Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ṣé Ìsìn ti Fẹ́ Kógbá Wọlé?

Ṣé Ìsìn ti Fẹ́ Kógbá Wọlé?

Gaffar tí wọ́n bí sí orílẹ̀-èdè Turkey máa ń kọminú sí ẹ̀kọ́ tí ìsìn rẹ̀ ń kọ́ni nípa Ọlọ́run pé kì í dárí jini. Àtìgbà tí ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Hediye ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-àn lọ̀rọ̀ ìsìn ti tojú sú u. Ó sọ pé: “Wọ́n kọ́ wa pé kádàrá ni gbogbo nǹkan tó bá dé bá ẹ̀dá. Torí pé ìyá àti bàbá mi ti kú, mo máa ń ronú pé, ‘Kí ló dé tí Ọlọ́run fi yan kádàrá yìí fún mi?’ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sunkún mọ́jú. Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], ọ̀rọ̀ ìsìn ti yọ lọ́kàn mi.”

ṢÉ Ọ̀RỌ̀ ìsìn ti tojú sú ìwọ náà? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló ń kọminú nípa ọ̀rọ̀ ìsìn. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ńṣe ni iye àwọn tí kò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, èyí fi hàn pé àwọn èèyàn ti ń pa dà lẹ́yìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Díẹ̀ rèé lára àwọn orílẹ̀-èdè yìí.

Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Pa Ìsìn Tì?

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú kí ọ̀rọ̀ ìsìn yọ lọ́kàn àwọn èèyàn lónìí. Lára rẹ̀ ni bí àwọn aṣáájú ìsìn ṣe ń fọwọ́ sí ìwà ipá tí wọ́n sì ń ṣètìlẹyìn fáwọn afẹ̀míṣòfò, tí wọ́n sì tún máa ń bá àwọn ọmọ ìjọ ṣèṣekúṣe. Àmọ́ àwọn nǹkan míì tún wà tó ń mú káwọn èèyàn pa ṣọ́ọ̀ṣì tì, irú bíi:

  • Ìfẹ́ adùn: Ìwé kan tó ń jẹ́ Global Index of Religion and Atheism sọ pé: “Bí owó rẹ bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìsìn á túbọ̀ máa yọ lọ́kàn rẹ.” Òótọ́ wà nínú ọ̀rọ̀ yìí torí pé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn nǹkan amáyédẹrùn ti túbọ̀ mú kí àwọn èèyàn máa gbádùn ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ. Ọ̀jọ̀gbọ́n John V. C. Nye, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé sọ pé láwọn ilẹ̀ kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbádùn ayé gbẹdẹmukẹ tó jẹ́ pé àwọn ọba ọlọ́lá ayé ìgbà kan kò rí irú ìgbádùn bẹ́ẹ̀ jẹ.

    OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìfẹ́ owó àti ìfẹ́ adùn máa bo ìfẹ́ táwọn èèyàn ní fún Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wọn. (2 Tímótì 3:1-5) Nígbà tí òǹkọ̀wé Bíbélì kan rí bí owó ṣe máa ń bo ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn èèyàn, ó bẹ Jèhófà Ọlọ́run pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Òun fúnra rẹ̀ dáhùn pé: “Kí n má bàa yó tán kí n sì sẹ́ ọ ní ti tòótọ́.”—Òwe 30:8, 9.

  • Ààtò ìsìn tí kò ní láárí àti ìwàkiwà: Ọ̀pọ̀ èèyàn, pàápàá àwọn ọ̀dọ́ máa ń wo lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bí ohun tí kò bóde mu mọ́. Àwọn míì ò sì fọkàn tán àwọn onísìn mọ́. Tim Maguire tó jẹ́ agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ àwọn tí kò gbà gbọ́ nínú ìsìn lórílẹ̀-èdè Scotland sọ pé: “Tí ẹ bá wo ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ńṣe làwọn èèyàn pa wọ́n tì torí pé wọn kò gbà pé ìsìn lẹ́nu ọ̀rọ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìwà rere.”

    OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn wòlíì èké, ó kìlọ̀ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀. . . . Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:15-18) Àwọn “èso tí kò ní láárí” yìí ní nínú, dídá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti lílọ́wọ́ sí àwọn ìwà tí Ọlọ́run kórìíra irú bíi, kí ọkùnrin máa fẹ́ ọkùnrin, kí obìnrin sì máa fẹ́ obìnrin. (Jòhánù 15:19; Róòmù 1:25-27) Bákan náà, wọn kò fi àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ̀ kọ́ni, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ààtò ìsìn tí kò ní láárí ni wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú. (Mátíù 15:3, 9) Ohun tí Jésù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” (Jòhánù 21:17) Àmọ́ lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn kò rí ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí gbà.

  • Bí owó ṣe fẹjú mọ́ àwọn aṣáájú ìsìn: Ìwádìí kan tí àjọ Pew Research Center ṣe fi hàn pé, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé owó ti fẹjú mọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jù. Ńṣe làwọn àlùfáà àtàwọn pásítọ̀ máa ń gbé ayé gbẹdẹmukẹ níbi táwọn ọmọ ìjọ ti ń jìyà. Bí àpẹẹrẹ, nílùú kan lórílẹ̀-èdè Jámánì tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ ti ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n tó rówó jẹun, wọ́n fẹ̀sùn kan bíṣọ́ọ̀bù wọn pé ayé ìjẹkújẹ ló ń jẹ. Ìgbésí ayé yìí ń múnú bí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Bákan náà, ìwé ìròyìn GEO sọ pé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi tó jẹ́ pé ‘nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] mílíọ̀nù èèyàn kì í ná ju igba [200] náírà lójúmọ́, níbẹ̀ làwọn pásítọ̀ kan ti ń jẹ ayé ìjẹkújẹ, èyí sì ti ń di ìṣòro.’

    OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 2:17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn abẹnugan nínú ìjọ Kristẹni ìgbàanì, ó máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kó má baà di bùkátà rẹ̀ sọ́rùn àwọn tó kù nínú ìjọ. (Ìṣe 20:34) Èyí fi hàn pé ó ń tẹ̀ lé àṣẹ tí Jésù pa pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:7, 8.

Àṣẹ yìí kan náà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé torí pé a kì í ta àwọn ìwé wa, ọ̀fẹ́ la sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A kì í gba ìdámẹ́wàá, a ò sì ń gbégbá owó nílé ìjọsìn wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọrẹ táwọn èèyàn bá fínnúfíndọ̀ ṣe la fi ń bójú tó iṣẹ́ wa.—Mátíù 6:2, 3.

Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Pé Àwọn Èèyàn Máa Pa Ìsìn Tì

Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, kò sẹ́ni tó lè gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn máa pa ìsìn tì. Àmọ́ tipẹ́tipẹ́ ni Ọlọ́run ti rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ó sì ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Ọlọ́run fi gbogbo ìsìn èké wé aṣẹ́wó kan tó ń jẹ ayé ìjẹkújẹ, ó pe aṣẹ́wó náà ní “Bábílónì Ńlá.”—Ìṣípayá 17:1, 5.

Àfiwé yìí bá a mù gan-an torí pé wọ́n ń fẹnu ṣe ti Ọlọ́run, lẹ́sẹ̀ kan náà wọ́n ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn olóṣèlú kí wọ́n lè rí ọlá àti agbára. Ìwé Ìṣípayá 18:9 sọ pé: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé . . . bá a ṣe àgbèrè.” Orúkọ náà “Bábílónì” bá ìsìn èké mu torí pé ìlú Bábílónì ìgbàanì ni ọ̀pọ̀ àwọn àṣà àti ẹ̀kọ́ èké ti bẹ̀rẹ̀. Irú bí ọkàn tí kì í kú, ọlọ́run mẹ́talọ́kan àti iṣẹ́ awo. Ìlú Bábílónì yìí kún fún ìsìn èké àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. *Aísáyà 47:1, 8-11.

Ìlú Bábílónì pa run nígbà tí omi Odò Yúfírétì tó yí ìlú náà ka “gbẹ” táwọn ọmọ ogun Mídíà àti Páṣíà sì rọ́nà wọlé sínú ìlú náà. (Jeremáyà 50:1, 2, 38) Kódà, alẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n ṣẹ́gun ìlú Bábílónì!—Dáníẹ́lì 5:7, 28, 30.

Bíbélì sọ pé, Bábílónì Ńlá náà “jókòó lórí omi púpọ̀.” Ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé omi yìí túmọ̀ sí “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀,” ìyẹn ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn tó ń ṣagbátẹrù ìsìn èké. (Ìṣípayá 17:1, 15) Bíbélì wá sọ tẹ́lẹ̀ pé omi ìṣàpẹẹrẹ yìí máa gbẹ, èyí ló máa ṣáájú ìparun Bábílónì tòde òní. (Ìṣípayá 16:12; 18:8) Àmọ́ ta ló máa pa Bábílónì run? Àwọn olóṣèlú tó mú lọ́rẹ̀ẹ́ ló máa pa á run, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un tẹ́lẹ̀ máa di ìkórìíra. Wọ́n á jẹ ẹran ara rẹ̀, ìyẹn ni pé wọ́n máa kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ lọ.—Ìṣípayá 17:16, 17. *

Bí omi odò tó yí Bábílónì ká ṣe gbẹ ń ṣàpẹẹrẹ bí àwọn èèyàn ṣe máa dẹ̀yìn lẹ́yìn Bábílónì Ńlá

“Ẹ Jáde Kúrò Nínú Rẹ̀”!

Torí ìparun tó ń bọ̀ lórí Bábílónì Ńlá, Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.” (Ìṣípayá 18:4) Ìkìlọ̀ yìí wà fún àwọn tó ń kọminú sí gbogbo ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì fẹ́ rí ojúure Ọlọ́run. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Gaffar àti Hediye tí a mẹ́nu kàn lókè.

Kí Gaffar tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ńṣe ló máa ń pa òfin Ọlọ́run mọ́ torí ó ń bẹ̀rù pé kí Ọlọ́run má fìyà jẹ òun. Ó wá sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Ara tù mí nígbà ti mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì fẹ́ ká pa òfin òun mọ́ nítorí ìfẹ́ tá a ní fún un.” (1 Jòhánù 4:8; 5:3) Ọkàn Hediye balẹ̀ nígbà tóun náà kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kọ́ ló pa ìyá àti bàbá òun àti pé Ọlọ́run kò kádàrá ìgbésí ayé òun. Àwọn ohun tó kọ́ nínú Bíbélì tù ú nínú, irú bí ohun tó wà nínú Jákọ́bù 1:13 tó sọ pé Ọlọ́run kì í fi nǹkan burúkú dán wa wò. Òun àti Gaffar kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, wọ́n sí sá kúrò nínú “Bábílónì.”—Jòhánù 17:17.

Nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ìpalára kankan kò ní dé bá àwọn tó ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ pé kí wọ́n jáde kúrò nínú rẹ̀, kí wọ́n lè máa “jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23) Ìrètí wọn ni pé kí ayé “kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, ìjọsìn èké àti gbogbo ìwà abèṣe tí wọ́n ń hù máa dópin torí pé Ọlọ́run “kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Àmọ́ ìjọsìn tòótọ́ ní tirẹ̀ máa wà títí láé!

^ ìpínrọ̀ 16 Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bábílónì Ńlá àti ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn òkú, irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti iṣẹ́ awo, ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.