Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́

Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́

Nǹkan Márùn-ún Tó O Lè Ṣe Láti Ríṣẹ́

TA LÓ máa ń ríṣẹ́ tó dáa jù? Ṣẹ́ni tó mọ iṣẹ́ yẹn jù ni? Ọ̀gbẹ́ni Brian tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn lórí iṣẹ́ wíwá sọ pé: “Kò rí bẹ́ẹ̀.” Ẹni tó bá mọṣẹ́ wá jù lọ́ ló máa ń ríṣẹ́.” Kí lo wá lè ṣe tí wàá fi túbọ̀ mọ béèyàn ṣe ń wáṣẹ́? Jẹ́ ká yẹ àbá márùn-ún yìí wò ná.

Jẹ́ Kí Gbogbo Nǹkan Ẹ Wà Létòletò

Tí iṣẹ́ dáadáa kan bá bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ tàbí tó ti tó ọjọ́ mélòó kan tó o ti ń jókòó sílé, ó ṣeé ṣe kí inú ẹ má dùn. Katharina tó ń ṣiṣẹ́ aránṣọ nílẹ̀ Jámánì sọ pé: “Nígbà tí iṣẹ́ kọ́kọ́ bọ́ lọ́wọ́ mi, èrò mi ni pé mo màá tó rí òmíràn. Àmọ́ nígbà tí oṣù bíi mélòó kan bẹ̀rẹ̀ sí gùn ún tí mi ò ríṣẹ́, ìdààmú bà mi. Nígbà tó yá, mo kàn ṣá rí i pé kì í wù mí láti máa bá àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ mọ́.”

Báwo lo ṣe lè gba ara ẹ lọ́wọ́ àìnírètí? Ìwé náà, Get a Job in 30 Days or Less dábàá pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kó o ní ètò táá jẹ́ kó dà bíi pé ò ń ṣiṣẹ́, èyí láá jẹ́ kó o lè máa rí nǹkan tí wàá máa ṣe bó o bá ṣe ń jí lójoojúmọ́.” Àwọn tó kọ ìwé yẹn dábàá pé ó yẹ kó o “lóhun tí wàá máa lé lójoojúmọ́, kó o sì máa ṣàkọ́sílẹ̀ ohun tó o gbé ṣe.” Láfikún sí i, wọ́n ní “bó o bá ṣe ń jí lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, máa múra bí ẹni tó ń lọ síbi iṣẹ́.” Kí nìdí? “Bó o bá ń múra dáadáa, ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀, kódà nígbà tó o bá ń bá èèyàn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù.”

Bó ṣe rí nìyẹn o, o gbọ́dọ̀ sọ iṣẹ́ wíwá di iṣẹ́ ni, títí dìgbà tí wàá fi rí, bó bá ṣe wù kó pẹ́ tó. Ohun tí Katharina tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣe nìyẹn. Ó ní: “Mo lọ sí ọ́fíìsì àwọn tó ń báni wáṣẹ́, mo sì gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà tẹlifóònù àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n gbà mí siṣẹ́. Bí mo bá rí ìkéde kan nínú ìwé ìròyìn, n kì í fojú pa á rẹ́. Mo wo inú àwọn ìwé tí wọ́n máa ń kọ nọ́ńbà tẹlifóònù sí, mo sì kọ àdírẹ́sì àwọn iléeṣẹ́ tó ṣeé ṣe kí wọ́n nílò òṣìṣẹ́ àmọ́ tí wọn ò tíì kéde ẹ̀, mo sì kàn sí wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Mo ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́, mo sì fi ránṣẹ́ sáwọn ilé iṣẹ́ náà.” Lẹ́yìn tó ti ń fi oríṣiríṣi ọgbọ́n wáṣẹ́, Katharina rí iṣẹ́ tó tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Máa Wádìí Nípa Iṣẹ́ Tó Lè Wà àmọ́ Tí Wọn Ò Kéde Ẹ̀

Apẹja tí àwọ̀n rẹ̀ bá tóbi jù ló ṣeé ṣe kó rí ẹja kó. Nítorí náà, ó yẹ kó o mọ bí wàá ṣe jẹ́ kí “àwọ̀n” tìẹ náà tóbi kí iṣẹ́ gidi bàa lè bọ́ sí ọ lọ́wọ́. Tó bá jẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n kéde nínú ìwé ìròyìn tàbí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìkan lo gbájú mọ́, àìmọye iṣẹ́ ló lè máa lọ mọ́ ẹ lára tó ò sì ní mọ̀. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni wọn kì í kéde ẹ̀ fáyé gbọ́. Báwo lo ṣe wá lè mọ àwọn ilé iṣẹ́ tó ń wá òṣìṣẹ́ àmọ́ tí wọn ò kéde ẹ̀?

Yàtọ̀ sí pé kó o kọ̀wé ìwáṣẹ́ sáwọn ilé iṣẹ́ tó bá sọ pé àwọn ń wá òṣìṣẹ́ nínú ìwé ìròyìn, ó yẹ kó o ṣe bíi ti Katharina tó wá àyè láti máa kàn sáwọn ilé iṣẹ́ tó rò pé wọ́n ní iṣẹ́ tóun lè ṣe. Má ṣe dúró dìgbà tí wọ́n máa kéde pé àwọn iṣẹ́ kan wà kó o tó kàn sí wọn. Bí ọ̀gá ilé iṣẹ́ kan bá sì sọ fún ọ pé àwọn ò ní iṣẹ́ táwọn lè fún ọ ṣe, bi í léèrè bóyá ó mọ ibòmíì tó o lè wáṣẹ́ sí àtẹni tó o lè kàn sí. Tó bá sọ ilé iṣẹ́ kan tó o lè lọ fún ọ, lọ síbẹ̀ kó o sì dárúkọ ẹni tó darí rẹ síbẹ̀ fún wọn.

Bí Tony, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ṣe ríṣẹ́ nìyẹn. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń lọ bá àwọn ilé iṣẹ́ kó tiẹ̀ tó di pé wọ́n kéde pé àwọn ń wá òṣìṣẹ́. Ilé iṣẹ́ kan sọ pé kò sí iṣẹ́ ńlẹ̀ báyìí ṣùgbọ́n kí n padà wá ní bí oṣù mẹ́ta sígbà yẹn. Mo kúkú padà lọ síbẹ̀, wọ́n sì gbà mí síṣẹ́.”

Primrose, ìyá kan tó ń dá tọ́mọ lórílẹ̀-èdè South Africa, ṣe ohun tó jọ ìyẹn náà. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì ń lọ síbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ìtọ́jú pàjáwìrì, mo rí ilé tuntun kan tí wọ́n ń kọ́ sódìkejì títì, mo sì mọ̀ pé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ni wọ́n fẹ́ fibẹ̀ ṣe. Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ bá olórí ilé ìtọ́jú náà sọ̀rọ̀ wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sọ fún mi pé kò tíì sí iṣẹ́ ńlẹ̀ ná. Àmọ́, ṣe ni mò ń pààrà ibẹ̀ bóyá wọ́n lè ríbi kan fi mí há níbẹ̀, kódà mi ò kọ̀ kí n jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni. Nígbà tó yá, wọ́n gbà mí síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ onígbà kúkúrú. Mo máa ń jára mọ́ iṣẹ́ yòówù tí wọ́n bá fún mi ṣe. Mo tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó tún gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ àti ìwé ẹ̀rí kún ìwé ẹ̀rí, bí wọ́n kúkú ṣe sọ mí di òṣìṣẹ́ ilé ìtọ́jú arúgbó yẹn nìyẹn.”

Ìwọ náà lè sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn ẹbí rẹ, àtàwọn àmọ̀rí rẹ míì pé kí wọ́n jẹ́ kó o gbọ́ tí wọ́n bá rí ibi tó o lè wáṣẹ́ lọ. Bí Jacobus, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ aláàbò ìlú lórílẹ̀-èdè South Africa ṣe ríṣẹ́ nìyẹn. Ó sọ pé: “Nígbà tí ilé iṣẹ́ tí mò ń bá ṣiṣẹ́ kógbá sílé, mo jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí mọ̀ pé mò ń wáṣẹ́. Lọ́jọ́ kan, ọ̀rẹ́ mi kan fetí kọ́ ọ̀rọ̀ kan nígbà tó tò sórí ìlà níbi tó ti fẹ́ sanwó ọjà tó lọ rà ní ṣọ́ọ̀bù ńlá kan. Ó gbọ́ tí obìnrin kan ń béèrè lọ́wọ́ ẹnì kejì bóyá ó mọ ẹnì kan tó ń wáṣẹ́. Ọ̀rẹ́ mi dá sí ọ̀rọ̀ yẹn ó sì sọ̀rọ̀ mi fún obìnrin náà. A yáa ṣètò bá a ṣe máa pàdé, iṣẹ́ yẹn sì bọ́ sí i.”

Má Kọ Iṣẹ́ Èyíkéyìí Tó Bá Yọjú

Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti tètè ríṣẹ́, o ò gbọ́dọ̀ kọ iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú. Jaime, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Bóyá lèèyàn lè rí iṣẹ́ tó lè bá irú èyí téèyàn ń fẹ́ gẹ́lẹ́ mu. Ṣe ni wàá jẹ́ kí iṣẹ́ tó o bá rí tẹ́ ọ lọ́rùn, bí iṣẹ́ ọ̀hún ò bá tiẹ̀ jẹ́ irú èyí tó wù ọ́ jù.”

Èyí lè gba pé kó o mọ bó o ṣe lè mú ìkórìíra tó o ti ní sáwọn iṣẹ́ kan kúrò lọ́kàn. Ìwọ wo ọ̀rọ̀ Ericka tó ń gbé ní Mẹ́síkò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ akọ̀wé àgbà ló kọ́, síbẹ̀ irú iṣẹ́ yẹn kọ́ ló kọ́kọ́ rí. Ó sọ pé: “Mo yáa kọ́ bí mo ṣe máa fara mọ́ iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá ti bójú mu. Mo fìgbà kan bá wọn tajà ní ṣọ́ọ̀bù kan. Mo tún kiri ìpápánu láàárín ìgboro, bákan náà, mo gbaṣẹ́ ìtọ́jú ilé àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tó yá, mo pàpà rí iṣẹ́ tí mo dìídì kọ́.”

Nígbà tíṣẹ́ akọ̀wé bọ́ lọ́wọ́ Mary tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, ó rí i pé ó yẹ kóun mọ bóun á ṣe máa fara mọ́ ibi tóun bá ti bára òun. Ó ṣàlàyé pé: “Mi ò fi dandan lé e pé irú iṣẹ́ tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ ni mò ń wá. Mi ò sì fojú pa iṣẹ èyíkéyìí tó bá yọjú rẹ́, kódà kó jẹ́ èyí táwọn kan lè kà sí iṣẹ́ yẹpẹrẹ . Ohun tó jẹ́ kí n ríṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà lórí àwọn ọmọ mi méjèèjì nìyẹn.”

Ṣe Ìwé Àkójọ Ẹ̀rí Ìtóótun fún Iṣẹ́

Ó pọn dandan fáwọn tó ń wá iṣẹ́ ọ́fíìsì láti ní ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́, kí wọ́n sì máa pín in fáwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n irú iṣẹ́ yòówù kó o máa wá, á ṣàǹfààní fún ọ tó o bá ní àkójọ ẹ̀rí ìtóótún fún iṣẹ́. Nigel tó jẹ́ agbaninímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ wíwá lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ohun tí ìwé àkójọ ẹ̀rí fún ìtóótun rẹ yóò sọ fún ẹni tó lè gbà ọ́ síṣẹ́ kò mọ sórí irú ẹni tó o jẹ́ nìkan, á tún sọ ohun tó o ti gbé ṣe, yóò sì jẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí wọ́n fi nílò rẹ.”

Báwo lo ṣe lè ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́? Kọ orúkọ rẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, àdírẹ̀sí rẹ, nọ́ńbà tẹlifóònù àti àdírẹ́sì tó o fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Sọ irú iṣẹ́ tó ò ń wá. Kọ àwọn ilé ìwé tó o lọ síbẹ̀ kó o sì kọ àwọn ohun tó o mọ̀-ọ́n ṣe àtohun tó o kọ́ tó bá iṣẹ́ tó ò ń wá mu. Sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa iṣẹ́ tó o ti ṣe rí. Má fi mọ sórí ohun tó o ti ṣe rí nìkan, fi àpẹẹrẹ àwọn ibi tó o ti pegedé kún un kó o sì kọ àwọn àǹfààní táwọn tó gbà ọ́ ṣíṣẹ́ rí jẹ lára rẹ. Bákan náà, sọ àwọn apá ibi tí iṣẹ́ tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ ti jẹ́ kó o lè yẹ lẹ́ni tó lè ṣe iṣẹ́ tó o fẹ́ gbà yìí. Fi àlàyé nípa ara rẹ kún un, èyí tó máa sọ irú èèyàn tó o jẹ́, àwọn nǹkan tó máa ń wù ọ́ ṣe, àtàwọn iṣẹ́ ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀ tó o máa ń ṣe. Ṣó o mọ̀ pé ilé iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ní ohun tó fi yàtọ̀ sí òmíràn, torí náà, ó lè pọn dandan pé kó o ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ rẹ lọ́nà táá fi máa bá iṣẹ́ tó o bá ti ń kọ̀wé fún mu.

Ṣé ó yẹ kó o ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ tó bá jẹ́ pé ìgbà akọ́kọ́ tó ò ń wáṣẹ́ nìyẹn? Ó yẹ bẹ́ẹ̀! Àwọn nǹkan kan lè wà tó o ti ṣe rí tó lè ṣeé kà mọ́ ìrírí tó o ti ní lẹ́nu iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ṣó o mọ àwọn nǹkan kan ṣe, irú bíi fífi igi ṣe ọ̀ṣọ́, tàbí bóyá o mọ̀ nípa títún mọ́tò tó ti gbó ṣe? O lè fi àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un. Ṣé o ti ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kankan rí? Kọ àwọn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni èyí tó o ti ṣe rí kó o sì kọ àwọn nǹkan tó o gbé ṣe lẹ́nu rẹ̀.—Wo àpótí náà “Àpẹẹrẹ Ìwé Àkójọ Ẹ̀rí Ìtóótun fún Iṣẹ́ Fáwọn Tí Kò Tíì Nírìírí Lẹ́nu Iṣẹ́.”

Bí kò bá wá ṣeé ṣe fún ọ láti rí agbaniṣíṣẹ́ tó máa pè ọ́ láti fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò, o lè ṣe káàdì pélébé kan tó ní orúkọ rẹ, àdírẹ́sì rẹ, nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ àti àdírẹ́sì tó o fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nínú. Jẹ́ kí irú káàdì bẹ́ẹ̀ tún ní àláyé ṣókí nípa àwọn nǹkan tó o ti gbé ṣe rí nínú. (Á dáa tó bá fi díẹ̀ fẹ̀ ju fọ́tò kékeré lọ.) O tún lè fi fọ́tò rẹ tàbí èyí tó o yà pẹ̀lú ìdílé rẹ sẹ́yìn irú káàdì bẹ́ẹ̀, tó bá bójú mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Pín káàdì yìí fún gbogbo àwọn tó bá lè bá ọ wáṣẹ́ kó o sì sọ fún wọn pé kí wọ́n fún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá rí pé ó ní irú iṣẹ́ tó ò ń wá. Nígbà tẹ́ni tó ń wá òṣìṣẹ́ bá rí irú káàdì bẹ́ẹ̀, ó lè pè ọ́ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, o sì lè gbabẹ̀ ríṣẹ́!

Tó o bá ní ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́, wàá lè fọkàn balẹ̀ pé lọ́jọ́ kan wàá ríṣẹ́. Nigel tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tó o bá ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́, á jẹ́ kó o lè pa ìrònú rẹ pọ̀ sọ́nà kan. Á tún fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ nítorí pé á jẹ́ kó o lè múra sílẹ̀ fún bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí wọ́n bi ọ́ nígbà tó o bá lọ síbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.”—Wo àpótí tó wà lójú ìwé 7.

Múra Sílẹ̀ Dáadáa Tó O Bá Ń Lọ Síbi Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Báwo lèèyàn ṣe ń múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ná? O lè lọ ṣèwádìí nípa iléeṣẹ́ tó o fẹ́ máa bá ṣiṣẹ́ náà. Bó o bá ṣe mọ̀ nípa ilé iṣẹ́ náà tó ló ṣe máa rọrún fún ọ tó láti sọ ohun tó máa wu olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà lórí. Ìwádìí tó o bá ṣe á tún jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni iléeṣẹ́ náà ní irú iṣẹ́ tó ò ń wá yẹn tàbí bóyá irú iléeṣẹ́ yẹn tiẹ̀ máa wù ọ láti bá ṣiṣẹ́.

Lẹ́yìn èyí, ronú lórí irú aṣọ tó o máa wọ̀ lọ síbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ tó gba agbára ni iṣẹ́ ọ̀hún, wọ aṣọ tó mọ́ tó sì bojú mu fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Aṣọ àti ìmúra tó mọ́ tónítóní tó sì wà létòletò ń sọ fún ẹni tó fẹ́ gbà ọ́ síṣẹ́ pé o dá ara rẹ lójú ó sì tún ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ dá ọ lójú. Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ọ́fíìsì ni iṣẹ́ náà, wọ aṣọ tó mọ níwọ̀n táwọn èèyàn máa ń wọ lọ sí ọ́fíìsì níbi tó ò ń gbé. Nigel sọ pé: “Tètè yan aṣọ tó o máa wọ̀ nígbà tí ọjọ́ tó o máa lọ síbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò bá ṣì jìnnà kó máa bàa di pé ò ń kánjú tọ́jọ́ bá sún mọ́ débi tí wàá fi gbé àníyàn sọ́kàn lọ síbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà.”

Nigel tún dá a lábàá pé kó o fi bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yára dé ibi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà. Lóòótọ́ o, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn tètè dé síbi tí wọ́n ti máa fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Ṣùgbọ́n téèyàn bá pẹ́ débẹ̀, ọ̀rọ̀ lè bẹ́yìn yọ. Àwọn ọ̀mọ̀ràn tiẹ̀ sọ pé ìṣẹ́jú àáyá mẹ́ta àkọ́kọ́ níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ṣe pàtàkì gan-an ni. Ìdí ni pé láàárin àkókò kúkúrú yẹn, olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò á máa wo ìdúró rẹ àti ìṣesí rẹ, èyí sì máa ń nípa lórí èrò tó máa ní nípa rẹ gan-an ni. Tó o bá fi lè pẹ́ dé, èrò tó máa ní nípa rẹ ò ní dáa rárá àti rárá. Rántí pé kì í sáàyè tí wàá fi tún èrò tó bá kọ́kọ́ ní nípa rẹ ṣe.

Tún fi sọ́kàn pé olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yẹn kì í ṣe ọ̀tá rẹ o. Ó ṣe tán, ó lè jẹ́ pé ṣe lòun náà kọ̀wé wáṣẹ́ tiẹ̀ náà síbẹ̀ yẹn, nítorí náà ó mọ bó ṣe ń ṣe ọ́. Kódà, ọkàn tiẹ̀ gan-an lè má balẹ̀, tó bá lọ jẹ́ pé kò tíì gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rí lórí bí wọ́n ṣe ń fọ̀rọ̀ wá èèyàn lẹ́nu wò. Bákan náà, tó bá jẹ́ pé fúnra ẹni tó fẹ́ gbà ọ́ síṣẹ́ ló ń fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò, fi sọ́kàn pé ó mọ̀ pé tóun bá lọ gba ẹni tí kò yẹ kóun gbà, ńṣe lòun á máa fowó jóná.

Kí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yẹn lè lọ bó ṣe yẹ, rẹ́rìn-ín músẹ́, bó bá sì bójú mu níbi tó ò ń gbé láti bọ ẹni tó fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò lọ́wọ́, bọ̀ ọ́ lọ́wọ́ kó o gbá ọwọ́ rẹ̀ mú gírígírí. Nígbà tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nwò yẹn bá ń lọ lọ́wọ́, ohun tí olùfọ̀rọ̀wánilẹnuwò yẹn bá bi ọ́ ni kó o máa dáhùn kó o sì máa sọ àwọn ohun tó o lè ṣe fún un. Nigel sọ àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣọ́ra fún, ó ní: “Fara balẹ̀, kó o sì jókòó dáadáa, ìyẹn á fi hàn pé ọkàn rẹ balẹ̀. Má sọ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò di ọ̀rọ̀ gbẹ̀fẹ́, má sì máa rojọ́ woroworo, má tiẹ̀ jẹ́ kọ́rọ̀ àlùfàáṣá jáde lẹ́nu ẹ rárá. Má sì sọ̀rọ̀ tí ò dáa nípa àwọn tó gbà ọ́ síṣẹ́ tẹ́lẹ̀ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ nígbà yẹn, nítorí pé tó o bá sọ̀rọ̀ wọn láìdáa, olùfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lè rò pé ojú tí ò dáa ni wàá fi máa wo iṣẹ́ tó o fẹ́ gbà yìí náà.”

Àwọn ọ̀mọ̀ràn sọ pé téèyàn bá débi tí wọ́n ti fẹ́ fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, bó ṣe yẹ kó ṣe rèé: Máa wo ojú ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò, máa fára ṣàpèjúwe bó ṣe mọ́ ẹ lára tó o bá ń sọ̀rọ̀, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ já gaara. Sọ̀rọ̀ ṣókí kó o sì jẹ́ kí gbogbo ìdáhùn rẹ jẹ́ òótọ́, béèrè àwọn ìbéèrè tó bá yẹ nípa iléeṣẹ́ náà àti iṣẹ́ tó o fẹ́ gbà yẹn. Lẹ́yìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà, tí iṣẹ́ yẹn bá ṣì wù ọ́, sọ pé wàá ṣe é. Bíbéèrè tó o bá béèrè lọ́wọ́ wọn nípa iṣẹ́ náà, á fi hàn pé iṣẹ́ náà wù ọ́ ṣe lóòótọ́.

Tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tá a sọ sókè yìí, ó lè máà pẹ́ tí wàá fi ríṣẹ́. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe láti má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ tó o rí náà bọ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àpẹẹrẹ Ìwé Àkójọ Ẹ̀rí Ìtóótun fún Iṣẹ́ Fáwọn Tí Kò Tíì Nírìírí Lẹ́nu Iṣẹ́

Orúkọ:

Àdírẹ́sì:

Nọ́ńbà Tẹlifóònù àti Àdírẹ́sì Ìgbalẹ́tà Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì:

Irú Iṣẹ́ Tí Mò Ń Wá: Mò ń fẹ́ iṣẹ́ tí wọ́n lè fún ẹni tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe nǹkan.

Ìwé Tí Mo Kà: Mo jáde ní Ilé Ìwé Hometown High School lọ́dún 2004.

Ẹ̀kọ́ Tí Mo Kọ́ Nílé Ìwé: Ẹ̀kọ́ nípa èdè, ìṣirò, ìmọ̀ kọ̀ǹpútà, iṣẹ́ fífi igi ṣe ọ̀ṣọ́.

Àwọn Nǹkan Tí Mo Lè Ṣe: Mo mọ iṣẹ́ ọwọ́ ṣe. Èmi ni mo máa ń ṣiṣẹ́ lára mọ́tò wa. Nílé wa, mo ti ṣe àga àti tábìlì onígi rí. Tí mo bá ń fi igi ṣiṣẹ́, mo máa ń lo òye tí mo ní nínú ìmọ̀ ìṣirò. Níbi iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni kan, mo bá wọn kan ilé. Mo lè lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú oríṣi kọ̀ǹpútà tó wà lóde, mo sì fẹ́ràn kí n máa kọ́ àwọn nǹkan tuntun nínú rẹ̀.

Irú Èèyàn Tí Mo Jẹ́: Ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni mí—ọjọ́ méjì péré ni mo pa jẹ láàárín ọdún tí mo lò kẹ́yìn nílé ìwé. Olóòótọ́ ni mí—mo ti dá pọ́ọ̀sì kan tó sọnù tówó sì wà nínú ẹ̀ padà rí. Mo máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́—mo máa ń kópa nínú iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni déédéé, mo sì nífẹ̀ẹ́ sí kí n máa ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Mo máa ń ṣe eré ìdárayá—mo fẹ́ràn bọ́ọ̀lù inú àwọ̀n. Ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí láti máa ṣe—mo gbádùn kí n máa tún mọ́tò ṣe, mo sì máa ń fi igi ṣe oríṣiríṣi nǹkan.

Àwọn Tó Lè Gbẹ̀rí Mi Jẹ́: Tẹ́ ẹ bá fẹ́ mọ̀ wọ́n, wọ́n wà. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn tí wàá fi ṣe ẹlẹ́rìí rẹ lè jẹ́ olùkọ́ rẹ tó mọ̀ ẹ́ dáadáa tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó mọ gbogbo ìdílé yín tó sì ní ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó. Tí ẹni tó fẹ́ gbà ọ́ síṣẹ́ náà bá béèrè fún un tó o sì sọ ọ́ fún un, ìyẹn lè jẹ́ ẹ̀rí tí wàá kọ́kọ́ fi mọ̀ pé ẹni náà lè fẹ́ gbà ọ́ síṣẹ́. Rí i dájú pé àwọn tó o fi ṣẹlẹ́rìí ti gbà pé kó o fi àwọn ṣe é kó o tó kọ́ orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí o.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ìbéèrè Tí Wọ́n Lè Bi Ọ́ Nígbà Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

❑ Kí nìdí tó o fi kọ̀wé fún iṣẹ́ yìí?

❑ Kí nìdí tó o fi fẹ́ bá ilé iṣẹ́ yìí gan-an ṣiṣẹ́?

❑ Kí lo mọ̀ nípa iṣẹ́ yìí, tàbí nípa ilé iṣẹ́ yìí tàbí ohun tí wọ́n ń ṣe nínú irú ilé iṣẹ́ báyìí?

❑ Ǹjẹ́ o ti ṣe irú iṣẹ́ yìí rí?

❑ Irú ẹ̀rọ wo lo mọ̀ ọ́n lò?

❑ Ọdún mélòó lo ti fi ṣe irú iṣẹ́ yìí rí?

❑ Kí làwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe tó lè mú kíṣẹ́ yìí tẹ̀ síwájú?

❑ Jẹ́ kí n mọ̀ ẹ́ díẹ̀ sí i.

❑ Ọ̀rọ̀ márùn-ún wo lo lè fi ṣàpèjúwe ara rẹ lọ́nà tó dáa jù lọ?

❑ Ǹjẹ́ o lè ṣiṣẹ́ lákòókò tíṣẹ́ bá gbomi mu?

❑ Kí ló mú kó o fiṣẹ́ tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀?

❑ Kí nìdí tó o fi wà láìníṣẹ́ lọ́wọ́ látiye ọjọ́ yìí?

❑ Kí lèrò ẹni tó gbà ọ́ síṣẹ́ gbẹ́yìn nípa rẹ?

❑ Báwo lo ṣe máa ń pabi iṣẹ́ jẹ tó níbi tó o ti ṣiṣẹ́ gbẹ̀yìn?

❑ Kí ni èròǹgbà rẹ fún ọjọ́ iwájú?

❑ Nígbà wo lo máa fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́?

❑ Ẹ̀bùn wo lo ní tó ṣe pàtàkì jù?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé Àwọn Abániwáṣẹ́ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì Lè Bá Èèyàn Wáṣẹ́?

Ọ̀kan lára àwọn ilé iṣẹ́ abániwáṣẹ́ tó tóbi jù lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ní ìkànnì sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì gbé ìwé ẹ̀rí ìtóótun mílíọ̀nù mẹ́tàdínlógún èèyàn sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fáwọn tó ń wá òṣìṣẹ́. Wọ́n sì gbé iṣẹ́ ogójì ọ̀kẹ́ [800,000] síbẹ̀ fẹ́ni tó bá ń wáṣẹ́. Ìwádìí fi hàn pé ìdá mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọ̀gọ́rùn-ún àwọn tó ń wáṣẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè kan ló ń wá a lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àmọ́ ṣá, ìwádìí tá a kó jọ látọ̀dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti ogójì orílẹ̀-èdè fi hàn pé ẹnì kan péré nínú ogún èèyàn tó bá wáṣẹ́ lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ń ríṣẹ́.

Tó o bá fi ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, á mú káwọn táá mọ̀ pé ò ń wáṣẹ́ lára àwọn tó lè gbà ọ́ síṣẹ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, àmọ́ ó gbẹ̀sọ̀ o. Ìdí ni pé ó tún lè mú kó o tètè kó sọ́wọ́ àwọn alágbèédá. Tórí náà, kó o má bàa tipa wíwáṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó sọ́wọ́ àwọn oníjìbìtì, àbá táwọn ògbógi abániwáṣẹ́ dá nìwọ̀nyí:

1. Kó o tó fi ìwé ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ sórí ìkànnì èyíkéyìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ka ohun tí wọ́n sọ lórí bí àsírí rẹ ṣe bò tó. Àwọn ilé iṣẹ́ abaníwáṣẹ́ kan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń ta ìsọfúnni táwọn èèyàn ní kí wọ́n fi báwọn wáṣẹ́ fáwọn iléeṣẹ́ ìtàjà aládàá-ńlá tàbí àwọn ẹlòmíì tó lè nífẹ̀ẹ́ sí i.

2. Ìwọ̀nba àwọn ilé iṣẹ́ abániwáṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọ́n lórúkọ rere láwùjọ ni kó o fi ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ ṣọwọ́ sí. Ó ṣe pàtàkì pé kó o pa àṣírí rẹ mọ́ káwọn èèyàn kan má bàa gbé ọ láyé lọ́wọ́. O ò gbọdọ̀ fi ìsọfúnni tẹ́nì kan nílò láti lè jà ọ́ lólè sínú ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́, kí wọ́n má bàa rán ẹ lóko gbèsè. Kò sí nǹkan táwọn ojúlówó agbanisíṣẹ́ fẹ́ fi nọ́ńbà àkáǹtì rẹ ní báńkì ṣe.

3. Ṣọ́ra fáwọn ìkéde iṣẹ́ tí ò ṣe pàtó. Pam Dixon tó jẹ́ olùṣèwádìí nílé iṣẹ́ àjọ World Privacy Forum sọ pé bí ìkéde iṣẹ́ kò bá ti sọ pàtó nípa iṣẹ́ náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò sí iṣẹ́ kankan níbẹ̀. Ó fi kún un pé: “Tó o bá rí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe pàtó bí ‘A ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún iṣẹ́ níbí’ tàbí ‘Àwa làwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá máa ń gbé iṣẹ́ wọn fún,’ ṣe ni kó o bá ẹsẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá ní kó o fi ìwé ẹ̀rí ìtóótun tuntun ránṣẹ́, ìyẹn pẹ̀lú léwu.”

Rántí pé ilé iṣẹ́ abániwáṣẹ́ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ṣeé gbìyè lé jù lọ gan-an ò lè darí ohun tí wọ́n lè fi ìwé ẹ̀rí ìtóótun rẹ ṣe báwọn tó ń wá òṣìṣẹ́ tàbí àwọn míì bá ti rí i lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

IṢẸ́ Á TẸ̀ Ọ́ LỌ́WỌ́

Múra sílẹ̀ dáadáa fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò

Ṣe ìwé àkójọ ẹ̀rí ìtóótun fún iṣẹ́ tó pé

Má kọ iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú

Wá bó o ṣe máa mọ̀ nípa àwọn ilé iṣẹ́ tó ń wá òṣìṣẹ́ àmọ́ tí wọn ò kéde ẹ̀

Jẹ́ kí gbogbo nǹkan ẹ wà létòletò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Èèyàn ní láti tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ wíwá kó sì máa ṣèwádìí dáadáa kó tó lè ríṣẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Tó o bá ní iṣẹ́ ṣe lóòótọ́, á hàn nígbà tí wọ́n bá ń fọ̀rọ̀ wá ọ lẹ́nu wò