Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo La Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà?

Ibo La Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà?

Ibo La Ti Lè Rí Ìtọ́sọ́nà?

IBO la lè yíjú sí báa bá fẹ́ káyé yẹ wá? Ti pé ká rí towó ṣe kọ́ là ń wí o, àmọ́ ká gbélé ayé ṣe ohun tó dáa. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mẹ́nu kàn án nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, bó ti wù kó kéré mọ, ẹni táyé bá máa yẹ gbọ́dọ̀ láwọn ìlànà yíyè kooro kó sì ní ohun gidi tó fẹ́ fayé ẹ̀ ṣe, ìyẹn àwọn ohun tí kò ní í ṣe pẹ̀lú òkìkí, ọrọ̀, tàbí agbára.

Ibo la ti lè rí àwọn ìlànà tó yè kooro àti ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tá a bá ní nípa ohun tó yẹ ká gbélé ayé ṣe? Ṣé ọwọ́ wa náà ni gbogbo ẹ̀ wà? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, èrò tí kò dáa, tó lè sìn wá lọ síbi tí kò yẹ ló sábà máa ń wá sọ́kàn wa. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Torí náà, àìmọye èèyàn ń bá a nìṣó láti máa lépa àwọn ohun asán tí Bíbélì pè ní “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nÌ ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) Ìwọ̀nyẹn kọ́ ló ń jẹ́ káyé yẹni, òfo àti òmúlẹ̀mófo tó ń yọrí sí ìjákulẹ̀ àti àìláyọ̀ ni. Torí náà, ohun tó dáa tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni pé wọ́n máa ń wá ìtọ́sọ́nà lọ sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa kí wọ́n bàa lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó gbàrònú. a

Ṣó Yẹ Ká Wá Ìtọ́sọ́nà Lọ Sọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká wá ìtọ́sọ́nà lọ sọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa? Ó mọ ìdí tó fi dá wa, torí náà, ó mọ ohun tó yẹ ká gbélé ayé ṣe. Ó mọ ṣe dá wa, ó mọ ohun tá à ń rò, ó sì mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa. Torí náà, Ọlọ́run ló mọ àwọn ìlànà tó dára jù lọ táwa èèyàn lè máa tẹ̀ lé. Ìyẹn nìkan kọ, Ọlọ́run ló tún jẹ́ àpẹẹrẹ ìfẹ́ tó ga jù lọ, torí náà, ó fẹ́ ká láyọ̀ ní tòótọ́ káyé sì yẹ wá. (1 Jòhánù 4:8) Ibo la ti lè rí ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ tó ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá? Inú Bíbélì Mímọ́ la ti lè rí i. Ọlọ́run ló ṣe Bíbélì fún wa, ó sì lo ogójì [40] èèyàn tó jẹ́ akọ̀wé. b (2 Tímótì 3:16, 17) Àmọ́, báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ìtọ́sọ́nà tá a máa rí nínú ìwé yẹn á ràn wá lọ́wọ́?

Jésù Kristi tó jẹ́ aṣojú pàtàkì jù lọ fún Ọlọ́run sọ pé, “a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́,” tàbí àbájáde rẹ̀. (Mátíù 11:19; Jòhánù 7:29) Ọgbọ́n Ọlọ́run máa ń jẹ́ káyé yẹni kéèyàn sì láyọ̀ tó tọ́jọ́, ó máa ń múni tọ “gbogbo ipa ọ̀nà ohun rere pátá,” nígbà tó jẹ́ pé ńṣe lọgbọ́n èèyàn tí kò ka ọgbọ́n Ọlọ́run sí máa ń fa ìkùnà tó sì máa ń bani láyọ̀ jẹ́.—Òwe 2:8, 9; Jeremáyà 8:9.

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn kan tó pera wọn ní abẹ́gbẹ́yodì fi wà láàárín ọdún 1960 sí ọdún 1969. Wọn kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà àti àṣẹ àwọn àgbà iwájú wọn, ọ̀pọ̀ ǹnkan ni wọ́n gbé lárugẹ, tó fi mọ́ lílo oògùn olóró, jíjayé òní àti níní ìbálòpọ̀ lọ́nà tí kò tọ́. Àmọ́, ṣé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ fi ọgbọ́n tòótọ́ hàn? Ṣó jẹ́ káwọn èèyàn rí ohun tó ní láárí fi ayé wọn ṣe? Ṣó jẹ́ kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà ọmọlúwàbí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó sì ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀ tó tọ́jọ́? Ìtàn fi hàn pé kò mú kí nǹkan sunwọ̀n fáwọn èèyàn, ńṣe ló mú kí ìwà ìbàjẹ́ máa gogò sí i láwùjọ.—2 Tímótì 3:1-5.

A ò lé fi ọgbọ́n Ọlọ́run wé tèèyàn, torí pé ìgbà gbogbo lọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì máa ń ṣeni láǹfààní. (Aísáyà 40:8) Bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ tó kàn lẹ́yìn èyí, ó ṣeé ṣe kó o rí ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀, torí pé ó jíròrò àwọn ìlànà mẹ́fà látinú Bíbélì tó ti ran àìmọye èèyàn lọ́wọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ apá ibi gbogbo lágbàáyé làwọn èèyàn wọ̀nyí ti wá, àmọ́ wọ́n ní ojúlówó ayọ̀, ayé sì yẹ wọ́n, láìka bí wọ́n ṣe lówó lọ́wọ́ tó tàbí bí wọ́n ṣe gbajúmọ̀ sí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí tó ní àkọlé náà,  “Ohun Tó Ń Mú Ká Rò Pé Ayé Ò Lè Yẹni.”

b Wo àkànṣe ìwé ìròyìn Jí! ti November 2007 lédè Gẹ̀ẹ́sì tó jíròrò ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Can You Trust the Bible?” (Jí! January–March, 2008, ojú ìwé 12 àti 13; 21 sí 23; 30 àti 31) Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú àkànṣe Jí! yìí lo ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí, ìtàn, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, àtàwọn ẹ̀rí míì láti fi hàn pé lóòótọ́ ní Ọlọ́run mí sí Bíbélì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

 OHUN TÓ Ń MÚ KÁ RÒ PÉ AYÉ Ò LÈ YẸNI

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tẹnu mọ́ ọn pé kò sí Ọlọ́run àti pé ńṣe làwa ẹ̀dá èèyàn ṣàdéédéé wà nípasẹ̀ ẹfolúṣọ̀n. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, a jẹ́ pé nípasẹ̀ èèṣì la fi wà, kò sì sídìí tá a fi ní láti máa wá ohun tá a máa fayé wa ṣe àtàwọn ìlànà tó borí ohun gbogbo tó yẹ ká máa tẹ̀ lé.

Àwọn míì gbà gbọ́ pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá ayé tán ló ti pa wá tì. Èyí tó túmọ̀ sí pé a jẹ́ ọmọ òrukàn nípa tẹ̀mí, láìmọ ohun tá a máa fayé wa ṣe, àtàwọn ìlànà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé. Gba èyí yẹ̀ wò: Ọlọ́run dá ọgbọ́n àdánidá mọ́ ẹranko kọ̀ọ̀kan láwùjọ àwọn ẹranko. Ọgbọ́n yìí ni wọ́n nílò láti ṣe ohun tí Ọlọ́run torí ẹ̀ dá wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, à ń rí ẹ̀rí ọgbọ́n rẹ̀ tó jinlẹ̀ nínú ayé tá à ń gbé. Ṣé irú Ẹlẹ́dàá kan náà yẹn wá lè dá àwa èèyàn kó sì fi wá sílẹ̀ ká máa táràrà nínú òkùnkùn? Ká má rí i!—Róòmù 1:19, 20.

Ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí táwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ fi ń kọ́ni mú kó dà bíi pé ẹni bá rí já jẹ tó sì lówó lọ́wọ́ nìkan layé yẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ipa rere tí Bíbélì ń ní lórí ìgbésí ayé ẹni fi hàn pé ọgbọ́n inú rẹ̀ yè kooro