Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Ọmọ Tí Òbí Wọn Jẹ́ Àjèjì
“Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 JÒH. 4.
ORIN: 88, 41
1, 2. (a) Ìṣòro wo ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí òbí wọn jẹ́ àjèjì máa ń ní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ARÁKÙNRIN JOSHUA táwọn òbí rẹ̀ ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì sọ pé: “Àtikékeré ni mo ti ń sọ èdè àwọn òbí mi nílé, òun náà la sì ń sọ nínú ìjọ. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ iléèwé, èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò ibi tá a kó lọ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í sọ. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, èdè yẹn nìkan ni mò ń sọ. Bó ṣe di pé mi ò lóye nǹkan tí wọ́n ń sọ nípàdé mọ́ nìyẹn, àṣà ìbílẹ̀ àwọn òbí mi ò sì bá mi lára mu mọ́.” Ọ̀pọ̀ èèyàn lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Joshua ti ṣẹlẹ̀ sí.
2 Lónìí, àwọn tó ju mílíọ̀nù lọ́nà igba ó lé ogójì [240,000,000] ló ń gbé lórílẹ̀-èdè tí kì í ṣe ìlú ìbílẹ̀ wọn. Tó bá jẹ́ pé ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ ṣí lọ sí ìlú míì, báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́”? (3 Jòh. 4) Báwo làwọn míì sì ṣe lè ràn yín lọ́wọ́?
Ẹ̀YIN ÒBÍ, Ẹ FI ÀPẸẸRẸ TÓ DÁA LÉLẸ̀ FÁWỌN ỌMỌ YÍN
3, 4. (a) Báwo làwọn òbí ṣe lè fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn? (b) Kí ni kò yẹ káwọn òbí máa retí látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ wọn?
3 Ẹ̀yin òbí, àpẹẹrẹ yín ṣe pàtàkì tẹ́ ẹ bá fẹ́ káwọn ọmọ yín máa rìn lọ́nà tó lọ sí ìyè. Táwọn ọmọ yín bá rí i pé ẹ̀ ń ‘wá ìjọba Mát. 6:33, 34) Torí náà, ẹ jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ yín lọ́rùn, ẹ máa yááfì àwọn nǹkan tara torí àwọn nǹkan tẹ̀mí, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ máa yááfì àwọn nǹkan tẹ̀mí torí àwọn nǹkan tara. Bákan náà, ẹ má ṣe tọrùn bọ gbèsè. Bẹ́ ẹ ṣe máa ní “ìṣúra ní ọ̀run,” ìyẹn bẹ́ ẹ ṣe máa rí ojúure Jèhófà ni kẹ́ ẹ máa wá, kì í ṣe bẹ́ ẹ ṣe máa kó ọrọ̀ jọ tàbí bẹ́ ẹ ṣe máa rí “ògo ènìyàn.”—Ka Máàkù 10:21, 22; Jòh. 12:43.
náà lákọ̀ọ́kọ́,’ èyí á mú káwọn náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè ohun tí wọ́n nílò lójoojúmọ́. (4 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ yín dí débi tẹ́ ò fi ní ráyè tàwọn ọmọ yín. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú yín máa dùn gan-an tí wọ́n bá fi ìjọsìn Jèhófà ṣáájú láyé wọn dípò kí wọ́n máa wá bí wọ́n á ṣe dolówó torí kí wọ́n lè tọ́jú ara wọn tàbí kí wọ́n lè tọ́jú ẹ̀yin òbí wọn. Kò yẹ káwa Kristẹni ní irú èrò táwọn èèyàn ní pé ó yẹ kọ́mọ lọ ṣiṣẹ́ owó torí káwọn òbí lè máa gbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ. Ká rántí ohun tí Bíbélì sọ pé, “kò yẹ fún àwọn ọmọ láti to nǹkan jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.”—2 Kọ́r. 12:14.
OHUN TẸ́YIN ÒBÍ LÈ ṢE TÁWỌN ỌMỌ YÍN Ò BÁ GBỌ́ ÈDÈ YÍN DÁADÁA
5. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí máa sọ nípa Jèhófà fáwọn ọmọ wọn?
5 Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” ló ń wá sínú ètò Ọlọ́run. (Sek. 8:23) Àmọ́ nígbà míì, ìṣòro èdè lè mú kó ṣòro fún àwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ máa rántí pé àwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ kẹ́ ẹ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn ọmọ yín. Tí wọ́n bá sì máa rí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú àfi kí wọ́n mọ Jèhófà. (Jòh. 17:3) Kẹ́ ẹ tó lè kọ́ àwọn ọmọ yín nípa Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ ‘máa sọ̀rọ̀ nípa’ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.—Ka Diutarónómì 6:6, 7.
6. Àǹfààní wo làwọn ọmọ rẹ máa rí tí wọ́n bá gbọ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
6 Àwọn ọmọ rẹ máa kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ nílùú tẹ́ ẹ kó lọ níléèwé tàbí kí wọ́n kọ́ ọ ládùúgbò. Àmọ́ wọ́n máa gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yín dáadáa tẹ́ ẹ bá ń bá wọn sọ̀rọ̀ déédéé lédè yín. Táwọn ọmọ yín bá gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yín dáadáa, ọ̀rọ̀ yín á yéra yín. Bákan náà, wọ́n á gbọ́ ju èdè kan lọ, èyí sì máa ṣe wọ́n láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, òye tí wọ́n ní máa pọ̀ sí i, wọ́n á sì lè mọ bí wọ́n á ṣe máa ṣe láwùjọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n á tún lè mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i. Carolina táwọn òbí rẹ̀ ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì sọ pé: “Mò ń gbádùn bí mo ṣe wà ní ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ mi. Ṣe ló dà bíi pé mò ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, èyí sì ń múnú mi dùn.”
7. Kí lẹ lè ṣe táwọn ọmọ yín kò bá gbọ́ èdè ìbílẹ̀ yín dáadáa?
7 Síbẹ̀, bí àwọn ọmọ bá ṣe ń sọ èdè ìlú tí wọ́n wà báyìí, tí àṣà ibẹ̀ sì ti ń mọ́ wọn lára, àwọn kan lè má fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè ìbílẹ̀ wọn mọ́ tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i mọ́. Ẹ̀yin òbí, tó bá jẹ́ pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ yín nìyẹn, ṣé ẹ̀yin náà lè sapá láti kọ́ èdè tí wọ́n ń sọ nílùú tẹ́ ẹ wà? Ó máa túbọ̀ rọrùn fún yín láti kọ́ àwọn ọmọ yín lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tẹ́ ẹ bá lóye bí wọ́n ṣe ń ronú, tẹ́ ẹ mọ eré ìnàjú tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí, tẹ́ ẹ mọ bí iṣẹ́ iléèwé wọn ṣe rí, tí ẹ̀yin fúnra yín sì lè bá àwọn olùkọ́ wọn sọ̀rọ̀. Ká sòótọ́, ó máa ń gba ìsapá, àkókò, ó sì máa ń gba kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ kó tó lè kọ́ èdè míì. Àmọ́ tí òbí kan bá lọ́mọ tó jẹ́ adití, ǹjẹ́ kò ní sapá láti kọ́ èdè àwọn adití kó lè máa bá a sọ̀rọ̀? Bákan náà, tó bá jẹ́ èdè míì lọmọ yín gbọ́ dáadáa, ṣé kò yẹ kẹ́ ẹ sapá láti kọ́ èdè náà kẹ́ ẹ lè jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa? *
8. Báwo lo ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ tó ò bá fi bẹ́ẹ̀ gbédè wọn?
2 Tím. 3:15) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, o ṣì lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti mọ Jèhófà kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Shan sọ pé: “Màmá wa ló dá tọ́ wa, wọn ò sì gbédè tá à ń sọ dáadáa, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwa ọmọ ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè tiwọn náà. Àmọ́ a máa ń rí bí wọ́n ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n ń gbàdúrà tí wọ́n sì ń sapá ká lè máa ṣe ìjọsìn ìdílé wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.”
8 Ká sòótọ́, àwọn òbí kan tó ṣí lọ síbòmíì lè má fi bẹ́ẹ̀ gbédè tí wọ́n ń sọ níbi tí wọ́n ń gbé báyìí. Ó sì lè jẹ́ èdè yẹn làwọn ọmọ wọn máa gbọ́ dáadáa. Èyí lè mú kó ṣòro fáwọn òbí yìí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní “ìwé mímọ́” lọ́nà tí òtítọ́ á fi jinlẹ̀ lọ́kàn wọn. (9. Tó bá gba pé kí ọmọ kan fi èdè méjì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, báwo làwọn òbí ṣe lè ran irú ọmọ bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?
9 Ó lè gba pé káwọn ọmọ kan fi èdè méjì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ìyẹn èdè tí wọ́n fi ń kọ́ wọn níléèwé àti èdè táwọn òbí wọn ń sọ nílé. Ìdí nìyẹn táwọn òbí kan ṣe máa ń lo àwọn ìwé, àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ àtàwọn fídíò tó wà lédè méjèèjì láti fi kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Èyí fi hàn pé iṣẹ́ ńlá làwọn òbí tó ṣí lọ síbòmíì ní torí ó máa gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá káwọn ọmọ wọn tó lè ní àjọṣe tó lágbára pẹ̀lú Jèhófà.
ÌJỌ WO LÓ YẸ KÓ O LỌ?
10. (a) Ta ló máa pinnu ìjọ tí ìdílé kan máa lọ? (b) Kí ló yẹ kó ṣe kó tó ṣèpinnu bẹ́ẹ̀?
10 Táwọn tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì bá ń gbé níbi tó jìnnà sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn, ìjọ tó ń sọ èdè àdúgbò ibẹ̀ ni wọ́n máa lọ. (Sm. 146:9) Àmọ́, tí ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn bá wà nítòsí, á dáa kí wọ́n fara balẹ̀ ronú lórí ìjọ tí wọ́n máa lọ. Olórí ìdílé ló máa ṣèpinnu yìí. Àmọ́, kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, kó fi í sádùúrà, kó sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. (1 Kọ́r. 11:3) Kí làwọn nǹkan tí olórí ìdílé máa fi sọ́kàn tó bá fẹ́ ṣèpinnu? Àwọn ìlànà wo ló máa ràn án lọ́wọ́? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ níbẹ̀.
11, 12. (a) Báwo ni èdè tí wọ́n ń sọ nípàdé ṣe kan bí ọmọ kan ṣe máa lóye ohun tí wọ́n ń sọ níbẹ̀? (b) Kí ló lè mú káwọn ọmọ kan má fẹ́ kọ́ èdè táwọn òbí wọn ń sọ?
11 Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú ohun táwọn ọmọ wọn nílò jù. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa ni wọ́n ń sọ níjọ tí wọ́n ń lọ, kì í ṣe wákàtí mélòó kan tí wọ́n ń lò níbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nìkan ló máa jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Ká má tíì wá sọ pé kí wọ́n máa lọ síjọ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa ni wọ́n ń sọ nípàdé, wọ́n á lóye ohun tí wọ́n ń sọ ju báwọn òbí wọn ṣe rò lọ. (Ka 1 Kọ́ríńtì 14:9, 11.) Nígbà míì, ọmọ kan máa gbọ́ èdè míì dáadáa ju bó ṣe gbọ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ lọ, ó sì lè jẹ́ pé èdè tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn nìyẹn. Kódà, àwọn ọmọ kan lè kọ́ bí wọ́n á ṣe máa dáhùn àti bí wọ́n á ṣe máa ṣiṣẹ́ níjọ tó ń sọ èdè abínibí wọn, àmọ́ kọ́rọ̀ tí wọ́n ń sọ má tọkàn wọn wá.
12 Bákan náà, kì í ṣe èdè nìkan ló máa ń jẹ́ kọ́rọ̀ wọ ọmọ lọ́kàn. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Joshua tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń jẹ́ Esther sọ pé: “Àtikékeré làwọn ọmọ ti máa ń kọ́ èdè àti àṣà àwọn òbí wọn, wọ́n sì tún máa ń ṣe ẹ̀sìn wọn.” Torí náà, tí àṣà ìbílẹ̀ àwọn òbí kò bá bá àwọn ọmọ lára mu, wọ́n lè má fẹ́ kọ́ èdè wọn, wọ́n sì lè má fẹ́ ṣe ẹ̀sìn wọn. Tí irú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí làwọn òbí tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì lè ṣe?
13, 14. (a) Kí nìdí táwọn òbí kan fi pinnu láti lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè àdúgbò ibi tí wọ́n ń gbé? (b) Kí làwọn òbí náà ṣe kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè túbọ̀ yé wọn?
13 Bí àwọn ọmọ ṣe máa sún mọ́ Jèhófà 1 Kọ́r. 10:24) Samuel tó jẹ́ bàbá Joshua àti Esther sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi kíyè sí àwọn ọmọ wa dáadáa ká lè mọ èdè tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, a sì gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà. Ohun tó wá ṣe kedere sí wa pé ká ṣe kò fi bẹ́ẹ̀ bá wa lára mu. Àmọ́, nígbà tá a rí i pé àwọn ọmọ wa ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ohun tí wọ́n ń sọ níjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wa, a pinnu pé a máa lọ sí ìjọ tó ń sọ èdè àdúgbò ibi tá à ń gbé. A jọ máa ń lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí déédéé. A tún máa ń pe àwọn ará pé kí wọ́n wá jẹun nílé wa, ká sì jọ gbafẹ́ jáde. Ohun tó jẹ́ káwọn ọmọ wa mọ àwọn ará dáadáa nìyẹn, ó tún mú kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì rí i bíi Bàbá àti Ọ̀rẹ́ wọn. Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí wa nìyẹn, kì í ṣe pé kí wọ́n ṣáà ti gbọ́ èdè wa.”
ló ṣe pàtàkì jù sáwọn òbí Kristẹni, kì í ṣe ohun táwọn fúnra wọn fẹ́. (14 Samuel tún sọ pé: “Èmi àtìyàwó mi máa ń lọ síjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wa kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè túbọ̀ yé wa sí i. Ọwọ́ wa máa ń dí gan-an, ó sì máa ń rẹ̀ wá. Àmọ́, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó bù kún gbogbo ìsapá wa àtàwọn ohun tá a yááfì. Ní báyìí, àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.”
OHUN TÁWỌN Ọ̀DỌ́ LÈ ṢE
15. Kí nìdí tí Arábìnrin Kristina fi lọ síjọ tó ń sọ èdè tí wọ́n ń lò níléèwé rẹ̀?
15 Àwọn ọmọ tó ti dàgbà lè rí i pé àwọn a túbọ̀ ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Jèhófà táwọn bá dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè táwọn lóye dáadáa. Tí ọmọ kan bá ṣe irú ìpinnu yìí, káwọn òbí má ṣe rò pé ọmọ náà fẹ́ pa àwọn tì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kristina sọ pé: “Mo lóye díẹ̀ nínú èdè àwọn òbí mi, àmọ́ èyí tí wọ́n ń sọ nípàdé kò yé mi rárá. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo lọ sí àpéjọ àgbègbè kan tí wọ́n ṣe ní èdè tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ níléèwé. Fúngbà àkọ́kọ́, òtítọ́ yé mi kedere! Bákan náà, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà ní èdè tí wọ́n fi ń kọ́ mi níléèwé, ṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá Jèhófà sọ̀rọ̀ látọkàn wá!” (Ìṣe 2:11, 41) Nígbà tí Kristina dàgbà, ó fọ̀rọ̀ náà lọ àwọn òbí rẹ̀, ó sì pinnu pé òun máa lọ síjọ tó ń sọ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò. Kristina sọ pé: “Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà lédè tí wọ́n fi ń kọ́ mi níléèwé ló mú kí n tẹ̀ síwájú.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Kristina bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
16. Kí nìdí tí inú Arábìnrin Nadia fi dùn pé òun ò kúrò níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn?
16 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ máa fẹ́ lọ síjọ tó ń sọ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kẹ́ ẹ bi ara yín pé, kí nìdí tó fi ń wù mí láti lọ? Ṣé ìyẹn máa jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? (Ják. 4:8) Ṣé torí káwọn òbí mi má bàa máa ṣọ́ mi lọ́wọ́ ṣọ́ mi lẹ́sẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ lọ, àbí torí pé mi ò fẹ́ máa ṣiṣẹ́ púpọ̀ nípàdé? Arábìnrin Nadia tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí sọ pé: “Nígbà táwa ọmọ dàgbà, a fẹ́ máa lọ síjọ tó ń sọ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò wa.” Àmọ́, àwọn òbí wọn mọ̀ pé tí wọ́n bá lọ, wọ́n lè má ṣe dáadáa nínú ìjọsìn wọn mọ́. Nadia wá sọ pé: “Inú wa dùn pé àwọn òbí wa sapá gan-an láti kọ́ wa lédè ìbílẹ̀ wa àti pé wọn ò jẹ́ ká lọ síjọ míì. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ti jẹ́ ká láǹfààní láti ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà.”
BÁWỌN MÍÌ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́
17. (a) Ta ni Jèhófà gbéṣẹ́ ọmọ títọ́ fún? (b) Báwo làwọn míì ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí òtítọ́ lè jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ wọn?
17 Ojúṣe tí Jèhófà fáwọn òbí ni pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú òtítọ́, kì í ṣe ojúṣe àwọn òbí wọn àgbà tàbí ti ẹlòmíì. (Ka Òwe 1:8; 31:10, 27, 28.) Síbẹ̀, táwọn òbí kan ò bá gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ ládùúgbò tí wọ́n ṣí lọ, ó lè gba pé káwọn míì ran àwọn òbí náà lọ́wọ́ káwọn òbí náà lè dọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ò sọ pé wọ́n ti gbéṣẹ́ wọn fún ẹlòmíì ṣe. Ṣe ni wọ́n fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí lè ní káwọn alàgbà gba àwọn nímọ̀ràn nípa báwọn ṣe lè máa ṣe ìjọsìn ìdílé àti báwọn ṣe lè rí ọ̀rẹ́ gidi fáwọn ọmọ wọn nínú ètò Ọlọ́run.
18, 19. (a) Báwo làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó dàgbà dénú ṣe lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́? (b) Kí làwọn òbí gbọ́dọ̀ máa ṣe?
18 Látìgbàdégbà, àwọn òbí lè máa pe àwọn ìdílé míì wá sí ìjọsìn ìdílé wọn. Yàtọ̀ síyẹn, táwọn ọ̀dọ́ bá ń bá àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú ṣọ̀rẹ́, wọ́n máa ń tẹ̀ síwájú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè máa bá irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kí wọ́n jọ lọ gbafẹ́. (Òwe 27:17) Shan tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Mi ò lè gbàgbé àwọn arákùnrin tó mú mi bí ọ̀rẹ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo máa ń kọ́ tá a bá jọ ń múra iṣẹ́ tí mo ní nípàdé sílẹ̀. Mo sì máa ń gbádùn àwọn àkókò tá a máa ń lò pa pọ̀.”
19 Ẹni táwọn òbí bá yàn pé kó ran ọmọ wọn lọ́wọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọmọ náà mọ̀ pé ó yẹ kó máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀. Ẹni náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó bá ń sọ̀rọ̀ tó dáa nípa àwọn òbí ọmọ náà, tí kò sì gba ojúṣe àwọn òbí náà ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ kó máa bá ọmọ náà ṣe àwọn eré táwọn èèyàn á máa kọminú sí, yálà nínú ìjọ àbí lójú àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. (1 Pét. 2:12) Kì í ṣe pé káwọn òbí kàn fa ọmọ wọn lé ẹnì kan lọ́wọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ mọ bí ẹni náà ṣe ń ran ọmọ náà lọ́wọ́. Ó yẹ káwọn òbí rántí pé àwọn gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fúnra wọn.
20. Kí làwọn òbí lè ṣe tí wọ́n bá fẹ́ káwọn ọmọ wọn túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
20 Ẹ̀yin òbí, ẹ bẹ Jèhófà pé kó ràn yín lọ́wọ́, kẹ́ ẹ sì ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ lè ṣe. (Ka 2 Kíróníkà 15:7.) Kì í ṣe ohun tó wù yín ló yẹ kẹ́ ẹ kà sí pàtàkì jù bí kò ṣe báwọn ọmọ yín ṣe máa sún mọ́ Jèhófà. Ẹ sapá láti rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dọ́kàn àwọn ọmọ yín. Ẹ má ṣe ronú láé pé àwọn ọmọ yín ò ní sin Jèhófà. Tí àwọn ọmọ yín bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó dáa tẹ́ ẹ fi lélẹ̀, á máa ṣe yín bíi ti àpọ́sítélì Jòhánù tó sọ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.”—3 Jòh. 4.
^ ìpínrọ̀ 7 Wo àpilẹ̀kọ náà “You Can Learn Another Language!” nínú Jí! March 2007 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 10 sí 12.