Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àwọn wo ni ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì, iṣẹ́ wo ni wọ́n sì ń ṣe?
Onírúurú iṣẹ́ làwọn ọmọ Léfì tí kì í ṣe àlùfáà máa ń ṣe, lára ẹ̀ ni kí wọ́n ṣe ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì tàbí iṣẹ́ ọlọ́pàá, olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì ló sì ń darí wọn. Ohun tí òǹkọ̀wé Júù kan tó ń jẹ́ Philo sọ nípa iṣẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí ni pé: “Àwọn kan lára [àwọn ọmọ Léfì] yìí ló máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí tẹ́ńpìlì, àwọn míì sì ń ṣọ́ inú [tẹ́ńpìlì] níwájú ibi mímọ́ kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣèèṣì tàbí mọ̀ọ́mọ̀ wọlé. Àwọn kan lára wọn máa ń rìn yí tẹ́ńpìlì náà ká kí wọ́n lè dáàbò bò ó. Wọ́n sì máa ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn láàárọ̀ àti lálẹ́.”
Àwọn ọlọ́pàá yìí máa ń ran ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn lọ́wọ́. Àwọn nìkan sì ni ìjọba Róòmù gbà láyè láti gbé ohun ìjà.
Ọ̀mọ̀wé kan tó ń jẹ́ Joachim Jeremias sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé ojoojúmọ́ ni òun ń kọ́ni nínú Tẹ́ńpìlì, síbẹ̀ tí wọn ò mú òun túbọ̀ ṣe kedere tó bá jẹ́ pé àwọn ọlọ́pàá Tẹ́ńpìlì ló wá fàṣẹ ọba mú un (Mát. 26:55).” Ọ̀mọ̀wé yìí kan náà gbà pé àwọn ọlọ́pàá tẹ́ńpìlì yẹn náà ni wọ́n rán nígbà kan pé kí wọ́n lọ mú Jésù wá. (Jòh. 7:32, 45, 46) Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn ọlọ́pàá yìí àti olórí wọn ni ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn rán pé kí wọ́n lọ mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá, àwọn ọlọ́pàá yẹn náà ló sì ṣeé ṣe kó wọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kúrò nínú tẹ́ńpìlì.—Ìṣe 4:1-3; 5:17-27; 21:27-30.