Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 1

Fara Balẹ̀, Kó O sì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Fara Balẹ̀, Kó O sì Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ TI ỌDÚN 2021: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”​—ÀÌSÁ. 30:15.

ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Bíi ti Ọba Dáfídì, ìbéèrè wo ni ọ̀pọ̀ wa lè béèrè?

GBOGBO wa la fẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ kí ayé wa sì dùn. A kì í fẹ́ kí ohunkóhun kó wa lọ́kàn sókè rárá. Àmọ́ nígbà míì, ìṣòro máa ń mu wá lómi ó sì máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa. Kódà, ìṣòro lè mú kí Kristẹni kan béèrè irú ìbéèrè tí Ọba Dáfídì bi Jèhófà, pé: “Ìgbà wo ni mi ò ní dààmú mọ́, tí ẹ̀dùn ọkàn mi ojoojúmọ́ á sì dópin?”​—Sm. 13:2.

2. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Òótọ́ kan ni pé gbogbo wa la máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe tí àníyàn ò fi ní gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àá kọ́kọ́ jíròrò àwọn nǹkan tó lè mú ká máa ṣàníyàn. Lẹ́yìn náà, àá jíròrò àwọn nǹkan mẹ́fà tá a lè ṣe táá mú kọ́kàn wa balẹ̀ bá a ṣe ń kojú àwọn ìṣòro náà.

ÀWỌN NǸKAN WO LÓ LÈ MÚ KÁ ṢÀNÍYÀN?

3. Kí làwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé tó lè mú ká ṣàníyàn, kí sì nìdí tá ò fi lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀?

3 Àwọn nǹkan kan wà tó lè mú ká máa ṣàníyàn, kò sì sóhun tá a lè ṣe sí i. Bí àpẹẹrẹ, kò sóhun tá a lè ṣe sí bí owó oúnjẹ, aṣọ àti ilé ṣe ń ga sí i lọ́dọọdún. Yàtọ̀ síyẹn, a ò lè pinnu iye ìgbà táwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa máa fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wá. Bákan náà, a ò lè dá ìwà ọ̀daràn dúró ní àdúgbò wa. Ìdí tá a fi ń kojú àwọn ìṣòro yìí ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ayé yìí mọ̀ pé àwọn kan máa jẹ́ kí “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí” gbà wọ́n lọ́kàn débi pé wọn ò ní rí ti Ọlọ́run rò. (Mát. 13:22; 1 Jòh. 5:19) Abájọ tí ìṣòro fi kúnnú ayé yìí!

4. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn jù?

4 Tá a bá ń gbé àwọn ìṣòro wa sọ́kàn jù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa ṣàníyàn pé owó tó ń wọlé lè má tó gbọ́ bùkátà wa tàbí pé a lè ṣàìsàn tí ò ní jẹ́ ká lè lọ síbi iṣẹ́ tàbí kíṣẹ́ tiẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ wa. Bákan náà, ẹ̀rù tún lè máa bà wá pé a lè rú òfin Ọlọ́run tá a bá kojú ìdẹwò. Yàtọ̀ síyẹn, láìpẹ́ Sátánì máa mú kí àwọn ìjọba ayé gbéjà ko àwa èèyàn Jèhófà, ẹ̀rù sì lè máa bà wá pé a lè bọ́hùn lásìkò yẹn. Torí náà, a lè máa ronú pé, ‘Ṣé ó burú tí mo bá ń ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan yìí ni?’

5. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn”?

5 A mọ̀ pé Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ yéé ṣàníyàn.” (Mát. 6:25) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé a ò gbọ́dọ̀ ṣàníyàn rárá àti rárá? Ó dájú pé ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn! Ó ṣe tán, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ ṣàníyàn, Jèhófà ò sì tìtorí ẹ̀ bínú sí wọn. * (1 Ọba 19:4; Sm. 6:3) Ṣe ni Jésù ń fi wá lọ́kàn balẹ̀. Kò fẹ́ ká máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a nílò débi tá ò fi ní ráyè ìjọsìn Jèhófà. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí la lè ṣe tí àníyàn ò fi ní gbà wá lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ? Wo àpótí náà, “ Bó O Ṣe Lè Ṣe É.”

NǸKAN MẸ́FÀ TÓ MÁA JẸ́ KỌ́KÀN WA BALẸ̀

Wo ìpínrọ̀ 6 *

6. Kí ni Fílípì 4:​6, 7 sọ tó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ tá a bá ń ṣàníyàn?

6 (1Máa gbàdúrà déédéé. Tí ohun kan bá ń kó ẹ lọ́kàn sókè, gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. (1 Pét. 5:7) Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ, á sì fún ẹ ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye” èèyàn. (Ka Fílípì 4:​6, 7.) Jèhófà máa jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tù wá nínú, kó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀.​—Gál. 5:22.

7. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń gbàdúrà?

7 Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ pátápátá ni kó o sọ fún Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà. Sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe fún ẹ gan-an. Jẹ́ kó mọ ìṣòro tó o ní àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ. Tí ojútùú bá wà sí ìṣòro náà, sọ fún un pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n àti okun tó o nílò láti yanjú ẹ̀. Tí kò bá sí nǹkan tó o lè ṣe sí ìṣòro náà, bẹ Jèhófà pé kó fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀, kó o má bàa gbọ́rọ̀ náà sọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ. Tó o bá sọ ohun tó o fẹ́ kí Jèhófà ṣe gan-an nínú àdúrà ẹ, ìyẹn á jẹ́ kó o rí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dáhùn àdúrà náà. Àmọ́ tí Jèhófà ò bá dáhùn àdúrà ẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Ohun kan ni pé bí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa sọ ohun tá a fẹ́ gan-an, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe fẹ́ ká máa gbàdúrà nígbà gbogbo​—Lúùkù 11:​8-10.

8. Kí ló yẹ ká fi kún àdúrà wa?

8 Tó o bá ń sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ fún Jèhófà, má gbàgbé láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa, kódà lásìkò tí nǹkan nira fún wa gan-an. Àmọ́ nígbà míì, ẹ̀dùn ọkàn wa lè pọ̀ débi pé a ò ní mọ bá a ṣe lè sọ ọ́ fún Jèhófà. Kí la lè ṣe nírú àsìkò bẹ́ẹ̀? Ká rántí pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà wa kódà kó jẹ́ pé gbogbo ohun tá a lè sọ ò ju ‘Jọ̀ọ́, ràn mí lọ́wọ́.’​—2 Kíró. 18:31; Róòmù 8:26.

Wo ìpínrọ̀ 9 *

9. Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀?

9 (2Àwọn ìlànà Jèhófà ni kó o máa tẹ̀ lé, kì í ṣe tara ẹ. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ Ṣ.S.K., àwọn ará Ásíríà bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn Júdà. Káwọn Júù yẹn má bàa bọ́ sábẹ́ àjàgà àwọn ará Ásíríà, wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Íjíbítì tó jẹ́ abọ̀rìṣà. (Àìsá. 30:​1, 2) Àmọ́, Jèhófà kìlọ̀ fún wọn pé ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa yọrí sí kò ní dáa. (Àìsá. 30:​7, 12, 13) Nípasẹ̀ Àìsáyà, Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ ohun tí wọ́n á ṣe tí wọn ò fi ní kó síṣòro, tí ọkàn wọn á sì balẹ̀. Ó ní: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé” Jèhófà.​—Àìsá. 30:15b.

10. Àwọn nǹkan wo ló lè ṣẹlẹ̀ táá mú ká fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

10 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí. Ká sọ pé wọ́n fiṣẹ́ kan tó máa mówó gidi wọlé lọ̀ ẹ́, àmọ́ iṣẹ́ náà máa gba ọ̀pọ̀ àkókò, kò sì ní jẹ́ kó o fi bẹ́ẹ̀ ráyè ìjọsìn Ọlọ́run, kí lo máa ṣe? Ká sọ pé ẹnì kan níbi iṣẹ́ yín tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, kí lo máa ṣe? Kí lo máa ṣe tí òbí ẹ, ọkọ tàbí aya ẹ bá sọ fún ẹ pé: “Ọ̀kan lo máa mú nínú àwọn tàbí Jèhófà”? Tó o bá bára ẹ nírú àwọn ipò yìí, ó lè ṣòro fún ẹ láti ṣèpinnu, àmọ́ Jèhófà máa tọ́ ẹ sọ́nà. (Mát. 6:33; 10:37; 1 Kọ́r. 7:39) Ìbéèrè náà ni pé, Ṣé wàá tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà bá fún ẹ?

Wo ìpínrọ̀ 11 *

11. Àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì wo la lè gbé yẹ̀ wò táá jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa?

11 (3Kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àpẹẹrẹ tó dáa àtèyí tí kò dáa tó wà nínú Bíbélì. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa fọkàn balẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bó o ṣe ń gbé àwọn ìtàn yìí yẹ̀ wò, kíyè sí ohun tó mú kọ́kàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń kojú inúnibíni tó le. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, ẹ̀rù ò bà wọ́n. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fìgboyà sọ fún wọn pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.” (Ìṣe 5:29) Kódà lẹ́yìn tí wọ́n nà wọ́n, ọkàn àwọn àpọ́sítélì náà balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ń ti àwọn lẹ́yìn, inú ẹ̀ sì ń dùn sáwọn. Ìyẹn ló mú kí wọ́n nígboyà láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. (Ìṣe 5:40-42) Bákan náà, nígbà táwọn alátakò fẹ́ pa Sítéfánù, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ débi pé ṣe lojú ẹ̀ “dà bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:12-15) Kí nìdí? Ìdí ni pé ó dá a lójú pé òun ti rí ojú rere Jèhófà.

12. Bó ṣe wà nínú 1 Pétérù 3:14 àti 4:​14, kí ló máa jẹ́ kínú wa dùn tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wa?

12 Ó dá àwọn àpọ́sítélì lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn. Ó ṣe tán, ó fún wọn lágbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu. (Ìṣe 5:12-16; 6:8) Àmọ́, àwa ò lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lónìí. Síbẹ̀, Jèhófà lo Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti mú un dá wa lójú pé tá a bá ń jìyà nítorí òdodo, a máa rí ojú rere òun, òun á sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. (Ka 1 Pétérù 3:14; 4:14.) Torí náà, dípò ká máa ronú ṣáá nípa ohun tá a máa ṣe tí wọ́n bá ṣenúnibíni sí wa lọ́jọ́ iwájú, ṣe ló yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe nísinsìnyí kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa tì wá lẹ́yìn, á sì gbà wá là. Bíi tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ìgbàanì, àwa náà gbọ́dọ̀ fi ìlérí Jésù sọ́kàn pé: “Màá fún yín ní àwọn ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n tí gbogbo àwọn alátakò yín lápapọ̀ ò ní lè ta kò tàbí kí wọ́n jiyàn rẹ̀.” Jésù tún jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Tí ẹ bá ní ìfaradà, ẹ máa lè pa ẹ̀mí yín mọ́.” (Lúùkù 21:​12-19) Ká má sì gbàgbé pé Jèhófà rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́. Tí wọ́n bá tiẹ̀ kú, Jèhófà máa jí wọn dìde.

13. Kí la lè kọ́ lára àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

13 A tún lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tá a bá gbé àwọn àpẹẹrẹ wọn yẹ̀ wò, kò ní jẹ́ ká ṣe irú àṣìṣe tí wọ́n ṣe. Ó ṣe tán àwọn èèyàn máa ń sọ pé, àgbà tó jìn sí kòtò, ó kọ́ ará yòókù lọ́gbọ́n. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn ọdún mélòó kan tí Ásà di ọba ilẹ̀ Júdà, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Etiópíà tó pọ̀ gan-an gbéjà kò ó. Àmọ́ ó gbára lé Jèhófà, Jèhófà sì mú kó ṣẹ́gun wọn. (2 Kíró. 14:​9-12) Nígbà tó yá, Bááṣà ọba Ísírẹ́lì gbéjà kò ó pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, àmọ́ dípò kó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bó ṣe ṣe tẹ́lẹ̀, àwọn ará Síríà ló lọ sanwó fún pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. (2 Kíró. 16:​1-3) Kódà nígbà tó ṣàìsàn tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú, kò gbára lé Jèhófà.​—2 Kíró. 16:12.

14. Kí la rí kọ́ látinú àṣìṣe tí Ásà ṣe?

14 Nígbà tí Ásà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, Jèhófà ló máa ń ké pè tó bá ti níṣòro. Àmọ́ nígbà tó yá, kò wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mọ́, dípò bẹ́ẹ̀ ó máa ń fẹ́ dá yanjú ìṣòro ara ẹ̀. Lójú èèyàn, ó lè jọ pé bí Ásà ṣe lọ bẹ àwọn ará Síríà lọ́wẹ̀ yẹn bọ́gbọ́n mu. Àmọ́ àlàáfíà tí wọ́n ní ò tọ́jọ́. Jèhófà wá tipasẹ̀ wòlíì kan sọ fún un pé: “Nítorí o gbẹ́kẹ̀ lé ọba Síríà, tí o kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àwọn ọmọ ogun ọba Síríà ti bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́.” (2 Kíró. 16:7) Tá a bá níṣòro, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ máa gbára lé òye tara wa, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká jẹ́ kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà tí nǹkan kan bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ tó sì gba pé ká ṣèpinnu ní pàjáwìrì, ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ ká sì gbára lé Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ ká ṣèpinnu tó tọ́.

Wo ìpínrọ̀ 15 *

15. Kí ló yẹ ká máa ṣe tá a bá ń ka Bíbélì?

15 (4Há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí. Tó o bá rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fọkàn balẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, gbìyànjú láti há wọn sórí. Á dáa kó o kà wọ́n sókè tàbí kó o kọ wọ́n sílẹ̀, kó o lè máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀ látìgbàdégbà. Ó ṣe tán, Jèhófà pàṣẹ fún Jóṣúà pé kó máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka Ìwé Òfin déédéé, kó lè máa hùwà ọgbọ́n. Àwọn ìránnilétí tó wà nínú Òfin yẹn máa jẹ́ kó nígboyà, kó sì máa darí àwọn èèyàn Ọlọ́run láìbẹ̀rù. (Jóṣ. 1:​8, 9) Ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì ló wà tó máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ kódà tó o bá kojú àwọn ìṣòro tó sábà máa ń kó àwọn èèyàn lọ́kàn sókè tàbí dẹ́rù bà wọ́n.​—Sm. 27:​1-3; Òwe 3:​25, 26.

Wo ìpínrọ̀ 16 *

16. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń lo àwọn tó wà nínú ìjọ láti fi wá lọ́kàn balẹ̀, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé e?

16 (5Máa bá àwọn èèyàn Ọlọ́run kẹ́gbẹ́. Jèhófà máa ń lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti fi wá lọ́kàn balẹ̀ ká lè gbẹ́kẹ̀ lé òun. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń jàǹfààní látinú àwọn àsọyé tá à ń gbọ́ nípàdé àti látinú ìdáhùn àwọn ará. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń fún ara wa níṣìírí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé. (Héb. 10:​24, 25) Bákan náà, ara máa ń tù wá tá a bá sọ àwọn ìṣòro wa fún ọ̀rẹ́ wa kan tá a fọkàn tán nínú ìjọ. “Ọ̀rọ̀ rere” tí ọ̀rẹ́ wa bá sọ lè fún wa níṣìírí, kó sì mú kọ́kàn wa balẹ̀.​—Òwe 12:25.

Wo ìpínrọ̀ 17 *

17. Bó ṣe wà nínú Hébérù 6:​19, báwo ni ìrètí tá a ní ṣe lè mú kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá kojú ìṣòro?

17 (6Jẹ́ kí ìrètí tó o ní túbọ̀ dá ẹ lójú. Ìrètí tá a ní dà “bí ìdákọ̀ró fún ọkàn” wa torí ó máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ tá a bá kojú ìṣòro tàbí tí àníyàn bá gbà wá lọ́kàn. (Ka Hébérù 6:19.) Máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe nípa ọjọ́ iwájú níbi tí ò ti ní sí ohunkóhun táá máa kó wa lọ́kàn sókè mọ́. (Àìsá. 65:17) Yàtọ̀ síyẹn, fojú inú wo ara rẹ nínú ayé tuntun níbi tí ò ti ní sí ìṣòro èyíkéyìí tàbí ìdààmú mọ́. (Míkà 4:4) Bákan náà, ìrètí tó o ní á túbọ̀ dá ẹ lójú tó o bá ń sọ nípa ẹ̀ fáwọn míì. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ‘ìrètí náà á dá ẹ lójú ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ títí dé òpin.’​—Héb. 6:11.

18. Àwọn ìṣòro wo ló ṣeé ṣe ká kojú lọ́jọ́ iwájú, kí ló sì yẹ ká ṣe nípa ẹ̀?

18 Bí òpin ayé burúkú yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, ó ṣeé ṣe ká túbọ̀ kojú àwọn ìṣòro táá kó wa lọ́kàn sókè. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2021 á jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà dípò òye tiwa, àá lè kojú àwọn ìṣòro yìí, ọkàn wa á sì balẹ̀. Torí náà jálẹ̀ ọdún 2021, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé: “Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.”​Àìsá. 30:15.

ORIN 8 Jèhófà Ni Ibi Ààbò Wa

^ ìpínrọ̀ 5 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2021 tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bá a ṣe ń kójú àwọn ìṣòro tó ń tánni lókun nísinsìnyí àtèyí tá a máa kojú lọ́jọ́ iwájú. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi ìmọ̀ràn inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún yìí sílò.

^ ìpínrọ̀ 5 Àwọn ará wa kan tó jẹ́ olóòótọ́ máa ń ní ìdààmú ọkàn tó lékenkà. Àìsàn tó lágbára ni èyí, ó sì yàtọ̀ sí irú àníyàn tí Jésù ń sọ.

^ ìpínrọ̀ 63 ÀWÒRÁN: (1) Léraléra ni arábìnrin kan ń gbàdúrà nípa ohun tó ń kó ìdààmú bá a.

^ ìpínrọ̀ 65 ÀWÒRÁN: (2) Nígbà tó gba ìsinmi ọ̀sán níbi iṣẹ́, ó ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó lè mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kóun ṣe.

^ ìpínrọ̀ 67 ÀWÒRÁN: (3) Ó ń ronú nípa àwọn àpẹẹrẹ tó dáa àtàwọn èyí tí kò dáa nínú Bíbélì.

^ ìpínrọ̀ 69 ÀWÒRÁN: (4) Ó kọ ẹsẹ Bíbélì kan tó fẹ́ràn sórí bébà, ó wá lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara fìríìjì rẹ̀ kó lè máa rántí.

^ ìpínrọ̀ 71 ÀWÒRÁN: (5) Ó ń lọ sóde ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn ará.

^ ìpínrọ̀ 73 ÀWÒRÁN: (6) Ó ń mú kí ìrètí tó ní túbọ̀ dá a lójú bó ṣe ń ronú nípa ọjọ́ iwájú aláyọ̀ tá à ń retí.