Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀gbọ́n Àtàwọn Àbúrò Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀gbọ́n Àtàwọn Àbúrò Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Wà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀gbọ́n Àtàwọn Àbúrò Mi?

Báwo ni àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ ṣe rí?

․․․․․ Ọ̀rọ̀ wa wọ̀ dáadáa

․․․․․ Kì í sábà sí wàhálà láàárín wa

․․․․․ A máa ń fara dà á fún ara wa

․․․․․ Ìjà ni ṣáá ní gbogbo ìgbà

ÀWỌN tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan wà tó jẹ́ pé kòríkòsùn ni wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, Felicia, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], sọ pé, “Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi àtàtà ni Irena, àbúrò mi ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].” a Bákan náà, Carly, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ nípa Eric, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọmọ ogún [20] ọdún pé: “Ọ̀rọ̀ wa wọ̀ gan-an ni. A kì í bára wa jà.”

Àmọ́, ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò míì dà bíi ti Lauren àti Marla. Lauren sọ pé, “Kò sóhun tí à kì í jà lé lórí, títí kan àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì.” Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Alice, ọmọ ọdún méjìlá [12] sọ nípa Dennis, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí. Ó sọ pé: “Ó máa ń múnú bí mi! Ṣe ló kàn máa ń já wọnú yàrá mi, tó sì máa ń mú ohun tó bá wù ú láìsọ fún mi. Kò mọ̀wà hù rárá!”

Ṣé o ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tó máa ń múnú bí ẹ? Òótọ́ ni pé, ojúṣe àwọn òbí yín ni láti rí sí i pé gbogbo yín ń gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ nínú ilé. Àmọ́, bópẹ́ bóyá, o máa ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń bá ẹlòmíì gbé ní ìrẹ́pọ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bó o ṣe lè bá àwọn ẹlòmíì gbé ní báyìí tó o ṣì wà nílé.

Ronú nípa awuyewuye tó ti wáyé láàárín ìwọ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ. Kí ló sábà máa ń fa ìjà yín? Wo àwọn ohun tá a kọ tẹ̀ lé e yìí, kó o sì fi àmì ✔ sí àpótí tó bá a mu tàbí kó o kọ ohun tó máa ń múnú bí ẹ.

Àwọn nǹkan mi. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi máa ń mú àwọn nǹkan mi láìsọ fún mi.

Ìwà wa kò bára mu. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi ò mọ̀ ju tara rẹ̀ lọ, kì í ronú jinlẹ̀, ṣe ló máa ń fẹ́ sọ gbogbo ohun tí màá ṣe fún mi.

Dídá wà. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi máa ń wọ yàrá mi láì kan ilẹ̀kùn, ó máa ń ka àwọn lẹ́tà tí mo ní lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù mi.

Nǹkan míì. ․․․․․

Bí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ bá ń múnú bí ẹ, tó máa ń fẹ́ ṣe bí ọ̀gá lé ẹ lórí tàbí tó máa ń fẹ́ mọ gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe, ó lè ṣòro fún ẹ láti gbójú fo àwọn ohun tó ń ṣe yìí dá. Àmọ́ òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Fífún imú pọ̀ sì ni ohun tí ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, fífún ìbínú jáde sì ni ohun tí ń mú aáwọ̀ jáde.” (Òwe 30:33) Tó o bá mú ẹnì kan sínú, ó lè mú kó o fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí onítọ̀hún, bí fífún imú pọ̀ ṣe lè mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn jáde ní imú. Ńṣe ni èyí á tún máa dá kún ìṣòro tó wà nílẹ̀. (Òwe 26:21) Kí lo lè ṣe tí ohun tó ń bí ẹ nínú kò fi ní fa awuyewuye? Ohun àkọ́kọ́ tó o ní láti ṣe ni pé kó o mọ ohun náà gan-an tó fa ìṣòro.

Ìṣòro àbí Ohun Tó Fa Ìṣòro?

Àwọn ìṣòro tó máa ń wà láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò dà bíi rorẹ́ tó máa ń sú síni lára. Ohun kan tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé kòkòrò wà nínú ara ni rorẹ́ tó máa ń sú síni lára. Bákan náà, bí ìjà bá wáyé láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, ohun tó fara hàn sóde la rí yẹn, èyí sì fi hàn pé, ìṣòro kan wà tó fa ìjà náà.

Èèyàn lè fọwọ́ tẹ rorẹ́ náà láti mú un kúrò. Àmọ́, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lo kàn mú ohun tó sú sí ẹ lára yẹn kúrò, èyí sì lè dá àpá sí ẹ lára tàbí kó mú kí kòkòrò náà gbèèràn. Ohun tó dáa jù ni pé kó o lo oògùn sí kòkòrò yẹn kó má bàa tàn kálẹ̀. Bí ọ̀ràn ìjà tó ṣeé ṣe kó wáyé láàárín tẹ̀gbọ́n tàbúrò ṣe rí nìyẹn. Gbìyànjú láti mọ ohun tó fa ìṣòro náà gan-an, ìyẹn ò ní jẹ́ kí ìjà náà kó ìdààmú bá ẹ, àmọ́, ńṣe ló máa jẹ́ kó o lè yanjú ìṣòro náà. Wàá tún lè fi ìmọ̀ràn Sólómọ́nì, ọlọ́gbọ́n Ọba sílò, èyí tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”—Òwe 19:11.

Bí àpẹẹrẹ, Alice, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ nípa Dennis ẹ̀gbọ́n rẹ pé, “Ńṣe ló kàn máa ń já wọnú yàrá mi, tó sì máa ń mú ohun tó bá wù ú láìsọ fún mi.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kí ni ohun náà gan-an tó o rò pé ó fa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò bọ̀wọ̀ fúnra wọn. b

Láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí, Alice lè sọ fún Dennis pé kò gbọ́dọ̀ wọ inú yàrá òun mọ́, kò sì gbọ́dọ̀ lo nǹkan òun. Àmọ́, ṣe ni èyí á kàn bójú tó ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, ó sì ṣeé ṣe kí èyí dá wàhálà míì sílẹ̀. Ó dájú pé àjọṣe Dennis àti Alice á túbọ̀ wọ̀ dáadáa bí Alice bá lè jẹ́ kí Dennis lóye pé ó yẹ kó máa fọ̀wọ̀ òun wọ òun àtàwọn nǹkan tó jẹ́ tòun, pàápàá nígbà tóun bá fẹ́ dá wà.

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro tàbí Kó O Dènà Rẹ̀

Tó o bá lóye àwọn ohun tó fa ìṣòro tó o ní pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ, apá kan lára bó o ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà lo ṣì mọ̀ yẹn. Kí lo lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà, kó o sì dènà awuyewuye tó ṣeé ṣe kó tún jẹ yọ? Gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun mẹ́fà yìí.

1. Ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ìlànà kan. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” (Òwe 15:22) Kí ọ̀rọ̀ náà lè yanjú, ronú nípa ohun tó o rí i pé ó fa ìṣòro tó wà láàárín ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ. Wò ó bóyá ẹ lè jọ fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ìlànà kan tó máa yanjú ohun tó ń fa ìṣòro náà gan-an. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé lílo nǹkan ara yín ló máa ń dá wàhálà sílẹ̀, Ìlànà Kìíní lè jẹ́: “Tó o bá fẹ́ mú ohunkóhun tó jẹ́ ti ẹlòmíì, kọ́kọ́ máa béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.” Ìlànà Kejì lè jẹ́: “Bí oní nǹkan bá sọ pé, ‘Má ṣe mú nǹkan mi,’ o ò gbọ́dọ̀ mú un.” Tẹ́ ẹ bá ń fi àwọn ìlànà yìí lélẹ̀, ẹ máa ronú nípa àṣẹ tí Jésù pa, pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Nípa báyìí, kò ní ṣòro fún yín láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tẹ́ ẹ bá fi lélẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ kí àwọn òbí yín mọ àwọn ìlànà tẹ́ ẹ ti fohùn ṣọ̀kan lé lórí, kẹ́ ẹ lè mọ̀ bóyá wọ́n fara mọ́ ọn.—Éfésù 6:1.

2. Ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí?” (Róòmù 2:21) Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Bí àpẹẹrẹ, bó o bá fẹ́ kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ máa fi ọ̀wọ̀ rẹ wọ̀ ẹ́, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa kan ìlẹ̀kùn kó o tó wọ yàrá rẹ̀ tàbí kó o máa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ kó o tó ka àwọn lẹ́tà tó ní lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù rẹ̀.

3. Má ṣe tètè máa bínú. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn yìí fi wúlò? Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí òwe Bíbélì kan ṣe sọ, “ìbínú ngbe ni àyà aṣiwèrè.” (Oníwàásù 7:9, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Tó o bá jẹ́ ẹni tó máa ń tètè bínú, o ò ní gbádùn ayé ẹ rárá. Kò sí àní-àní pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ máa sọ̀rọ̀ tàbí kó ṣe ohun tó máa bí ẹ nínú. Àmọ́, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé èmi náà ti ṣe ohun tó jọ èyí fún un rí?’ (Mátíù 7:1-5) Jenny sọ pé, “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13], mo máa ń ronú pé ohun tí mo bá ti sọ ló ṣe pàtàkì jù lọ, òun làwọn ẹlòmíì sì gbọ́dọ̀ ṣe. Àbúrò mi náà ti wá ń ronú bí mo ṣe ń ronú nígbà yẹn. Torí náà, mi kì í ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí bàbàrà.”

4. Máa Dárí Jini pátápátá. Ó yẹ kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó bá le, kẹ́ ẹ sì yanjú rẹ̀. Àmọ́, ṣé gbogbo ìgbà tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ bá ti ṣe àṣìṣe lo gbọ́dọ̀ máa pè é jókòó láti bá a sọ̀rọ̀? Inú Jèhófà Ọlọ́run máa dùn tó o bá lè máa “gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Alison, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Èmi àti Rachel àbúrò mi máa ń tètè yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín wa. Àwa méjèèjì máa ń tètè tọrọ àforíjì, a sì máa ń ṣàlàyé ohun tá a bá rò pé ó fa èdè àìyedè náà. Ìgbà míì wà tí mo máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dá ọ̀rọ̀ náà dúró di ọjọ́ kejì kí n lè ronú dáadáa kí n tó lọ bá àbúrò mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, tó bá máa fi di àárọ̀ ọjọ́ kejì, ó máa ń rọrùn láti gbàgbé ọ̀rọ̀ náà pátápátá débi pé mi ò tiẹ̀ ní sọ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́.”

5. Jẹ́ kí àwọn òbí yín dá sí ọ̀rọ̀ náà. Bí ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ò bá lè yanjú ìjà tó wà láàárín yín, àwọn òbí yín lè bá yín dá sí i. (Róòmù 14:19) Àmọ́, máa rántí pé, tẹ́ ẹ bá lè máa yanjú èdè àìyedè tó wà láàárín yín láìjẹ́ pé àwọn òbí yín dá sí i, ìwà àgbà lẹ̀ ń hù yẹn.

6. Mọyì àwọn ànímọ́ rere tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ní. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ ní àwọn ànímọ́ tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Kọ ohun kan tó o mọyì lára ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ.

Orúkọ Ohun tí mo mọyì lára rẹ̀

․․․․․ ․․․․․

Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa àwọn ibi tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ kù sí, o ò ṣe wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ àwọn ohun tó o fẹ́ràn nípa ìwà wọn fún wọn?—Sáàmù 130:3; Òwe 15:23.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Tó o bá jáde kúrò nílé, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tí ìwà wọn ń bí ẹ nínú ló máa yí ẹ ká, irú bí àwọn tẹ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ẹlòmíì tí kò mọ ìwà hù, tí wọn kò ka nǹkan sí, tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ. Láti inú ilé lo ti máa kọ́ bó o ṣe lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Tó o bá ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tí ọ̀rọ̀ yín kò fi bẹ́ẹ̀ wọ̀, ńṣe ni kó o máa fojú tó dáa wo ọ̀rọ̀ náà. Gbà pé ẹ̀kọ́ pàtàkì tó máa wúlò fún ẹ nígbà tó bá yá lò ń kọ́ yẹn.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í fìgbà gbogbo jẹ́ pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni ló máa sún mọ́ni jù lọ. (Òwe 18:24) Àmọ́, ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ lè túbọ̀ mọwọ́ ara yín, tẹ́ ẹ bá ń “bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,” kódà bí ẹ bá ní “ìdí fún ẹjọ” lòdì sí ara yín. (Kólósè 3:13) Tó o bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, o ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa bínú sí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ mọ́. Àwọn náà ò sì ní fi bẹ́ẹ̀ máa bínú sí  mọ́.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Wo  àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí fún àlàyé síwájú sí i.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ìṣòro àti ohun tó fà á?

● Èwo nínú àwọn nǹkan mẹ́fà tá a sọ yìí ló yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí jù lọ?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

 MỌ OHUN TÓ FA ÌṢÒRO GAN-AN

Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ bó o ṣe lè lóye ohun tó ń fa ìṣòro láàárín àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, ka àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọmọ tó fi ilé sílẹ̀, tó sì lọ fi ogún tí bàbá rẹ̀ fún un ṣòfò.—Lúùkù 15:11-32.

Kíyè sí ohun tí ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ṣe nígbà tí àbúrò rẹ̀ pa dà wálé. Kó o wá dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bínú?

Kí lo rò pé ó fa ìṣòro yẹn gan-an?

Báwo ni bàbá wọn ṣe gbìyànjú láti yanjú ìṣòro náà?

Kí ni ẹ̀gbọ́n inú ìtàn náà ní láti ṣe kí ìṣòro náà lè yanjú?

Wá ronú nípa awuyewuye kan tó wáyé láàárín ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ láìpẹ́ yìí. Kó o sì kọ ìdáhùn rẹ síwájú àwọn ìbéèrè yìí.

Kí ló ṣẹlẹ̀?

Kí lo rò pé ó ṣeé ṣe kó fa ìṣòro náà gan-an?

Àwọn òfin wo lẹ lè fohùn ṣọ̀kan lé lórí, tó máa mú kí ìṣòro náà yanjú tí kò sì ní jẹ́ kí awuyewuye tún wáyé nígbà míì?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Mo fẹ́ kí èmi àtàwọn àbúrò mi jẹ́ ọ̀rẹ́ títí ayé, torí náà, àfi kí n sọ wọ́n dọ̀rẹ́ láti ìsinsìnyí lọ.”

“A máa ń ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, ìyẹn sì jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. A kì í fi bẹ́ẹ̀ jiyàn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.”

“Láwọn ọ̀nà kan, bí ọ̀sán àti òru lèmi àti àbúrò mi ṣe yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, kò sí ẹni tí mo lè fi àbúrò mi wé. Mi kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣeré rárá!”

“Ìgbà tí mo bá wà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi, ni inú mi máa ń dùn jù lọ. Torí náà, ìmọ̀ràn mi fún gbogbo àwọn tó ní ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni pé ‘kí wọ́n má ṣe fọ̀rọ̀ wọn ṣeré o!’”

[Àwọn àwòrán]

Tia

Bianca

Samantha

Marilyn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Àwọn ìṣòro tó máa ń jẹyọ láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò dà bí rorẹ́, ńṣe ló yẹ kó o lo oògùn sí i, kò yẹ kó o kàn máa tẹ̀ ẹ́