Àwọn arákùnrin tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán jáde máa ń fi “àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí” ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ. Bí àwọn ará ṣe ń pa àwọn àṣẹ yìí mọ́, ńṣe ni “àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.” Ẹ̀kọ́ wo ni àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí kọ́ wa tó bá dọ̀rọ̀ ọwọ́ tó yẹ ká fi mú àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run ń fún wa lónìí?
ṢÉ O MÁA Ń TẸ̀ LÉ ÌTỌ́NI?
11. Kí ló yẹ káwọn tó ń múpò iwájú ṣe tí wọ́n bá gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run?
11 Lónìí, tí àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka tàbí Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè, àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà bá gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ètò Ọlọ́run, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn ká sì máa tẹrí ba. (Diu. 30:16; Héb. 13:7, 17) Nínú ètò Ọlọ́run, kò yẹ ká máa ṣe tinú wa tàbí ká máa ṣàríwísí torí irú ìwà bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ìfẹ́ àti àlàáfíà wà nínú ìjọ, ó sì máa ń dá ìyapa sílẹ̀. Ó dájú pé kò sí ẹnì kankan táá fẹ́ fìwà jọ Dìótíréfè tó ń sọ̀rọ̀ burúkú nípa àwọn tó ń múpò iwájú tí kì í sì í bọ̀wọ̀ fún wọn. (Ka 3 Jòhánù 9, 10.) A lè bi ara wa pé: ‘Ṣé mo máa ń fún àwọn míì níṣìírí láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ètò Ọlọ́run bá fún wa? Ṣé mo máa ń tètè gba ìtọ́ni táwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú fún wa, ṣé mo sì máa ń tì wọ́n lẹ́yìn?’
12. Àtúnṣe wo ni ètò Ọlọ́run ṣe sí bí a ṣe ń yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ?
12 Ẹ jẹ́ ká wo àtúnṣe kan tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe láìpẹ́ yìí. Nínú “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 2014, ètò Ọlọ́run ṣe àtúnṣe sí bí a ṣe ń yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Àpilẹ̀kọ yẹn sọ pé ìgbìmọ̀ olùdarí ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fún àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò láṣẹ láti máa yan àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ. Torí náà, láti September 1, 2014, àwọn alábòójútó àyíká ló ń yan àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Alábòójútó àyíká tó ń bẹ ìjọ wò máa gbìyànjú láti mọ àwọn arákùnrin tí wọ́n fẹ́ yàn sípò, á sì bá wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tó bá ṣeé ṣe. Alábòójútó àyíká tún máa wo bí ìdílé àwọn arákùnrin náà ṣe ń ṣe sí. (1 Tím. 3:4, 5) Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà àti alábòójútó àyíká máa wá jọ ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ ní kí wọ́n kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ láti di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.—1 Tím. 3:1-10, 12, 13; 1 Pét. 5:1-3.
13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni táwọn alàgbà ń fún wa?
13 A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́ni táwọn alàgbà ń fún wa látinú Bíbélì. Àwọn ìlànà “afúnni-nílera” tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn alàgbà olóòótọ́ yìí ń tẹ̀ lé. (1 Tím. 6:3) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa nípa àwọn tó ń ṣe ségesège nínú ìjọ. Nígbà yẹn, àwọn kan ò ṣiṣẹ́ rárá nínú ìjọ, ṣe ni “wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.” Ó dájú pé àwọn alàgbà ti máa fún wọn ní ìmọ̀ràn, àmọ́ wọn ò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá ní kí wọ́n ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀? Ó ní: ‘Ẹ sàmì sí ẹni yìí, kí ẹ sì dẹ́kun bíbá a kẹ́gbẹ́.’ Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò sọ pé ká sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di ọ̀tá. (2 Tẹs. 3:11-15) Lónìí, àwọn alàgbà lè pinnu pé á dáa káwọn sọ àsọyé kan láti kìlọ̀ fún ìjọ nípa ìwà tẹ́nì kan ń hù, tí irú ìwà bẹ́ẹ̀ sì lè ran àwọn ẹlòmíì nínú ìjọ. Ó lè jẹ́ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fẹ́ ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (1 Kọ́r. 7:39) Táwọn alàgbà bá sọ irú àsọyé yìí, báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ? Ká sọ pé o mọ ẹni tí ọ̀rọ̀ yẹn ń bá wí, ṣé wàá ṣì máa bá ẹni náà ṣe wọléwọ̀de? Tó o bá yẹra fún un, òun náà á mọ̀ pé inú Jèhófà ò dùn sí ohun tóun ń ṣe, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ yí pa dà. [1]
JẸ́ KÍ ÌJỌ WÀ NÍ MÍMỌ́, KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ NÍBẸ̀ KÓ SÌ WÀ NÍṢỌ̀KAN
14. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́?
14 Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń fi hàn pé a fẹ́ kí ìjọ wà ní mímọ́. Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Kọ́ríńtì nígbà yẹn. Pọ́ọ̀lù fi ìtara wàásù níbẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn “ẹni mímọ́” bíi tiẹ̀ tó wà níbẹ̀. (1 Kọ́r. 1:1, 2) Ó dájú pé kò ní rọrùn fún un láti yanjú ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tí wọ́n fàyè gbà nínú ìjọ yẹn. Pọ́ọ̀lù sọ pé káwọn alàgbà fa ọkùnrin oníṣekúṣe náà lé Sátánì lọ́wọ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Kí ìjọ lè wà ní mímọ́, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ mú oníwà àìtọ́ náà kúrò láàárín wọn torí ó lè kó bá àwọn míì tó wà nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:1, 5-7, 12) Tí ẹnì kan bá hùwà àìtọ́, tí kò sì ronú pìwà dà, táwọn alàgbà bá yọ ẹni náà lẹ́gbẹ́, ó yẹ ká fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n ṣe. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìjọ á wà ní mímọ́, ẹni náà sì lè wá yí pa dà kó sì tọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Jèhófà.
15. Báwo la ṣe lè pa kún àlàáfíà tó wà nínú ìjọ?
15 Ìṣòro míì tún wà nínú ìjọ Kọ́ríńtì tí Pọ́ọ̀lù gbọ́dọ̀ bójú tó. Àwọn arákùnrin kan ń gbé àwọn ará bíi tiwọn lọ sílé ẹjọ́. Pọ́ọ̀lù wá bi wọ́n pé: “Èé ṣe tí ẹ kò kúkú jẹ́ kí a ṣe àìtọ́ sí ẹ̀yin fúnra yín?” (1 Kọ́r. 6:1-8) Irú ẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ lónìí. Nígbà míì, táwọn ará bá dòwò pọ̀, nǹkan lè dojú rú kí wọ́n sì wọko gbèsè. Ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa fẹ̀sùn olè kan ara wọn. Àwọn ará kan ti gbé àwọn arákùnrin wọn lọ sílé ẹjọ, àmọ́ Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé ó sàn kí wọ́n rẹ́ wa jẹ ju ká mú àbàwọ́n bá orúkọ Ọlọ́run lọ tàbí ká dá ìyapa sílẹ̀ nínú ìjọ. [2] Tá a bá fẹ́ yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó le gan-an pàápàá, ìmọ̀ràn Jésù ló yẹ ká fi sílò. (Ka Mátíù 5:23, 24; 18:15-17.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà.
16. Kí nìdí táwa èèyàn Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan?
16 Bíbélì sọ ìdí táwa èèyàn Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ wà níṣọ̀kan. Onísáàmù kan sọ Sm. 133:1) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà létòletò, wọ́n sì wà níṣọ̀kan ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń ṣègbọràn sí Jèhófà. Nígbà tí Jèhófà ń sọ bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe máa wà níṣọ̀kan lọ́jọ́ iwájú, ó sọ pé: “Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran.” (Míkà 2:12) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún lo wòlíì Sefanáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè mímọ́ gaara [ìyẹn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run], kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà, kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sef. 3:9) Inú wa mà dùn o, pé a láǹfààní láti máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan!
pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!” (17. Tí ìjọ bá máa wà ní mímọ́ tó sì tún máa wà níṣọ̀kan, báwo ló ṣe yẹ káwọn alàgbà máa bójú tó ìwà àìtọ́?
17 Kí ìjọ lè wà ní mímọ́ kó sì wà níṣọ̀kan, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ tètè máa bójú tó ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìwà àìtọ́, kí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa lóòótọ́, síbẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ó máa ń gbójú fo ìwà àìtọ́. (Òwe 15:3) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ ìwé Kọ́ríńtì Kìíní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ ló sún Pọ́ọ̀lù láti kọ ìwé yìí, síbẹ̀ ó sojú abẹ níkòó. Lóṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Kọ́ríńtì Kejì, ìwé náà sì fi hàn pé àwọn ará ní Kọ́ríńtì ti ń ṣàtúnṣe torí pé àwọn alàgbà tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fún wọn. Torí náà, bí ẹnì kan bá ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nípa rẹ̀, kí àwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí tọ́ ẹni náà sọ́nà pẹ̀lú ìwà tútù.—Gál. 6:1.
18. (a) Báwo ni ìtọ́ni látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ́wọ́? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Ó ṣe kedere pé ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ran àwọn ará Kọ́ríńtì àtàwọn míì lọ́wọ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n fi sílò mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan, kí àlàáfíà wà, kí ìjọ sì wà ní mímọ́. (1 Kọ́r. 1:10; Éfé. 4:11-13; 1 Pét. 3:8) Torí pé àwọn ará yẹn ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń rí gbà, wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù láṣeyọrí. Wọ́n wàásù débi tí Pọ́ọ̀lù pàápàá fi sọ pé wọ́n ti wàásù fún “gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kól. 1:23) Bákan náà lónìí, àwa èèyàn Ọlọ́run tá a wà nínú ètò tó wà níṣọ̀kan ń wàásù kárí ayé nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáráyé. Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a tún máa rí àwọn ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń fọwọ́ pàtàkì mú Bíbélì, wọ́n sì ń bọlá fún Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.—Sm. 71:15, 16.
^ [1] (ìpínrọ̀ 13) Wo A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 134 sí 136.
^ [2] (ìpínrọ̀ 15) Tó o bá fẹ́ mọ àwọn nǹkan tó lè mú kí Kristẹni kan gbé Kristẹni míì lọ sílé ẹjọ́, wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà nínú ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ojú ìwé 223.