Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22

Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi

Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi

“Kí a sì batisí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín.”​—ÌṢE 2:38.

ORIN 72 À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé kí àwọn èrò tó kóra jọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe?

ÈRÒ rẹpẹtẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù. Ìlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá, èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ń sọ. Ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ṣàdédé làwọn Júù kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè ìbílẹ̀ àwọn àlejò náà! Àmọ́, ọ̀rọ̀ táwọn Júù yẹn sọ fáwọn àlejò náà àtohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ tún yani lẹ́nu jùyẹn lọ. Lára ohun tí wọ́n sọ fún wọn ni pé tí wọ́n bá nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun tí àwọn àlejò yẹn gbọ́ lọ́jọ́ yẹn wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an. Kódà, wọ́n béèrè pé: “Kí ni ká ṣe?” Pétérù wá sọ fún wọn pé ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ṣèrìbọmi.​—Ìṣe 2:37, 38.

Arákùnrin kan àtìyàwó ẹ̀ ń fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (Wo ìpínrọ̀ 2)

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)

2 Mánigbàgbé lohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló ṣèrìbọmi lọ́jọ́ yẹn, tí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù. Àtìgbà yẹn ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu, iṣẹ́ yẹn la sì ń ṣe títí dòní. Àmọ́ lónìí, a ò lè sọ ẹnì kan dọmọ ẹ̀yìn ká sì ṣèrìbọmi fún un láàárín wákàtí mélòó kan péré. Ó lè tó oṣù mélòó kan, ọdún kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó lè tẹ̀ síwájú, kó sì ṣèrìbọmi. Gbogbo àwa tá à ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ la mọ̀ pé iṣẹ́ kékeré kọ́ ni iṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bó o ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú kó sì ṣèrìbọmi.

RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ RẸ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ MÁA FI OHUN TÓ Ń KỌ́ SÍLÒ

3. Kí ni Mátíù 28:19, 20 sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè ṣèrìbọmi?

3 Kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ máa fi ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. (Ka Mátíù 28:19, 20.) Tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bá ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ó máa dà bí “ọkùnrin kan tó ní òye” tí Jésù ṣàkàwé pé ó walẹ̀ jìn kó lè kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. (Mát. 7:24, 25; Lúùkù 6:47, 48) Báwo la ṣe lè ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè fi ohun tó ń kọ́ sílò? Ẹ jẹ́ ká wo ohun mẹ́ta tá a lè ṣe.

4. Kí lo lè ṣe láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú, kó sì ṣèrìbọmi? (Wo àpótí náà “ Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Mọ Ohun Tó Yẹ Kó Ṣe àti Bó Ṣe Lè Ṣe Wọ́n.”)

4 Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ ohun tó lè ṣe. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí. Ká sọ pé o fẹ́ rìnrìn àjò kan tó jìnnà gan-an, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ dúró láwọn ibì kan kẹ́ ẹ lè sinmi kára sì tù yín. Ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìrìn náà sú yín. Lọ́nà kan náà, tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ẹ̀ lè tètè bà, tó sì lé wọn bá, á rí i pé ìrìbọmi kì í ṣe àfojúsùn tọ́wọ́ òun ò lè tẹ̀. Lo apá tá a pè ní “Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè tẹ̀ síwájú. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, ẹ jíròrò bí ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ fẹ́ ṣe ṣe bá ohun tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ mu. Tó o bá ní nǹkan míì tó o fẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe, o lè kọ ọ́ sí apá tá a pè ní “Àwọn Nǹkan Míì.” Ẹ jọ máa jíròrò apá yìí látìgbàdégbà kẹ́ ẹ lè mọ àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ̀ lè tètè bà àtèyí tó máa gba àkókò díẹ̀.

5. Kí ni Jésù sọ pé kí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan ṣe nínú Máàkù 10:17-22, kí sì nìdí?

5 Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé ẹ̀. (Ka Máàkù 10:17-22.) Jésù mọ̀ pé ó máa ṣòro fún ẹni tó lọ́rọ̀ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀. (Máàkù 10:23) Síbẹ̀, ohun tí Jésù sọ pé kí ọkùnrin yẹn ṣe gan-an nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nígbà míì, a lè má fẹ́ sọ fún akẹ́kọ̀ọ́ wa pé kó ṣe àwọn àyípadà kan torí a ronú pé kò ní rọrùn fún un. Ó lè gba àkókò kí ẹnì kan tó lè bọ́ ìwà àtijọ́ sílẹ̀ kó sì gbé ìwà tuntun wọ̀. (Kól. 3:9, 10) Àmọ́ tó o bá tètè bá a sọ ọ́, ìyẹn á jẹ́ kó lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn àyípadà tó yẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.​—Sm. 141:5; Òwe 27:17.

6. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ wa sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀?

6 Ó ṣe pàtàkì ká bi akẹ́kọ̀ọ́ wa láwọn ìbéèrè táá jẹ́ ká mọ èrò ẹ̀ nípa ohun tó ń kọ́. Ìyẹn máa jẹ́ ká mọ bó ṣe lóye ohun tó ń kọ́ àtohun tó gbà gbọ́. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòro fún un láti gbà gbọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ní àwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó o mọ ohun tó wà lọ́kàn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó wà ní ẹ̀kọ́ 4 ni: “Lérò tìẹ, báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà tó o bá ń lo orúkọ rẹ̀?” Bákan náà ní ẹ̀kọ́ 9, ìbéèrè kan wà níbẹ̀ tó sọ pé: “Àwọn nǹkan wo ló wù ẹ́ kó o béèrè nínú àdúrà rẹ?” Níbẹ̀rẹ̀, ó lè má rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè yìí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè jẹ́ kó ronú nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì àtàwọn àwòrán tó wà níbẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó lè sọ èrò ẹ̀.

7. Báwo la ṣe lè fi ìrírí àwọn ará ran akẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́?

7 Tí kò bá rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ ẹ láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, o lè sọ ìrírí àwọn ará tó ti ṣe irú àwọn àyípadà yẹn fún un, kó lè rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ṣòro fún akẹ́kọ̀ọ́ rẹ láti máa wá sípàdé, ẹ lè jọ wo fídíò Jèhófà Bìkítà Nípa Mi tó wà ní apá “Ṣèwádìí” ní ẹ̀kọ́ kẹrìnlá (14). Nínú ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! wàá rí irú àwọn ìrírí yìí ní apá tá a pè ní “Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀” tàbí “Ṣèwádìí.” * Ṣọ́ra kó o má fi akẹ́kọ̀ọ́ rẹ wé ẹlòmíì, kó o wá máa sọ pé, “Tí ẹni yìí bá lè ṣe é, ìwọ náà lè ṣe é.” Kàkà bẹ́ẹ̀, mẹ́nu kan àwọn ìlànà Bíbélì tó ran ẹni náà lọ́wọ́. O tún lè mẹ́nu kan àwọn ohun pàtó tí onítọ̀hún ṣe. Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó mọ bí Jèhófà ṣe ran ẹni náà lọ́wọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, á mọ bí òun ṣe lè fi ẹ̀kọ́ ibẹ̀ sílò.

8. Báwo la ṣe lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

8 Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lọ́nà wo? Máa tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ Jèhófà ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run aláyọ̀ ni Jèhófà, ó sì máa ń ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lẹ́yìn. (1 Tím. 1:11; Héb. 11:6) Jẹ́ kó mọ̀ pé ó máa jàǹfààní tó bá ń fi ohun tó ń kọ́ sílò, ìyẹn sì máa jẹ́ kó dá a lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Àìsá. 48:17, 18) Bí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á yá a lára láti ṣe àwọn àyípadà tó yẹ.​—1 Jòh. 5:3.

FOJÚ AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ MỌ ÀWỌN ARÁ

9. Kí ni Máàkù 10:29, 30 sọ tó máa jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ yááfì àwọn nǹkan kan kó lè ṣèrìbọmi?

9 Kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó lè ṣèrìbọmi, ó gbọ́dọ̀ yááfì àwọn nǹkan kan. Bíi ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tá a mẹ́nu bà lẹ́ẹ̀kan, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan gbọ́dọ̀ ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan tara. Tí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ò bá bá ìlànà Bíbélì mu, ó máa gba pé kí wọ́n wá iṣẹ́ míì. Àwọn míì máa ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ wọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sílẹ̀. Ní tàwọn míì, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí kò nífẹ̀ẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè pa wọ́n tì. Jésù sọ pé ó lè ṣòro fún àwọn kan láti yááfì àwọn nǹkan yìí. Àmọ́, ó ṣèlérí pé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn òun máa rí ìbùkún gbà. Táwọn mọ̀lẹ́bí wọn bá tiẹ̀ pa wọ́n tì, àwọn ará máa gbárùkù tì wọ́n, wọ́n á sì fìfẹ́ hàn sí wọn. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Kí lo lè ṣe táá jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ rí ẹ̀bùn tí Jésù ṣèlérí yìí gbà?

10. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tí Manuel sọ?

10 Mú akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́rẹ̀ẹ́. Ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Arákùnrin Manuel tó ń gbé ní Mẹ́síkò sọ nípa ẹni tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Ó ní: “Ká tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ló ti máa ń béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún mi. Ìyẹn máa ń jẹ́ kára mi balẹ̀, ó sì máa ń rọrùn fún mi láti bá a sọ ohunkóhun. Mo mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ mi lóòótọ́.”

11. Àǹfààní wo làwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa máa rí tá a bá mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́?

11 Máa lo àkókò pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ bí Jésù ṣe lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Jòh. 3:22) Tó bá bọ́gbọ́n mu, o lè ní kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ wá sílé rẹ, kẹ́ ẹ jọ jẹun tàbí kẹ́ ẹ jọ wo ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa mọrírì irú ìkésíni bẹ́ẹ̀ pàápàá lásìkò táwọn èèyàn ń ṣọdún tí kò sì rẹ́ni fojú jọ. Arákùnrin Kazibwe tó ń gbé ní Uganda sọ pé: “Yàtọ̀ sí àwọn àkókò tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ nípa Jèhófà lọ́dọ̀ ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ láwọn ìgbà tá a jọ máa ń wà pa pọ̀. Mo rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ẹ̀ gan-an, wọ́n sì ń láyọ̀. Ohun tó wu èmi náà nìyẹn.”

Tó o bá ń mú àwọn akéde míì lọ sọ́dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, á rọrùn fún un láti máa wá sípàdé (Wo ìpínrọ̀ 12) *

12. Kí nìdí tó fi dáa ká máa mú akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ wa?

12 Máa mú àwọn akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ. Nígbà míì, ó lè ṣe wá bíi pé ká máa dá lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tàbí ká máa lọ pẹ̀lú akéde kan náà ní gbogbo ìgbà. Ó lè rọrùn fún wa lóòótọ́, àmọ́ akẹ́kọ̀ọ́ wa máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń mú akéde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Dmitrii tó ń gbé ní Moldova sọ pé: “Akéde kọ̀ọ̀kan tó wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ mi ló ní ẹ̀bùn tiẹ̀, bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣàlàyé nǹkan yàtọ̀ síra. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n rí onírúurú ọ̀nà tí mo lè gbà fi ohun tí mò ń kọ́ sílò. Yàtọ̀ síyẹn, ojú ò tì mí nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sípàdé torí pé ọ̀pọ̀ àwọn ará yẹn ni mo ti mọ̀.”

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa wá sípàdé?

13 Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kó lè máa wá sípàdé. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ti pàṣẹ fáwa ìránṣẹ́ ẹ̀ pé ká máa kóra jọ láti jọ́sìn òun. (Héb. 10:24, 25) Yàtọ̀ síyẹn, ṣe làwa tá a wà nínú ìjọ dà bí ọmọ ìyá. Tá a bá wà nípàdé, ṣe ló dà bí ìgbà tí gbogbo wa jọ ń jẹ oúnjẹ aládùn. Tó o bá ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lọ́wọ́ láti máa wá sípàdé, ìgbésẹ̀ pàtàkì kan lo ràn án lọ́wọ́ láti gbé yẹn. Ìyẹn á mú kó tẹ̀ síwájú láti ṣèrìbọmi. Àmọ́ ó lè má rọrùn fún un láti gbé ìgbésẹ̀ yìí. Báwo ni ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ṣe lè ràn án lọ́wọ́?

14. Kí la lè ṣe táá mú kó wu akẹ́kọ̀ọ́ wa láti máa wá sípàdé?

14 O lè lo ẹ̀kọ́ kẹwàá nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ máa wá sípàdé. Ká tó mú ìwé yìí jáde, a ní káwọn akéde kan tó nírìírí lo ẹ̀kọ́ yìí láti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn akéde náà sọ pé ẹ̀kọ́ náà mú kó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn láti máa wá sípàdé. Àmọ́, kò dìgbà tẹ́ ẹ bá dé ẹ̀kọ́ kẹwàá, kó o tó ní kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ máa wá sípàdé. Àtìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti sọ fún un pé kó máa wá sípàdé, kó o sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà. Àmọ́ fi sọ́kàn pé ìṣòro ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń ní. Torí náà, mọ ìṣòro akẹ́kọ̀ọ́ rẹ, kó o sì ràn án lọ́wọ́. Má jẹ́ kó sú ẹ tí kò bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Ṣe ni kó o mú sùúrù, kó o sì máa rán an létí.

RAN AKẸ́KỌ̀Ọ́ RẸ LỌ́WỌ́ KÓ LÈ BORÍ OHUN TÓ Ń BÀ Á LẸ́RÙ

15. Àwọn nǹkan wo ló lè máa ba akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lẹ́rù?

15 Ṣé o rántí bí ẹ̀rù ṣe ń ba ìwọ náà nígbà tó o fẹ́ di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Bóyá o tiẹ̀ rò pé o ò ní lè wàásù láti ilé dé ilé, ẹ̀rù sì lè bà ẹ́ pé àwọn ìdílé ẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ máa ta kò ẹ́. Tó bá ṣe ẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá lóye bí nǹkan ṣe rí lára akẹ́kọ̀ọ́ rẹ. Jésù náà gbà pé ẹ̀rù lè ba àwọn ọmọlẹ́yìn òun. Àmọ́, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má jẹ́ kí ìbẹ̀rù dí wọn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà. (Mát. 10:16, 17, 27, 28) Kí ni Jésù ṣe láti mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ borí ìbẹ̀rù wọn? Báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

16. Báwo la ṣe lè kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ wa kó lè máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn ẹlòmíì?

16 Máa kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ pé kó máa sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn míì. Ó ṣeé ṣe kẹ́rù ba àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù nígbà tó ní kí wọ́n lọ wàásù. Àmọ́ Jésù mú kó rọrùn fún wọn nígbà tó sọ ohun tí wọ́n máa wàásù àti ibi tí wọ́n ti máa wàásù fún wọn. (Mát. 10:5-7) Báwo lo ṣe lè fara wé Jésù? Jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ mọ àwọn tó lè wàásù fún. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi í pé ṣé ó mọ ẹnì kan tí nǹkan tó ń kọ́ yìí máa ṣe láǹfààní. Kó o wá ràn án lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe máa ṣàlàyé òtítọ́ náà lọ́nà tó rọrùn. Kódà, ẹ lè lo apá tá a pè ní “Àwọn Kan Sọ Pé” àti “Ẹnì Kan Lè Béèrè Pé” nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! láti dánra wò. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá bi í lọ́nà tó ṣe pàtó àti bó ṣe lè fọgbọ́n ṣe é.

17. Báwo la ṣe lè lo Mátíù 10:19, 20, 29-31 láti ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

17 Ran akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ lọ́wọ́ kó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé Jèhófà máa ràn wọ́n lọ́wọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. (Ka Mátíù 10:19, 20, 29-31.) Fi dá akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lójú pé Jèhófà máa ran òun náà lọ́wọ́. O lè ràn án lọ́wọ́ láti gbára lé Jèhófà tó o bá ń fi àfojúsùn rẹ̀ sínú àdúrà tẹ́ ẹ̀ ń gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Franciszek tó ń gbé ní Poland sọ pé: “Ẹni tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ sábà máa ń mẹ́nu ba àwọn àfojúsùn mi nínú àdúrà. Bí mo ṣe rí i tí Jèhófà ń dáhùn àdúrà ẹni tó kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà. Mo rí i pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an nígbà tí mo ní kí wọ́n fún mi láyè lẹ́nu iṣẹ́ kí n lè máa lọ sípàdé àti àpéjọ agbègbè.”

18. Báwo ni iṣẹ́ kíkọ́ni wa ṣe rí lára Jèhófà?

18 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa gan-an. Jèhófà mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá là ń ṣe bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ òun, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. (Àìsá. 52:7) Ká tiẹ̀ wá sọ pé o ò lẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, tó o bá ń tẹ̀ lé àwọn akéde míì lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn, wàá láyọ̀ pé ìwọ náà ń ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi ṣèrìbọmi.

ORIN 60 Wọ́n Máa Rí Ìyè Tí Wọ́n Bá Gbọ́

^ ìpínrọ̀ 5 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jésù ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti báwa náà ṣe lè fara wé e. A tún máa jíròrò àwọn apá kan nínú ìwé tuntun náà Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! A dìídì ṣe ìwé yìí kó lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n á fi ṣèrìbọmi.

^ ìpínrọ̀ 7 O tún lè rí àwọn ìrírí nínú (1) Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ àkòrí náà “Bíbélì,” wá wo ìsọ̀rí náà “Ìwúlò Bíbélì,” kó o tún wá wo “‘Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà’ (Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́)” lábẹ́ ìsọ̀rí náà tàbí (2) “Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àti Ìrírí” nínú JW Library®.

^ ìpínrọ̀ 62 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan àtìyàwó ẹ̀ ń kọ́ ọkùnrin kan lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ó ní káwọn arákùnrin míì tẹ̀ lé òun lọ.