Ohun Kẹrin: Ọ̀wọ̀
Ohun Kẹrin: Ọ̀wọ̀
“Kí ẹ mú gbogbo . . . ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Éfésù 4:31.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Kò sí ìdílé tí aáwọ̀ kì í wà, yálà ìdílé tó tòrò tàbí èyí tí ìjà ti máa ń wáyé. Àmọ́, bí àwọn ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan bá ní ọ̀rọ̀ láti bára wọn sọ, wọn kì í pẹ̀gàn ara wọn, wọn kì tàbùkù síra wọn, wọn kì í sì í búra wọn ní ọ̀nà èyíkéyìí. Ohun tí àwọn tó wà nínú ìdílé bá fẹ́ kí wọ́n ṣe sí àwọn ni àwọn náà máa ń ṣe sí àwọn ẹlòmíì.—Mátíù 7:12.
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Bí ohun ìjà ogun ṣe ń pani lára bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ ẹnu ṣe lè pani lára. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ó sàn láti máa gbé ní ilẹ̀ aginjù ju gbígbé pẹ̀lú aya alásọ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú pákáǹleke.” (Òwe 21:19) Àmọ́, obìnrin nìkan kọ́ ni ẹsẹ Bíbélì yìí bá wí o. Bó bá sì di ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kólósè 3:21) Bí àwọn òbí bá ń rí sí àwọn ọmọ nígbà gbogbo, ó lè mú káwọn ọmọ máa ronú pé kò sí ohun táwọn lè ṣe tó máa tẹ́ àwọn òbí àwọn lọ́rùn. Wọ́n tiẹ̀ lè dẹ́kun àtimáa tẹ̀ síwájú.
Gbìyànjú èyí wò. Lo àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti fi ṣàgbéyẹ̀wò bẹ́ ẹ ṣe ń bọ̀wọ̀ fúnra yín tó nínú ìdílé.
◼ Nínú ìdílé mi, ṣé èdèkòyédè máa ń le débi pé ńṣe ni ẹnì kan á bínú jáde kúrò nínú ilé?
◼ Bí mo bá ń bá ọkọ, aya, tàbí àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, ṣé mo máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ tó máa kàn wọ́n lábùkù, bí “arìndìn,” “òpònú,” tàbí irú èdè míì bẹ́ẹ̀?
◼ Ṣé ibi tí àwọn èèyàn ti máa ń búra wọn ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà?
Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ohun kan tàbí méjì tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ, bó o bá fẹ́ máa sọ ọ̀rọ̀ tó fi ọ̀wọ̀ hàn. (Àbá: Pinnu láti máa lo gbólóhùn bíi “èmi” dípò “o.” Bí àpẹẹrẹ, “ó máa ń dùn mí bó o bá . . . ,” dípò “gbogbo ìgbà ni o máa ń . . . ”)
O ò ṣe jẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ mọ ohun tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ? Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, ní kí ọkọ tàbí aya rẹ sọ ibi tó o ti tẹ̀ síwájú dé fún ẹ.
Ronú nípa ohun tó o lè ṣe tó ò fi ní máa sọ̀rọ̀ èébú nígbà tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀.
O ò ṣe tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ rẹ bó o bá ti le koko mọ́ wọn tàbí tó o ti sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí wọn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Bí ìgbì omi òkun ṣe lè mú kí àpáta líle gbagidi jẹ wọnú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí ń pani lára ṣe lè sọ ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan di ahẹrẹpẹ