ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́
Tí Ọmọ Rẹ Bá Ń Purọ́
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Ọmọ rẹ kékeré ń ṣeré nínú yàrá kejì. Lójijì lo gbọ́ ariwo bíi pé nǹkan kan fọ́. Lo bá sáré wọnú yàrá náà láti wo ohun tó ṣẹlẹ̀, nígbà tó o débẹ̀, àwo aláràbarà kan ti fọ́ sílẹ̀. Bí ọmọ rẹ ṣe ń wò fi hàn pé òun ló fọ́ àwo náà.
Lo bá bi í pé: “Ṣé ìwọ lo fọ́ àwo yìí?”
Kíá lòun náà fèsì pé: “Rárá o, èmi kọ́ ni mo fọ́ ọ!”
Ìdáhùn rẹ̀ kọ ẹ́ lóminú torí pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tó máa purọ́ ojúkojú nìyí, bẹ́ẹ̀ kò tíì ju ọmọ ọdún márùn-ún lọ. Kí ló yẹ kó o ṣe?
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
Gbogbo irọ́ ló burú. Bíbélì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra “ahọ́n èké.” (Òwe 6:16, 17) Kódà Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kà á léèwọ̀ fún ẹnikẹ́ni láti ṣèké tàbí tan ọmọnìkejì rẹ̀ jẹ.—Léfítíkù 19:11, 12.
Irọ́ ju irọ́ lọ. Àwọn kan máa ń mọ̀ọ́mọ̀ purọ́ burúkú, irọ́ tó lè pa ẹlòmíì lára. Bẹ́ẹ̀, ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù àti jìyà ló máa ń mú káwọn míì purọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 18:12-15) Gbogbo irọ́ ló burú, àmọ́ irọ́ ju irọ́ lọ. Torí náà, bí ọmọ rẹ bá purọ́, kọ́kọ́ wo ti ọjọ́ orí rẹ̀ mọ́ ọn lára, kó o sì ronú lórí ohun tó mú kó purọ́.
Tètè jáwọ́ ọmọ rẹ nínú irọ́ nígbà tó ṣì kéré. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ David Walsh sọ pé: “Ara ohun tó yẹ kéèyàn máa kọ́ ọmọ ni pé ó dáa ká máa sọ òtítọ́ pàápàá láwọn àkókò tí kò bá rọrùn. Òtítọ́ máa ń jẹ́ kí àjọṣe dán mọ́rán, àmọ́ ọjọ́ tá a bá purọ́ fún àwọn èèyàn ni àjọṣe wa pẹ̀lú wọn bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́.” *
Má jáyà jù. Torí pé ọmọ rẹ purọ́ lónìí kò sọ pé á di èèyàn burúkú lọ́la. Rántí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí.” (Òwe 22:15) Ìwà òmùgọ̀ lè mú káwọn ọmọ míì purọ́ kí òbí wọ́n má bàa nà wọ́n, bẹ́ẹ̀, wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn. Bí ọmọ rẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì kó o mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Kọ́kọ́ wádìí ohun tó fà á tí ọmọ rẹ fi ń purọ́. Ṣé ẹ̀rù àti jẹgba ló bà á ni àbí kò fẹ́ kó o bínú sí òun? Bí ọmọ rẹ bá kúndùn kó máa sọ àsọdùn fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣé kì í ṣe pé ọmọdé ló ń ṣe é àti pé kò mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwàdà àti òótọ́ ọ̀rọ̀? Bó o bá lóye ìdí tí ọmọ rẹ ṣe ń purọ́, á jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe kọ́ ọ láti jáwọ́ nínú rẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: 1 Kọ́ríńtì 13:11.
Kúkú sojú abẹ níkòó kàkà tí wàá máa fi ìbéèrè lọ́ ọ lọ́fun. Nínú àpẹẹrẹ tá a fi bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìyá náà mọ̀ pé ọmọ yẹn ló fọ́ àwo, kò yẹ kó tún bi ọmọ náà pé: “Ṣé ìwọ lo fọ́ àwo yìí?” Ìbẹ̀rù pé ìyá òun máa bínú ló jẹ́ kí ọmọ yẹn purọ́. Ńṣe ni ìyá yẹn ò bá kàn sọ pé: “Áà, ìwọ ọmọ yìí, o ti fọ́ àwo!” Nígbà tí ọmọ náà sì ti mọ ohun tí òun ṣe, ọ̀rọ̀ yẹn ò ní bá a lójijì débi tó fi máa purọ́, á tún jẹ́ kó mọ́ ọn lára láti máa sọ òótọ́.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:9.
Gbóríyìn fún ọmọ rẹ nígbàkúùgbà tó bá sọ òtítọ́. Gbogbo ọmọdé ló máa ń fẹ́ ṣe ohun tó dùn mọ́ àwọn òbí wọn, torí náà gba apá ibẹ̀ yẹn wọlé sí i lára. Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ìwà ọmọlúwàbí ni kéèyàn máa ṣòótọ́, o sì fẹ́ kó máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo.—Ìlànà Bíbélì: Hébérù 13:18.
Jẹ́ kó yé ọmọ rẹ pé bó bá ń purọ́, kò sẹ́ni tó máa gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́ torí wọ́n á sọ ọ́ dí òpùrọ́, á sì pẹ́ gan-an káwọn èèyàn tó gba ohun tó bá sọ gbọ́. Torí náà, bí ọmọ rẹ bá sọ òtítọ́, gbóríyìn fún un gidigidi. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé, “Ọmọ dáadáa ni ẹ́, gbogbo ìgbà tó o bá sọ òtítọ́, inú mi máa ń dùn gan-an.”
Jẹ́ àwòkọ́ṣe rere fáwọn ọmọ rẹ. Bí ìwọ fúnra rẹ bá ń purọ́, ó máa ṣòro fún ọmọ rẹ láti máa sọ òtítọ́, pàápàá tó o bá ń sọ fún un pé: “Sọ fún ẹni tó wà lẹ́nu ilẹ̀kùn pé mi ò sí nílé” tó o sì wà nílé tàbí tó o sọ fún ẹnì kan lórí fóònù pé “Ara mi ò yá” tó sì jẹ́ pé ara rẹ yá.—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 3:17.
Fi Bíbélì kọ́ wọn. Àwọn ìlànà àtàwọn ìtàn tó wà nínú Bíbélì kọ́ wa pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo. Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, sọ àwọn ìlànà tó máa wúlò fún àwọn ọmọ rẹ. Wo orí 22 tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́.” (Ka díẹ̀ nínú rẹ̀ lábẹ́ àpótí tá a pè ní “ Ìwé Kan Tó Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́.”) Ìwé
^ ìpínrọ̀ 11 Àyọkà láti inú ìwé No: Why Kids—of All Ages—Need to Hear It and Ways Parents Can Say It.