ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19
ORIN 22 Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!
Kí La Mọ̀ Nípa Bí Jèhófà Ṣe Máa Ṣèdájọ́ Lọ́jọ́ Iwájú?
“Jèhófà . . . kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.”—2 PÉT. 3:9.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ó dá wa lójú pé lọ́jọ́ iwájú, Jèhófà máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.
1. Kí nìdí tá a fi sọ pé àkókò táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ la wà yìí?
ÀKÓKÒ tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ la wà yìí! Ojoojúmọ́ la sì ń rí báwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ń ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù” ń bá ara wọn jà torí pé àwọn méjèèjì fẹ́ ṣàkóso ayé. (Dán. 11:40, àlàyé ìsàlẹ̀) Yàtọ̀ síyẹn, à ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló sì ń ṣe àwọn àyípadà tó yẹ kí wọ́n lè sin Jèhófà. (Àìsá. 60:22; Mát. 24:14) Bákan náà, à ń rí onírúurú ìwé àti fídíò tó dá lórí Bíbélì gbà “ní àkókò tó yẹ.”—Mát. 24:45-47.
2. Kí ló dá wa lójú, àmọ́ kí ló yẹ ká máa rántí?
2 Jèhófà ò fi wá sílẹ̀, ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ lóye àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú. (Òwe 4:18; Dán. 2:28) Torí náà, ó dá wa lójú pé tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, àá ti mọ gbogbo nǹkan tó yẹ ká mọ̀ táá jẹ́ ká fara dà á, táá sì jẹ́ ká túbọ̀ wà níṣọ̀kan lásìkò tí nǹkan máa le gan-an yẹn. Àmọ́ o, ó yẹ ká máa rántí pé àwọn nǹkan kan wà tá ò mọ̀ nípa ọjọ́ iwájú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kọ́kọ́ jíròrò ìdí tá a fi ṣàtúnṣe ohun tá a ti sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú. Lẹ́yìn ìyẹn, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a mọ̀ tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú àtohun tí Baba wa ọ̀run máa ṣe.
ÀWỌN NǸKAN TÁ Ò MỌ̀
3. Àlàyé wo la ṣe tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà táwọn èèyàn ò ní láǹfààní mọ́ láti wá sin Jèhófà, kí sì nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
3 Àlàyé tá a ṣe tẹ́lẹ̀ ni pé tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn ò ní láǹfààní mọ́ láti wá sin Jèhófà, wọn ò sì ní la Amágẹ́dọ́nì já. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Òye tá a ní tẹ́lẹ̀ ni pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi Nóà ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, ohun tá a rò ni pé bí Jèhófà ṣe ti ọkọ̀ áàkì nígbà Ìkún Omi tí kò sì sẹ́ni tó lè wọlé mọ́, bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn ò ní láǹfààní mọ́ láti wá sin Jèhófà tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí wọ́n rí ìgbàlà.—Mát. 24:37-39.
4. Ṣé ó yẹ ká ṣì máa wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi pé ó ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣàlàyé.
4 Ṣé ó yẹ ká ṣì máa wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi pé ó ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Rárá o. Kí ló jẹ́ ká sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé kò sí ẹsẹ Bíbélì kan pàtó tó sọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. a Òótọ́ ni pé Jésù fi “àwọn ọjọ́ Nóà” wé ìgbà tóun máa wà níhìn-ín, àmọ́ kò sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé bí Jèhófà ṣe ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ Nóà nígbà yẹn ṣàpẹẹrẹ nǹkan kan. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé a ò lè rí nǹkan kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìkún Omi ọjọ́ Nóà.
5. (a) Àwọn nǹkan wo ni Nóà ṣe kí Ìkún Omi tó dé? (Hébérù 11:7; 1 Pétérù 3:20) (b) Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tí Nóà ṣe nígbà ayé ẹ̀ ṣe jọ èyí tá à ń ṣe lónìí?
5 Nígbà tí Jèhófà sọ fún Nóà pé òun máa fi Ìkún Omi pa ayé run, ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kan ọkọ̀ áàkì. (Ka Hébérù 11:7; 1 Pétérù 3:20.) Lọ́nà kan náà, àwọn èèyàn tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run lásìkò wa yìí gbọ́dọ̀ ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. (Ìṣe 3:17-20) Pétérù pe Nóà ní “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Àmọ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Bíbélì ò sọ pé gbogbo èèyàn ni Nóà wàásù fún kí Ìkún Omi tó dé. Bákan náà lónìí, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè wàásù fáwọn èèyàn kárí ayé, a sì ń fìtara ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́ kò sí bá a ṣe sapá tó, a ò ní lè wàásù ìhìn rere náà fún gbogbo èèyàn tó wà láyé kí òpin tó dé. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
6-7. Kí nìdí tá a fi sọ pé a ò ní lè wàásù fún gbogbo èèyàn tó wà láyé kí òpin tó dé?
6 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Ó sọ pé a máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) Àsìkò tá a wà yìí gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń ṣẹ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, ètò Ọlọ́run ti ṣe àwọn ìwé tá a fi ń wàásù, wọ́n sì wà ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún (1,000) lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìkànnì jw.org ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn láyé gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
7 Àmọ́, Jésù tún sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé wọn ò ní lè “lọ yí ká àwọn ìlú Ísírẹ́lì tán” tàbí kí wọ́n wàásù fún gbogbo èèyàn kóun tó dé. (Mát. 10:23; 25:31-33) Ó dájú pé ohun tí Jésù sọ yìí máa ṣẹ lásìkò tiwa náà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń gbé lágbègbè tá ò ti lómìnira láti wàásù. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ọmọ làwọn èèyàn ń bí lójoojúmọ́. Ká sòótọ́, à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wàásù ìhìn rere náà fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.” (Ìfi. 14:6) Àmọ́, kò sí bá a ṣe lè wàásù fún gbogbo èèyàn tó wà láyé kí òpin tó dé.
8. Ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe ká bi ara wa nípa bí Jèhófà ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn lọ́jọ́ iwájú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
8 Àwọn nǹkan tá a ti sọ yìí lè mú ká bi ara wa pé: Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀? Báwo ni Jèhófà àti Ọmọ ẹ̀ tó yàn láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ṣe máa dá wọn lẹ́jọ́? (Jòh. 5:19, 22, 27; Ìṣe 17:31) Ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé sọ pé Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fẹ́ ni pé kí “gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.” (2 Pét. 3:9; 1 Tím. 2:4) A mọ̀ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ nìyẹn, ṣùgbọ́n a ò tíì mọ bó ṣe máa ṣèdájọ́ àwọn èèyàn tí ò láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a ò lè fipá mú Jèhófà kó sọ àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wa.
9. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti jẹ́ ká mọ̀ nínú Bíbélì?
9 Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tóun máa ṣe fún wa nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà máa jí àwọn “aláìṣòdodo” dìde, ìyẹn àwọn tí ò láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn pa dà. (Ìṣe 24:15; Lúùkù 23:42, 43) Ohun tá a mọ̀ yìí tún jẹ́ ká bi ara wa láwọn ìbéèrè kan.
10. Àwọn ìbéèrè míì wo la máa dáhùn?
10 Ṣé gbogbo àwọn tó bá kú nígbà ìpọ́njú ńlá ni ò ní jíǹde? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn alátakò tí Jèhófà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ máa pa run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì ò ní jíǹde. (2 Tẹs. 1:6-10) Àmọ́ nígbà ìpọ́njú ńlá, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tí àìsàn àti jàǹbá ọkọ̀ pa, títí kan àwọn tí èèyàn pa? (Oníw. 9:11; Sek. ) Ṣé wọ́n máa wà lára àwọn “aláìṣòdodo” tí Jèhófà máa jí dìde nínú ayé tuntun? A ò mọ̀. 14:13
ÀWỌN NǸKAN TÁ A MỌ̀
11. Kí ni Jèhófà máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì?
11 A mọ àwọn nǹkan kan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́, ohun tó máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn ni bí wọ́n ṣe ran àwọn arákùnrin òun lọ́wọ́, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró. (Mát. 25:40) Àwọn tó bá ran àwọn ẹni àmì òróró àti Kristi lọ́wọ́ ni Jésù máa pè ní àgùntàn. Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró ṣì máa wà láyé lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀ àti pé tó bá kù díẹ̀ kí ogun Amágẹ́dọ́nì bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n máa lọ sọ́run. Táwọn arákùnrin Kristi bá ṣì wà láyé, ó ṣeé ṣe káwọn kan ṣì wá sin Jèhófà nígbà yẹn, kí wọ́n sì láǹfààní láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. (Mát. 25:31, 32; Ìfi. 12:17) Kí nìdí táwọn nǹkan tá a sọ yìí fi ṣe pàtàkì?
12-13. Kí ló ṣeé ṣe káwọn kan ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá rí i pé “Bábílónì Ńlá” ti pa run? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Kódà lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe káwọn kan tí wọ́n rí i pé “Bábílónì Ńlá” ti pa run rántí pé ó ti pẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń sọ pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ṣé ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn tó rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà yí pa dà, kí wọ́n sì wá sin Jèhófà?—Ìfi. 17:5; Ìsík. 33:33.
13 Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní yà wá lẹ́nu torí pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní Íjíbítì nígbà ayé Mósè. Ṣé ẹ rántí pé “oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ” ló tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì? (Ẹ́kís. 12:38) Mósè ti kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà tẹ́lẹ̀ pé Ìyọnu Mẹ́wàá ń bọ̀, torí náà ó ṣeé ṣe káwọn kan lára àwọn èèyàn yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í nígbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà tí wọ́n rí i pé ohun tó sọ ṣẹ. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ lásìkò wa yìí lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ṣé a ò ní sọ pé kò dáa torí pé àwọn tí kò mọ Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wá dara pọ̀ mọ́ wa nígbà tó kù díẹ̀ kí òpin dé? Kò yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀! Ìdí ni pé ó yẹ ká fara wé Jèhófà tó jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” b—Ẹ́kís. 34:6.
14-15. Ṣé ìgbà tẹ́nì kan kú tàbí ibi tó ń gbé ló máa pinnu bóyá onítọ̀hún máa wà láàyè títí láé? Ṣàlàyé. (Sáàmù 33:4, 5)
14 Nígbà míì, arákùnrin tàbí arábìnrin kan lè sọ pé: “Á dáa kí mọ̀lẹ́bí mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kú kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀ torí Jèhófà ṣì lè jí i dìde.” Kò burú tá a bá nírú èrò yẹn. Àmọ́, kì í ṣe ìgbà tẹ́nì kan kú ló máa pinnu bóyá onítọ̀hún máa wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. A mọ̀ pé Onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà, ó sì máa ń dájọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Ka Sáàmù 33:4, 5.) Torí náà, ó dá wa lójú pé “Onídàájọ́ gbogbo ayé” máa ṣe ohun tó tọ́.—Jẹ́n. 18:25.
15 Ó bọ́gbọ́n mu tá a bá sọ pé kì í ṣe ibi tẹ́nì kan ń gbé ló máa pinnu bóyá onítọ̀hún máa wà láàyè títí láé lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, Jèhófà ò ní pe ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ní “ewúrẹ́” torí pé wọ́n ń gbé níbi tí wọn ò ti láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 25:46) Jèhófà Onídàájọ́ gbogbo ayé nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn yìí ju bá a ṣe rò lọ, ó sì máa gba tiwọn rò. A ò mọ ohun tí Jèhófà máa ṣe láti yí àwọn nǹkan kan pa dà nígbà ìpọ́njú ńlá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan táwọn èèyàn yìí bá ń rí tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá lè mú kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ tó bá ń dá orúkọ ẹ̀ láre lójú gbogbo èèyàn.—Ìsík. 38:16.
Lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀, . . . ṣé ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn kan tó rí i pé Bábílónì Ńlá ti pa run yí pa dà, kí wọ́n sì wá sin Jèhófà?
16. Àwọn nǹkan wo la mọ̀ nípa Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí àwa èèyàn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ó jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà, ká lè wà láàyè títí láé. (Jòh. 3:16) Gbogbo wa la sì ti jàǹfààní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa yìí. (Àìsá. 49:15) Ó mọ orúkọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kódà ó mọ̀ wá débi pé tá a bá tiẹ̀ kú, ó lè jí wa dìde torí pé ó mọ bá a ṣe jẹ́ tẹ́lẹ̀ àti bá a ṣe ń hùwà! (Mát. 10:29-31) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Bàbá wa ọ̀run tó nífẹ̀ẹ́ wa máa fàánú hàn sí wa, á sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—Jém. 2:13.
17. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
17 Òye tuntun tá a ní yìí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Kí ló sì ń jẹ́ ká máa fìtara wàásù? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
ORIN 76 Báwo Ló Ṣe Máa Ń Rí Lára Rẹ?
a Kó o lè mọ àlàyé nípa ìdí tá a fi ṣàtúnṣe òye wa lórí ọ̀rọ̀ yìí, wo àpilẹ̀kọ náà “Èyí Ni Ọ̀nà Tí Ìwọ Tẹ́wọ́ Gbà” nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2015, ojú ìwé 7-11.
b Lẹ́yìn tí Bábílónì Ńlá bá pa run, a máa dán gbogbo àwa èèyàn Jèhófà wò nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá gbéjà kò wá. Bákan náà, a máa dán àwọn tó bá dara pọ̀ mọ́ àwa èèyàn Jèhófà wò nígbà yẹn.
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn àwòrán mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yẹn jẹ́ ká rí i pé ìhìn rere tá à ń wàásù kárí ayé lè má dé ọ̀dọ̀ àwọn kan: (1) Torí pé ẹ̀sìn tí obìnrin kan ń ṣe ló pọ̀ jù níbi tó ń gbé, tí ibẹ̀ sì léwu fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù, ìyẹn ò jẹ́ kó lè gbọ́ ìwàásù, (2) tọkọtaya kan ń gbé níbi táwọn olóṣèlú ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn ò jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ ìwàásù àti (3) ọkùnrin kan ń gbé níbi táwọn èèyàn ò lè dé láti wàásù.
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Ọ̀dọ́bìnrin kan tí ò sin Jèhófà mọ́ rántí ohun tó kọ́ pé “Bábílónì Ńlá” máa pa run. Ó pinnu pé òun á pa dà máa sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn òbí òun, ó sì pa dà sílé. Tírú nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, ó yẹ ká fara wé Jèhófà Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, kínú wa sì dùn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ti pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀.