Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Ìjọsìn Jèhófà Ló Gbawájú ní Ìgbésí Ayé Yín?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Ìjọsìn Jèhófà Ló Gbawájú ní Ìgbésí Ayé Yín?

“Yí àwọn iṣẹ́ rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà tìkára rẹ̀, a ó sì fìdí àwọn ìwéwèé rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”​—ÒWE 16:3.

ORIN: 135, 144

1-3. (a) Ìpinnu wo ló di dandan káwọn ọ̀dọ́ ṣe? Ṣàpèjúwe. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́?

JẸ́ KÁ sọ pé o fẹ́ lọ síbi ayẹyẹ pàtàkì kan, ibẹ̀ jìnnà gan-an, o sì gbọ́dọ̀ wọkọ̀ kó o tó débẹ̀. Nígbà tó o dé ibùdókọ̀, o bá èrò rẹpẹtẹ táwọn náà fẹ́ rìnrìn-àjò, bẹ́ẹ̀ làwọn onímọ́tò ń pe onírúurú ibi tí wọ́n ń lọ, ìyẹn wá mú kí nǹkan tojú sú ẹ. Ṣé wàá kàn bọ́ sínú mọ́tò kan láìbéèrè ibi tó ń lọ? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀, torí pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ibòmíì ló máa gbé ẹ lọ.

2 Àwọn ọ̀dọ́ ló dà bí àwọn tó wà ní ibùdókọ̀ tí wọ́n ń rìnrìn-àjò yẹn. Bí ìrìn-àjò ni ìgbésí ayé rí, ìrìn-àjò náà sì jìnnà gan-an. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn ọ̀dọ́ lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe, ìyẹn sì lè mú kí nǹkan tojú sú wọn nígbà míì. Torí náà ẹ̀yin ọ̀dọ́, ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ mọ ibi tẹ́ ẹ fẹ́ forí lé nígbèésí ayé yín. Ìbéèrè náà ni pé, ibo ló yẹ kẹ́ ẹ forí lé?

3 Àpilẹ̀kọ yìí máa dáhùn ìbéèrè yìí, á sì jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ fi ìgbésí ayé yín sin Jèhófà. Ìyẹn gba pé kẹ́ ẹ fi Jèhófà sọ́kàn nígbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ pinnu bó ṣe yẹ kẹ́ ẹ kàwé tó, irú iṣẹ́ tẹ́ ẹ máa ṣe, ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ọmọ bíbí àtàwọn nǹkan míì. Ó tún gba pé kẹ́ ẹ láwọn àfojúsùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún àwọn ọ̀dọ́ tó bá fayé wọn sìn ín, ayé wọn á sì dùn bí oyin.​—Ka Òwe 16:3.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O NÍ ÀFOJÚSÙN NÍNÚ ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN?

4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

4 Ó bọ́gbọ́n mu pé kẹ́yin ọ̀dọ́ ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí nígbà tẹ́ ẹ ṣì kéré. Kí nìdí? A máa jíròrò ìdí mẹ́ta. Ìdí àkọ́kọ́ àti kejì máa jẹ́ kẹ́ ẹ rí i pé ẹ máa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tẹ́ ẹ bá ní àfojúsùn tẹ̀mí. Ìdí kẹta máa jẹ́ kẹ́ ẹ rí àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn ní àfojúsùn tẹ̀mí láti kékeré.

5. Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o láwọn àfojúsùn tẹ̀mí?

5 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká láwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni pé a fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣe fún wa. Onísáàmù kan sọ pé: “Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà . . . Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ; mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Sm. 92:​1, 4) Ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ronú àwọn nǹkan tí Jèhófà fún ẹ. Òun ló jẹ́ kó o wà láàyè, ó jẹ́ kó o mọ òtítọ́, ó jẹ́ kó o mọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ kó o wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì jẹ́ kó o ní ìrètí láti wà láàyè títí láé. Torí náà, o lè fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó o bá fi ìjọsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ ọn.

6. (a) Àǹfààní wo la máa rí tá a bá láwọn àfojúsùn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (b) Kí làwọn nǹkan tá a lè fi ṣe àfojúsùn wa láti kékeré?

6 Ìdí kejì tó fi yẹ kó o láwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni pé, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa kíyè sí gbogbo ìgbésẹ̀ tó ò ń gbé kọ́wọ́ rẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn yẹn, èyí sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Kò sí bó o ṣe kéré tó, tí o ò lè ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́wàá péré ni Christine nígbà tó pinnu pé òun á máa ka ìtàn ìgbésí ayé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà déédéé. Ọmọ ọdún méjìlá [12] ni Toby nígbà tóun náà pinnu pé òun máa ka Bíbélì látòkèdélẹ̀ kóun tó ṣèrìbọmi. Ọmọ ọdún mọ́kànlá [11] ni Maxim, àbúrò rẹ̀ Noemi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá nígbà táwọn méjèèjì ṣèrìbọmi, àwọn méjèèjì sì pinnu pé àwọn máa ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Kí wọ́n lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, wọ́n lẹ fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì sára ògiri nínú ilé wọn. O ò ṣe ronú lórí àwọn nǹkan pàtàkì tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó o sì sapá kọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀ wọ́n?​—Ka Fílípì 1:​10, 11.

7, 8. (a) Tó o bá ní àfojúsùn, báwo nìyẹn á ṣe mú kó rọrùn fún ẹ láti ṣèpinnu? (b) Kí nìdí tí ọ̀dọ́ kan fi pinnu pé òun ò ní lọ sí yunifásítì?

7 Ìdí kẹta tó fi yẹ kó o ní àfojúsùn nígbà tó o ṣì kéré ni pé, ọ̀pọ̀ ìpinnu ló wà tó o ṣì máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wàá ní láti pinnu ibi tó o máa kàwé dé, irú iṣẹ́ tó o máa ṣe àtàwọn nǹkan míì. Ṣíṣe ìpinnu dà bí ìgbà tó o wà ní oríta kan, tó o bá ti mọ ibi tó ò ń lọ, wàá mọ ibi tó yẹ kó o yà sí. Lọ́nà kan náà, tó o bá ti pinnu ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe, kò ní nira fún ẹ láti ṣèpinnu. Òwe 21:5 sọ pé: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” Tó o bá ti tètè pinnu ohun tó o fẹ́ fayé rẹ ṣe, ọwọ́ rẹ á tètè tẹ ohun tó ò ń lé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Damaris nìyẹn nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan nígbà tó wà ní ọ̀dọ́.

8 Nígbà tí Damaris parí ilé ẹ̀kọ́ girama, èsì ìdánwò rẹ̀ tayọ. Ìyẹn wá fún un láǹfààní àtilọ sí yunifásítì lọ́fẹ̀ẹ́ kó sì kàwé láti di lọ́yà. Dípò ìyẹn, ṣe ni Damaris yàn láti ṣe iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ó sọ pé: “Mo pinnu pé iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ni màá ṣe, torí náà mi ò lè ṣe iṣẹ́ tó máa gba gbogbo àkókò mi. Lóòótọ́ tí mo bá kàwé tí mo sì di lọ́yà, màá lówó rẹpẹtẹ, àmọ́ bóyá ni màá rí iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́.” Ogún [20] ọdún rèé tí Damaris ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ǹjẹ́ ó kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́? Ó ní: “Àwọn lọ́yà máa ń wá sí ibi tí mo ti ń ṣiṣẹ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ kan. Mo máa ń rí i pé ọ̀pọ̀ wọn ni ò láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà, iṣẹ́ témi náà ì bá sì máa ṣe nìyẹn ká sọ pé mo lọ sí yunifásítì. Àmọ́ torí pé mo yàn láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà, mi ò kì í ṣe gbogbo kòókòó jàn-án-jàn-án táwọn kan máa ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ bó-o-jí-o-jí-mi. Yàtọ̀ síyẹn, mò ń láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ọ̀pọ̀ ọdún ni mo sì ti wà lẹ́nu rẹ̀ báyìí.”

9. Kí nìdí tá a fi ń gbóríyìn fún ẹ̀yin ọ̀dọ́?

9 A gbóríyìn fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ tó wà láwọn ìjọ wa kárí ayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára yín lẹ̀ ń fayé yín sin Jèhófà, ẹ sì ti pinnu àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ìyẹn ń mú kẹ́ ẹ máa láyọ̀, ó sì ń mú kẹ́ ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà ní gbogbo apá ìgbésí ayé yín. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀ ń fi ìlànà Jèhófà sọ́kàn tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ibi tó yẹ kẹ́ ẹ kàwé dé àti irú iṣẹ́ tó yẹ kẹ́ ẹ ṣe. Sólómọ́nì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. . . . Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:​5, 6) Jèhófà mọyì ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa lọ́pọ̀lọpọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ yín gan-an, ó ń dáàbò bò yín, ó ń tọ́ yín sọ́nà, ó sì ń bù kún yín.

MÚRA SÍLẸ̀ LÁTI WÀÁSÙ

10. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé iṣẹ́ ìwàásù ló yẹ kó gbawájú láyé wa? (b) Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

10 Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ Jèhófà lò ń fayé rẹ ṣe, á máa wù ẹ́ láti sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáwọn èèyàn. Jésù Kristi sọ pé “a ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà.” (Máàkù 13:10) Níwọ̀n bí iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kánjúkánjú, òun ló yẹ kó gbawájú láyé wa. Torí náà, ṣé o lè ṣètò ara rẹ lọ́nà tí wàá fi túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà? Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o kì í gbádùn iṣẹ́ ìwàásù ńkọ́? Kí lo lè ṣe? Ohun méjì yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́: Àkọ́kọ́, máa múra sílẹ̀ dáadáa. Ìkejì, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ láti máa sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ tí wàá rí á kọjá àfẹnusọ.

Múra sílẹ̀ kó o lè wàásù fáwọn ojúgbà rẹ (Wo ìpínrọ̀ 11 àti 12)

11, 12. (a) Báwo lẹ̀yin ọ̀dọ́ ṣe lè múra sílẹ̀ láti wàásù? (b) Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe lo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti wàásù níléèwé?

11 O lè bẹ̀rẹ̀ sí í múra bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè táwọn ọmọléèwé rẹ sábà máa ń béèrè. Ọ̀kan lára ìbéèrè tí wọ́n lè bi ẹ́ ni, “Kí ló mú kó o gbà pé Ọlọ́run wà?” Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ tá a dìídì ṣe fún ẹ̀yin ọ̀dọ́, àwọn àpilẹ̀kọ yìí máa mú kó o lè dáhùn ìbéèrè yẹn. Wo abala Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́. Lọ́wọ́ ìsàlẹ̀, wàá rí “Ìwé Àjákọ fún Àwọn Ọ̀dọ́.” Ọ̀kan lára àwọn ìwé àjákọ yìí ní àkọlé náà “Kí Nìdí Tí Mo Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà?” Ìwé àjákọ náà máa jẹ́ kó o lè wá ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Wàá rí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o lè fi ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, bíi Hébérù 3:​4, Róòmù 1:20 àti Sáàmù 139:14. Àwọn ìwé àjákọ yìí máa jẹ́ kó o lè dáhùn onírúurú ìbéèrè.​—Ka 1 Pétérù 3:15.

12 Tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ, sọ fún àwọn ọmọléèwé rẹ pé kí wọ́n máa lọ sórí ìkànnì jw.org. Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Luca ṣe nìyẹn. Lọ́jọ́ kan tí olùkọ́ wọn ń kọ́ wọn nípa oríṣiríṣi ẹ̀sìn tó wà, Luca kíyè sí i pé ìwé tí olùkọ́ náà ń lò kò sọ òótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún Luca, síbẹ̀ ó bẹ olùkọ́ rẹ̀ pé kó jẹ́ kóun ṣàlàyé òótọ́ ọ̀rọ̀ náà, olùkọ́ náà sì gbà. Yàtọ̀ sí pé Luca fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́, ó tún fi ìkànnì wa han àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ àti olùkọ́ rẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Olùkọ́ náà fún àwọn ọmọ kíláàsì Luca ní iṣẹ́ àṣetiléwá, ó ní kí wọ́n wo fídíò eré ojú pátákó tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà. Inú Luca dùn gan-an pé òun wàásù lọ́jọ́ yẹn.

13. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa tí nǹkan kò bá lọ bá a ṣe fẹ́?

13 Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ tí nǹkan kò bá lọ bó o ṣe fẹ́. (2 Tím. 4:2) Ìṣòro yòówù kó yọjú, ibi tó ò ń lọ ni kó o kọjú sí. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Katharina pinnu pé òun á máa wàásù fún àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Ọ̀kan lára wọn máa ń bú u, àmọ́ Katharina kò jẹ́ kíyẹn dí òun lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń hùwà rere. Ará ibiṣẹ́ rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Hans kíyè sí ìwà rere tí Katharina ń hù, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé wa nìyẹn, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ó sì ṣèrìbọmi. Ní gbogbo ìgbà yẹn, Katharina kò sí níbi iṣẹ́ yẹn mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò mọ̀ pé Hans ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ lọ́dún mẹ́tàlá [13] lẹ́yìn náà. Ìpàdé ni Katharina àti ìdílé rẹ̀ wà nígbà tí wọ́n sọ pé Hans ọjọ́sí ni àlejò olùbánisọ̀rọ̀. Ẹ wo bí inú Katharina ṣe dùn tó lọ́jọ́ yẹn pé òun ò jẹ́ kó sú òun láti máa wàásù níbi iṣẹ́!

MÁ ṢE JẸ́ KÍ NǸKAN MÍÌ PÍN ỌKÀN Ẹ NÍYÀ

14, 15. (a) Kí ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ fi sọ́kàn táwọn ojúgbà wọn bá fẹ́ tì wọ́n síbi tí kò yẹ? (b) Kí ló máa ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ tí wọn ò fi ní lọ́wọ́ sí nǹkan tí kò dáa bíi tàwọn ojúgbà wọn?

14 Àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ kó o rí i pé ìjọsìn Jèhófà ló yẹ kó gbawájú nígbèésí ayé rẹ. Ìyẹn ni pé bí ọwọ́ rẹ ṣe máa tẹ àwọn àfojúsùn tẹ̀mí ló yẹ kó gbà ẹ́ lọ́kàn. Ó dájú pé wàá rí àwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ tí wọ́n láwọn ń gbádùn ara wọn, wọ́n tiẹ̀ lè máa rọ̀ ẹ́ pé kíwọ náà wá dara pọ̀ mọ́ wọn. Má ṣe jẹ́ káwọn ojúgbà ẹ tì ẹ́ síbi tí kò yẹ. Ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí wọ́n mọ ìpinnu tó o ti ṣe. Má gbàgbé àpèjúwe tá a sọ níbẹ̀rẹ̀, ó dájú pé o ò kàn ní kó sínú ọkọ̀ kan láìbéèrè ibi tó ń lọ torí ó jọ pé àwọn tó wà nínú ọkọ̀ yẹn ń gbádùn ara wọn.

15 Kí lo lè ṣe táwọn ojúgbà ẹ ò fi ní sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà? Àkọ́kọ́, yẹra fáwọn nǹkan tó máa mú kó o ṣe ohun tó lòdì sí ìpinnu rẹ. (Òwe 22:3) Ìkejì, má gbàgbé pé àwọn tó bá lọ́wọ́ sí nǹkan burúkú máa tìka àbámọ̀ bọnu. (Gál. 6:7) Ìkẹta, jẹ́ káwọn míì mọ ìṣòro tó o ní, kó o sì gbàmọ̀ràn. Tó o bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á rọrùn fún ẹ láti gbàmọ̀ràn àwọn òbí ẹ àtàwọn míì tó dàgbà nípa tẹ̀mí nínú ìjọ.​—Ka 1 Pétérù 5:​5, 6.

16. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.

16 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Christoph ní jẹ́ kó gbàmọ̀ràn. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ síbi tí wọ́n ti máa ń ṣe eré ìmárale. Àwọn ọ̀dọ́ bíi tiẹ̀ tó wà níbẹ̀ wá ń rọ̀ ọ́ pé kó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eléré ìdárayá àwọn. Christoph wá lọ bá alàgbà kan pé kó gba òun nímọ̀ràn. Alàgbà yẹn sọ fún un pé ohun tó fẹ́ ṣe yẹn lè jẹ́ kó ní ẹ̀mí ìbánidíje, torí náà á dáa kó ronú nípa ewu tó wà nínú ẹ̀ kó tó ṣèpinnu. Síbẹ̀, Christoph dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ yẹn. Nígbà tó yá, ó rí i pé ìwà ipá ló kúnnú eré ìdárayá ọ̀hún, ó sì léwu gan-an. Ó tún lọ bá àwọn alàgbà mélòó kan sọ̀rọ̀, gbogbo wọn ló sì fún un nímọ̀ràn látinú Ìwé Mímọ́. Christoph wá sọ pé: “Jèhófà ló rán wọn sí mi, mo sì gbàmọ̀ràn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò tètè ṣe bẹ́ẹ̀.” Ìwọ ńkọ́? Ṣé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ débi pé wàá lè gbàmọ̀ràn tó dáa táwọn míì bá fún ẹ?

17, 18. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ fáwọn ọ̀dọ́? (b) Kí nìdí táwọn kan fi ń kábàámọ̀ nígbà tí wọ́n dàgbà, kí ló yẹ kó o ṣe tírú ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Sọ àpẹẹrẹ kan.

17 Bíbélì sọ pé: “Máa yọ̀, ọ̀dọ́kùnrin [tàbí ọ̀dọ́bìnrin], ní ìgbà èwe rẹ, sì jẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ ṣe ọ́ ní ire ní àwọn ọjọ́ ìgbà ọ̀dọ́kùnrin rẹ.” (Oníw. 11:9) Jèhófà fẹ́ kẹ́yin ọ̀dọ́ máa láyọ̀. Àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ kó o rí bíyẹn ṣe lè ṣeé ṣe. Torí náà, pọkàn pọ̀ sórí àwọn àfojúsùn tó o ní nínú ìjọsìn Ọlọ́run, sì máa fi Jèhófà sọ́kàn nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, Jèhófà á máa tọ́ ẹ sọ́nà, á máa dáàbò bò ẹ́, á sì máa bù kún ẹ. Máa ronú lórí àwọn ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kó o sì máa fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”​—Oníw. 12:1.

18 Rántí pé ọmọdé kì í pẹ́ dàgbà. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan ti ń tìka àbámọ̀ bọnu báyìí, torí pé ohun tí kò tọ́ ni wọ́n lé nígbà tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́, kódà àwọn kan ò tiẹ̀ ní àfojúsùn rárá. Àmọ́ àwọn tó gbájú mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run nígbà tí wọ́n ṣì kéré máa ń láyọ̀, wọn kì í sì kábàámọ̀ nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Bí ọ̀rọ̀ Arábìnrin Mirjana ṣe rí nìyẹn, kó tó pé ọmọ ogún ọdún ló ti mọ eré ìdárayá ṣe gan-an. Torí náà, wọ́n ní kó wá kópa nínú ìdíje Winter Olympic Games, àmọ́ ó kọ̀ jálẹ̀. Dípò ìyẹn, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ọgbọ̀n [30] ọdún ti kọjá báyìí, síbẹ̀ Mirjana ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Ó sọ pé: “Ìgbà ò lọ bí òréré, béèyàn bá ní òkìkí, tó nípò láwùjọ, tó lọ́rọ̀ tó sì gbajúmọ̀, bó pẹ́ bó yá á dìtàn, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn ò lè fúnni láyọ̀ tòótọ́. Ohun tó dáa jù téèyàn lè fi ayé rẹ̀ ṣe ni pé kó sin Jèhófà, kó sì máa ran àwọn míì lọ́wọ́ káwọn náà lè wá sìn ín.”

19. Sọ àǹfààní téèyàn máa rí tó bá gbájú mọ́ ìjọsìn Jèhófà nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́.

19 A gbóríyìn fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ wa torí láìka gbogbo ìṣòro tẹ́ ẹ̀ ń kojú sí, ẹ ti pinnu pé Jèhófà lẹ máa fayé yín sìn. Bẹ́ ẹ ṣe ń pinnu àwọn nǹkan tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà náà lẹ̀ ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà, ẹ ti pinnu pé ẹ ò ní jẹ́ kí ohunkóhun nínú ayé yìí pín ọkàn yín níyà. Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé gbogbo ìsapá yín ò ní já sásán. A sì fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé gbogbo wa la nífẹ̀ẹ́ yín, àá sì máa tì yín lẹ́yìn. Paríparí ẹ̀, torí pé ẹ̀ ń fayé yín sin Jèhófà, ìgbésí ayé yín máa ládùn, á sì lóyin.