Àwọn Ọba Tó Ń Bára Wọn Jà Lákòókò Òpin Yìí
Àwọn kan lára àsọtẹ́lẹ̀ tá a tọ́ka sí nínú àtẹ yìí ní ìmúṣẹ lásìkò kan náà. Gbogbo wọn ló jẹ́rìí sí i pé “àkókò òpin” là ń gbé yìí.—Dán. 12:4.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìfi. 11:7; 12:13, 17; 13:1-8, 12
Àsọtẹ́lẹ̀ Ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ọdún ni “ẹranko” náà fi ṣàkóso àwọn èèyàn. Ní àkókò òpin, wọ́n dá ọgbẹ́ sí ìkeje lára orí ẹranko náà. Nígbà tó yá, ọgbẹ́ náà jinná “gbogbo ayé” sì tẹ̀ lé ẹranko náà. Sátánì wá lo ẹranko náà láti “bá àwọn tó ṣẹ́ kù” lára ẹni àmì òróró jagun.
Ìmúṣẹ Lẹ́yìn Ìkún Omi, àwọn ìjọba tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àwọn èèyàn. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta (3,000) lẹ́yìn náà, Ilẹ̀ Ọba Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọba yẹn fara pa gan-an nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Ó kọ́fẹ pa dà nígbà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tì í lẹ́yìn. Pàápàá jù lọ ní àkókò òpin yìí, Sátánì ń lo àwọn ìjọba ayé láti ṣenúnibíni sáwọn èèyàn Ọlọ́run.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 11:25-45
Àsọtẹ́lẹ̀ Ọba àríwá àti ọba gúúsù máa bára wọn jà lákòókò òpin.
Ìmúṣẹ Ilẹ̀ Jámánì bá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà jagun. Lọ́dún 1945, Soviet Union àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá. Lọ́dún 1991, ìjọba Soviet Union wá sópin ó sì pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Nígbà tó yá Rọ́ṣíà àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di ọba àríwá.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Àìsá. 61:1; Mál. 3:1; Lúùkù 4:18
Àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà máa rán “ìránṣẹ́” rẹ̀ láti “tún ọ̀nà ṣe” kí Ìjọba Mèsáyà tó fìdí múlẹ̀. Ìránṣẹ́ yìí máa “kéde ìhìn rere fún àwọn oníwà pẹ̀lẹ́.”
Ìmúṣẹ Bẹ̀rẹ̀ látọdún 1870, Arákùnrin C. T. Russell àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ṣèwádìí jinlẹ̀ nínú Bíbélì kí wọ́n lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Lọ́dún 1881, wọ́n rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa wàásù. Torí náà, wọ́n gbé àwọn àpilẹ̀kọ bí “À Ń Wá Ẹgbẹ̀rún Oníwàásù” àti “A Fòróró Yàn Wọ́n Láti Wàásù” jáde.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Mát. 13:24-30, 36-43
Àsọtẹ́lẹ̀ Ọ̀tá kan máa gbin èpò sí àárín àlìkámà, wọ́n máa jẹ́ kí àwọn méjèèjì jọ dàgbà débi pé èpò máa bo àlìkámà mọ́lẹ̀, wọ́n á sì wà bẹ́ẹ̀ títí dìgbà ìkórè. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n á ya èpò sọ́tọ̀ kúrò lára àlìkámà.
Ìmúṣẹ Àtọdún 1870 ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àtàwọn èké Kristẹni ti túbọ̀ ṣe kedere. Lákòókò òpin yìí, Jèhófà ti kó àwọn Kristẹni tòótọ́ jọ sínú ìjọ rẹ̀, ó sì ti yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èké Kristẹni.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 2:31-33, 41-43
Àsọtẹ́lẹ̀ Ère gìrìwò kan tó jẹ́ ti wúrà, fàdákà, bàbà àti irin ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀.
Ìmúṣẹ Amọ̀ náà ṣàpẹẹrẹ àwọn gbáàtúù tó wà lábẹ́ àkóso Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà. Àwọn èèyàn yìí ń ta ko ìjọba, ìyẹn sì mú kó ṣòro fún ìjọba láti lo agbára wọn tó dà bí irin.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Mát. 13:30; 24:14, 45; 28:19, 20
Àsọtẹ́lẹ̀ Wọ́n máa kó “àlìkámà” jọ sínú “ilé ìkẹ́rùsí,” Jésù máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pé kó máa bójú tó àwọn “ará ilé” rẹ̀. Wọ́n sì máa wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.”
Ìmúṣẹ Lọ́dún 1919, Jésù yan ẹrú olóòótọ́ pé kó máa bójú tó àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àtìgbà yẹn làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù. Lónìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ní ilẹ̀ tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) lọ, a sì ń tẹ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì jáde ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 12:11; Ìfi. 13:11, 14, 15
Àsọtẹ́lẹ̀ Ẹranko kan tó “ní ìwo méjì” máa sọ fún àwọn tó ń gbé ayé pé kí wọ́n ṣe “ère ẹranko” kan, á sì fún ère “ẹranko náà ní èémí.”
Ìmúṣẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ló dá Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè míì sì dara pọ̀ mọ́ Ìmùlẹ̀ yìí. Nígbà tó yá, ọba àríwá náà dara pọ̀ mọ́ ọn, ìyẹn láti ọdún 1926 sí 1933. Ṣe làwọn èèyàn ń gbógo tó yẹ Ìjọba Ọlọ́run fún Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ohun kan náà ni wọ́n sì ṣe fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n dá sílẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 8:23, 24
Àsọtẹ́lẹ̀ Ọba kan tí ojú rẹ̀ le máa “mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀.”
Ìmúṣẹ Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì àti Amẹ́ríkà ti pa àìlóǹkà èèyàn, ó sì ti pa ọ̀pọ̀ ilẹ̀ run. Bí àpẹẹrẹ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fa ìparun tí kò láfiwé nígbà tó ju bọ́ǹbù méjì sí ilẹ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀tá òun àti ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Dán. 11:31; Ìfi. 17:3, 7-11
Àsọtẹ́lẹ̀ Ẹranko “aláwọ̀ rírẹ̀dòdò” kan tó ní ìwo mẹ́wàá máa jáde látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀, òun sì ni ọba kẹjọ. Ìwé Dáníẹ́lì pe ọba yìí ní “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro.”
Ìmúṣẹ Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò lágbára mọ́. Lẹ́yìn tí ogun náà parí, ‘wọ́n gbé’ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kalẹ̀. Ṣe làwọn èèyàn ń gbógo tó yẹ Ìjọba Ọlọ́run fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè bíi ti Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tó wà ṣáájú rẹ̀. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa gbéjà ko ẹ̀sìn.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ 1 Tẹs. 5:3; Ìfi. 17:16
Àsọtẹ́lẹ̀ Àwọn orílẹ̀-èdè máa kéde “àlàáfíà àti ààbò,” bẹ́ẹ̀ sì ni “ìwo mẹ́wàá” àti “ẹranko náà” máa gbéjà ko “aṣẹ́wó náà,” wọ́n sì máa pa á run. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run yán-án-yán.
Ìmúṣẹ Àwọn orílẹ̀-èdè máa sọ pé àwọn ti jẹ́ kí àlàáfíà àti ààbò wà láyé. Lẹ́yìn náà, àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè lẹ́yìn máa pa gbogbo ẹ̀sìn èké run. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. Ìpọ́njú ńlá yìí máa dópin nígbà tí Jésù bá pa èyí tó ṣẹ́ kù lára ayé Sátánì run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìsík. 38:11, 14-17; Mát. 24:31
Àsọtẹ́lẹ̀ Gọ́ọ̀gù máa wọ ilẹ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, àwọn áńgẹ́lì máa kó “àwọn àyànfẹ́” jọ.
Ìmúṣẹ Ọba àríwá àtàwọn ìjọba ayé yòókù máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí ìgbéjàkò yẹn bá bẹ̀rẹ̀, Jèhófà máa kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró lọ sọ́run.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ìsík. 38:18-23; Dán. 2:34, 35, 44, 45; Ìfi. 6:2; 16:14, 16; 17:14; 19:20
Àsọtẹ́lẹ̀ ‘Ẹni tó jókòó sórí ẹṣin funfun’ máa “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” nígbà tó bá pa Gọ́ọ̀gù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run. Wọ́n máa ju “ẹranko náà” sínú “adágún iná tó ń jó,” òkúta kan sì máa rún ère gìrìwò náà wómúwómú.
Ìmúṣẹ Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa wá gba àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀. Òun àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n á jọ ṣàkóso pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun ọ̀run máa pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run run, ìyẹn ló sì máa fòpin sí ìṣàkóso Sátánì.