Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16

Jẹ́ Kí Inú Ẹ Máa Dùn Bó O Ṣe Ń Ṣe Gbogbo Ohun Tó O Lè Ṣe fún Jèhófà

Jẹ́ Kí Inú Ẹ Máa Dùn Bó O Ṣe Ń Ṣe Gbogbo Ohun Tó O Lè Ṣe fún Jèhófà

“Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò.”​—GÁL. 6:4.

ORIN 37 Máa Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒ *

1. Kí ló ń jẹ́ ká láyọ̀ ní gbogbo ìgbà?

 JÈHÓFÀ fẹ́ ká máa láyọ̀. Ohun tó sì jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé ayọ̀ jẹ́ apá kan èso tẹ̀mí tí Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní. (Gál. 5:22) Torí pé ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ, ayọ̀ wa máa ń pọ̀ sí i tá a bá ń wàásù déédéé, tá a sì ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́ lónírúurú ọ̀nà.​—Ìṣe 20:35.

2-3. (a) Bó ṣe wà nínú Gálátíà 6:4, nǹkan méjì wo lá jẹ́ ká máa láyọ̀ nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

2 Nínú Gálátíà 6:4, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nǹkan méjì táá jẹ́ ká máa láyọ̀ nìṣó. (Kà á.) Ohun àkọ́kọ́ tó sọ ni pé ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, a máa láyọ̀. (Mát. 22:36-38) Ohun kejì ni pé a ò gbọ́dọ̀ máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. Ibi tí ìlera wa, àwọn ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá a ti gbà àtàwọn ẹ̀bùn tá a ní bá lè jẹ́ ká ṣiṣẹ́ ìsìn wa dé, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Ó ṣe tán, Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní. Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan lè ṣe jù wá lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ṣe ló yẹ kí inú wa máa dùn pé wọ́n ń lo ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wọn láti máa yìn ín, kì í ṣe pé wọ́n ń lò ó láti máa gbé ara wọn lárugẹ tàbí wá àǹfààní tara wọn. Torí náà, dípò tí a ó fi máa bá wọn díje, ṣe ló yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn.

3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ò ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì tá a bá ń rò pé a ò ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. A tún máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà lo ẹ̀bùn tá a ní àti ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára àwọn ẹlòmíì.

TÁ A BÁ Ń RÒ PÉ A Ò ṢE TÓ BÁ A ṢE FẸ́

Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà láti kékeré títí tá a fi dàgbà, inú Jèhófà máa dùn sí wa (Wo ìpínrọ̀ 4-6) *

4. Kí ló lè mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì? Sọ àpẹẹrẹ kan.

4 Ọjọ́ ogbó àti àìlera ò jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ṣe tó bí wọ́n ṣe fẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Carol nìyẹn. Nígbà kan, ó láǹfààní láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Nígbà tó wà níbẹ̀, àwọn márùndínlógójì (35) ló ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ran ọ̀pọ̀ lára wọn lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Iṣẹ́ ìwàásù Carol so èso rere. Nígbà tó yá, ó ṣàìsàn, kò sì lè fi bẹ́ẹ̀ jáde nílé mọ́. Ó sọ pé: “Nítorí àìlera mi, mi ò lè ṣe tó bí mo ṣe fẹ́ bíi tàwọn ẹlòmíì, ìyẹn sì ń jẹ́ kí n máa rò pé wọ́n ń sin Ọlọ́run jù mí lọ. Àìsàn tó ń ṣe mí ò jẹ́ kí n ṣe tó bí mo ṣe fẹ́, èyí sì máa ń jẹ́ kí n rẹ̀wẹ̀sì.” Ó wu Carol pé kó ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ohun tó dáa ló fẹ́ ṣe. Síbẹ̀, bí kò tiẹ̀ lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀, ó dájú pé inú Ọlọ́run wa aláàánú ń dùn gan-an torí pé Carol ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe.

5. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ti ń rẹ̀wẹ̀sì torí pé a ò lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́? (b) Báwo ni arákùnrin tó wà nínú àwòrán yẹn ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

5 Tó o bá ti ń rẹ̀wẹ̀sì torí pé o ò lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà fẹ́ kí n ṣe?’ Jèhófà fẹ́ kó o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe bí agbára ẹ bá ṣe gbé e tó. Ká sọ pé arábìnrin kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin (80) ọdún ti ń rẹ̀wẹ̀sì torí pé kò lè ṣe tó bó ṣe máa ń ṣe nígbà tó lé lẹ́ni ogójì (40) ọdún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó rò pé ohun tóun ń ṣe fún Jèhófà ò tó. Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, tí arábìnrin yìí bá lè máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà nígbà tó ti lé lẹ́ni ogójì ọdún, tó sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún, ó dájú pé ó ṣì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe fún Jèhófà. Tá a bá rò pé ohun tá à ń ṣe fún Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa ò tó, ká rántí pé Jèhófà fúnra ẹ̀ ló máa sọ bóyá ohun tá à ń ṣe fún òun tó tàbí kò tó. Torí náà, tá a bá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, Jèhófà máa sọ fún àwa náà pé: “O káre láé!”​—Fi wé Mátíù 25:20-23.

6. Kí la rí kọ́ lára Maria?

6 Àá máa láyọ̀ tó bá jẹ́ pé ohun tá a lè ṣe la gbájú mọ́ dípò ohun tá ò lè ṣe. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń jẹ́ Maria. Ó ní àìsàn kan tí kò jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tí àìsàn náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ẹ̀dùn ọkàn bá a, ó sì rò pé òun ò wúlò mọ́. Àmọ́ nígbà tó ronú nípa arábìnrin kan tí wọ́n jọ wà nínú ìjọ kan náà, tí àìsàn tó ń ṣe é ò jẹ́ kó lè kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì, Maria pinnu pé òun máa ràn án lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Èmi àti arábìnrin náà ṣètò pé àá jọ máa wàásù látorí fóònù àti nípasẹ̀ lẹ́tà. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti pa dà délé látọ̀dọ̀ arábìnrin yẹn ni inú mi máa ń dùn pé mo ti ràn án lọ́wọ́.” Inú tiwa náà á máa dùn sí i tó bá jẹ́ pé ohun tá a lè ṣe la gbájú mọ́, dípò ohun tá ò lè ṣe. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o ṣì lè ṣe púpọ̀ sí i ńkọ́ àbí tó jẹ́ pé àwọn apá ibì kan lo ti ń ṣe dáadáa gan-an, kí ló yẹ kó o ṣe?

MÁA LO Ẹ̀BÙN TÓ O NÍ!

7. Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wo ni àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni?

7 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí àpọ́sítélì Pétérù kọ sáwọn ará, ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n lo ẹ̀bùn èyíkéyìí tí wọ́n bá ní láti fi ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́. Ó sọ nínú lẹ́tà náà pé: “Bí kálukú bá ṣe ń rí ẹ̀bùn gbà, ẹ máa fi ṣe ìránṣẹ́ fún ara yín bí ìríjú àtàtà tó ń rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run gbà.” (1 Pét. 4:10) Kò yẹ ká máa bẹ̀rù láti lo ẹ̀bùn tá a ní bóyá torí a rò pé àwọn èèyàn máa jowú wa tàbí ká máa rò pé ìrẹ̀wẹ̀sì á mú wọn torí wọn ò nírú ẹ̀bùn tá a ní. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní lè lo ẹ̀bùn wa fún Jèhófà.

8.1 Kọ́ríńtì 4:6, 7 ṣe sọ, kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fọ́nnu nípa àwọn ẹ̀bùn tá a ní?

8 Ó yẹ ká lo àwọn ẹ̀bùn tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà débi tá a bá lè lò ó dé, àmọ́ kò yẹ ká máa fọ́nnu nípa ẹ̀. (Ka 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7.) Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ẹ̀bùn gidi la ní yẹn, ó sì yẹ ká lò ó dáadáa! Àmọ́ ìyàtọ̀ wà nínú kéèyàn ní ẹ̀bùn kan àti kéèyàn máa fọ́nnu nípa ẹ̀. Ká sọ pé o wàásù fún ẹnì kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹ̀. Ó wù ẹ́ pé kó o sọ ìrírí náà fáwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní àwùjọ iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tẹ́ ẹ pàdé pọ̀, arábìnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í sọ bí òun ṣe wàásù fún ẹnì kan, tí ẹni náà sì gba ìwé ìròyìn. O lè wá máa rò ó pé, ṣebí ìwé ìròyìn nìkan ló fi sóde, èmi ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan. Kí lo máa wá ṣe? O mọ̀ pé tó o bá sọ ìrírí tó o ní fáwọn ará, ó máa fún wọn níṣìírí gan-an. Àmọ́ ṣé kò ní dáa kó o dúró dìgbà míì kó o tó sọ ọ́ kíyẹn má bàa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá arábìnrin náà torí ó lè máa rò pé òun ò ṣe tó ẹ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o gba tiẹ̀ rò. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé kó o má fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn mọ́ o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé o mọ bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí náà máa lo ẹ̀bùn tó o ní!

9. Báwo ló ṣe yẹ ká máa lo àwọn ẹ̀bùn tá a ní?

9 Ẹ jẹ́ ká máa fi sọ́kàn pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ẹ̀bùn tá a ní. Torí náà, ó yẹ ká lo àwọn ẹ̀bùn wa láti gbé àwọn ará ró, kì í ṣe pé ká máa fi gbé ara wa lárugẹ. (Fílí. 2:3) Tá a bá ń lo okun àti ẹ̀bùn tá a ní láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, inú wa máa dùn. Kì í ṣe torí pé a fẹ́ fi hàn pé a mọ nǹkan ṣe ju àwọn míì lọ tàbí pé a dáa jù wọ́n lọ la ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fi àwọn ẹ̀bùn tá a ní yin Jèhófà lógo.

10. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn míì?

10 Tá ò bá ṣọ́ra, a lè máa ṣe fọ́rífọ́rí lórí àwọn nǹkan tá a mọ̀ ọ́n ṣe torí pé àwọn míì ò lè ṣe nǹkan náà bíi tiwa. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan lè mọ bí wọ́n ṣe ń sọ àsọyé, káwọn ará sì gbádùn ẹ̀. Ohun tó mọ̀ ọ́n ṣe nìyẹn. Àmọ́ nínú ọkàn ẹ̀ lọ́hùn-ún, ó lè máa fojú tẹ́ńbẹ́lú arákùnrin míì tí ò lè sọ àsọyé bíi tiẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, arákùnrin kejì yẹn lè mọ àwọn nǹkan míì ṣe jù ú lọ, bíi kó mọ bí wọ́n ṣe ń ṣàlejò, bó ṣe yẹ kéèyàn tọ́ ọmọ yanjú, kó sì tún nítara lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Inú wa dùn gan-an pé a láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ń lo ẹ̀bùn tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tí wọ́n sì tún fi ń ran àwọn míì lọ́wọ́!

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA ÀWỌN ẸLÒMÍÌ

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

11 Kò yẹ ká máa fi ohun tá ò lè ṣe wé ohun táwọn míì lè ṣe, àmọ́ a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, a kì í ṣe ẹni pípé bíi ti Jésù, àmọ́ a lè fìwà jọ ọ́. (1 Pét. 2:21) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, àjọṣe àwa àti Jèhófà á túbọ̀ gún régé, àá sì túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

12-13. Kí la rí kọ́ lára Ọba Dáfídì?

12 Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àtobìnrin aláìpé tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ló wà nínú Bíbélì, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. (Héb. 6:12) Àpẹẹrẹ kan ni Ọba Dáfídì tí Jèhófà pè ní “ẹni tí ọkàn mi fẹ́” tàbí bí Bíbélì míì ṣe túmọ̀ ẹ̀, “ẹni bí ọkàn mi.” (Ìṣe 13:22) Dáfídì kì í ṣe ẹni pípé, kódà ó ṣe àwọn àṣìṣe ńlá kan. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ tó dáa ló jẹ́ fún wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé nígbà tí wọ́n bá a wí, kò dá ara ẹ̀ láre. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gba ìbáwí líle tí wọ́n fún un, ó sì fi hàn pé òun kábàámọ̀ ohun tóun ṣe. Torí náà, Jèhófà dárí jì í.​—Sm. 51:3, 4, 10-12.

13 Tá a bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lára Dáfídì, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Kí ni mo máa ń ṣe tí wọ́n bá bá mi wí? Ṣé mo máa ń tètè gbà pé mo ṣàṣìṣe àbí ṣe ni mo máa ń dá ara mi láre? Ṣé mi ò kì í dá àwọn èèyàn lẹ́bi tí mo bá ṣàṣìṣe? Ṣé mo máa ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí n má bàa ṣàṣìṣe yẹn mọ́?’ Tó o bá ń kà nípa àwọn ọkùnrin àtobìnrin olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì, o tún lè bi ara ẹ láwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí. Ṣé irú ìṣòro tí mo ní làwọn náà ní? Àwọn ìwà tó dáa wo ni wọ́n ní? Bó o ṣe ń kà nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, bi ara ẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ bíi ti ìránṣẹ́ Jèhófà yìí?’

14. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń kíyè sí àwọn ará tá a jọ wà nínú ìjọ?

14 A máa jàǹfààní gan-an tá a bá ń kíyè sí àwọn àgbàlagbà àtàwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ìjọ wa. Bí àpẹẹrẹ, ṣé o mọ ẹnì kan nínú ìjọ yín tó ń fara da ìṣòro kan, bíi káwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ máa fúngun mọ́ ọn pé kó ṣe ohun tí ò dáa, káwọn ìdílé ẹ̀ máa ṣenúnibíni sí i tàbí kó máa ṣàìsàn? Ṣé o kíyè sí ìwà kan tó dáa lára ẹni náà tíwọ náà máa fẹ́ ní? Tó o bá ń ronú nípa àpẹẹrẹ tó dáa tí ẹni náà fi lélẹ̀, ó máa rọrùn fún ẹ láti fara da àwọn ìṣòro tó o ní. Inú wa dùn gan-an pé a láwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nígbàgbọ́ tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn lónìí!​—Héb. 13:7; Jém. 1:2, 3.

JẸ́ KÍ INÚ Ẹ MÁA DÙN BÓ O ṢE Ń SIN JÈHÓFÀ

15. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa táá jẹ́ ká máa láyọ̀ bá a ṣe ń sin Jèhófà?

15 Kí àlàáfíà tó lè wà nínú ìjọ, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni nígbà àtijọ́. Ohun tí wọ́n lè ṣe yàtọ̀ síra, ẹ̀bùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sì ní. (1 Kọ́r. 12:4, 7-11) Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí wọ́n máa bá ara wọn díje tàbí kó fa ìyapa láàárín wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe “láti gbé ara Kristi ró.” Ó kọ̀wé sáwọn ará Éfésù pé: “Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.” (Éfé. 4:1-3, 11, 12, 16) Nígbà tí wọ́n fi ìmọ̀ràn yìí sílò, àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. Ohun táwa náà sì ń ṣe lónìí nìyẹn.

16. Kí ló yẹ ká pinnu pé a máa ṣe? (Hébérù 6:10)

16 Pinnu pé o ò ní máa fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ lára Jésù, kó o sì sapá láti fìwà jọ ọ́. Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn olóòótọ́ tó wà nínú Bíbélì àtàwọn tòde òní. Bó o ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, má gbàgbé pé Jèhófà “kì í ṣe aláìṣòdodo tó fi máa gbàgbé iṣẹ́” rẹ. (Ka Hébérù 6:10.) Jẹ́ kínú ẹ máa dùn bó o ṣe ń sin Jèhófà, kó o sì mọ̀ pé Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀.

ORIN 65 Ẹ Tẹ̀ Síwájú!

^ ìpínrọ̀ 5 Gbogbo wa la máa jàǹfààní tá a bá ń kíyè sí ohun táwọn míì ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́, kò yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. Torí náà, àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí bá a ṣe lè máa láyọ̀ nìṣó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó tún máa jẹ́ ká rí ìdí tí kò fi yẹ ká máa gbéra ga tá a bá rí i pé à ń ṣe ju àwọn míì lọ àti ìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì táwọn míì bá ń ṣe jù wá lọ.

^ ìpínrọ̀ 49 ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, ó gbéyàwó, òun àtìyàwó ẹ̀ sì ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó bímọ, ó kọ́ wọn bí wọ́n ṣe máa wàásù, wọ́n sì jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Ó ti wá dàgbà báyìí, síbẹ̀ ó ṣì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe, ó ń fi lẹ́tà wàásù.