OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ikú
Ibo làwọn òkú wà?
“Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Èrò àwọn kan ni pé téèyàn bá kú, ó lè lọ sí ọ̀run rere, ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì tàbí Limbo. Àwọn míì sì gbà gbọ́ pé téèyàn bá kú, ńṣe ni onítọ̀hún á tún pa dà wáyé, àmọ́ ó lè máà jẹ́ èèyàn mọ́, ó lè jẹ́ igi, ẹranko tàbí nǹkan míì. Èrò àwọn ti kò gba ohun tí ìsìn sọ gbọ́ ni pé ikú ni òpin ìgbésí ayé ẹ̀dá.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Oníwàásù 9:10 sọ pé, “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn àtàwọn ẹranko tí wọ́n bá kú. Ó ní: “Ibì kan náà ni gbogbo wọ́n ń lọ. Inú ekuru ni gbogbo wọ́n ti wá, gbogbo wọ́n sì ń padà sí ekuru.”—Oníwàásù 3:20.
Ipò wo ni àwọn òkú wà?
“Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ohun tí wọ́n kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ohun téèyàn bá ṣe nígbà tó wà láyé ló máa ń pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i nígbà tó bá tún ayé wá. Tó bá ṣe rere, adùn ayérayé ló máa jẹ́ èrè rẹ̀, àmọ́ tó bá jẹ́ èèyàn búburú, ńṣe lá máa joró nínú iná títí ayé. Wọ́n sọ pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ kí wọ́n tó lè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ìbànújẹ́ ayérayé ló sì máa jẹ́ ti àwọn tí a kò bá wẹ̀ mọ́.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn tó ti kú kì í láyọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í jìyà. Torí pé wọn ò mọ nǹkan kan rárá, wọn ò ní ìmọ̀lára ohunkóhun; wọn ò lè ran alààyè lọ́wọ́, wọn ò sì lè fìyà jẹ wọ́n. Oníwàásù 9:5, 6 sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, . . . Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé nísinsìnyí, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin nínú ohunkóhun tí a ó ṣe lábẹ́ oòrùn.”
Ǹjẹ́ ìrètí kankan wà fún àwọn tó ti kú?
“Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí? Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé.”—Jóòbù 14:14.
OHUN TÍ ÀWỌN KAN SỌ
Ọ̀pọ̀ gbà pé kò sí ìrètí kankan fún ẹni tó bá lọ sí ọ̀run àpáádì. Wọ́n sọ pé ńṣe ni ẹni náà á máa joró títí láé. Àmọ́, wọ́n gbà pé tó bá jẹ́ pé pọ́gátórì ni wọ́n lọ, wọ́n máa fi iná yọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí wọ́n tó lọ sọ́run láti máa jẹ̀gbádùn ayérayé.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn tó ti kú ń sinmi ni, Ọmọ Ọlọ́run máa jí wọn dìde lọ́jọ́ iwájú, wọ́n á tún pa dà wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:26, 28, 29) Ìwà tẹ́nì kan bá wá hù lẹ́yìn ìgbà yẹn ló máa pinnu bóyá ó máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. a
a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa àjíǹde, jọ̀wọ́ ka orí 7 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. O tún lè rí àlàyé lórí ìkànnì wa www.jw.org/yo.