Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Alisa

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​​—Ní Tọ́kì

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​​—Ní Tọ́kì

ÀWỌN Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sọ “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn. (Mát. 24:14) Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ lọ wàásù láwọn ilẹ̀ míì. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó lọ síbi tá a wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí, ó sì wàásù jákèjádò ilẹ̀ náà. * Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 2014, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ṣètò láti wàásù nílé lóko lórílẹ̀-èdè Tọ́kì. Kí nìdí tá a fi ṣerú ètò yẹn? Àwọn wo ló sì kópa nínú rẹ̀?

“KÍ LÓ Ń ṢẸLẸ̀?”

Iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní ilẹ̀ Tọ́kì tó mílíọ̀nù mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79], àmọ́ àwọn ará tó wà níbẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Díẹ̀ ni wọ́n fi lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [2,800]. Èyí túmọ̀ sí pé akéde kan máa wàásù fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n [28,000] èèyàn. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ìwọ̀nba èèyàn ni àwọn akéde náà lè wàásù fún lórílẹ̀-èdè náà. Ìdí nìyẹn tá a fi ṣètò àkànṣe ìwàásù ká lè wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn láàárín àkókò díẹ̀. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lórílẹ̀-èdè míì tí wọ́n gbédè ilẹ̀ Tọ́kì rìnrìn-àjò lọ sí Tọ́kì kí wọ́n lè dara pọ̀ mọ́ àwọn akéde ilẹ̀ náà láti wàásù. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé àádọ́ta [550]. Kí ni wọ́n gbéṣe?

Wọ́n wàásù níbi gbogbo. Ìjọ kan nílùú Istanbul kọ̀wé pé: “Nígbà táwọn èèyàn rí wa, wọ́n béèrè pé: ‘A kàn ń rí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri. Ṣé ẹ fẹ́ ṣe àkànṣe àpéjọ nílùú wa ni?’ ” Ìjọ kan tó wà nílùú Izmir kọ̀wé pé: “Ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ ní páàkì àwọn onítakisí béèrè lọ́wọ́ alàgbà kan pé, ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ ná? Kí ló dé tẹ́ ẹ kún ìgboro báyìí?’ ” Ó dájú pé àwọn èèyàn kíyè sí ohun tá a ṣe.

Steffen

Àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì gbádùn iṣẹ́ ìwàásù náà gan-an. Bí àpẹẹrẹ, Steffen tó wá láti Denmark sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni mò ń pàdé àwọn tí kò tíì gbọ́ nípa Jèhófà, tí mo sì ń wàásù fún wọn. Inú mi dùn pé mò ń jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run.” Jean-David tó wá láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Ó máa ń gbà wá lọ́pọ̀ wákàtí ká tó parí òpópónà kan ṣoṣo. Ó yà mí lẹ́nu gan-an! Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ ni ò mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé tá a dé la ti rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀, a fàwọn fídíò wa hàn wọ́n, a sì fún wọn láwọn ìwé wa.”

Jean-David (àárín)

Àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lé àádọ́ta [550] tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè míì yẹn fi ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta [60,000] sóde láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré! Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ìwàásù náà délé dóko.

Ó mú kí ìtara àwọn ará túbọ̀ pọ̀ sí i. Àkànṣe ìwàásù yẹn mú káwọn ará tó wà ní Tọ́kì fi kún ìtara wọn. Ọ̀pọ̀ ti ń ronú àtibẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Kódà, iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé tó wà lórílẹ̀-èdè náà ti fi méjìlélọ́gọ́rin [82] lé sí iye tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì ṣẹlẹ̀ láàárín ọdún kan tí wọ́n ṣe àkànṣe ìwàásù náà.

Şirin

Ìtara àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè míì náà pọ̀ sí i, pàápàá lẹ́yìn tí wọ́n pa dà délé. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Şirin tó lọ láti orílẹ̀-èdè Jámánì sọ pé: “Bí ẹni fẹran jẹ̀kọ làwọn ará ní Tọ́kì máa ń wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Tẹ́lẹ̀, ojú máa ń tì mí láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. Àmọ́ ní báyìí, èmi náà ò kẹ̀rẹ̀, àkànṣe ìwàásù tá a ṣe yẹn ló ràn mí lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, àpẹẹrẹ àwọn ará ní Tọ́kì àti àdúrà náà tún ràn mí lọ́wọ́. Kódà, mo máa ń wàásù fáwọn èèyàn nínú ọkọ̀ ojú irin, mo sì máa ń fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú. Ní báyìí, ojú kì í tì mí mọ́.”

Johannes

Arákùnrin Johannes tóun náà lọ láti Jámánì sọ pé: “Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ lára àwọn ará yẹn mú kí n túbọ̀ sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ó máa ń yá àwọn ará tó wà ní Tọ́kì lára láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, wọ́n máa ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù. Nígbà tí mo pa dà délé, mo pinnu pé ohun témi náà á máa ṣe nìyẹn. Ní báyìí, àwọn tí mò ń wàásù fún ti pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”

Zeynep

Arábìnrin Zeynep tó lọ láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Àkànṣe ìwàásù tá a ṣe yẹn mú kí n tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù mi gan-an. Ó mú kí n túbọ̀ nígboyà, kí n sì túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”

Ó mú káwọn ará túbọ̀ sún mọ́ra wọn. Gbogbo àwọn tó kópa rí i pé lóòótọ́ la wà níṣọ̀kan, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa. Jean-David, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Ó wú wa lórí nígbà tá a rí báwọn ará ṣe gbà wá lálejò.” Ó wá fi kún un pé: “Wọ́n mú wa lọ́rẹ̀ẹ́, wọ́n ṣe wá bí ọmọ ìyá, wọ́n sì gbà wá sílé. Mo ti máa ń kà á nínú ìwé wa pé ẹgbẹ́ ará kárí ayé ni wá, àmọ́ ní báyìí ó ti wá ṣe kedere sí mi pé bó ṣe rí gan-an nìyẹn, kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu. Inú mi dùn pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn Jèhófà, mo sì ń dúpẹ́ pé ó mú kí n ní àǹfààní ńlá yìí.”

Claire (àárín)

Arábìnrin Claire tóun náà lọ láti ilẹ̀ Faransé sọ pé: “Ibi yòówù ká ti wá, ì báà jẹ́ ilẹ̀ Denmark, Faransé, Jámánì tàbí Tọ́kì, ìdílé kan ni gbogbo wa. Ṣe ló dà bíi pé Jèhófà mú àwọn ibodè tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kúrò.”

Arábìnrin Stéphanie tó lọ láti ilẹ̀ Faransé fi kún un pé: “Àkànṣe ìwàásù yẹn kọ́ mi pé ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló so wá pọ̀, kì í ṣe àṣà tàbí èdè.”

Stéphanie (àárín)

WỌ́N RÍ ÀǸFÀÀNÍ ỌLỌ́JỌ́ PÍPẸ́

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó lọ ṣe àkànṣe ìwàásù ní Tọ́kì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú àtiṣí lọ sórílẹ̀-èdè náà. Kódà, díẹ̀ lára wọn ti kó lọ síbẹ̀. A mọyì àwọn tó lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ yìí gan-an.

Bí àpẹẹrẹ, àwùjọ àdádó kan wà tó ní akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] péré. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé alàgbà kan péré ló wà níbẹ̀. Ẹ wo bí inú wọn ṣe dùn tó nígbà táwọn mẹ́fà láti ilẹ̀ Jámánì àti Netherlands ṣí lọ síbẹ̀ lọ́dún 2015 láti ràn wọ́n lọ́wọ́!

À Ń SÌN NÍBI TÍ ÀÌNÍ GBÉ PỌ̀

Kí làwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ ní Tọ́kì sọ nípa bí nǹkan ṣe rí fún wọn? Lóòótọ́, nǹkan ò rọrùn, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìbùkún ló wà nínú kéèyàn lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn kan lára wọn sọ:

Federico

Orílẹ̀-èdè Sípéènì ni Arákùnrin Federico ti wá, ó ti lé díẹ̀ lẹ́ni ogójì ọdún, ó sì ti ṣègbéyàwó. Ó sọ pé: “Ara tù mí torí pé mi ò ní ẹrù rẹpẹtẹ, ìyẹn sì mú kí n pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù.” Nígbà tí wọ́n bi í pé ṣé ó lè gba àwọn míì níyànjú láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, ó sọ pé: “Gbogbo ẹnu ni mo fi sọ pé bẹ́ẹ̀ ni! Téèyàn bá lọ sílẹ̀ òkèèrè torí àtikọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, ṣe ló ń fi ara rẹ̀ síkàáwọ́ Jèhófà. Á sì túbọ̀ rọ́wọ́ Jèhófà lára rẹ̀.”

Rudy

Arákùnrin Rudy, tó wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọgọ́ta ọdún, òun náà sì ti ṣègbéyàwó. Ó sọ pé: “Inú wa dùn gan-an pé a wà lára àwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, tá a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọ̀pọ̀ ni ò gbọ́ nípa Jèhófà rí, àmọ́ bí òtítọ́ ṣe túbọ̀ ń ṣe kedere sí wọn bẹ́ẹ̀ ni inú wọn ń dùn, ìyẹn sì ń fún wa láyọ̀.”

Sascha

Orílẹ̀-èdè Jámánì ni Arákùnrin Sascha ti wá, ó ti lé díẹ̀ lẹ́ni ogójì ọdún, òun náà sì ti ṣègbéyàwó. Ó sọ pé: “Tí mo bá wà lóde ẹ̀rí, mo máa ń pàdé àwọn tí kò gbọ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí. Inú mi máa ń dùn gan-an pé mo lè kọ́ àwọn èèyàn yẹn nípa Jèhófà.”

Atsuko

Orílẹ̀-èdè Japan ni Arábìnrin Atsuko ti wá, ó ti lọ́kọ, ó sì ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ó sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo máa ń ronú pé kí Amágẹ́dọ́nì tètè dé. Àmọ́ mi ò kí í ronú bẹ́ẹ̀ mọ́ látìgbà tí mo ti kó lọ sí Tọ́kì. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà ṣì ń mú sùúrù fún wa. Bí mo ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń darí iṣẹ́ ìwàásù, ṣe ni mo túbọ̀ ń sún mọ́ ọn.”

Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ni Arábìnrin Alisa ti wá, ó sì ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń sin Jèhófà níbí ti jẹ́ kí n tọ́ Jèhófà wò, mo sì ti rí i pé ẹni rere ni.” (Sm. 34:8) Ó tún wá sọ pé: “Jèhófà kì í ṣe Bàbá mi nìkan, Ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ tún ni, kò sí ipò tí mo wà tí mi kì í rí ọwọ́ Jèhófà lára mi. Ìgbésí ayé mi ládùn, mo láwọn ìrírí tó ń múnú mi dùn, mo sì ń rí ìbùkún rẹpẹtẹ!”

‘Ẹ WO ÀWỌN PÁPÁ’

Ìwàásù àkànṣe táwọn ará ṣe ní Tọ́kì ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn míì gbọ́ ìhìn rere náà. Síbẹ̀, iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe torí ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ la ò tíì wàásù dé. Ojoojúmọ́ làwọn tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ máa ń pàdé àwọn tí kò gbọ́ nípa Jèhófà rí. Ṣé ìwọ náà á fẹ́ sìn nírú ìpínlẹ̀ bẹ́ẹ̀? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ẹ́ pé kó o fi ìmọ̀ràn Bíbélì yìí sọ́kàn, pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Ṣé ìwọ náà lè ṣèrànwọ́ láwọn ilẹ̀ tí pápá wọn “ti funfun fún kíkórè”? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Ohun kan tó dájú ni pé tó o bá fi kún ìsapá rẹ láti wàásù ìhìn rere náà “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” ayọ̀ àti ìbùkún tó o máa rí kò ní lẹ́gbẹ́!​—Ìṣe 1:8.