ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 23
Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Yín Dà Bí “Ọwọ́ Iná Jáà”
“Ọwọ́ iná [ìfẹ́] dà bí iná tó ń jó, ọwọ́ iná Jáà.”—ORIN SÓL. 8:6.
ORIN 131 ‘Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀’
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ a
1. Kí ni Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ tòótọ́?
“ỌWỌ́ iná [ìfẹ́] dà bí iná tó ń jó, ọwọ́ iná Jáà. Omi tó ń ru gùdù ò lè paná ìfẹ́, odò kò sì lè gbé e lọ.” b (Orin Sól. 8:6, 7) Ẹ ò rí i pé àwọn ọ̀rọ̀ tó dùn ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe ìfẹ́ tòótọ́! Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí fi àwọn tọkọtaya lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n lè ní ìfẹ́ tòótọ́ síra wọn.
2. Kí ló yẹ káwọn tọkọtaya ṣe kí ìfẹ́ wọn má bàa di tútù?
2 Táwọn tọkọtaya bá máa ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ síra wọn títí láé, ọwọ́ wọn ló wà. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá dáná igi, tá a sì ń koná mọ́ ọn, kò ní kú. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí i tá ò bá koná mọ́ ọn? Ó dájú pé ó máa kú. Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ tó wà láàárín ọkọ àti aya kan á máa lágbára sí i tí wọ́n bá ń koná mọ́ ọn. Àmọ́ nígbà míì, ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn tọkọtaya kan lè má lágbára mọ́ torí ìṣòro ìṣúnná owó, àìsàn tàbí torí pé kò rọrùn fún wọn láti tọ́ àwọn ọmọ wọn. Torí náà, tó o bá ti ṣègbéyàwó, báwo lo ṣe lè mú kí ìfẹ́ tó dà bí “ọwọ́ iná Jáà” máa jó lala láàárín yín? Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tó o lè ṣe kí ìfẹ́ tó wà láàárín yín lè máa lágbára sí i, kẹ́ ẹ sì máa láyọ̀. c
JẸ́ KÍ ÀJỌṢE Ẹ PẸ̀LÚ JÈHÓFÀ TÚBỌ̀ MÁA LÁGBÁRA
3. Tí tọkọtaya kan bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe lè mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn túbọ̀ lágbára? (Oníwàásù 4:12) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
3 Kí “ọwọ́ iná Jáà” tó lè máa jó láàárín yín, ẹ̀yin tọkọtaya gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára. Báwo nìyẹn ṣe máa mú kí ìfẹ́ tó wà láàárín yín túbọ̀ lágbára? Tí tọkọtaya kan bá mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà, á rọrùn fún wọn láti máa fi ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò, wọn ò ní máa ṣe ohun táá fa ìṣòro, tí ìṣòro bá sì dé, wọ́n á ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti borí ẹ̀ kí ìfẹ́ wọn má bàa di tútù. (Ka Oníwàásù 4:12.) Ó yẹ káwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà sapá láti fara wé Jèhófà, kí wọ́n láwọn ìwà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní bí inúure àti sùúrù, kí wọ́n sì máa dárí ji ara wọn. (Éfé. 4:32–5:1) Ó máa rọrùn fáwọn tọkọtaya tó bá ní àwọn ànímọ́ yìí láti fìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn síra wọn. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lena, tó sì ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) sọ pé: “Ó máa ń rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀, kéèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un.”
4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jósẹ́fù àti Màríà ni Jèhófà yàn pé kí wọ́n bí Mèsáyà?
4 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú Bíbélì. Nígbà tí Jèhófà fẹ́ yan àwọn tó máa bí Mèsáyà, Jósẹ́fù àti Màríà ni Jèhófà yàn láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Dáfídì. Kí nìdí? Àwọn méjèèjì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, Jèhófà sì mọ̀ pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òun máa mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn túbọ̀ lágbára. Ẹ̀yin tọkọtaya, kí lẹ lè rí kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà?
5. Kí lẹ̀yin ọkọ lè rí kọ́ lára Jósẹ́fù?
5 Ìgbà gbogbo ni Jósẹ́fù máa ń fi ìmọ̀ràn Jèhófà sílò, ìyẹn ló sì mú kó jẹ́ ọkọ rere. Ó kéré tán, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ ohun tó máa ṣe nípa ìdílé ẹ̀ fún un. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sì máa ń gbé ìgbésẹ̀ kódà nígbà tó ní láti ṣe àwọn àyípadà tó le gan-an. (Mát. 1:20, 24; 2:13-15, 19-21) Torí pé Jósẹ́fù ṣe ohun tí Jèhófà sọ, ó dáàbò bo Màríà, ó ràn án lọ́wọ́, ó sì pèsè àwọn nǹkan tó nílò. Ẹ wo bí àwọn nǹkan tí Jósẹ́fù ṣe yẹn ṣe máa mú kí Màríà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, kó sì bọ̀wọ̀ fún un! Ẹ̀yin ọkọ, ẹ lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù tẹ́ ẹ bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bẹ́ ẹ ṣe máa bójú tó ìdílé yín. d Tó o bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, tó bá tiẹ̀ máa gba pé kó o ṣe àwọn àyípadà kan, wàá fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ, okùn ìfẹ́ yín á sì máa lágbára sí i. Arábìnrin kan láti Vanuatu tó ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé lógún (20) ọdún sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí ọkọ mi bá ní kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà, tó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ ni mo túbọ̀ máa ń bọ̀wọ̀ fún un. Ọkàn mi máa ń balẹ̀, mo sì máa ń fọkàn tán an pé ìpinnu tó dáa ló máa ṣe.”
6. Kí lẹ̀yin aya lè kọ́ lára Màríà?
6 Màríà fúnra ẹ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kì í ṣe torí pé Jósẹ́fù ń sin Jèhófà lòun náà ṣe ń sin Jèhófà. Ó mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Lúùkù 1:46, nwtsty-E) Yàtọ̀ síyẹn, ó tún máa ń wáyè ronú lórí ohun tó kọ́ nípa Jèhófà. (Lúùkù 2:19, 51) Ó dájú pé àjọṣe tó dáa tí Màríà ní pẹ̀lú Jèhófà mú kó jẹ́ aya rere. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn aya ló ń sapá láti ṣe bíi ti Màríà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Emiko sọ pé: “Mo máa ń dá gbàdúrà, mo sì máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo ṣègbéyàwó, ọkọ mi ló máa ń gbàdúrà fún wa tó sì máa ń darí ohunkóhun tá a bá fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn wa, ìyẹn ni ò jẹ́ kí n máa ṣe àwọn nǹkan tí mo máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ mọ́. Mo rí i pé àfi kémi fúnra mi ṣiṣẹ́ kára kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà lè lágbára. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ya àkókò sọ́tọ̀ láti dá gbàdúrà sí Jèhófà, kí n máa ka Bíbélì, kí n sì máa ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tí mo bá kà.” (Gál. 6:5) Torí náà tó o bá jẹ́ aya, tó o sì ń mú kí àjọṣe ẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, ọkọ ẹ á túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ, á sì máa yìn ẹ́.—Òwe 31:30.
7. Kí làwọn tọkọtaya lè kọ́ lára Jósẹ́fù àti Màríà nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀?
7 Jósẹ́fù àti Màríà tún ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà lè túbọ̀ lágbára. Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ nínú ìdílé. (Lúùkù 2:22-24, 41; 4:16) Ìyẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn pàápàá nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ, tí ìdílé wọn sì ń tóbi sí i, síbẹ̀ wọ́n rí i pé àwọn ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa ni wọ́n jẹ́ fún ẹ̀yin tọkọtaya òde òní! Tẹ́ ẹ bá láwọn ọmọ bíi ti Jósẹ́fù àti Màríà, ó lè má rọrùn fún yín láti máa lọ sípàdé tàbí láti máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé. Kódà, ó lè nira gan-an fún ẹ̀yin tọkọtaya láti máa wáyè kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀, kẹ́ ẹ sì jọ máa gbàdúrà. Síbẹ̀, ẹ rántí pé tí ẹ bá ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀, ẹ máa túbọ̀ sún mọ́ ọn, ẹ̀ẹ́ sì túbọ̀ sún mọ́ra yín. Torí náà, ẹ rí i dájú pé ìjọsìn Jèhófà ló gbawájú nínú ìdílé yín.
8. Kí làwọn tọkọtaya tí ìfẹ́ wọn ti ń di tútù lè ṣe kí wọ́n lè jọ máa gbádùn ìjọsìn ìdílé?
8 Tí ìfẹ́ tó wà láàárín ẹ̀yin tọkọtaya bá ti ń di tútù, kí lẹ lè ṣe? Ó lè má rọrùn láti jọ jókòó pé ẹ fẹ́ ṣe ìjọsìn ìdílé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò pọ̀ jù, kó sì jẹ́ nǹkan tẹ́ ẹ jọ gbà pé kẹ́ ẹ fi ṣe ìjọsìn ìdílé yín kẹ́ ẹ lè gbádùn ẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín, á sì máa wù yín láti jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀.
Ẹ MÁA WÀ PA PỌ̀
9. Kí nìdí tó fi yẹ kẹ́yin tọkọtaya máa wà pa pọ̀?
9 Ẹ̀yin tọkọtaya, ẹ lè mú kí iná ìfẹ́ tó wà láàárín yín máa jó lala tẹ́ ẹ bá ń lo àkókò yín pa pọ̀. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní jìnnà síra yín, á sì rọrùn fún yín láti mọ ohun tí ọkọ tàbí aya yín ń rò àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ̀. (Jẹ́n. 2:24) Ẹ gbọ́ ohun tí Lilia àti Ruslan kíyè sí lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó ní ohun tó ju ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ. Lilia sọ pé: “A rí i pé kò ṣeé ṣe fún wa láti lo àkókò pa pọ̀ tó bá a ṣe rò. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti iṣẹ́ ilé máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò wa, ọwọ́ wa sì tún máa ń dí gan-an nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. A wá rí i pé àfi ká wá nǹkan ṣe ká lè máa wà pa pọ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àá bẹ̀rẹ̀ sí í jìnnà síra wa.”
10. Báwo lẹ̀yin tọkọtaya ṣe lè máa fi ìlànà tó wà nínú Éfésù 5:15, 16 sílò?
10 Kí lẹ̀yin tọkọtaya lè ṣe kẹ́ ẹ lè máa wà pa pọ̀? Ó lè gba pé kẹ́ ẹ dìídì ya àkókò sọ́tọ̀ kẹ́ ẹ lè wà pa pọ̀. (Ka Éfésù 5:15, 16.) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Uzondu lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sọ pé: “Tí mo bá ti ń ṣètò bí iṣẹ́ mi ṣe máa lọ, mo máa ń fi àkókò tí màá lò pẹ̀lú ìyàwó mi sínú ẹ̀, mo sì máa ń rí i pé mo lo àkókò yẹn pẹ̀lú ẹ̀.” (Fílí. 1:10) Ẹ jẹ́ ká wo bí Arábìnrin Anastasia tó jẹ́ ìyàwó alábòójútó àyíká kan lórílẹ̀-èdè Moldova ṣe máa ń lo àkókò ẹ̀ lọ́nà tó dáa jù. Ó sọ pé: “Mo máa ń rí i pé àsìkò tí ọkọ mi ń bójú tó ọ̀rọ̀ ìjọ ni mo máa ń fi ṣe àwọn nǹkan tí mo fẹ́ ṣe. Ìyẹn ló máa ń jẹ́ ká lè ráyè wà pa pọ̀ lẹ́yìn náà.” Àmọ́, tí iṣẹ́ yín ò bá jẹ́ kẹ́ ẹ ráyè wà pa pọ̀ ńkọ́?
11. Àwọn nǹkan wo ni Ákúílà àti Pírísílà máa ń ṣe pa pọ̀?
11 Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Ákúílà àti Pírísílà gan-an, ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ̀yin tọkọtaya òde òní sì lè kọ́ lára wọn. (Róòmù 16:3, 4) Lóòótọ́, Bíbélì ò sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa tọkọtaya yìí, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n jọ máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, wọ́n jọ máa ń wàásù, wọ́n sì jọ máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Ìṣe 18:2, 3, 24-26) Kódà, nígbàkigbà tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa Ákúílà àti Pírísílà, àwọn méjèèjì ló máa ń dárúkọ pa pọ̀.
12. Kí lẹ̀yin ọkọ àti ẹ̀yin aya lè ṣe kẹ́ ẹ lè túbọ̀ máa wà pa pọ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Báwo lẹ̀yin tọkọtaya ṣe lè fara wé Ákúílà àti Pírísílà? Ronú nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí ẹ̀yin méjèèjì fẹ́ ṣe. Ṣé ẹ lè jọ ṣe díẹ̀ lára ẹ̀ dípò kí ìwọ nìkan dá ṣe gbogbo ẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń wàásù. Ṣé ẹ̀yin náà máa ń ṣètò àkókò yín kẹ́ ẹ lè jọ máa wàásù? Yàtọ̀ síyẹn, Ákúílà àti Pírísílà jọ máa ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí ẹ̀yin méjèèjì ń ṣe lè yàtọ̀ síra, àmọ́ ṣé ẹ lè jọ máa ṣiṣẹ́ ilé pa pọ̀? (Oníw. 4:9) Tí ẹ bá ń ṣe àwọn iṣẹ́ kan pa pọ̀, ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ ṣe ara yín lọ́kan, ẹ̀ẹ́ sì tún láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀. Robert àti Linda ti ṣègbéyàwó ní ohun tó lé ní àádọ́ta (50) ọdún. Robert sọ pé: “Kí n sòótọ́, a kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè jọ ṣeré jáde. Àmọ́ tí mo bá ń fọ abọ́, tí ìyàwó mi sì ń nù ún tàbí tí mo bá ń gé koríko níta, tí ìyàwó mi sì wá ràn mí lọ́wọ́, inú mi máa ń dùn gan-an. Bá a ṣe jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀ ń mú ká túbọ̀ fà mọ́ra wa. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìfẹ́ wa lágbára gan-an.”
13. Tí tọkọtaya kan bá fẹ́ ṣe ara wọn lọ́kan, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe?
13 Ẹ máa rántí pé tí ọkọ àti ìyàwó kan bá tiẹ̀ wà pa pọ̀, kò túmọ̀ sí pé wọ́n ń ṣe ara wọn lọ́kan. Ìyàwó kan lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fa ìpínyà ọkàn. Torí náà, téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè máa ronú pé òun ń lo àkókò pẹ̀lú ẹnì kejì òun, ó ṣe tán inú ilé kan náà làwọn ń gbé. Mo ti rí i pé kì í ṣe ká kàn jọ wà pa pọ̀ nìkan, àmọ́ ó tún yẹ ká jọ gbádùn àkókò yẹn.” Ẹ jẹ́ ká wo bí Bruno àti ìyàwó ẹ̀ Tays ṣe ń rí i pé àwọn wáyè fún ara àwọn. Bruno sọ pé: “Tá a bá wà pa pọ̀ láwọn ìgbà tí ọwọ́ wa dilẹ̀, a máa ń gbé fóònù wa jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, àá sì jọ gbádùn àkókò yẹn.”
14. Tí tọkọtaya kan kì í bá gbádùn àkókò tí wọ́n ń lò pa pọ̀, kí ni wọ́n lè ṣe?
14 Ká sọ pé ẹ̀yin méjèèjì kì í gbádùn àkókò tẹ́ ẹ jọ máa ń lò ńkọ́? Ó lè jẹ́ pé ohun tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀ síra, ó sì lè jẹ́ pé ẹnì kejì ẹ láwọn ìwà kan tó máa ń múnú bí ẹ. Kí lo lè ṣe? Ẹ jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ iná igi tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni iná náà máa ràn, táá sì máa jó lala. Ó máa gba pé ká kọ́kọ́ máa ki àwọn igi kéékèèké sínú ẹ̀, lẹ́yìn ìyẹn, a lè wá máa ki igi ńláńlá sínú ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ẹ ò ṣe máa lo àkókò díẹ̀ pa pọ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? Ẹ rí i pé nǹkan tẹ́yin méjèèjì nífẹ̀ẹ́ sí lẹ jọ ń ṣe, kì í ṣe nǹkan tó máa fa èdèkòyédè láàárín yín. (Jém. 3:18) Tẹ́ ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo àkókò díẹ̀díẹ̀ pa pọ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní síra yín á túbọ̀ jinlẹ̀.
Ẹ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÚN ARA YÍN
15. Tẹ́yin tọkọtaya bá fẹ́ kí iná ìfẹ́ yín máa jó, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ara yín?
15 Ó ṣe pàtàkì pé kẹ́yin tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara yín. A lè fi wé afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ sí iná igi kan kó lè jó dáadáa. Tí ò bá sí afẹ́fẹ́, iná náà máa tètè kú. Lọ́nà kan náà, tí tọkọtaya kan kì í bá bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn máa tètè di tútù. Lọ́wọ́ kejì, tí tọkọtaya kan bá ń ṣiṣẹ́ kára láti máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn ò ní yẹ̀ láé. Síbẹ̀, ó yẹ ká máa rántí pé ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ká kàn rò pé à ń bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì wa, àmọ́ ó ṣe pàtàkì kí ọkọ tàbí aya wa mọ̀ pé à ń bọ̀wọ̀ fún òun lóòótọ́. Penny àti Aret ti ṣègbéyàwó ní ohun tó ju ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lọ. Penny sọ pé: “Torí pé èmi àti ọkọ mi máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wa, inú wa máa ń dùn, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀ nínú ilé. Ó máa ń rọrùn fún wa láti sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa torí a kì í fi ọ̀rọ̀ ara wa ṣeré.” Torí náà, kí lo lè ṣe kí ọkọ tàbí aya ẹ lè rí i pé ò ń bọ̀wọ̀ fún òun lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Sérà yẹ̀ wò.
16. Kí lẹ̀yin ọkọ lè kọ́ lára Ábúráhámù? (1 Pétérù 3:7) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Ábúráhámù máa ń bọ̀wọ̀ fún Sérà gan-an. Ó máa ń gba ti Sérà rò, ó sì máa ń ronú nípa bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Ìgbà kan wà tí nǹkan tojú sú Sérà, ó sì bínú sí Ábúráhámù, kódà ó di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru Ábúráhámù pàápàá. Ṣé Ábúráhámù wá gbaná jẹ? Rárá o. Ó mọ̀ pé aya rere ni Sérà, ó máa ń tẹrí ba fún òun, ó sì máa ń ti òun lẹ́yìn. Torí náà, Ábúráhámù gbọ́ ohun tó sọ, ó sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. (Jẹ́n. 16:5, 6) Kí lẹ̀yin ọkọ rí kọ́ lára Ábúráhámù? Ẹ̀yin ọkọ, òótọ́ ni pé ẹ̀yin lẹ láṣẹ láti ṣèpinnu fún ìdílé yín. (1 Kọ́r. 11:3) Síbẹ̀, ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ gbé ohun tí ìyàwó yín sọ yẹ̀ wò kẹ́ ẹ tó ṣèpinnu, pàápàá tó bá jẹ́ pé ìpinnu yẹn máa kàn án. (1 Kọ́r. 13:4, 5) Láwọn ìgbà míì, ó ṣeé ṣe kí nǹkan tojú sú ìyàwó ẹ kó sì fẹ́ sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Ṣé wàá fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún un? (Ka 1 Pétérù 3:7.) Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n (30) ọdún tí Angela àti Dmitry ti ṣègbéyàwó. Angela sọ pé ọkọ òun máa ń bọ̀wọ̀ fún òun gan-an, ó ní: “Kò sígbà tínú ń bí mi tí mo sì fẹ́ bá Dmitry sọ̀rọ̀ tí kì í tẹ́tí sí mi. Ó máa ń ní sùúrù fún mi kódà nígbà tọ́rọ̀ náà ṣì ń gbóná lára mi.”
17. Kí lẹ̀yin aya rí kọ́ lára Sérà? (1 Pétérù 3:5, 6)
17 Sérà fi hàn pé òun bọ̀wọ̀ fún Ábúráhámù torí pé ó máa ń ti ìpinnu tí ọkọ ẹ̀ bá ṣe lẹ́yìn. (Jẹ́n. 12:5) Ìgbà kan wà tí àwọn èèyàn kan tí Ábúráhámù ò retí wá sọ́dọ̀ ẹ̀, ó sì fẹ́ ṣe wọ́n lálejò. Torí náà ó ní kí Sérà fi ohun tó ń ṣe sílẹ̀, kó sì lọ ṣe búrẹ́dì rẹpẹtẹ fáwọn àlejò náà. (Jẹ́n. 18:6) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sérà lọ ṣe ohun tí Ábúráhámù ní kó ṣe, ó sì fi hàn pé òun fara mọ́ ìpinnu tí ọkọ òun ṣe. Ẹ̀yin aya, ẹ̀yin náà lè fara wé Sérà, kẹ́ ẹ sì fi hàn pé ẹ̀ ń fara mọ́ ìpinnu tí ọkọ yín bá ṣe. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àárín yín á túbọ̀ gún régé. (Ka 1 Pétérù 3:5, 6.) Dmitry tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú ìpínrọ̀ tó ṣáájú sọ bó ṣe máa ń rí lára ẹ̀ tí ìyàwó ẹ̀ bá ń bọ̀wọ̀ fún un. Ó ní: “Mo mọrírì bí Angela ṣe máa ń fara mọ́ àwọn ìpinnu tí mo bá ṣe, kódà láwọn ìgbà tí èrò wa ò bá ṣọ̀kan. Tí nǹkan náà ò bá sì rí bá a ṣe rò, kì í dá mi lẹ́bi.” Ẹ ò rí i pé ó máa rọrùn gan-an láti nífẹ̀ẹ́ ẹni tó bá ń bọ̀wọ̀ fún wa!
18. Àǹfààní wo lẹ̀yin tọkọtaya máa rí tẹ́ ẹ bá ń ṣiṣẹ́ kára kí iná ìfẹ́ tó wà láàárín yín lè máa jó lala?
18 Lónìí, bí Sátánì ṣe máa paná ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó ló ń wá. Ó mọ̀ pé táwọn tọkọtaya ò bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn mọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n fi Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, kò sóhun tó lè paná ìfẹ́ tòótọ́ láé! Àdúrà wa ni pé kí ìfẹ́ tó o ní sí ọkọ tàbí aya ẹ dà bí ìfẹ́ tá a sọ nínú ìwé Orin Sólómọ́nì. Torí náà, Jèhófà ni kẹ́ ẹ fi ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbéyàwó yín, ẹ máa wáyè láti wà pa pọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún ara yín, kẹ́ ẹ sì máa gba ti ara yín rò. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó yín máa fi ògo àti ọlá fún Jèhófà ẹni tó jẹ́ Orísun ìfẹ́ tòótọ́. Bí iná igi ṣe máa ń jó tí atẹ́gùn bá fẹ́ sí i dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ni iná ìfẹ́ yín á máa jó lala títí láé.
ORIN 132 A Ti Di Ọ̀kan Ṣoṣo
a Jèhófà ló ṣètò ìgbéyàwó fáwa èèyàn, ìyẹn ló sì ń mú kó ṣeé ṣe fáwọn tọkọtaya láti fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn síra wọn. Àmọ́ nígbà míì, ìfẹ́ yẹn lè má lágbára mọ́. Tó o bá ti ṣègbéyàwó, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sí ọkọ tàbí aya ẹ máa lágbára sí i, kẹ́ ẹ sì máa láyọ̀.
b Ìfẹ́ tòótọ́ kì í yí pa dà, ó sì máa ń wà pẹ́ títí. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “ọwọ́ iná Jáà” torí ọ̀dọ̀ Jèhófà ni irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ti wá.
c Kódà tí ọkọ tàbí aya ẹ kì í bá ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìmọ̀ràn yìí ṣì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín yín lè máa lágbára sí i.—1 Kọ́r. 7:12-14; 1 Pét. 3:1, 2.
d Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” lórí ìkànnì jw.org àti lórí JW Library®.