ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 5
Ohun Tí Lílọ sí Ìpàdé Ń Sọ Nípa Wa
‘Ẹ máa pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.’—1 KỌ́R. 11:26.
ORIN 18 A Mọyì Ìràpadà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *
1-2. (a) Kí ni Jèhófà máa ń rí bó ṣe ń kíyè sí àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi? (Wo àwòrán iwájú ìwé ìròyìn yìí.) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ÀWỌN nǹkan kan wà tí Jèhófà máa ń kíyè sí bó ṣe ń wo ẹgbàágbèje èèyàn tó pésẹ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi. Kì í ṣe báwọn èèyàn ṣe pọ̀ nìkan ló ń kíyè sí, ó tún ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà níbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń kíyè sí àwọn tó ń wá lọ́dọọdún. Lára irú àwọn bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń wá láìka inúnibíni tí wọ́n ń kojú sí. Àwọn míì sì wà tí kì í wá sáwọn ìpàdé ìjọ àmọ́ tí wọn kì í pa Ìrántí Ikú Kristi jẹ. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún máa ń kíyè sí àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi fúngbà àkọ́kọ́ torí pé wọ́n fẹ́ wá wo bá a ṣe ń ṣe é.
2 Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn bó ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ ń wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (Lúùkù 22:19) Àmọ́ kì í ṣe báwọn tó wá síbẹ̀ ṣe pọ̀ tó ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà, bí kò ṣe ohun tó mú kí wọ́n wá. Ó ṣe tán, ohun tó ń súnni ṣe nǹkan ló ṣe pàtàkì sí Jèhófà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan. Ìbéèrè náà ni pé, Kí nìdí tá a fi ń pésẹ̀ sáwọn ìpàdé tí Jèhófà ṣètò fáwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn Ìrántí Ikú Kristi tá à ń ṣe lọ́dọọdún àtàwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀ LÓ Ń MÚ KÁ WÁ SÍPÀDÉ
3-4. (a) Kí nìdí tá a fi ń pésẹ̀ sípàdé? (b) Kí ni bá a ṣe ń lọ sípàdé ń sọ nípa wa? (d) Bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 11:23-26, kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa Ìrántí Ikú Kristi jẹ?
3 Ìdí pàtàkì tá a fi ń pésẹ̀ sáwọn ìpàdé ìjọ ni pé ó jẹ́ apá kan ìjọsìn wa. A tún máa ń pésẹ̀ síbẹ̀ torí pé ibẹ̀ ni Jèhófà ti ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn tó bá jẹ́ agbéraga kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọ́ wọn ní ohunkóhun. (3 Jòh. 9) Àmọ́ ní tiwa, ó máa ń wù wá kí Jèhófà àti ètò rẹ̀ kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́.—Aísá. 30:20; Jòh. 6:45.
1 Kọ́ríńtì 11:23-26.) Ìpàdé pàtàkì yìí máa ń jẹ́ kí ìrètí ọjọ́ iwájú túbọ̀ dá wa lójú, ó sì máa ń rán wa létí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Bó ti wù kó rí, Jèhófà mọ̀ pé kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún la nílò àwọn ìránnilétí àti ìṣírí. Ìdí nìyẹn tó fi ṣètò àwọn ìpàdé míì tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó sì sọ pé ká máa pésẹ̀ síbẹ̀. Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, àá máa ṣègbọràn sí àṣẹ yìí. Abájọ tá a fi máa ń ṣètò àkókò wa ká lè múra sílẹ̀ ká sì pésẹ̀ sáwọn ìpàdé yìí.
4 Bá a ṣe ń pésẹ̀ sípàdé déédéé fi hàn pé a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, a sì fẹ́ kí Jèhófà kọ́ wa. Kì í ṣe torí ká ṣáà ti wà níbi Ìrántí Ikú Kristi la ṣe ń pésẹ̀ síbẹ̀, àmọ́ à ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé a fẹ́ pa àṣẹ Jésù mọ́, èyí tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Ka5. Kí nìdí táwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà?
5 Lọ́dọọdún, Jèhófà máa ń pe àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun, àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísá. 50:4) Wọ́n láyọ̀ pé àwọn wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé míì tá à ń ṣe. (Sek. 8:20-23) Yàtọ̀ síyẹn, inú gbogbo wa lápapọ̀ máa ń dùn bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, tá a sì ń gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ wa “àti Olùpèsè àsálà fún [wa].” (Sm. 40:17) Ká tiẹ̀ sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kí ló ṣe pàtàkì tó sì gbádùn mọ́ni tó pé kí Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n máa kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́?—Mát. 17:5; 18:20; 28:20.
6. Báwo lẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí ọkùnrin kan ní ṣe mú kó wá sí Ìrántí Ikú Kristi?
6 Lọ́dọọdún, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa ń wá sípàdé yìí. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n fún ọkùnrin kan ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi, àmọ́ ọkùnrin náà sọ pé òun ò ní lè wá. Sí ìyàlẹ́nu, lálẹ́ ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, ọkùnrin náà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, inú arákùnrin tó pè é sì dùn gan-an. Àwọn ará yọ̀ mọ́ ọkùnrin náà, inú rẹ̀ sì dùn débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kódà lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ẹ̀ẹ̀mẹta péré ni kò lè wá sípàdé. Kí ló mú kó fọwọ́ gidi mú ìpàdé? Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní ló mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Arákùnrin tó fún un ní ìwé ìkésíni sọ pé, “Ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an.” Ní báyìí, ọkùnrin náà ti ṣèrìbọmi, ó sì ń fayọ̀ sin Jèhófà. Kò sí àní-àní pé Jèhófà ló fa ọkùnrin náà sọ́dọ̀ ara rẹ̀.—2 Sám. 22:28; Jòh. 6:44.
7. Báwo làwọn ohun tá à ń kọ́ nípàdé àtohun tá à ń kà nínú Bíbélì ṣe ń mú ká túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
7 Ohun tá à ń kọ́ nípàdé àtohun tá à ń kà nínú Bíbélì lè mú ká túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Láwọn ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, àwọn ìpàdé wa máa ń dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ lára Jésù àti bó ṣe rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ tó sì fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Yàtọ̀ síyẹn, láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ kí Jésù tó kú àti lẹ́yìn tó jíǹde. Àwọn ohun tá à ń kọ́ nípàdé lásìkò yìí àtohun tá à ń kà nínú Bíbélì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ìràpadà tí Jésù ṣe fún wa. Ìyẹn máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ká sì máa ṣe ìfẹ́ Jèhófà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn.—Lúùkù 22:41, 42.
ÌGBOYÀ Ń MÚ KÁ MÁA PÉSẸ̀ SÍPÀDÉ
8. Báwo ni Jésù ṣe fi ìgboyà hàn?
8 A tún máa ń sapá láti lo ìgboyà bíi ti Jésù. Ẹ ronú nípa bí Jésù ṣe lo ìgboyà láwọn ọjọ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀. Ó mọ̀ pé láìpẹ́ Mát. 20:17-19) Síbẹ̀, kò fà sẹ́yìn, ó gbà kí wọ́n pa òun. Nígbà tí àsìkò tó, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ tí wọ́n jọ wà ní Gẹtisémánì pé: “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ. Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.” (Mát. 26:36, 46) Nígbà táwọn jàǹdùkú náà dé, ṣe ni Jésù bọ́ síwájú, ó sọ fún wọn pé òun lẹni tí wọ́n ń wá, ó sì ní kí wọ́n jẹ́ káwọn àpọ́sítélì òun máa lọ. (Jòh. 18:3-8) Àbí ẹ ò rí i pé Jésù nígboyà! Bíi ti Jésù, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn náà ń lo ìgboyà. Lọ́nà wo?
àwọn ọ̀tá máa fi òun ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n máa lu òun, wọ́n á sì pa òun. (9. (a) Kí nìdí tá a fi nílò ìgboyà ká tó lè máa wá sípàdé déédéé? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ wa ṣe lè ṣàǹfààní fún àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n?
9 Lásìkò tí nǹkan bá le, ó gba ìgboyà ká tó lè máa wá sípàdé déédéé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan máa ń wá sípàdé déédéé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ìṣòro bí àìlera, ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí ikú èèyàn wọn. Àwọn míì sì wà tó ń fojú winá àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé wọn tàbí àwọn aláṣẹ, síbẹ̀ wọn ò yé wá sípàdé. Àwọn àpẹẹrẹ yìí ń ṣàǹfààní fún àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn. (Héb. 13:3) Táwọn arákùnrin yìí bá ń gbọ́ pé à ń sin Jèhófà nìṣó láìka àwọn àdánwò tá à ń kojú, ìyẹn á fún wọn lókun, á sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ìgboyà kí wọ́n sì pinnu pé àwọn ò ní fi Jèhófà sílẹ̀. Ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tó wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé àwọn ará ń sin Jèhófà nìṣó láìbọ́hùn. (Fílí. 1:3-5, 12-14) Kí wọ́n tó dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n tàbí kété lẹ́yìn tí wọ́n dá a sílẹ̀ ló kọ lẹ́tà sáwọn Hébérù. Nínú lẹ́tà yẹn, ó rọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ náà pé kí wọ́n “jẹ́ kí ìfẹ́ ará tí [wọ́n] ní máa bá a lọ,” kí wọ́n má sì kọ ìpéjọpọ̀ ara wọn sílẹ̀.—Héb. 10:24, 25; 13:1.
10-11. (a) Àwọn wo ló yẹ ká pè wá sí Ìrántí Ikú Kristi? (b) Bó ṣe wà nínú Éfésù 1:7, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
10 Tá a bá pe àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn aládùúgbò wa sí Ìrántí Ikú Kristi, ṣe là ń fi hàn pé a nígboyà. Kí nìdí tá a fi ń pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé a mọyì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa gan-an débi pé a fẹ́ káwọn náà wà nípàdé yẹn. A fẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì rí ohun tí wọ́n lè ṣe káwọn náà lè jàǹfààní “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tí Jèhófà fi hàn sí wa nípasẹ̀ ìràpadà Jésù.—Ka Éfésù 1:7; Ìṣí. 22:17.
11 Ó ṣe kedere pé bá a ṣe ń wá sípàdé fi hàn pé a nígboyà. Yàtọ̀ síyẹn, ànímọ́ míì tún wà tá à ń fi hàn, ànímọ́ yìí ló sì gbawájú jù lọ nínú àwọn ànímọ́ tí Jèhófà àti Jésù ní.
ÌFẸ́ Ń MÚ KÁ MÁA PÉSẸ̀ SÍPÀDÉ
12. (a) Báwo làwọn ìpàdé wa ṣe ń mú ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù? (b) Kí ni 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15 rọ̀ wá pé ká ṣe ká lè fìwà jọ Jésù?
12 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti Jésù ló ń mú ká máa wá sípàdé. Ohun tá a sì ń kọ́ níbẹ̀ Róòmù 5:8) Ìrántí Ikú Kristi tó jẹ́ ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ máa ń rán wa létí bí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa ṣe jinlẹ̀ tó, kódà wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kò tíì mọyì ìràpadà náà. Torí pé a mọyì ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wa, a máa ń sapá láti fara wé Jésù bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa ojoojúmọ́. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Bákan náà, a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, a sì máa ń yìn ín torí pé ó rà wá pa dà. Ọ̀nà kan tá à ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni bá a ṣe ń dáhùn nípàdé.
ń jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún wọn túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa. (13. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀? Ṣàlàyé.
13 A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ tá a bá ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan nítorí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, onírúurú nǹkan la máa ń yááfì ká lè pésẹ̀ sáwọn ìpàdé wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìjọ ló máa ń ṣe ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ wọn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tó ti rẹ àwọn èèyàn. A sì tún máa ń ṣe ìpàdé míì ní òpin ọ̀sẹ̀ lásìkò tọ́pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ sinmi. Ṣé Jèhófà máa ń rí ìsapá tá à ń ṣe láti wá sípàdé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wá? Ó dájú pé ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bí ohun tá a yááfì bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa túbọ̀ mọyì ìfẹ́ tá a ní fún un.—Máàkù 12:41-44.
14. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn ṣe tán láti yááfì nǹkan tàbí kó fara ẹ̀ jìn fáwọn míì?
14 Jésù fi àpẹẹrẹ tó tayọ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn yááfì nǹkan tàbí kó fara ẹ̀ jìn fáwọn míì. Yàtọ̀ sí pé Jésù múra tán láti kú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ojoojúmọ́ ló tún máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó fi ire wọn ṣáájú tiẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́ gan-an, tó sì ní ìdààmú ọkàn. (Lúùkù 22:39-46) Bákan náà, bó ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn lè ṣe fún un. (Mát. 20:28) Tí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àtàwọn ará wa bá lágbára bíi ti Jésù, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi, àá sì máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé míì tá à ń ṣe.
15. Àwọn wo lọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lọ́kàn jù lọ?
15 Inú ẹgbẹ́ ará kan ṣoṣo tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú la wà, inú wa sì ń dùn bá a ṣe ń pe àwọn ẹni tuntun láti dara pọ̀ mọ́ wa. Gál. 6:10) A lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn tá a bá ń fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n wá sípàdé, pàápàá jù lọ Ìrántí Ikú Kristi. Bíi ti Jèhófà àti Jésù, inú wa máa ń dùn gan-an tí irú àwọn bẹ́ẹ̀ bá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ Baba wa ọ̀run àti Olùṣọ́ Àgùntàn wa.—Mát. 18:14.
Síbẹ̀, àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lọ́kàn jù làwọn ‘tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́’ àmọ́ tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. (16. (a) Báwo la ṣe lè máa fún ara wa níṣìírí, àǹfààní wo sì làwọn ìpàdé wa máa ń ṣe wá? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àkókò yìí ló dáa jù láti rántí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 3:16?
16 Ìrọ̀lẹ́ Friday, April 19, 2019 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Torí náà, a rọ gbogbo wa pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti túbọ̀ pe àwọn èèyàn wá sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí. (Wo àpótí náà “ Pe Àwọn Èèyàn Wá”) Jálẹ̀ ọdún yìí, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé tí Jèhófà àti ètò rẹ̀ ṣètò fún wa, tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá túbọ̀ máa fún ara wa níṣìírí. Bí òpin ayé yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, a gbọ́dọ̀ máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé torí pé wọ́n á jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká nígboyà, ká sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́. (1 Tẹs. 5:8-11) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé tọkàntara la fi mọyì ìfẹ́ tí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ní sí wa!—Ka Jòhánù 3:16.
ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
^ ìpínrọ̀ 5 Ní ìrọ̀lẹ́ Friday April 19, 2019, a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi tó jẹ́ ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́dún. Kí nìdí tá a fi ń lọ sípàdé yìí? Kò sí àní-àní pé torí ká lè múnú Jèhófà dùn ni. Bá a ṣe ń lọ sí Ìrántí Ikú Kristi àtàwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ń sọ nǹkan kan nípa wa. Kí nìyẹn? A máa rí ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí.
^ ìpínrọ̀ 50 ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
^ ìpínrọ̀ 52 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ rẹ̀ gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀. Inú rẹ̀ dùn pé wọn ò gbàgbé òun, ó sì láyọ̀ pé ìyàwó àtọmọ rẹ̀ ń ṣe dáadáa bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fara rọ lágbègbè wọn.