ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Mo Ti Rí i Pé Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Nígbàgbọ́
Ó ṢEÉ ṣe kó o rántí ọ̀rọ̀ tí ìwọ àtẹnì kan jọ sọ tó ò lè gbàgbé láé. Ní tèmi, mi ò lè gbàgbé ọ̀rọ̀ témi àtọ̀rẹ́ mi kan jọ sọ ní nǹkan bí àádọ́ta (50) ọdún sẹ́yìn. Lọ́jọ́ náà, ẹ̀gbẹ́ iná kan tá a dá la jókòó sí lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Oòrùn pa wá gan-an, àwọ̀ wa sì ti yí pa dà torí pé ọ̀pọ̀ oṣù la ti fi rìnrìn àjò. Nígbà témi àtọ̀rẹ́ mi jọ ń sọ̀rọ̀ nípa fíìmù kan tó dá lórí ẹ̀sìn, ọ̀rẹ́ mi sọ pé: “Ohun tí Bíbélì sọ kọ́ ló wà nínú fíìmù yẹn o.”
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín torí mo mọ̀ pé ọ̀rẹ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run. Mo wá bi í pé: “Kí lo mọ̀ nípa Bíbélì?” Àmọ́ kò tètè dáhùn. Nígbà tó yá, ó sọ fún mi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìyá òun, ó sì ti kọ́ òun láwọn nǹkan kan nínú Bíbélì. Torí pé mo fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bi í lóríṣiríṣi ìbéèrè.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo òru yẹn la fi sọ̀rọ̀. Ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi pé ohun tí Bíbélì sọ ni pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí. (Jòh. 14:30) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtikékeré ló ti mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ní tèmi, ó ṣàjèjì sí mi, ó sì yà mí lẹ́nu gan-an, torí ó ti pẹ́ tí mo ti máa ń gbọ́ pé aláàánú ni Ọlọ́run, òun ló sì ń darí ayé. Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ti jẹ́ kí n rí i pé Ọlọ́run kọ́ ló ń darí ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni mí, ojú mi ti rí tó.
Ọ̀kan lára àwọn Ọmọ Ogun Òfúrufú Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ni bàbá mi. Torí náà, àtikékeré ni mo ti mọ̀ pé ogun runlérùnnà lè ṣẹlẹ̀, ìgbàkigbà làwọn sójà sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í yin bọ́ǹbù tó máa pa ọ̀pọ̀ èèyàn. Ìgbà tí mo wà ní yunifásítì ní California ni wọ́n ja ogun Vietnam. Torí náà, mo dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ iléèwé tí wọ́n máa ń wọ́de. Àwọn ọlọ́pàá tó mú kóńdó dání máa ń lé wa, a kì í lè mí dáadáa, a sì máa ń dijú kí tajútajú táwọn ọlọ́pàá dà sínú afẹ́fẹ́ má bàa kó sí wa lójú bá a ṣe ń sáré lọ. Àwọn èèyàn máa ń ṣọ̀tẹ̀ síjọba gan-an nígbà yẹn, ìgboro sì máa ń dà rú. Àwọn olóṣèlú máa ń para wọn, àwọn èèyàn máa ń wọ́de, àwọn èèyàn sì tún máa ń bára wọn jà níbi gbogbo. Kálukú ló ní èrò tiẹ̀, ìròyìn oríṣiríṣi làwọn èèyàn sì ń gbé káàkiri. Ṣe ni gbogbo ẹ̀ wá tojú sú mi.
Lọ́dún 1970, mo ríṣẹ́ kan sí apá àríwá orílẹ̀-èdè Alaska, owó gọbọi ló sì ń wọlé fún mi. Nígbà tó yá, mo lọ sílùú London, mo ra alùpùpù kan, mo sì gùn ún lọ sí apá àríwá láì níbì kankan tí mò ń lọ. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, mo dé Áfíríkà. Bí mo ṣe ń rìnrìn àjò lọ, mo pàdé àwọn èèyàn táwọn náà ń sá kúrò lórílẹ̀-èdè wọn torí ìṣòro tó dé bá wọn.
Torí ohun tójú mi ti rí tí mo sì ti gbọ́, mo gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé Sátánì ló ń darí ayé.
Àmọ́ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń darí ayé, iṣẹ́ wo ló wá ń ṣe? Mo fẹ́ mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.Mo rí ìdáhùn ìbéèrè yẹn láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e. Nígbà tó yá, mo wá mọ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo, láìka ipò tí wọ́n wà sí, mo sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo wọn gan-an.
NORTHERN IRELAND—“ORÍLẸ̀-ÈDÈ TÍ WỌ́N TI Ń YÌNBỌN, TÍ WỌ́N SÌ Ń JU BỌ́ǸBÙ”
Nígbà tí mo pa dà sílùú London, mo lọ sọ́dọ̀ ìyá ọ̀rẹ́ mi, ó sì fún mi ní Bíbélì kan. Nígbà tó yá, mo lọ sílùú Amsterdam nílẹ̀ Netherlands. Ọkùnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan rí mi níbi tí mo ti ń ka Bíbélì lábẹ́ iná tó wà lópòópónà kan, ó sì ṣàlàyé àwọn nǹkan kan fún mi nínú Bíbélì. Lẹ́yìn náà, mo lọ sílùú Dublin, nílẹ̀ Ireland, mo sì rí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Mo wá yà síbẹ̀, mo sì kan ilẹ̀kùn àbáwọlé. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Arákùnrin Arthur Matthews, arákùnrin náà nírìírí, ó sì gbọ́n. Mo sọ fún un pé kó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Tọkàntọkàn ni mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ara mi sì máa ń wà lọ́nà láti ka àwọn ìwé ńlá àtàwọn ìwé ìròyìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún máa ń ka Bíbélì, mo sì máa ń gbádùn ẹ̀ gan-an! Tí mo bá lọ sípàdé, mo máa ń kíyè sí i pé àwọn ọmọdé máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn ọ̀mọ̀wé ti ń wá ìdáhùn ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Lára àwọn ìbéèrè náà ni: ‘Kí nìdí tí ìwà ibi fi pọ̀ láyé? Ta ni Ọlọ́run? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?’ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi. Ohun tó jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe ni pé àwọn nìkan ni mo mọ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí n sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1972, lẹ́yìn ọdún kan, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sì ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ kékeré kan ní Newry, lórílẹ̀-èdè Northern Ireland. Mo gba ilé síbi ẹ̀gbẹ́ òkè kan, ilé yẹn nìkan ló sì wà níbẹ̀. Àwọn màlúù kan máa ń jẹko ní pápá tó wà níbi òkè náà, mo sì máa ń múra àsọyé mi sílẹ̀ níwájú àwọn màlúù náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń jẹko, ó máa ń dà bíi pé wọ́n ń tẹ́tí sóhun tí mò ń sọ dáadáa. Òótọ́ ni pé wọn ò lè sọ fún mi tí mo bá ṣàṣìṣe nígbà tí mò ń sọ àsọyé, àmọ́ wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti mọ bí mo ṣe lè máa wojú àwùjọ. Lọ́dún 1974, mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Èmi àti Nigel Pitt la jọ ń ṣiṣẹ́ náà, a sì di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.
Ìjà kan tí wọ́n ń pè ní “Rògbòdìyàn” gbòde kan ní Northern Ireland nígbà yẹn. Torí náà, àwọn kan máa ń pe Northern Ireland ní “orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń yìnbọn, tí wọ́n sì ń ju bọ́ǹbù.” Ìjà ìgboro, àwọn ayọ́kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́, àwọn tó ń yìnbọn àtàwọn tó ń ju bọ́ǹbù sínú mọ́tò pọ̀ lágbègbè náà. Àwọn olóṣèlú máa ń bára wọn jà, ìjà ẹ̀sìn sì tún máa ń ṣẹlẹ̀. Àmọ́ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àtàwọn Kátólíìkì mọ̀ pé
àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù níbi gbogbo láìbẹ̀rù. Tá a bá wà lóde ìwàásù, àwọn tá à ń wàásù fún sábà máa ń mọ ibi tí rògbòdìyàn ti fẹ́ ṣẹlẹ̀ àti ìgbà tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, wọ́n sì máa ń kìlọ̀ fún wa pé ká má lọ síbẹ̀.Àmọ́, àwọn nǹkan tó léwu máa ń ṣẹlẹ̀. Lọ́jọ́ kan, èmi àti arákùnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Denis Carrigan lọ wàásù nílùú kan tó wà nítòsí ibi tá à ń gbé, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀, ẹ̀ẹ̀kan la sì lọ síbẹ̀ rí. Obìnrin kan fẹ̀sùn kàn wá pé sójà ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wá àti pé a wá fimú fínlẹ̀ ni. Ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ kò jọ báwọn èèyàn Northern Ireland ṣe ń sọ̀rọ̀. Nígbà tá a gbọ́ ẹ̀sùn tó fi kàn wá, ẹ̀rù bà wá gan-an torí pé tí wọ́n bá mọ̀ pé ọ̀rẹ́ sójà lẹnì kan, wọ́n lè torí ẹ̀ yìnbọn pa á tàbí kí wọ́n yìnbọn fún un ní orúnkún. Bá a ṣe wà níta nínú òtútù, tá à ń dúró de bọ́ọ̀sì tá a fẹ́ wọ̀, ṣàdédé la rí i tí ọkọ̀ kan dúró síwájú ṣọ́ọ̀bù tí obìnrin yẹn ti fẹ̀sùn kàn wá. Obìnrin tó fẹ̀sùn kàn wá yẹn jáde nínú ṣọ́ọ̀bù náà, ó ń bá àwọn ọkùnrin méjì tó wà nínú ọkọ̀ yẹn sọ̀rọ̀, ó sì ń nawọ́ sí wa. Àwọn ọkùnrin náà rọra wa mọ́tò wá síbi tá a wà, wọ́n sì bi wá láwọn ìbéèrè kan nípa ìgbà tí bọ́ọ̀sì tá a fẹ́ wọ̀ máa dé. Nígbà tí bọ́ọ̀sì yẹn dé, wọ́n bá awakọ̀ bọ́ọ̀sì náà sọ̀rọ̀, àmọ́ a ò gbọ́ ohun tí wọ́n bá a sọ. Kò sẹ́nì kankan nínú bọ́ọ̀sì náà, torí náà, a gbà pé àwọn ló ní kí bọ́ọ̀sì yẹn wá gbé wa, kí wọ́n lè lọ fìyà jẹ wá. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà tí mo bọ́lẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì náà, mo bi awakọ̀ náà pé: “Àwọn ọkùnrin méjì tó wá bá ẹ yẹn, kí ni wọ́n ń bi ẹ́ nípa wa?” Ó ní: “Mo sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín. Torí náà, ẹ fọkàn yín balẹ̀, kò séwu.”
Lọ́dún 1976, ní àpéjọ agbègbè kan tá a ṣe nílùú Dublin, mo pàdé aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Pauline Lomax, orílẹ̀-èdè England ló sì ti wá. Arábìnrin tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni, ó nírẹ̀lẹ̀, ó sì níwà tó dáa. Àtikékeré lòun àti àbúrò ẹ̀ ọkùnrin tó ń jẹ́ Ray ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọdún kan lẹ́yìn náà, èmi àti Pauline ṣègbéyàwó, a sì ń bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nìṣó nílùú Ballymena, lórílẹ̀-èdè Northern Ireland.
A bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ alábòójútó àyíká, a sì ṣe é fúngbà díẹ̀. A máa ń lọ bẹ àwọn ará wò ní Belfast, Londonderry àti láwọn agbègbè míì tó léwu. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa yìí nígbàgbọ́ tó lágbára, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n pa ẹ̀kọ́ èké tì, tí ò jẹ́ kí wọ́n ṣe ẹ̀tanú mọ́, tí ò sì jẹ́ kí wọ́n kórìíra àwọn èèyàn mọ́ kí wọ́n lè wá sin Jèhófà. Èyí wú wa lórí gan-an torí Jèhófà bù kún wọn, ó sì dáàbò bò wọ́n!
Ọdún mẹ́wàá ni mo fi gbé lórílẹ̀-èdè Northern Ireland. Nígbà tó yá, lọ́dún 1981 wọ́n pe èmi àtìyàwó mi wá sí kíláàsì kejìléláàádọ́rin (72) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn tá a kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ní ká lọ máa sìn lórílẹ̀-èdè Sierra Leone, ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà.
ÀWỌN ARÁ NÍ SIERRA LEONE NÍGBÀGBỌ́ BÍ WỌN Ò TIẸ̀ LÓWÓ LỌ́WỌ́
Ilé àwọn míṣọ́nnárì là ń gbé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mọ́kànlá (11) la sì jọ ń gbébẹ̀. Ilé ìdáná kan, ilé ìgbọ̀nsẹ̀ mẹ́ta, ilé ìwẹ̀ méjì, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ kan, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń fọṣọ kan àti ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbẹ aṣọ kan ni gbogbo wa ń lò. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń múná lọ, a kì í sì í mọ̀gbà tí wọ́n máa mú un pa dà wá. Eku pọ̀ gan-an lórí òrùlé wa, ejò ṣèbé náà sì máa ń wọnú àjà ilẹ̀ ilé náà.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún wa níbẹ̀, a máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù wa gan-an. Àwọn èèyàn fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ará ìlú yẹn máa ń pè mí ní “Ọ̀gbẹ́ni Robert,” wọ́n sì máa ń pe Pauline ìyàwó mi ní “Ìyáàfin Robert.” Nígbà tó yá, ọwọ́ mi máa ń dí gan-an nítorí iṣẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tí mò ń ṣe, mi kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ lọ sóde ẹ̀rí. Làwọn aráàlú bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í pe ìyàwó mi ní “Ìyáàfin Pauline,” wọ́n
sì ń pe èmi ní “Ọ̀gbẹ́ni Pauline.” Àmọ́ Pauline ìyàwó mi nífẹ̀ẹ́ orúkọ tí wọ́n ń pè wá yẹn!Ọ̀pọ̀ àwọn ará ni ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, àmọ́ Jèhófà máa ń bójú tó wọn, ó sì máa ń pèsè fún wọn lọ́nà tí wọn ò retí. (Mát. 6:33) Mo rántí arábìnrin kan tó jẹ́ pé gbogbo owó tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ ló fẹ́ fi ra oúnjẹ tóun àtàwọn ọmọ ẹ̀ máa jẹ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ó kó gbogbo owó náà fún arákùnrin kan tí ara ẹ̀ ò yá, tí ibà ń ṣe, tí ò sì lówó kankan tó máa fi ra oògùn. Nígbà tó yá, lọ́jọ́ yẹn kan náà, ṣàdédé ni obìnrin kan wá bá arábìnrin wa, ó sọ pé kó bá òun ṣerun, ó sì sanwó ẹ̀ fún un. Ọ̀pọ̀ irú ìrírí báyìí làwọn ará wa ní.
MO KỌ́ ÀṢÀ ÌBÍLẸ̀ TUNTUN NÍ NÀÌJÍRÍÀ
Lẹ́yìn tá a lo ọdún mẹ́sàn-án ní Sierra Leone, ètò Ọlọ́run ní ká máa lọ sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Nàìjíríà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì Nàìjíríà tóbi gan-an ju tibi tá a wà tẹ́lẹ̀. Iṣẹ́ ọ́fíìsì tí mò ń ṣe nígbà tá a wà ní Sierra Leone náà ni mò ń ṣe nígbà tá a dé Nàìjíríà, àmọ́ iṣẹ́ Pauline yí pa dà, kò sì rọrùn fún un. Tẹ́lẹ̀, ó máa ń lo àádóje (130) wákàtí lóde ìwàásù lóṣooṣù, àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Àmọ́ ní Bẹ́tẹ́lì tá a wà báyìí, ibi tí wọ́n ti ń ránṣọ ni wọ́n ti ní kó máa ṣiṣẹ́. Ó máa ń tún àwọn aṣọ tó ti ya rán, ibẹ̀ ló sì máa ń wà jálẹ̀ ọjọ́ kan. Ó gba àkókò díẹ̀ kí ibẹ̀ tó mọ́ ọn lára, àmọ́ nígbà tó rí i pé àwọn èèyàn mọyì iṣẹ́ tóun ń ṣe, ìyẹn jẹ́ kó lè fún àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì níṣìírí.
Nígbà tá a dé Nàìjíríà, àṣà ìbílẹ̀ wọn ṣàjèjì sí wa, a sì rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan la ní láti kọ́. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan wá sí ọ́fíìsì mi, ó sì fi arábìnrin kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pè sí Bẹ́tẹ́lì hàn mí. Bí mo ṣe fẹ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́ báyìí, ṣe ló kúnlẹ̀ síwájú mi. Ìyẹn jọ mí lójú gan-an! Mo rántí ẹsẹ Bíbélì méjì kan lójú ẹsẹ̀, ìyẹn Ìṣe 10:25, 26 àti Ìfihàn 19:10. Mo wá sọ lọ́kàn mi pé, ‘Àbí kí n sọ fún un pé kó má kúnlẹ̀ kí mi mọ́ ni?’ Àmọ́ mo tún rò ó pé wọ́n ti pe ẹni yìí wá sí Bẹ́tẹ́lì, torí náà ó máa lóye ohun tí Bíbélì sọ dáadáa.
Kí n sòótọ́, ara mi ò balẹ̀ ní gbogbo àkókò tá a fi jọ ń sọ̀rọ̀, àmọ́ nígbà tó yá, mo ṣèwádìí nípa ọ̀nà tó gbà kí mi yẹn. Mo wá rí i pé àṣà ìbílẹ̀ arábìnrin yẹn ló jẹ́ kó kí mi bẹ́ẹ̀, bí wọ́n sì ṣe ń kí àwọn àgbàlagbà nìyẹn. Láwọn apá ibì kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣe làwọn ọkùnrin máa ń dọ̀bálẹ̀, àwọn obìnrin sì máa ń kúnlẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ kí àgbàlagbà. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà, kì í ṣe pé wọ́n ń jọ́sìn wọn. Àwọn èèyàn tó ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀ náà wà nínú Bíbélì. (1 Sám. 24:8) Inú mi dùn pé mi ò sọ ohun tó lè kó ìtìjú bá arábìnrin yẹn torí mi ò mọ̀ pé bí wọ́n ṣe ń kí àwọn àgbàlagbà nìyẹn.
a Ìgbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ló kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ nígbà tó yá, àyẹ̀wò táwọn oníṣègùn ṣe fi hàn pé ó lárùn ẹ̀tẹ̀. Wọ́n ní kó lọ máa gbé ní àgọ́ àwọn adẹ́tẹ̀, òun nìkan sì ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dojú kọ àtakò tó le gan-an, àwọn adẹ́tẹ̀ tó ju ọgbọ̀n (30) lọ ló kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀.
Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tipẹ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà la bá pàdé. Ọ̀kan lára wọn ni Arákùnrin Isaiah Adagbona.ÀWỌN ARÁ NÍ SÙÚRÙ FÚN MI GAN-AN NÍGBÀ TÍ MO WÀ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ KẸ́ŃYÀ
Lọ́dún 1996, wọ́n ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà. Bí mo ṣe sọ níṣàájú, mo ti wá sí Kẹ́ńyà rí, àmọ́ ìgbà tí ètò Ọlọ́run rán wa wá síbí ni mo láǹfààní láti tún pa dà wá. Inú Bẹ́tẹ́lì là ń gbé. Àwọn ọ̀bọ máa ń ṣeré wá síbẹ̀ dáadáa, wọ́n sì máa ń jí lára èso táwọn arábìnrin máa ń gbé dání. Lọ́jọ́ kan, arábìnrin kan gbàgbé láti ti wíńdò yàrá ẹ̀. Nígbà tó fi máa dé, ó bá àwọn ọ̀bọ tó pọ̀ nínú yàrá ẹ̀, tí wọ́n ń fi oúnjẹ tí wọ́n bá nínú yàrá ẹ̀ ṣara rindin. Ló bá figbe ta, ó sì sá jáde kúrò nínú yàrá. Báwọn ọ̀bọ náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo nìyẹn, wọ́n sì sá gba ojú wíńdò jáde.
Èmi àti Pauline dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó ń sọ èdè Swahili. Kò pẹ́ sígbà yẹn, wọ́n ní kí n máa darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ (tá à ń pè ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ báyìí). Àmọ́ mi ò tíì mọ bí wọ́n ṣe ń sọ èdè náà dáadáa. Mo máa ń múra apá ibi tá a fẹ́ kà sílẹ̀ dáadáa, ìyẹn máa ń jẹ́ kí n béèrè ìbéèrè lọ́nà tó máa yé àwọn ará. Tí ìdáhùn àwọn ará bá tiẹ̀ yàtọ̀ díẹ̀ sóhun tó wà nínú ìwé tá à ń kà, kì í yé mi. Kò rọrùn fún mi rárá! Inú mi kì í dùn torí pé mi ò lè kọ́ wọn dáadáa. Àmọ́ ó wú mi lórí gan-an pé wọ́n máa ń ní sùúrù fún mi tí mo bá ń darí ìpàdé torí pé wọ́n nírẹ̀lẹ̀.
ÀWỌN ARÁ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ NÍGBÀGBỌ́ BÓ TIẸ̀ JẸ́ PÉ WỌ́N LỌ́RỌ̀
A ò tíì lò tó ọdún kan ní Kẹ́ńyà, ni ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa lọ́dún 1997 pé ká máa bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn nílùú New York. Ní báyìí, a ti wà lórílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, ìyẹn náà sì lè fa àwọn ìṣòro kan. (Òwe 30:8, 9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè yìí lọ́rọ̀, àwọn ará wa ń fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ tó lágbára. Wọ́n ń lo àkókò àti ohun ìní wọn láti fi ti ètò Ọlọ́run lẹ́yìn, wọn ò lo àkókò wọn láti fi kó ọ̀rọ̀ jọ.
Látọdún yìí wá, a ti rí báwọn ará wa ṣe fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ lónírúurú ipò tí wọ́n bá ara wọn. Nígbà tá a wà lórílẹ̀-èdè Ireland, àwọn ará fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé rògbòdìyàn máa ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tá a wà nílẹ̀ Áfíríkà, àwọn ará fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, táwọn kan sì ń gbé ní àdádó níbi tí kò ti sí àwọn Ẹlẹ́rìí kankan. Nígbà tá a pa dà sí Amẹ́ríkà, àwọn ará níbẹ̀ fi hàn pé àwọn náà nígbàgbọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ṣẹnuure fún wọn. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó, bó ṣe ń wo àwọn ará látọ̀run, tó ń rí bí wọ́n ṣe ń fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun ní onírúurú ipò tí wọ́n bá ara wọn!
Ọjọ́ ọ̀hún rèé bí àná, àwọn ọdún tá a ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ti yára kọjá, ó “yára sáré ju ohun èlò tí wọ́n fi ń hun aṣọ.” (Jóòbù 7:6) Ní báyìí, àwọn ará tí wọ́n wà ní oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, New York la jọ ń ṣiṣẹ́, inú wa sì máa ń dùn láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn torí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. À ń láyọ̀, a ní ìtẹ́lọ́rùn, inú wa sì ń dùn pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa ran Kristi Jésù Ọba wa lọ́wọ́, ẹni tó máa san èrè fún àìmọye olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà láìpẹ́.—Mát. 25:34.
a Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Isaiah Adagbona wà nínú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1998, ojú ìwé 22-27. Ó kú lọ́dún 2010.