Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àlàáfíà​—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?

Àlàáfíà​—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?

INÚ ayé tó kún fún wàhálà là ń gbé, torí náà a gbọ́dọ̀ sapá ká tó lè ní àlàáfíà. Síbẹ̀, tá a bá tiẹ̀ ní àlàáfíà déwọ̀n àyè kan, kì í pẹ́ tí nǹkan míì á fi kó wa lọ́kàn sókè. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tó máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ ká sì ní àlàáfíà tó máa wà pẹ́ títí? Báwo la ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́ káwọn náà lè ní àlàáfíà?

KÍ LÓ MÁA JẸ́ KÁ NÍ ÀLÀÁFÍÀ TÓ WÀ PẸ́ TÍTÍ?

Tá a bá máa gbádùn àlàáfíà tó wà pẹ́ títí, ọkàn wa gbọ́dọ̀ balẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì ká láwọn ọ̀rẹ́ tó dáa. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a bá fẹ́ ní àlàáfíà ni pé ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwọn àníyàn ìgbésí ayé kì í mú kọ́kàn àwọn èèyàn balẹ̀

Tá a bá ń pa àwọn òfin Jèhófà mọ́, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, ṣe là ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e àti pé ó wù wá láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. (Jer. 17:​7, 8; Ják. 2:​22, 23) Ìyẹn máa mú kí Jèhófà sún mọ́ wa, á sì jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Aísáyà 32:17 sọ pé: “Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà; iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Tá a bá fẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, àfi ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà látọkàn wá.​—Aísá. 48:​18, 19.

Baba wa ọ̀run tún fún wa ní ẹ̀bùn pàtàkì kan tó máa jẹ́ ká ní àlàáfíà tó máa wà pẹ́ títí, ìyẹn sì ni ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.​—Ìṣe 9:31.

Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ ỌLỌ́RUN Ń JẸ́ KÁ NÍ ÀLÀÁFÍÀ

Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa “èso ti ẹ̀mí,” ohun kẹta tó mẹ́nu kàn ni àlàáfíà. (Gál. 5:​22, 23) Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń fúnni ní àlàáfíà, tá a bá fẹ́ ní àlàáfíà àfi ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa darí wa. Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn ọ̀nà méjì tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbà fúnni ní àlàáfíà.

Àkọ́kọ́, a máa ní àlàáfíà, ọkàn wa sì máa balẹ̀ tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. (Sm. 1:​2, 3) Bá a ṣe ń ronú lórí ohun tá a kà nínú Bíbélì, ẹ̀mí Ọlọ́run máa jẹ́ ká lóye ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀pọ̀ nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, a máa rí bí Jèhófà ṣe jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti ìdí tó fi fẹ́ káwa náà máa wá àlàáfíà. Ó dájú pé tá a bá ń fi ohun tá à ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ọkàn wa máa túbọ̀ balẹ̀, a sì máa ní àlàáfíà.​—Òwe 3:​1, 2.

Ìkejì, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Jèhófà ṣèlérí pé tá a bá bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ òun, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílí. 4:​6, 7) Tá a bá ń gbàdúrà déédéé pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó dájú pé ó máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀. Àwọn tó bá sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fún nírú ìbàlẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀.​—Róòmù 15:13.

Báwo làwọn kan ṣe fi ìlànà Bíbélì yìí sílò tí wọ́n sì ṣe àwọn ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn? Báwo nìyẹn ṣe jẹ́ kí wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà, pẹ̀lú àwọn míì, kí ọkàn wọn sì balẹ̀?

BÍ WỌ́N ṢE RÍ ÀLÀÁFÍÀ TÓ WÀ PẸ́ TÍTÍ

Lónìí, àwọn kan wà nínú ìjọ tó jẹ́ pé wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ onínúfùfù, àmọ́ ní báyìí wọ́n ti dẹni pẹ̀lẹ́, onínúure, onísùúrù àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà. * (Òwe 29:22) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran àwọn akéde méjì kan tí wọ́n jẹ́ onínúfùfù lọ́wọ́ láti di ẹlẹ́mìí àlàáfíà.

Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tá a sì ń gbàdúrà fún ẹ̀mí Ọlọ́run, àá ní àlàáfíà

Ìwà David ò dáa rárá, ọ̀rọ̀ burúkú ló sì kún ẹnu ẹ̀. Kó tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó máa ń ṣàríwísí àwọn èèyàn, ó sì máa ń sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ìdílé rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, David rí i pé ó yẹ kóun ṣàtúnṣe. Kí ló mú kó di ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ó sọ pé, “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, èyí mú kí n máa bọ̀wọ̀ fún ìdílé mi àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀wọ̀ fún mi.”

Ibi tí Rachel gbé dàgbà ló jẹ́ kó di onínúfùfù. Ó sọ pé, “Kódà ní báyìí, mo ṣì máa ń sapá gan-an láti ṣẹ́pá ìbínú mi torí pé inú ilé tínú ti tètè máa ń bí àwọn èèyàn ni mo dàgbà sí.” Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti di ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ó sọ pé, “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́.”

David àti Rachel kàn jẹ́ méjì lára àwọn tó ti di ẹlẹ́mìí àlàáfíà lẹ́yìn tí wọ́n fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tí wọ́n sì gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run. Ó ṣe kedere pé bá a tiẹ̀ ń gbé inú ayé burúkú, a lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ìdílé wa àtàwọn ará. Síbẹ̀, Jèhófà rọ̀ wá pé ká “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” (Róòmù 12:18) Àmọ́ ṣé ìyẹn ṣeé ṣe, àwọn àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ń wá àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn?

MÁA WÁ ÀLÀÁFÍÀ PẸ̀LÚ ÀWỌN ÈÈYÀN

Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe ń mú káwọn èèyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. (Aísá. 9:​6, 7; Mát. 24:14) Inú wa dùn pé ọ̀pọ̀ ló ti wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì ti mú kí wọ́n gbọ́kàn kúrò lórí àwọn nǹkan tó ń bani nínú jẹ́ tó sì ń múnú bíni nínú ayé yìí. Ní báyìí, wọ́n nírètí pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n ‘máa wá àlàáfíà, kí wọ́n sì máa lépa rẹ̀.’​—Sm. 34:14.

Àmọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ń tẹ́tí sí wa, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n gbọ́ ìwàásù ni wọ́n tẹ́wọ́ gbà á. (Jòh. 3:19) Síbẹ̀, ẹ̀mí Ọlọ́run ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wàásù fáwọn èèyàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Bá a ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, à ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Jésù fún wa nínú Mátíù 10:​11-13, níbi tó ti sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà; bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín.” Tá a bá ṣe ohun tí Jésù sọ yìí, a ò ní bá ẹnikẹ́ni fa wàhálà, ó sì ṣeé ṣe kí ẹni tí kò gbọ́ wa lónìí tẹ́tí sí wa lọ́jọ́ míì.

Ọ̀nà míì tá a lè gbà jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni pé ká máa bá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, títí kan àwọn tó ń tako ìjọsìn wa. Bí àpẹẹrẹ, ìjọba orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà kọ̀ láti fún wa ní ìwé àṣẹ ká lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba torí ẹ̀tanú tí wọ́n ní sí wa. Àmọ́ ká lè fi pẹ̀lẹ́tù yanjú ọ̀rọ̀ náà, ètò Ọlọ́run rán arákùnrin kan tó ti ṣe míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè yẹn nígbà kan pé kó lọ rí Kọmíṣọ́nnà Àgbà fún orílẹ̀-èdè yẹn nílùú London, England. Ìdí tí arákùnrin yìí fi lọ ni pé ó fẹ́ kí kọmíṣọ́nnà náà mọ iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tó débẹ̀?

Arákùnrin yẹn sọ pé: “Nígbà tí mo wọnú ọ́fíìsì tí wọ́n ń gbàlejò sí, mo kíyè sí i pé obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ múra bíi ti ẹ̀yà kan lórílẹ̀-èdè yẹn. Torí pé mo gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yẹn, èdè yẹn gan-an ni mo fi kí i. Ó yà á lẹ́nu gan-an, ó wá bi mí pé, ‘Kí lẹ wá ṣe?’ Mo wá sọ fún un pé mo fẹ́ rí Kọmíṣọ́nnà Àgbà. Ó pe ọ̀gá rẹ̀ lórí fóònù, ọ̀gá náà sì jáde wá kí mi kódà èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ ló fi kí mi. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí mi, mo sì ṣàlàyé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún un.”

Bí arákùnrin yẹn ṣe fara balẹ̀ ṣàlàyé ọ̀rọ̀ lọ́jọ́ yẹn mú kí èrò tí kọmíṣọ́nnà yẹn ní yí pa dà, kò sì ṣe ẹ̀tanú sí wa mọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà náà, ìjọba orílẹ̀-èdè yẹn fọwọ́ sí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tá a fẹ́ ṣe. Ẹ wo bí inú àwọn ará wa ti dùn tó nígbà tí wọ́n rí ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí! Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn máa fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, lára ẹ̀ sì ni pé àá wà ní àlàáfíà pẹ̀lú wọn.

GBÁDÙN ÀLÀÁFÍÀ TÓ MÁA WÀ TÍTÍ LÁÉ

Lónìí, àwa èèyàn Jèhófà ń gbádùn àlàáfíà nínú Párádísè tẹ̀mí. Ìwọ náà lè pa kún àlàáfíà yìí tó o bá ń sapá láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà nígbèésí ayé rẹ. Àmọ́ ìbùkún tó ṣe pàtàkì jù ni pé inú Jèhófà máa dùn sí ẹ, wàá sì gbádùn àlàáfíà yanturu tó máa wà títí láé nínú ayé tuntun.​—2 Pét. 3:​13, 14.

^ ìpínrọ̀ 13 Inú rere wà lára àwọn ànímọ́ tá a máa jíròrò nínú ọ̀wọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run.