“Ibi Tówó Ń Bá Wọlé Jù Lágbàáyé”
“Ibi Tówó Ń Bá Wọlé Jù Lágbàáyé”
Lọ́dọọdún, ẹgbẹ̀ta [600] mílíọ̀nù èèyàn ló ń rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè míì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù èèyàn míì ló sì ń rìnrìn-àjò káàkiri orílẹ̀-èdè wọn nítorí iṣẹ́ àti nítorí àtigbádùn ara wọn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ tó jẹ mọ́ rírìnrìn-àjò afẹ́ ni “ibi tówó ń bá wọlé jù lágbàáyé.” Lára irú àwọn ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òtẹ́ẹ̀lì, ibi ìgbafẹ́, ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, ilé iṣẹ́ tó ń bani ṣètò ìrìn-àjò àtàwọn ilé iṣẹ́ míì tó ń bójú tó àwọn arìnrìn-àjò.
KÁÀKIRI àgbáyé, òbítíbitì owó tó ń wọlé látàrí rírìnrìn-àjò afẹ́ máa ń tó mílíọ̀nù lọ́nà mílíọ̀nù mẹ́rin dọ́là. Àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ káàkiri yìí lè má mọ̀ pé àwọn wà lára àwọn tó ń mú kí àlàáfíà rídìí jókòó káàkiri ayé o, síbẹ̀ ohun tí àjọ tó ń rí sí ìrìn-àjò afẹ́ lábẹ́ àsíá Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè sọ nípa wọn nìyẹn. Lọ́dún 2004, Ọ̀gbẹ́ni Francesco Frangialli, ọ̀gá àgbà àjọ náà sọ fáwọn ààrẹ tó ń ṣèpàdé àpérò kan ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn pé: “Kò sí bá a ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ àlàáfíà tá ò ní sọ̀rọ̀ ìrìn-àjò afẹ́. Ìrìn-àjò afẹ́ lágbára débi pé ó lè ṣàtúnṣe sóhun tá a ti gbà pé kò ṣeé tún ṣe, ó sì lè parí aáwọ̀ táwọn èèyàn ti gbà pé kò lè parí mọ́.”
Báwo ni ìrìn-àjò afẹ́ tó lágbára tó báyìí ṣe bẹ̀rẹ̀? Ṣé ìrìn-àjò afẹ́ lóore gidi kan tó ń ṣe lóòótọ́? Ṣé “ìrìn-àjò afẹ́ lágbára débi pé” ó lè mú àlàáfíà wá nítòótọ́?
Bí Ìrìn-Àjò Afẹ́ Ṣe Bẹ̀rẹ̀
Láàárín ọdún 1801 sí 1900 làwọn èèyàn nílẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sí ìrìn-àjò afẹ́ irú èyí tí wọ́n ń rìn lóde òní. Lákòókò táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀rọ ṣe gbogbo nǹkan, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ṣọ̀mù fáwọn èèyàn púpọ̀ sí i láwọn orílẹ̀-èdè náà, ọ̀pọ̀ sì wá rí i pé àwọn lówó lọ́wọ́, àwọn sì rí àyè táwọn lè fi rìnrìn-àjò.
Yàtọ̀ síyẹn, oríṣiríṣi àwọn ohun ìrìnnà tó lè kó èrò tó pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà tún bẹ̀rẹ̀ sí yọjú. Àwọn ọkọ ojú irin tó lágbára ń gbé àwọn èèyàn káàkiri àwọn ìlú ńláńlá tí wọ́n wà jákèjádò ayé. Bẹ́ẹ̀ sì làwọn ọkọ̀ ojú omi jìmàwò ń gbé àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè kan dé orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú iná piti. Láti lè tọ́jú àwọn arìnrìn-àjò tó ń pọ̀ sí i yìí, àwọn èèyàn túbọ̀ ń dá òtẹ́ẹ̀lì sílẹ̀ nítòsí ibùdókọ̀ ojú irin àti èbúté.
Nígbà tó di ọdún 1841, Ọ̀gbẹ́ni Thomas Cook, oníṣòwò tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, rí i pé ó máa dá a gan-an béèyàn bá pa gbogbo òwò tó jẹ mọ́ títọ́jú àwọn rírìnrìn-àjò pọ̀. Òun ló kọ́kọ́ ní ilé iṣẹ́ tó ń ṣètò pa pọ̀ fún fífi ọkọ̀ gbé àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ àti gbígbà wọ́n lálejò, tó sì ń ṣètò àwọn ohun ìgbafẹ́ táá jẹ́ kí wọ́n gbádùn ìrìn-àjò wọn níbi tí wọ́n ń lọ. Ọ̀gbẹ́ni William Gladstone, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó jẹ́ èèkàn nínú ọ̀ràn ìṣèjọba láàárín ọdún 1860 sí 1869, sọ pé: “Látàrí ọgbọ́n tí Ọ̀gbẹ́ni Cook dá yìí, ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tó wá rọrùn fún toníwá, tẹlẹ́mù láti máa rìnrìn-àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì kí wọ́n sì lè mọ àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Èyí ló sì wá ń mú káwọn èèyàn máa wo àwọn ará ibòmíì bí ọ̀rẹ́ dípò ọ̀tá.”
Bó Ṣe Gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Láàárín Ọdún 1901 sí 2000
Ó bani nínú jẹ́ pé pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe ń rìnrìn-àjò káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n sì túbọ̀ ń lóye àwọn ará ibòmíì, kò ní kí ogun àgbáyé má jà lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn lọ́dún 1914 àti lọ́dún 1939. Ṣùgbọ́n, kàkà káwọn ogun tó jà yẹn mú káwọn èèyàn fìdí mọ́lé wọn, ṣe ni ìyípadà tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ àti ìtẹ̀síwájú tó ń dé bá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lẹ́yìn àwọn ogun yẹn mú káwọn èèyàn máa túbọ̀ rìnrìn-àjò.
Nígbà yẹn, ọkọ̀ òfuurufú túbọ̀ ń yára sí i, owó tí wọ́n fi ń wọ̀ ọ́ sì dín kù. Bákan náà, àwọn ọ̀nà márosẹ̀ wà láti apá ibì kan dé ibòmíì láyé, mọ́tò sì pọ̀ bíi rẹ́rẹ. Nígbà tí ọ̀rúndún ogun fi máa dé ìdajì, àwọn ará Yúróòpù àti Amẹ́ríkà ti sọ rírìnrìn-àjò afẹ́ lákòókò ìsinmi di àṣà wọn, ó sì ti rọrùn fún onírúurú èèyàn láti rìnrìn-àjò níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti ra tẹlifíṣọ̀n sílé, èyí sì ń jẹ́ kí wọ́n lè máa ráwọn ibi tó lẹ́wà láyé wò, ó sì ń mú kó máa wù wọ́n láti lọ sí ìdálẹ̀.
Láàárín ọdún 1961 sí ọdún 1963, ó tó àádọ́rin mílíọ̀nù èèyàn tó ń rìnrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn lọ́dún. Nígbà tó fi máa di àárín ọdún 1994 sí ọdún 1996, iye wọn ti di mílíọ̀nù lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta! Ṣe làwọn èèyàn kàn ń dá ibi ìgbafẹ́ sílẹ̀ nílé, lóko àti lẹ́yìn odi, káwọn arìnrìn-àjò láti òkèèrè àti ní etílé lè máa ríbi gbádùn ẹ̀mí wọn. Àwọn ilé iṣẹ́ míì tí wọn ò tìtorí ìrìn-àjò afẹ́ dá sílẹ̀ náà ń rọ́bẹ̀ lá lára àwọn arìnrìn-àjò afẹ́. Ohun tó sì fà á ni pé àwọn tó ń rìnrìn-àjò máa ń ra oúnjẹ àti ohun mímú tó pọ̀ gan-an, wọ́n sì máa ń náwó yàfùnyàfùn lórí àwọn ọjà míì tàbí iṣẹ́ míì tí wọ́n á ní káwọn èèyàn bá àwọn ṣe.
Lákòókò yìí ìrìn-àjò afẹ́ ṣe pàtàkì débi pé ó wà lára ohun tó ń mówó wọlé jù lọ fún orílẹ̀-èdè márùnlélọ́gọ́fà [125]. Nínú àtẹ̀jáde kan tí àjọ tó ń bójú tó ìrìn-àjò kárí ayé lábẹ́ àsíá Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn lọ́dún 2004, ó ṣàlàyé pé ìrìn-àjò lè dín òṣì kù. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn èèyàn ń tìtorí rẹ̀ dá ilé iṣẹ́ ńláńlá àti kéékèèké sílẹ̀. Báwọn èèyàn ṣe ń tìtorí rẹ̀ dáṣẹ́ sílẹ̀ yìí, ó lè mú káráyé túbọ̀ “mọ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, kí wọ́n mọ̀ nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìbágbépọ̀ ẹ̀dá.”
Àmọ́ o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Báwo ni ìrìn-àjò afẹ́ ṣe lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀? Oore wo ló lè ṣe fáwọn ìṣẹ̀dá bí ẹranko, ewéko, àti igbó tó yí èèyàn ká?’
Àbẹ̀wò Sọ́gbà Ọ̀gbìn àti Ọgbà Ẹranko Ni Ò Jẹ́ Kó Parun
Láàárín ọdún 1981 sí 1983, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn tó ń ṣe fíìmù bẹ̀rẹ̀ sí múra sí ọ̀ràn títọ́jú àwọn igbó kìjikìji, ibi tí ohun tó dà bí òkìtì ìlẹ̀kẹ̀ ti yọrí láàárín omi, àtàwọn ohun alààyè tó ń gbé níbẹ̀. Ìròyìn tí wọ́n ń mú tibẹ̀ bọ̀ àtàwọn ètò tí wọ́n ń gbé jáde lórí afẹ́fẹ́ nípa bí ibẹ̀ ṣe rí ti mú káwọn èèyàn fẹ́ máa ṣèbẹ̀wò sáwọn ibi àwòyanu tí Ẹlẹ́dàá dá yìí. Kíá làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ máa ṣòwò níbẹ̀ láti máa tajà fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì àtàwọn onífíìmù tí wọ́n lọ wo àwọn ohun alààyè tó wà níbẹ̀.
Àwọn tó ń rìnrìn-àjò afẹ́ láti lọ wo àwọn ohun alààyè níbòmíì ti wá ń pọ̀ sí i báyìí, èyí sì mú káwọn èèyàn tún máa fìyẹn ṣòwò, òwò yẹn sì ni iṣẹ́ ajé tó ń yára gbòòrò jù lọ. Ká sòóótọ́, èrè ńlá ló wà nídìí gbígbé àwọn ohun àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá dá sáyé lárugẹ.
Obìnrin oníròyìn kan tó ń jẹ́ Martha S. Honey ṣàlàyé pé: “Ibi ìrìn-àjò afẹ́ táwọn èèyàn ń rìn láti lọ wo àwọn ohun tí Ẹlẹ́dàá dá ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti ń pa owó ilẹ̀ òkèèrè jù. Kódà, iye tó ń mú wọlé ju iye tí orílẹ̀-èdè Costa Rica ń pa lórí ọ̀gẹ̀dẹ̀, ó ju iye tí orílẹ̀-èdè Tanzania àti orílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà ń pa lórí kọfí, ó sì ju iye tí orílẹ̀-èdè Íńdíà ń pa lórí aṣọ àti ohun ọ̀ṣọ́.”Látinú ohun tá a sọ lókè yìí, a lè rí i pé owó tí wọ́n ń rí lórí ìrìn-àjò afẹ́ ti mú káwọn èèyàn fẹ́ máa dáàbò bo àwọn ewéko àti ẹranko. Obìnrin oníròyìn náà tún sọ pé: “Lórílẹ̀-èdè Kẹ́ńyà, wọ́n ní owó táwọn èèyàn fi ń wo kìnnìún kan lọ́dún á tó ẹgbẹ̀rún méje dọ́là, iye tí wọ́n sì fi ń wo agbo erin kan á tó dọ́là ẹgbẹ̀ta àti mẹ́wàá.” Lórílẹ̀-èdè Hawaii sì rèé, iye tí wọ́n ń pa lọ́dún lórí wíwò táwọn èèyàn ń wo ohun tó dà bí òkìtì ìlẹ̀kẹ̀ létí omi á tó ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún [360] mílíọ̀nù dọ́là!
Ìrìn-Àjò Afẹ́ Láti Wo Ìṣẹ̀dá
Àjọ kan tó ń bójú tó àyíká lábẹ́ àsíá àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè gbé ìròyìn kan jáde tí wọ́n fi sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè mú káwọn ohun alààyè máa gbé pọ̀ láìpa ara wọn lára. Ìròyìn náà, tí wọ́n pè ní Ecotourism: Principles, Practices and Policies for Sustainability, sọ pé: “Àwọn èèyàn tó ń dáṣẹ́ sílẹ̀ nítorí ìrìn-àjò afẹ́ sábà máa ń fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rírìnrìn-àjò afẹ́ síbi táwọn nǹkan mèremère tí Ẹlẹ́dàá dá sáyé wà, nínú ìwé wọn. Bákan náà, táwọn ìjọba bá fẹ́ káwọn èèyàn ṣèbẹ̀wò sórílẹ̀-èdè wọn, wọ́n á ní kí wọ́n wá wo àwọn ohun tí Ẹlẹ́dàá dá síbẹ̀. Ṣe ni wọ́n kàn ń polongo lásán, wọn ò ṣetán láti ṣe ohun tó ń mú kí irú ìrìn-àjò bẹ́ẹ̀ ṣeé pè ní [ìrìn-àjò afẹ́].” Báwo lo ṣe lè mọ̀ bó bá jẹ́ pé ìrìn-àjò afẹ́ tó ò ń gbèrò àtirìn jẹ́ láti lọ wo àwọn ohun mèremère tí Ẹlẹ́dàá dá?
Ìyáàfin Megan Epler Wood tó kọ ìròyìn tó wà lókè yìí sọ pé ká tó lè sọ pé ìrìn-àjò afẹ́ kan jẹ́ èyí tá a rìn torí àtirí ohun mèremère tí Ẹlẹ́dàá dá, ó gbọ́dọ̀ láwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí: Kó tó di pé èèyàn kúrò nílùú rẹ̀, ó ní láti mọ̀ nípa àṣà ibi tó fẹ́ lọ àti bí ibẹ̀ ṣe rí, ó gbọ́dọ̀ ti mọ bí wọ́n ṣe ń wọṣọ àti bí wọ́n ṣe ń hùwà níbẹ̀; òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń lọ tún ní láti mọ bí ilẹ̀ ibẹ̀ ṣe rí àti irú àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ tó fi mọ́ bí ipò ìṣèlù ṣe rí níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún yẹ kó mọ̀ pé òun máa rẹ́ni tóun lè lọ kí níbi tóun ń lọ yàtọ̀ sáwọn tóun bá bá pàdé níbi ìtajà; ó tún níláti rí i pé gbogbo owó ìwọlé ti wà ní sẹpẹ́; ibi tóun sì máa dé sí kò ní ṣàkóbá fáwọn ohun alààyè tó wà níbẹ̀.
Oore Tí Ìrìn-Àjò Afẹ́ Ti Ṣe
Ìrìn-àjò téèyàn rìn láti lọ wo àwọn ohun tí ẹlẹ́dàá dá sáyé kì í kàn ṣe ìrìn-àjò afẹ́ lásán. Àwọn kan sọ pé ó jẹ́ “ìrìn-àjò téèyàn dìídí rìn láti lọ mọ̀ nípa àṣà àwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ àti ìtàn àwọn igbó àti ẹranko tó wà níbẹ̀, láìsì ṣàkóbá fún ìbágbépọ̀ àwọn ohun alààyè tó wà níbẹ̀. Irú ìrìn-àjò bẹ́ẹ̀ á ṣàlékún ọrọ̀ ajé ibẹ̀, á sì mú káwọn èèyàn rí èrè lórí bí wọn ò ṣe pa igbó wọn run.”
Ǹjẹ́ ohun tí wọ́n ń pè ní ìrìn-àjò afẹ́ ti ṣe àwọn nǹkan dáadáa tó yẹ kó ṣe yìí? Ọ̀gbẹ́ni Martin Wikelski, láti ilé ìwé gíga Princeton University, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó fà á tí agbáríjọ erékùṣù Galapagos ṣì fi wà láìléwu dòní
ni bí wọ́n ṣe ń rìnrìn-àjò afẹ́ láti lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.” Lórílẹ̀-èdè Rwanda nílẹ̀ Áfíríkà, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣètò ìrìn-àjò afẹ́ láti wo ìṣẹ̀dá ni kò tíì jẹ́ kí wọ́n pa àwọn ìnàkí orí òkè tán nítorí pé wọ́n fọ̀nà míì táwọn ará ibẹ̀ tíì bá máa dẹ̀gbẹ́ á ti máa rówó hàn wọ́n. Láwọn orílẹ̀-èdè míì nílẹ̀ Áfíríkà, ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè máa rówó tọ́jú àwọn igbó tí wọ́n dá sí fáwọn ẹran ìgbẹ́ ni báwọn arìnrìn-àjò ṣe wá ń náwó tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀.Káàkiri àgbáyé, ìrìn-àjò afẹ́ ti mú kí nǹkan gbé pẹ́ẹ́lí sí i láyìíká àti láàárín ọmọnìyàn, ó sì ti ṣe ọrọ̀ ajé ọ̀pọ̀ èèyàn láǹfààní dájúdájú. Àmọ́ ṣá, ṣé oore nìkan ló wà nínú àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìrìn-àjò afẹ́? Báwo lọ̀rọ̀ ìrìn-àjò afẹ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àbá Fáwọn Tó Ń Rìnrìn-Àjò Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Mìíràn a
Kó o tó lọ
1. Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìwé pàtàkì tó o mú dání, irú bí ohun tó wà nínú ìwé ìrìnnà rẹ, nọ́ńbà tó wà lórí káàdì tó o fi ń rajà, tíkẹ́ẹ̀tì tó o fi ń wọkọ̀ àtàwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì nípa ṣẹ́ẹ̀kì àwọn arìnrìn-àjò. Fi ẹ̀dà kan sílé kó o sì mú ẹ̀dà kan dání.
2. Rí i dájú pé ìwé ìrìnnà rẹ pé pérépéré, kó sì jẹ́ ojúlówó, tó bá yẹ kó o gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kan, ṣètò bó o ṣe máa gbà á.
3. Rí i dájú pé o ṣètò báwọn abánigbófò ṣe máa kájú ìtọ́jú rẹ, nítorí pé, tọ́ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀, tàbí tó bá di pé kó o wọkọ̀ lọ tọ́jú ara rẹ lórílẹ̀-èdè míì, ó lè ná ẹ lówó gọbọi. Tó o bá ní ohun kan tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu, á dáa kó o gba lẹ́tà dání látọ̀dọ̀ dókítà rẹ èyí tó máa sọ ohun tó ń ṣe ọ́ àti oògùn tó o máa ń lò sí i. (Fi sọ́kàn pé ó lè lòdì sófin àwọn orílẹ̀-èdè kan láti mú oògùn wọbẹ̀. Torí náà, béèrè kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa èyí lọ́wọ́ iléeṣẹ́ tó ń ṣojú orílẹ̀-èdè tó o fẹ́ rìnrìn-àjò lọ, èyí tó bá sún mọ́ ẹ jù lọ.)
Nígbà tó o bá ń rìnrìn-àjò
1. Má ṣe mú ohunkóhun táá dùn ọ́ bó bá sọnù dání.
2. Jẹ́ kí ìwé ìrìnnà rẹ àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì wà lára rẹ, má fi sínú báàgì tó o gbé dání tàbí sínú àpò tójú ẹlòmíì lè tó. Tó bá jẹ́ pé gbogbo yín nínú ìdílé lẹ̀ ń lọ pa pọ̀, ẹ má ṣe kó gbogbo ìwé tó bá ṣe pàtàkì sọ́wọ́ ẹnì kan ṣoṣo.
3. Bó o bá fi pọ́ọ̀sì rẹ sápò, fi rọ́bà tó máa ń ràn dì í dáadáa, ìyẹn ni kò ní jẹ́ káwọn jáwójáwó lè tètè rí i yọ lápò rẹ.
4. Máa kíyè sí bó o ṣe ń ra nǹkan, má sì ná kọjá iye tó o pinnu láti ná. Tó o bá ná kọjá iye tó wà nínú àkáǹtì ẹ, láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n lè tì ọ́ mọ́lé.
5. Ṣọ́ra tó o bá fẹ́ ya fọ́tò àwọn sójà tàbí ti iléeṣẹ́ wọn tàbí fọ́tò àwọn ilé iṣẹ́ ìjọba bí èbúté, ibùdókọ̀ ojú irin tàbí pápákọ̀ òfuurufú. Àwọn orílẹ̀-èdè kan lè máà fẹ́ kéèyàn ya irú àwọn fọ́tò yìí nítorí ààbò orílẹ̀-èdè wọn.
6. Má ṣe gbé ẹrù fún ẹnikẹ́ni tó ò mọ̀ dáadáa.
Bó o bá ń ra nǹkan tí wàá mú relé
1. Má gbàgbé pé àwọn orílẹ̀-èdè kan fòfin de kíkó àwọn ọjà kan wọlé, kódà bó jẹ́ kékeré irú ẹ̀. Irú àwọn ọjà bẹ́ẹ̀ ni eyín erin, ìkarahun, irúgbìn, awọ ẹranko àtàwọn nǹkan míì.
2. Ṣọ́ra kó o tó ra àwọn nǹkan tí wọ́n fi amọ̀ ṣe tó dà bíi tánganran nítorí pé bí wọn ò bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bó ṣe yẹ, ó lè ní èròjà lẹ́ẹ̀dì tó ń pani nínú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀dọ̀ ilé iṣẹ́ ìjọba Amẹ́ríkà tó ń tẹ ìwé la ti rí ìsọfúnni yìí. Nọ́ńbà ìwé náà ni 10542.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣe ni ìrìn-àjò afẹ́ túbọ̀ ń gbajúmọ̀