Ohun Kẹfà: Ìdáríjì
Ohun Kẹfà: Ìdáríjì
“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.”—Kólósè 3:13.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí. Àwọn ìdílé tó wà níṣọ̀kan máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn kọjá; àmọ́ wọn kì í gbé aáwọ̀ tó ti kọjá sọ́kàn kí wọ́n sì wá lò ó láti máa ṣàròyé pé, “Gbogbo ìgbà lo máa ń pẹ́” tàbí “O kì í fetí sílẹ̀.” Ọkọ àti aya gbà pé “ẹwà ni ó . . . jẹ́ . . . láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”—Òwe 19:11.
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì. Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini,” àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá ò rí bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 86:5) Bí tọkọtaya ò bá sì yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀, ó lè mú kí ẹ̀dùn ọkàn wọn pọ̀ débi pé wọn ò ní lè dárí ji ara wọn. Á wá di pé kí ọkọ àti aya máa bára wọn yan odì, kí wọ́n má sì ri ti ẹnì kejì wọn rò mọ́. Bí eré bí eré, ìfẹ́ ò ní ríbi gbé mọ́ nínú ìgbéyàwó wọn.
Gbìyànjú èyí wò. Wo fọ́tò tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ yà nígbà tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tàbí nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà. Gbìyànjú láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, kó tó di pé ìjà tó wáyé yí ojú tẹ́ ẹ fi ń wo ara yín pa dà. Lẹ́yìn náà, kó o wá ronú lórí àwọn ànímọ́ tó mú kó o fẹ́ràn ọkọ tàbí aya rẹ nígbà yẹn.
◼ Ní báyìí, àwọn ànímọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ ní wo ló fà ẹ́ mọ́ra jù lọ?
◼ Ronú nípa àwọn àbájáde rere tó lè tìdí ẹ̀ wá fáwọn ọmọ rẹ bó o bá túbọ̀ ń dárí jini.
Pinnu ohun tó o máa ṣe. Ronú nípa ọ̀nà kan tàbí méjì tó ò fi ní máa fi èdè àìyedè tó ti wáyé láàárín yín nígbà kan hùwà bí èdè àìyedè míì bá wáyé láàárín ìwọ àti ẹni kejì rẹ nínú ìgbéyàwó.
O ò ṣe yin ọkọ tàbí aya rẹ nítorí àwọn ànímọ́ tó ń dá ẹ lọ́rùn lára rẹ̀?—Òwe 31:28, 29.
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà díẹ̀ tó o lè gbà máa dárí ji àwọn ọmọ rẹ.
O ò ṣe bá àwọn ọmọ rẹ jíròrò nípa ìdáríjì àti àǹfààní tí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé máa jẹ bí gbogbo yín bá ń dárí ji ara yín?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Bó o bá dárí ji ẹnì kan, ńṣe ló dà bí ìgbà tó o wọ́gi lé gbèsè tí onítọ̀hún jẹ, o ò ní retí pé kó san gbèsè náà mọ́