Ṣé Dandan Ni Kó O Lọ sí Ibi Ìjọsìn Kó O Tó Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Dandan Ni Kó O Lọ sí Ibi Ìjọsìn Kó O Tó Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló máa ń lọ sí ilé ìjọsìn déédéé torí kí wọ́n lè lọ gbàdúrà sí Ọlọ́run. Àwọn míì tiẹ̀ máa ń rin ìrìn àjo lọ sí ilẹ̀ mímọ́ tàbí ibi ìjọsìn wọn. Ǹjẹ́ o rò pé ó pọn dandan kéèyàn lọ sí tẹ́ńpìlì, ojúbọ tàbí ṣọ́ọ̀ṣì kó tó lè gbàdúrà sí Ọlọ́run? Àbí o rò pé ní tìẹ, o lè gbàdúrà sí Ọlọ́run níbikíbi tàbí nígbàkigbà tó o bá fẹ́? Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?
Nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá àwa èèyàn, kò sí ilé ìjọsìn kankan. Ọgbà kan tó lẹ́wà ló dá fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pé kí wọ́n máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:8) Látinú ọgbà yìí ni wọ́n ti máa ń bá Jèhófà Ẹlẹ́dàá wọn sọ̀rọ̀. Bí àwọn èèyàn ṣe wá ń pọ̀ sí í láyé, àwọn ọkùnrin olódodo, irú bíi Nóà “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kò jọ́sìn Ọlọ́run ní ilé ìjọsìn kankan, wọ́n lẹ́mìí àdúrà, wọ́n fẹ́ràn Jèhófà, wọ́n sì rí ojú rere rẹ̀.
Ọlọ́run Kì Í Gbé Inú Àwọn Ilé Tí A Fi Ọwọ́ Kọ́
Àwọn ọkùnrin olódodo ayé ìgbàanì mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ayé òun ọ̀run kì í gbé inú àwọn ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Abájọ tí Sólómọ́nì ọlọgbọ́n ọba fi sọ pé: “Ọlọ́run yóò ha máa bá aráyé gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́.” (2 Kíróníkà 6:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àgọ́ ìjọsìn, nígbà tó sì yá, wọ́n tún kọ́ tẹ́ńpìlì níbi tí wọ́n máa ń pé jọ sí láti ṣe ayẹyẹ àjọyọ̀ ọdọọdún bí Òfin Ọlọ́run ṣe sọ pé kí wọ́n máa ṣe. (Ẹ́kísódù 23:14-17) Síbẹ̀, wọ́n lè gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbàkigbà tó bá wù wọ́n, yálà nígbà tí wọ́n ń da àwọn ẹran wọn, nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ nínú pápá, tí wọ́n bá wà pẹ̀lú àwọn ìdílé wọn tàbí lákòókò tí wọ́n bá dá wà tí wọ́n sì fẹ́ ronú jinlẹ̀.—Sáàmù 65:2; Mátíù 6:6.
Bákan náà, àwa náà lè gbàdúrà sí Ọlọ́run níbikíbi àti nígbàkigbà. Jésù tó jẹ́ àwòkọ́ṣe wa sábà máa ń lọ sáwọn ibi tó pa rọ́rọ́ kó lè gbàdúrà. (Máàkù 1:35) Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí “ó jáde lọ sórí òkè ńlá láti gbàdúrà, ó sì ń bá a lọ nínú àdúrà gbígbà sí Ọlọ́run ní gbogbo òru náà.”—Lúùkù 6:12.
Lóòótọ́ Júù ni Jésù, ó sì máa ń rí i dájú pé òun lọ síbi àjọyọ̀ ìsìn tó máa ń wáyé nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. (Mátíù 21:12, 13) Síbẹ̀, ó sọ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí tẹ́ńpìlì yẹn kò ní jẹ́ ibi ìjọsìn mímọ́ mọ́. Nígbà tí Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ lẹ́bàá òkè ńlá kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará ibẹ̀ ní tẹ́ńpìlì tiwọn, Jésù sọ fún un pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí kì í ṣe ní òkè ńlá yìí tàbí ní Jerúsálẹ́mù ni ẹ ó ti máa jọ́sìn Baba.” Ó wá sọ pé àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ yóò máa “jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:21, 23.
Lójú Jésù, ilé ìjọsìn tí a fi bíríkì àti àpòrọ́ mọ kọ́ ló ṣe pàtàkì bí kò ṣe kéèyàn jọ́sìn Ọlọ́run látọkàn wá. Àmọ́, ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun, tá a wá mọ̀ sí àwọn Kristẹni, kò ní máa lo ilé kankan fún ìjọsìn wọn? (Ìṣe 11:26) Rárá o. Ìdí pàtàkì wà tó fi sọ ohun tó sọ yẹn.
Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Jẹ́ Ara Ìdílé Kan Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run
Àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ ara ìdílé kan nínú ìjọsìn. (Lúùkù 8:21) Àwọn ìdílé tí ìfẹ́ bá wà láàárín wọn máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, irú bíi kí wọ́n jọ jẹun, èyí sì máa ń mú kí àárín wọn túbọ̀ gún dáadáa. Bákan náà lọ̀rọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run. Àwọn ìpàdé Kristẹni tá a máa ń ṣe dà bí àsè tẹ̀mí tó ń mú kí irú ẹni tá a jẹ́ sunwọ̀n sí i, ó sì ń jẹ́ kí àjọṣe wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run túbọ̀ lágbára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí òun náà jẹ́ Kristẹni kọ̀wé pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì.”—Hébérù 10:24, 25.
Ìdí nìyí tí àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ fi gbà pé wíwà láàárín àwùjọ àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn níwà tó yẹ Kristẹni, èyí tó lè má ṣeé ṣe láti ní téèyàn bá ń dá jọ́sìn Ọlọ́run. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́, ìdáríjì, inú rere, ìwà tútù àti àlááfíà.—2 Kọ́ríńtì 2:7; Gálátíà 5:19-23.
Ibo wá ni àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Kristẹni máa ń pé jọ sí láti jọ́sìn Ọlọ́run? Lọ́pọ̀ ìgbà wọ́n máa ń pé jọ ní àwọn ilé àdáni. (Róòmù 16:5; Kólósè 4:15) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fẹ́ kọ lẹ́tà sí ẹnì kan tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni, ó darí lẹ́tà rẹ̀ sí ‘ìjọ tí ó wà ní ilé rẹ̀.’ a—Fílémónì 1, 2.
Bákan náà lónìí, kò pọn dandan kí àwọn tó fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run lọ kọ́ ilé ìjọsìn gàgàrà kan tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ lọ́nà àrà, ohun tí wọ́n nílò kò ju ilé kan tó mọ níwọ̀n tí á sì gba gbogbo ẹni tó bá wá síbẹ̀. Irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lò, èyí tí wọ́n máa ń pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ. Àwọn ilé yìí máa ń mọ níwọ̀n, wọ́n sì máa ń lò ó fún ìjọsìn wọn. Lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn wọn ni orin kíkọ, àdúrà gbígbà, àti ìjíròrò Bíbélì.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọyì yíya àkókò kan sọ́tọ̀ fúnra wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run. Torí náà, wọ́n máa ń ní àkókò tí wọ́n ń lò lójoojúmọ́ láti fi gbàdúrà ara ẹni tàbí kí wọ́n fi gbàdúrà pa pọ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn. Jákọ́bù 4:8 sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìjọ” tún lè túmọ̀ sí “ṣọ́ọ̀ṣì.”
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì tí a fi ọwọ́ kọ́?—2 Kíróníkà 6:18.
● Ibo ni Jésù ti gbàdúrà ní gbogbo òru?—Lúùkù 6:12.
● Kí nìdí táwọn olùjọ́sìn tòótọ́ fi máa ń pé jọ?—Hébérù 10:24, 25.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
Ǹjẹ́ ó láwọn ibì kan tó o ti gbọ́dọ̀ gbàdúrà kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà rẹ?