Arábìnrin Kan Rẹ́rìn-ín Músẹ́!
ÀWỌN obìnrin méjì kan jọ ń rìn ní agbègbè tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé nílùú Baguio City, lórílẹ̀-èdè Philippines. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n rí àtẹ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ wọn ò yà. Arábìnrin Helen tó dúró síbi àtẹ náà rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin náà ò yà síbi àtẹ ìwé yẹn, ẹ̀rín tí Helen rín sí wọn múnú wọn dùn gan-an.
Nígbà táwọn obìnrin náà ń pa dà sílé, wọ́n rí àkọlé jw.org gàdàgbà tí wọ́n kọ sára Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Wọ́n rántí pé àkọlé yẹn náà ni wọ́n rí lára àtẹ ìwé níbi tí Helen dúró sí. Ṣe ni wọ́n bọ́lẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì tí wọ́n wọ̀, tí wọ́n sì lọ wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ ìpàdé tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ara géètì Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.
Àwọn obìnrin méjèèjì lọ sí ìpàdé tó tẹ̀ lé e. Ǹjẹ́ ẹ mẹni tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe dé Gbọ̀ngàn Ìjọba? Helen ni! Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n rántí pé òun ló rẹ́rìn-ín sí àwọn níbi àtẹ ìwé. Helen sọ pé: “Nígbà tí wọ́n wá bá mi, ẹ̀rù kọ́kọ́ bà mí torí mo ronú pé àbí mo ti ṣe nǹkan kan fún wọn ni.” Àmọ́, àwọn obìnrin náà ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Helen.
Àwọn obìnrin náà gbádùn ìpàdé yẹn, ara sì tù wọ́n níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n rí àwọn ará tó ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe lẹ́yìn ìpàdé, wọ́n béèrè bóyá àwọn lè fọwọ́ kún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan nínú àwọn obìnrin náà ò gbé Philippines mọ́, èkejì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, ó sì ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe? Torí pé arábìnrin kan rẹ́rìn-ín músẹ́ ni!