Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò

Bí O Ṣe Lè Borí Ìdẹwò

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Àwọn ọmọge kan sọ pé kí n fún àwọn ní nọ́ńbà fóònù mi, wọ́n tún sọ pé kí n gbé àwọn sùn. Ṣùgbọ́n, mi ò dá wọn lóhùn, mo kàn ń bá tèmi lọ. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán, mo sọ nínú ọkàn mi pé, ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ gan-an tí mo bá tiẹ̀ fún wọn ní nọ́ńbà mi?’ Ká má parọ́, àwọn ọmọge yẹn wà pa gan-an. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, ó lè máà rí nǹkan kan tó burú nínú ohun tí wọ́n sọ yẹn.”​—Carlos, a ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].

Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Carlos ti ṣe é rí? Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ dájú pé o borí ìdẹwò yẹn.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Tó o bá gba ìdẹwò láyè, wàá kó ara ẹ sí wàhálà

Àtàgbà, àtọmọdé, kò sẹ́ni tí ò lè kó sí ìdẹwò. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ìdẹwò lè gbà yọjú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kì í ṣe ọmọdé nígbà tó kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run . . . , ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.” (Róòmù 7:​22, 23) Láìka bí nǹkan ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù sí, kò gba ìdẹwò náà láàyè. Ìwọ náà lè borí ìdẹwò bí i ti Pọ́ọ̀lù. Àti pé, èrè wo ló wà nínú kéèyàn sọ ara rẹ̀ di ẹrú fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara? (1 ­Kọ́ríńtì 9:27) Àmọ́ ní báyìí tó o ṣì kéré, tó o bá kọ́ béèyàn ṣe lè dènà ìdẹwò, wà á bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn nísinsìnyí, wà á tún lè kojú àwọn ìṣòro míì tó lè yọjú tó o bá dàgbà.

Fíìmù, orin àtàwọn ìwé míì máa ń koná mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Bíbélì sọ pé “ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” máa ń lágbára gan-an. (2 Tímótì 2:​22) Àwọn fíìmù, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, orin àtàwọn ìwé tí wọ́n ń ṣe fáwọn ọ̀dọ́ máa ń koná mọ́ ìfẹ́ ìṣekúṣe. Wọ́n máa ń jẹ́ kò dá bíi pé kò sóhun tó burú téèyàn bá juwọ́ sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, kó sì tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀pọ̀ fíìmú òde oní, tí ọkùnrin kan àti obìnrin kan bá ti yófẹ̀ẹ́, ó dájú pé kí fí ìmù náà tó parí, wọ́n á ba ara wọn sùn. Àmọ́, Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó bá ‘ta kété sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara’ ló gbayì jù. (1 Pétérù 2:​11) Èyí fi hàn pé ìwọ náà borí ìdẹwò. Àmọ́ báwo lo ṣe lè ṣe é?

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Mọ ibi tó o kù sí. Rántí pé bí ògiri ò bá lanu, aláǹgbá ò lè wọ ògiri. Torí náà, kíyè sára kó má bàa jẹ́ pé ibi tó o kù sí ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara á ti wọlé sí ẹ lára. Torí náà, apá ibo ló yẹ kó o tètè ṣiṣẹ́ lé?​—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 1:​14.

Múra sílẹ̀ de ìdẹwò. Ronú lórí àwọn ibi tó ti lè ṣeé ṣe kó o kojú ìdẹwò. Múra ọkàn rẹ sílẹ̀, kó o sì wéwèé ohun tó máa ṣe tí ìdẹwò náà bá dé.​—Ìlànà Bíbélì: Òwe 22:3.

Ṣe ìpinnu tó lágbára. Bíbélì sọ èsì tí Jósẹ́fù fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ tó fẹ́ bá a ṣèṣekúṣe, ó ní: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Ọ̀rọ̀ náà, “báwo ni èmi ṣe lè” tí Jósẹ́fù sọ, fi hàn pé ìpinnu rẹ̀ láti kọ ìṣekúṣe náà lágbára gan-an. Ṣé ìpinnu tìẹ náà ­lágbára?

Àwọn ọmọlúwàbí ni kó o bá ṣọ̀rẹ́. Wàhálà ìṣekúṣe ò ni pọ̀ lọ́rọ̀ ẹ tó bá ń bá àwọn tó kórìíra ìwà pálapàla rìn. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”​—Òwe 13:20.

Yẹra fún àwọn ipò tó lè kó ẹ sí ìjàngbọ̀n. Bí àpẹẹrẹ:

  • Má ṣe máa dá wà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ.

  • Má ṣe lo íńtánẹ́ẹ̀tì ní àkókò tàbí ibi tó ti lè máa ṣe é bí ko wo àwòrán oníhòòhò.

  • Yẹra fáwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ ìṣekúṣe tàbí tí wọ́n ń hu ìwàkiwà.

Àwọn ìpinnu wo lo lè ṣe tó ò fi ní kó sínú ìdẹwò?​—Ìlànà Bíbélì: 2 Tímótì 2:​22.

Gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.’ (Mátíù 26:41) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o borí ìdẹwò, ó sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”​—1 Kọ́ríńtì 10:13.

a A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.