ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 4
Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ Ní fún Ara Yín Túbọ̀ Jinlẹ̀
“Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín.”—RÓÒMÙ 12:10.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1. Kí ló fi hàn pé kò sí ìfẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé mọ́?
BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di ọjọ́ ìkẹyìn, “ìfẹ́ àdámọ́ni” máa ṣọ̀wọ́n tàbí lédè míì, àwọn èèyàn ò ní ní ìfẹ́ tó yẹ káwọn ọmọ ìyá ní síra wọn mọ́. (2 Tím. 3:1, 3) Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn náà ló sì ń ṣẹ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló ń kọ ara wọn sílẹ̀ tíyẹn sì ń mú kí wọ́n máa bínú síra wọn. Yàtọ̀ síyẹn, wọn kì í rí tàwọn ọmọ wọn rò, ìyẹn sì máa ń mú káwọn ọmọ náà ronú pé àwọn òbí àwọn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn. Kóńkó jabele kálukú ló ń ṣe tiẹ̀ lọ̀rọ̀ àwọn ìdílé míì bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jọ ń gbé lábẹ́ òrùlé kan náà. Ọkùnrin kan tó máa ń gba àwọn ìdílé nímọ̀ràn sọ pé: “Àwọn òbí kì í fi bẹ́ẹ̀ ráyè bá ara wọn àtàwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Bí wọn ò sí nídìí tẹlifíṣọ̀n, wọ́n á máa tẹ fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ọmọ á máa gbá géèmù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé yìí ń gbé pa pọ̀, wọn ò mọra wọn rárá.”
2-3. (a) Àwọn wo ni Róòmù 12:10 sọ pé ká ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Nínú ayé, àwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Torí náà, ó yẹ ká sapá kí wọ́n má bàa kó èèràn ràn wá. (Róòmù 12:2) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa ká lè túbọ̀ máa fìfẹ́ hàn sáwọn tá a jọ wà nínú ìdílé, ká sì jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀. (Ka Róòmù 12:10.) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí àwa àti àwọn míì ní àjọṣe tímọ́tímọ́, irú èyí tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá. Irú ìfẹ́ yìí ló yẹ ká ní fún àwọn ará wa, ó ṣe tán, ọmọ ìyá la jẹ́ nípa tẹ̀mí. Tá a bá ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì, ìyẹn á jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ.—Míkà 2:12.
3 Ká lè mọ bá a ṣe lè máa fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wa, a máa jíròrò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nínú Bíbélì.
“JÈHÓFÀ NÍ ÌFẸ́ ONÍJẸ̀LẸ́ŃKẸ́” GAN-AN
4. Kí ni Jémíìsì 5:11 sọ tó jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ Jèhófà jinlẹ̀ gan-an?
4 Bíbélì jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòh. 4:8) Ohun tí Bíbélì sọ yìí máa ń jẹ́ kó wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, Bíbélì tún sọ pé Jèhófà “ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” gan-an. (Ka Jémíìsì 5:11.) Ẹ ò rí i pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wa kọjá àfẹnusọ!
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fàánú hàn, báwo la sì ṣe lè fara wé e?
5 Ẹ kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Jémíìsì 5:11 sọ pé Jèhófà ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó tún sọ ohun míì tó jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìyẹn ni pé ó jẹ́ aláàánú. (Ẹ́kís. 34:6) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fàánú hàn sí wa ni pé ó máa ń dárí jì wá tá a bá ṣàṣìṣe. (Sm. 51:1) Nínú Bíbélì, ká fàánú hàn kọjá pé ká dárí ji ẹnì kan. Ó tún gba pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn míì máa jẹ wá lọ́kàn, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Nígbà tí Jèhófà ń sọ bó ṣe máa ń wù ú láti ràn wá lọ́wọ́, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ tóun ní sí wa kọjá èyí tí abiyamọ máa ń ní sí ọmọ ẹ̀ lọ. (Àìsá. 49:15) Tá a bá wà nínú ìṣòro, Jèhófà máa ń ṣàánú wa, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 37:39; 1 Kọ́r. 10:13) Àwa náà lè ṣàánú àwọn ará wa tá a bá ń dárí jì wọ́n, tá ò sì dì wọ́n sínú tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. (Éfé. 4:32) Àmọ́, ọ̀nà tó dáa jù tá a lè gbà fàánú hàn sáwọn ará wa ni pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì dúró tì wọ́n nígbà ìṣòro. Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tá a sì ń fàánú hàn sí wọn, ṣe là ń fara wé Jèhófà tí ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ ò láfiwé.—Éfé. 5:1.
JÓNÁTÁNÌ ÀTI DÁFÍDÌ “DI Ọ̀RẸ́ TÍMỌ́TÍMỌ́”
6. Báwo ni Jónátánì àti Dáfídì ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn tó?
6 Bíbélì sọ nípa àwọn èèyàn aláìpé tí wọ́n fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sáwọn míì. Àpẹẹrẹ kan ni ti Jónátánì àti Dáfídì. 1 Sám. 18:1) Dáfídì ni Jèhófà yàn láti jọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Ìyẹn wá mú kí Sọ́ọ̀lù máa jowú Dáfídì, ó sì ń wọ́nà àtipa á. Àmọ́, Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù ò fara mọ́ ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ ṣe yìí, torí náà kò dara pọ̀ mọ́ ọn láti lépa Dáfídì. Kódà, ṣe ni Jónátánì àti Dáfídì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, wọ́n sì jọ ṣàdéhùn pé àwọn ò ní dalẹ̀ ara àwọn.—1 Sám. 20:42.
Bíbélì sọ pé: “Jónátánì àti Dáfídì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.” (7. Sọ ohun kan tó lè mú kí Jónátánì pinnu pé òun ò ní bá Dáfídì ṣọ̀rẹ́.
7 Ìfẹ́ tó wà láàárín Jónátánì àti Dáfídì ṣàrà ọ̀tọ̀, pàápàá tá a bá ronú àwọn nǹkan tó lè mú kí Jónátánì pinnu pé òun ò ní bá Dáfídì ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbà tó ọgbọ̀n (30) ọdún lọ́wọ́ rẹ̀. Jónátánì lè ronú pé òun ò lè bá Dáfídì ṣọ̀rẹ́ torí pé òun kì í ṣẹgbẹ́ ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìrírí. Bó ti wù kó rí, Jónátánì ò fojú ọmọdé wo Dáfídì, kò sì kà á sí aláìní ìrírí.
8. Kí lo rò pó fà á tí Jónátánì fi jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi sí Dáfídì?
8 Ká sọ pé Jónátánì fẹ́ jowú Dáfídì, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ rántí pé Jónátánì ni ọmọ Ọba Sọ́ọ̀lù, òun ló sì yẹ kó rọ́pò bàbá ẹ̀ lẹ́yìn tó bá kú. Bó ti wù kó rí, kò jowú Dáfídì. (1 Sám. 20:31) Ìdí sì ni pé onírẹ̀lẹ̀ ni Jónátánì, ó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Torí náà, tinútinú ló fi fara mọ́ ìpinnu tí Jèhófà ṣe pé kí Dáfídì di ọba lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Bákan náà, ó tún dúró ti Dáfídì gbágbáágbá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá ẹ̀ ń bínú sí i torí pé ó ń gbè sẹ́yìn Dáfídì.—1 Sám. 20:32-34.
9. Ṣé Jónátánì jowú Dáfídì? Ṣàlàyé.
9 Torí pé Jónátánì ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Dáfídì, kò jowú rẹ̀ rárá. Akin lójú ogun ni Jónátánì, atamátàsé sì ni pẹ̀lú. Kódà, àwọn èèyàn máa ń sọ nípa Jónátánì àti Sọ́ọ̀lù bàbá ẹ̀ pé wọ́n “yára ju ẹyẹ idì lọ,” wọ́n sì “lágbára ju kìnnìún lọ.” (2 Sám. 1:22, 23) Torí náà, Jónátánì lè máa fọ́nnu nípa àwọn ohun ribiribi tó ti gbé ṣe lójú ogun, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kò wá bó ṣe máa gbayì ju Dáfídì lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò jowú àwọn nǹkan ribiribi tí Dáfídì ṣe lójú ogun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì bí Dáfídì ṣe lo ìgboyà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì ni Jónátánì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Dáfídì bí ara ẹ̀. Báwo làwa náà ṣe lè ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
BÁ A ṢE LÈ FI ÌFẸ́ TÓ JINLẸ̀ HÀN
10. Kí ló túmọ̀ sí pé ká “ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara [wa] látọkàn wá”?
10 Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká “ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara [wa] látọkàn wá.” (1 Pét. 1:22) Tó bá di pé ká fi ìfẹ́ hàn, kò sí ẹlẹgbẹ́ Jèhófà, òun ló fi àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ lélẹ̀. Ìfẹ́ tó ní sí wa jinlẹ̀ gan-an débi pé tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i, kò sóhun tó máa yà wá kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “jinlẹ̀” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí gba pé kéèyàn sapá tàbí kó lo gbogbo okun rẹ̀. Nígbà míì, ó lè gba pé ká “sapá” tàbí “ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe” ká lè fìfẹ́ hàn sí ẹnì kan nínú ìjọ. Táwọn èèyàn bá ṣẹ̀ wá, á dáa ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé “ẹ máa fara dà á fún ara yín nínú ìfẹ́, kí ẹ máa sapá lójú méjèèjì láti pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.” (Éfé. 4:1-3) Tá a bá fẹ́ kí “àlàáfíà” wà nínú ìjọ, a ò ní máa wá ibi tí àwọn ará wa kù sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará wa wò wọ́n.—1 Sám. 16:7; Sm. 130:3.
11. Kí ló lè mú kó ṣòro fún wa láti fi ìfẹ́ hàn nígbà míì?
11 Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, pàápàá tá a bá mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn. Ó jọ pé irú ìṣòro yìí làwọn Kristẹni kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ní. Bí àpẹẹrẹ, kò jọ pé ó ṣòro fún Yúódíà àti Síńtíkè láti ṣiṣẹ́ “pẹ̀lú [Pọ́ọ̀lù] nítorí ìhìn rere.” Àmọ́ fáwọn ìdí kan, àárín àwọn méjèèjì ò gún. Torí náà, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé “kí wọ́n ní èrò kan náà nínú Olúwa.”—Fílí. 4:2, 3.
12. Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀?
12 Kí la lè ṣe táá jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin túbọ̀ jinlẹ̀ lónìí? Tá a bá sapá láti túbọ̀ mọ àwọn ará wa, àá túbọ̀ lóye wọn, ìyẹn á sì mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wọn. A lè di ọ̀rẹ́ wọn yálà wọ́n kéré sí wa tàbí wọ́n dàgbà jù wá lọ tàbí pé àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa. Ẹ rántí pé nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jónátánì fi ju Dáfídì lọ, síbẹ̀ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni wọ́n. Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ yín tó kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí tó dàgbà jù ẹ́ lọ tó o lè mú lọ́rẹ̀ẹ́? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe lò ń fi hàn pé o “nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.”—1 Pét. 2:17.
13. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ la lè mú lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́?
13 Níbi tá a bọ́rọ̀ dé yìí, ó ṣe kedere pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ló yẹ ká ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí. Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé gbogbo wọn la lè mú lọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́? Rárá, ìyẹn lè má ṣeé ṣe. Kò sóhun tó burú tá a bá sún mọ́ àwọn kan ju àwọn míì lọ torí ohun tá a jọ nífẹ̀ẹ́ sí. Bí àpẹẹrẹ, Jésù pe gbogbo àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní “ọ̀rẹ́” rẹ̀, àmọ́ ó sún mọ́ Jòhánù ju àwọn yòókù lọ. (Jòh. 13:23; 15:15; 20:2) Àmọ́ o, Jésù ò ka Jòhánù sí pàtàkì ju àwọn yòókù lọ. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jòhánù àti Jémíìsì tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò béèrè fún ipò ọlá nínú Ìjọba Ọlọ́run, Jésù sọ fún wọn pé: “Èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi tàbí sí òsì mi.” (Máàkù 10:35-40) Torí náà bíi ti Jésù, kò yẹ ká máa ka àwọn ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ sí pàtàkì ju àwọn ará tó kù nínú ìjọ lọ. (Jém. 2:3, 4) Tá a bá ń ka àwọn kan sí pàtàkì ju àwọn míì lọ, ó lè ba àlàáfíà àti ìṣọ̀kan inú ìjọ jẹ́.—Júùdù 17-19.
14. Kí ni Fílípì 2:3 sọ tí kò ní jẹ́ ká máa bá ara wa díje?
14 Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ dénú, a ò ní máa bá ara wa díje. Ẹ rántí pé Jónátánì ò jowú Dáfídì, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wò ó bíi pé ó ń bá òun du ipò ọba. Á dáa kí gbogbo wa fìwà jọ Jónátánì, ká má ṣe máa jowú àwọn ará wa nítorí ẹ̀bùn tí wọ́n ní. Kàkà bẹ́ẹ̀, ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò pé: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ.” (Ka Fílípì 2:3.) Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kò sẹ́ni tí ò wúlò nínú ìjọ. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, tá ò sì jọ ara wa lójú, àá mọyì ẹ̀bùn táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní, àá sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn.—1 Kọ́r. 12:21-25.
15. Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tanya àtàwọn ọmọ ẹ̀?
15 Tí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀ sí wa, Jèhófà lè tù wá nínú ní ti pé ó lè lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa láti fìfẹ́ hàn sí wa, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìdílé kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2019. Lẹ́yìn tí wọ́n parí ìpàdé ọjọ́ Saturday ti Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé!,” wọ́n ń pa dà sí òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n dé sí. Arábìnrin Tanya sọ pé: “Bí èmi àtàwọn ọmọ mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe ń wakọ̀ pa dà sí ibi tá a dé sí, ṣàdédé ni ọkọ̀ kan tí bíréèkì rẹ̀ já yíwọ́ sọ́dọ̀ wa, ó sì kọ lù wá. Kò sẹ́nì kankan lára wa tó ṣèṣe, torí
náà a jáde kúrò nínú mọ́tò, a dúró sétí ọ̀nà, ara wa sì ń gbọ̀n. Ká tó mọ̀, ẹnì kan ti páàkì sétí ọ̀nà, ó sì ní ká máa bọ̀ lọ́dọ̀ òun kára wa lè balẹ̀. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn la wá mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tá a jọ ṣèpàdé yẹn ni. Kì í ṣe òun nìkan ló páàkì mọ́tò rẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin márùn-ún míì tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Sweden náà dúró. Àwọn arábìnrin yẹn gbá èmi àti ọmọbìnrin mi mọ́ra, ìyẹn sì mú kára tù wá gan-an! Mo sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣèyọnu, pé wọ́n lè máa lọ, a máa yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́, wọn ò fi wá sílẹ̀. Kódà, wọ́n dúró tì wá títí àwọn dókítà fi dé, wọ́n sì rí i dájú pé a ní gbogbo ohun tá a nílò. Ní gbogbo àsìkò yẹn, a rọ́wọ́ ìfẹ́ Jèhófà lára wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa yìí mú kí ìfẹ́ tá a ní fáwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin túbọ̀ jinlẹ̀, ó sì mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì mọyì rẹ̀ gan-an.” Ṣé ìwọ náà rántí ìgbà kan tó o nílò ìrànwọ́, tí ẹnì kan nínú ìjọ sì fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́?16. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì?
16 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá ń fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì. Ó ń mú ká tu àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú nígbà ìṣòro. Ó ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan túbọ̀ gbilẹ̀ láàárín àwa èèyàn Jèhófà. Bákan náà, bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn jẹ́ ká fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni wá, ìyẹn sì ń jẹ́ káwọn olóòótọ́ ọkàn lè wá jọ́sìn Jèhófà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, à ń fògo fún Jèhófà “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́r. 1:3) Torí náà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa sapá láti fi ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí ara wa lẹ́nì kìíní kejì!
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
^ ìpínrọ̀ 5 Jésù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní síra wọn làwọn èèyàn fi máa dá wọn mọ̀. Ó dájú pé gbogbo wa là ń sapá láti máa fìfẹ́ hàn síra wa lẹ́nì kìíní kejì. Síbẹ̀, a lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀ tá a bá ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún wọn, ìyẹn irú ìfẹ́ táwọn ọmọ ìyá kan náà máa ń ní síra wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní fún àwọn ará wa túbọ̀ jinlẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 55 ÀWÒRÁN: Alàgbà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lára alàgbà míì tó jẹ́ àgbàlagbà. Alàgbà tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí àti ìyàwó rẹ̀ lọ sílé alàgbà kejì náà, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jọ fìfẹ́ hàn síra wọn, wọ́n sì tún fún ara wọn ní nǹkan.