GBÓLÓHÙN KAN LÁTINÚ BÍBÉLÌ
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jini Kí Jésù Tó San Ìràpadà?
Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, àfi ká nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà tí Jésù fi ẹ̀jẹ̀ ẹ̀ san. (Éfé. 1:7) Àmọ́ ṣáájú kí Jésù tó fi ẹ̀mí ẹ̀ rà wá pa dà, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run, nínú ìmúmọ́ra rẹ̀, ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé nígbà àtijọ́ jini.” (Róòmù 3:25) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni Jèhófà ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini kí Jésù tó san ìràpadà, síbẹ̀ tí Jèhófà ṣì jẹ́ onídàájọ́ òdodo?
Lójú Jèhófà, ṣe ló dà bíi pé ó ti san ìràpadà náà ní gbàrà tó ṣèlérí pé òun máa yọ̀ǹda “ọmọ” kan tó máa gba aráyé là, ìyẹn àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí tó ṣe. (Jẹ́n. 3:15; 22:18) Torí náà, ó dá Ọlọ́run lójú pé Ọmọ bíbí ẹ̀ kan ṣoṣo máa fi tinútinú yọ̀ǹda ara ẹ̀, kó lè ra àwọn èèyàn pa dà nígbà tó bá fẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Gál. 4:4; Héb. 10:7-10) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù wà láyé, Jèhófà fún un láṣẹ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn èèyàn, nígbà tí kò tíì san ìràpadà náà. Torí náà, Jésù lè dárí ji àwọn tó bá nígbàgbọ́ torí ó mọ̀ pé ìràpadà tí òun máa san lọ́jọ́ iwájú máa mú ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.—Mát. 9:2-6.