Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bí Ẹ Ṣe Lè Gbà Fún Ara Yín

Bí Ẹ Ṣe Lè Gbà Fún Ara Yín

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ní èrò to yàtọ̀ síra lórí nǹkan kan. Èwo nínú mẹ́ta yìí lo máa ṣe:

  1. Yarí pé èrò tìẹ lẹ gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé.

  2. Rọ́jú gbà pẹ̀lú rẹ̀ bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀.

  3. Ẹ jọ gbà fún ara yín.

O lè rò pé bí ẹ bá jọ gbà fún ara yín, ńṣe ló máa dà bíi pé kò sẹ́nì kankan nínú yín tó máa ní àǹfààní láti ṣe ohun tó fẹ́.

Ṣùgbọ́n ohun tó dáa nìyẹn torí pé bí ẹ bá jọ gbà fún ara yin ní ìtùnbí-ìnùbí, ọ̀rọ̀ náà á lójú, ẹ̀yin méjèèjì á sì láyọ̀. Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kó o mọ̀ nípa bí ẹ ṣe lè jọ gbà fún ara yín.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Ó gba pé kí ẹ fi ìmọ̀ ṣọ̀kan. Ó ti mọ́ ọ̀pọ̀ lára láti máa dá ṣe ìpinnu kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Àmọ́ ní báyìí tí ẹnì kejì ti wà, ìgbéyàwó yín ló ṣe pàtàkì jù kì í ṣe ìfẹ́ inú ara ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Ó lè máà rọrùn àmọ́ èrè wà níbẹ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Alexandra sọ èrè tó wà níbẹ̀, ó ní: “Èrò tí ẹ̀yin méjèèjì bá jọ gbé kalẹ̀ máa gbéṣẹ́, á sì yọrí sí rere ju èrò ẹnì kan ṣoṣo.”

Ó gba pé kó o máa gba ti ẹnì kejì rẹ rò. John M. Gottman tó máa ń gba àwọn tọkọtaya nímọ̀ràn sọ pé: “Àwọn ìgbà míì wà tí èrò rẹ lè yàtọ̀ pátápátá sí ti ọkọ tàbí aya rẹ, ó ṣì yẹ kó o gba tiẹ̀ rò látọkàn wá, kó o sì ro ti ipò rẹ̀ nínú ìdílé. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kejì bá ń sọ èrò rẹ̀ lọ́wọ́, tó o wá káwọ́ gbera tàbí tí o ń mirí àbí tí o kò jẹ́ kó bọ́rọ̀ rẹ̀ délẹ̀ tó o fi ń ta kò ó, kò dájú pé ìjíròrò náà lè sèso rere.” *

Ó gba pé kó o ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan kan. Kò sẹ́ni tó wù kó máa gbé pẹ̀lú ọkọ tàbí aya tó jẹ́ pé tiẹ̀ nìkan ló mọ̀, tó jẹ́ pé tí o kò bá gba tiẹ̀, wàhálà dé nìyẹn. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kí ẹ̀yin méjèèjì ṣe tán láti fara mọ́ ohun tí ẹnì kejì ń fẹ́. Obìnrin kan tó ń jẹ́ June sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń fara mọ́ ohun tí ọkọ mi bá fẹ́ kí inú rẹ̀ lè dùn, òun náà sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún mi. Jẹ kí n jẹ lọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, kì í ṣọ̀rọ̀ tìẹ nìkan.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ẹ fi ohùn pẹ̀lẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yín. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohùn tẹ́ ẹ bá fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò yín náà lẹ máa fi parí rẹ̀. Bí ẹ bá jọ gbé e gbóná fún ara yín látìbẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà lè máà lójú. Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì kẹ́ ẹ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Ẹ fi . . . ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Irú àwọn ìwà yìí ò ní jẹ́ kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ máa bá ara yín fa ọ̀rọ̀, èyí á mú kí ẹ lè yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 4:6.

Ẹ wá ibi tọ́rọ̀ yín ti wọ̀. Bó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà lẹ máa ń bá ara yín jiyàn, ó lè jẹ pé ibi tí èrò yín ti yàtọ̀ síra ni ìjíròrò yín sábà máa ń dá lé. Àríyànjiyàn á dín kù tí ẹ bá wá ibi tọ́rọ̀ yín ti wọ̀. Bí ẹ bá fẹ́ ṣe ìyẹn yọrí, ọ̀kan lára ohun tí ẹ lè ṣe nìyí:

Fa ilà sí abala ìwé láti pín in sí méjì. Lápá àkọ́kọ́, kọ àwọn ibi tí èrò rẹ ti yàtọ̀. Lápá kejì kọ àwọn èrò tó o rò pé o lè fara mọ́. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jọ jíròrò àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà. Wàá rí i pé ibi tí èrò yín ti yàtọ̀ ò tó nǹkan. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kò yẹ kó ṣòro fún yín láti fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀pọ̀ nǹkan. Kódà bó bá tiẹ̀ ṣe kedere pé èrò yín yàtọ̀ síra, ẹ ṣì kọ́kọ́ kọ àwọn èrò yín sílẹ̀ ná, ìyẹn á jẹ́ kí ẹ̀yin méjèèjì lè rí bọ́rọ̀ náà ṣe rí ní kedere.

Ẹ jọ fikùnlukùn. Àwọn ọ̀rọ̀ míì wà tó máa rọrùn láti yanjú, àwọn míì sì wà tó lè ṣòro láti yanjú. Ó máa gba pé kí ẹ̀yin méjèèjì jọ ronú pọ̀ kí ẹ lè rí ojútùú sí ìṣòro náà. Bí ẹ bá sì jọ ronú pọ̀, ẹ lè rí ojútùú tí ẹnì kan ṣoṣo lè má ronú sí.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 4:9.

Má rin kinkin mọ́ èrò rẹ. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Bí ìfẹ́ bá wà, tẹ́ ẹ sì bọ̀wọ̀ fúnra yín, àríyànjiyàn á dín kù, kò sì ní ṣòro fún ẹ̀yin méjèèjì láti jọ gba èrò ara yín. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Cameron sọ pé: “Àwọn nǹkan míì wà tó o lè ti pinnu pé o kò ní ṣe àmọ́ tí aya rẹ bá ṣàlàyé adùn tó wà nínú nǹkan náà, o lè wá rí i pé ohun tí o máa nífẹ̀ẹ́ sí ni.”—Ìlànà Bíbélì: Jẹ́nẹ́sísì 2:18.

^ ìpínrọ̀ 12 Àyọkà láti inú ìwé The Seven Principles for Making Marriage Work.