Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀dọ́bìnrin Kan Bá Dẹnu Ìfẹ́ Kọ Mí?
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Yẹ Kí N Ṣe Bí Ọ̀dọ́bìnrin Kan Bá Dẹnu Ìfẹ́ Kọ Mí?
“Susan ló kọ́kọ́ la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀, èmi ò kàyẹn sóhun tójú ò rí rí. Ó sì bá mi lára mu.”—James. a
“Bó bá jẹ́ pé ṣe lọkùnrin kan ń gbé àwọn obìnrin lọ́kàn sókè, ewu wà ńbẹ̀ o.”—Roberto.
KÁ NÍ ọ̀dọ́bìnrin kan sọ fún ẹ pé òun ní nǹkan kan tóun fẹ́ bi ẹ́. Ó sì jẹ́ ẹni tó o ti máa ń rí òun àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀, o sì mọ̀ ọ́n bí ẹni tó ṣeé bá sọ̀rọ̀ tó sì ṣeé bá da nǹkan pọ̀. Ṣùgbọ́n, èyí tó wá sọ yìí kà ẹ́ láyà. Ó ní ó wu òun kẹ́ ẹ máa fẹ́ra àti pé òun fẹ́ mọ̀ bóyá bó ṣe ń ṣe ìwọ náà nìyẹn.
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu lóòótọ́, àgàgà tó o bá wà lára àwọn tó gbà pé ọkùnrin ló yẹ kó dẹnu kọ obìnrin. Bó bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, fi sọ́kàn pé lílà tí ọ̀dọ́bìnrin náà la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ ò sọ pé ó ti tẹ ìlànà Bíbélì èyíkéyìí lójú. b Mímọ̀ tó o mọ̀ bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o mọ bó ṣe yẹ kó o ṣe.
Lẹ́yìn tó o ti ronú lórí ọ̀rọ̀ náà dáadáa, o lè kíyè si pé ọjọ́ orí tìẹ fúnra ẹ ṣì kéré láti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà tàbí pé ọ̀dọ́bìnrin ọ̀hún ò wù ẹ́ láti fẹ́. O tiẹ̀ tún lè bẹ̀rẹ̀ sí dá ara ẹ lẹ́bi lórí àwọn nǹkan kan tó o ṣe tó lè mú kí obìnrin náà máa ronú pé o máa fẹ́ òun. Kí ló yẹ kó o ṣe lórí ọ̀ràn yìí? Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o fira ẹ sípò tí obìnrin náà wà.
Fi Ọ̀ràn Rẹ̀ Ro Ara Rẹ Wò
Ronú nípa ohun tí ọmọbìnrin tó bá wà nírú ipò yìí ní láti là kọjá ná. Nítorí pé á fẹ́ sọ̀rọ̀ tó máa dùn létí ẹ, ó lè ti lo ọ̀pọ̀ ọjọ́ láti múra bó ṣe máa gbọ́rọ̀ ọ̀hún kalẹ̀ níwájú ẹ. Lẹ́yìn tó ti wá mọ bó ṣe máa sọ ọ́ táá fi dùn mọ́ ẹ, á tún bẹ̀rù kó o má lọ sọ pé o ò gbà. Ẹ̀yìn ìgbà tó ti rò ó sọ́tùn-ún sósì, síwá sẹ́yìn, tó sì ti borí ìbẹ̀rù ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ fún ẹ yẹn.
Kí ló fà á tó fi ṣe nǹkan tó le tó yẹn? Ó lè jẹ́ pé àìronújinlẹ̀ ló jẹ́ kí ìfẹ́ ẹ kó sí i lórí. Àbí, kó jẹ́ pé àwọn ànímọ́ rere tó o ní ló ń dá a lọ́rùn lọ́nà kan tó yàtọ̀ sí bó ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn tó mọ̀ ẹ́. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tó ń sọ yẹn fi hàn pé ó gba tìẹ ju báwọn èèyàn míì ṣe gba tìẹ lọ.
Kó o lè rántí pé kì í ṣẹni tó o gbọ́dọ̀ kanra mọ ni, la ṣe mẹ́nu ba àwọn kókó tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, a ò fi dandan lé e pé kó o yí ìpinnu ẹ
padà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Julie sọ pé: “Ká tiẹ̀ ní kò ní fẹ́ obìnrin náà, ó ṣì yẹ kí inú ọkùnrin náà dùn pé ẹnì kan tiẹ̀ mọyì òun. Nítorí náà, dípò tó kàn fi máa sọ ṣàkó pé òun ò lè fi ṣaya, ṣe ló yẹ kó sọ ọ́ lóhùn pẹ̀lẹ́, kó má dà bíi pé ò ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́.” Ní báyìí, jẹ́ ká gbà pé ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an nìyẹn, ìyẹn ni pé ó fẹ́ sọ fún un “lóhùn pẹ̀lẹ́ pé o ò ní lè fẹ́ ẹ,” tàbí pé o fẹ́ fi sùúrù sọ fún un pé kò ní lè ṣeé ṣe.Ká wá sọ pé o ti fìgbà kan rí sọ fún un pé kò ní ṣeé ṣe ńkọ́? Bóyá o tiẹ̀ ti ń ronú láti fi ìkanra sọ fún un pé kó fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀. Máà dán irú ẹ̀ wò. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Báwo lo ṣe wá lè sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ní “ahọ́n ọlọ́gbọ́n”?
O lè kọ́kọ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀ pé ó tiẹ̀ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ẹ àti bó ṣe fojú èèyàn pàtàkì wò ẹ́. Bẹ̀ ẹ́, torí pé o tiẹ̀ ti lè ṣe àwọn nǹkan kan tó mú kó ṣì ẹ́ lóye. Kó o wá fi ohùn pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé fún un yékéyéké pé kò wù ẹ́ pé kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín. Bí ohun tó ò ń sọ ò bá tíì yé e, tó o sì fẹ́ ṣàlàyé fún un débi tó fi máa gbà pé ìpinnu ẹ ò tíì yí padà, rí i pé o ò kanra mọ́ ọn, bẹ́ẹ̀ lo ò sì gbọ́dọ̀ nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀. Má gbàgbé pé ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ ló wà ní ìkáwọ́ tìẹ báyìí, nítorí náà, pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ o. Ká ní pé ìwọ lo kọ́kọ́ sọ fún un pé kẹ́ ẹ máa fẹ́ra yín, ṣé inú ẹ ò ní dùn tó bá fẹ̀sọ̀ ṣàlàyé fún ẹ pé kò ní lè ṣeé ṣe?
Síbẹ̀, obìnrin náà ṣì lè takú pé ṣe lo dìídì tan òun. Ó lè mẹ́nu ba nǹkan kan tó o ṣe tó mú kóun bẹ̀rẹ̀ sí ronú bẹ́ẹ̀. Ó lè sọ pé: ‘Ṣó o rántí ọjọ́ tó o já òdòdó ìfẹ́ fún mi?’ tàbí kó sọ pé, ‘O ò ṣá ní sọ pé o ti gbàgbé ọ̀rọ̀ tó o bá mi sọ lọ́jọ́sí nígbà tí ìrìn pa wá pọ̀?’ Tóò, ó yẹ kó o ronú lé ọ̀rọ̀ náà lórí dáadáa.
Mọ Ẹ̀bi Ẹ Lẹ́bi
Láyé àtijọ́, báwọn olùṣàwárí ṣe máa ń fi ìlú tí wọ́n bá ṣàwárí ṣèfà jẹ làwọn ọkùnrin kan ṣe máa ń ṣe sáwọn obìnrin lóde òní. Ìyẹn ni pé wọ́n gbádùn kí wọ́n máa gbé oríṣiríṣi obìnrin ṣùgbọ́n wọ́n ò ṣe tán àtifi wọ́n ṣaya. Wọn ò ní sọ bóyá àwọn máa fẹ́ wọn tàbí àwọn ò ní fẹ́ wọn, títí tí wọ́n á fi kó sí obìnrin náà lórí. Ṣe ni ọkùnrin tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń fẹ̀tàn kó obìnrin náà nífà. Kristẹni alàgbà kan sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan gbádùn àtimáa ti ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin kan dé ọ̀dọ̀ ọmọbìnrin mìíràn. Kò dáa kéèyàn máa fi ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn obìnrin kan ṣeré nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀.” Ǹjẹ́ irú ìwà ìmọtara ẹni nìkan bẹ́ẹ̀ máa ń sin èèyàn dé ibi tó dáa?
“Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ya wèrè tí ń fi ohun ọṣẹ́ oníná tafà, àwọn ọfà àti ikú, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí ó ṣe àgálámàṣà sí ọmọnìkejì rẹ̀, tí ó sì wí pé: ‘Eré ha kọ́ ni èmi ń ṣe?’ ” (Òwe 26:18, 19) Bí ọkùnrin kan bá ń tìtorí ìfẹ́ tara tiẹ̀ nìkan tan obìnrin kan bíi pé ó máa fẹ́ ẹ, kò sígbà tí obìnrin náà ò ní mọ̀ pé ṣe lọkùnrin náà ń tan òun. Tó bá sì mọ̀, ó ṣeé ṣe kí ìjákulẹ̀ yẹn da ọkàn rẹ̀ rú bí ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí ṣe fi hàn.
Ọ̀dọ́kùnrin kan wà tó máa ń ṣe bí ẹni tó máa fẹ́ ọ̀dọ́bìnrin kan báyìí, bẹ́ẹ̀ ó sì mọ̀ pé òun ò lè fẹ́ ẹ o. Ó máa ń gbé e lọ sílé àrójẹ tó gbáfẹ́, wọ́n sì tún jọ máa ń lọ sóde àríyá. Bí ọ̀dọ́bìnrin yẹn ṣe máa ń wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà máa ń dùn mọ́ ọ̀dọ́kùnrin yìí, inú ọ̀dọ́bìnrin yẹn náà sì máa ń dùn pé ọ̀dọ́kùnrin yẹn nífẹ̀ẹ́ òun tó sì ń lérò pé ó ń fẹ́ òun sọ́nà ni. Nígbà tí obìnrin yìí fi máa mọ̀ pé ó kàn mú òun bí ọ̀rẹ́ lásán ni, ó dùn ún wọra.
Kódà ká tiẹ̀ sọ pé o ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan tó mú kí ọ̀dọ́bìnrin kan máa ronú pé ó fẹ́ fẹ́ òun, tó sì wá bá ẹ pé kẹ́ ẹ máa fẹ́ra, kí ló yẹ kó o ṣe? Bó bá jẹ́ pé ṣe lò ń wí àwíjare torí kó o lè yọ ara rẹ, ṣe lò ń dá kún ẹ̀dùn ọkàn obìnrin náà o. Kíyè sí ìlànà Bíbélì yìí: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Nítorí náà, òótọ́ ni kó o sọ. Ọ̀nà yóòwù kí àìgbọ́ra-ẹni-yé gbà wáyé, gba ẹ̀bi ẹ lẹ́bi. Bó bá sì jẹ́ pé ṣe lo mọ̀ọ́mọ̀ ń gbé obìnrin náà lọ́kàn sókè torí bó ṣe ń ṣe sí ọ, tètè gbà pé o ti ṣe àṣìṣe tó burú jáì. Àfi kó o bẹ̀ ẹ́ dáadáa.
Àmọ́, má retí pé ibi tó o ti bẹ̀ ẹ́ yẹn ló máa parí sí o. Ó ṣeé ṣe kí inú ẹ ṣì máa bí i fún àkókò kan. Ó lè gba pé kó o ṣàlàyé ìwà tó o hù yẹn fáwọn òbí ẹ̀. Ó tiẹ̀ tún lè jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gálátíà 6:7 ṣàlàyé pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” Ṣùgbọ́n bó o bá ti bẹ̀ ẹ́, tó o sì ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn á jẹ́ kó lè gbọ́kàn fò ó. Èyí á sì lè kọ́ ẹ pé lọ́jọ́ míì nínú ohun yòówù tó bá ń ṣe láyé ẹ títí kan ọ̀ràn tó lè da ìwọ àwọn obìnrin pọ̀, ó yẹ kó máa ‘ṣọ́ ètè rẹ kúrò nínú ṣíṣe ẹ̀tàn.’—Sáàmù 34:13.
Rò Ó Re Kó O Tó Fèsì
Ká wá sọ pé o túbọ̀ fẹ́ mọ ọ̀dọ́bìnrin náà dáadáa ńkọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìfẹ́sọ́nà kọjá kẹ́ ẹ kàn jọ máa sọ̀rọ̀ tàbí kẹ́ ẹ jọ máa gbáfẹ́ kiri. Bí ọkùnrin àtobìnrin tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ṣe túbọ̀ ń kẹ́ ara wọn wà lára ohun tó ń fi bí wọ́n ṣe ń múra sílẹ̀ fún ìgbéyàwó tó hàn. Bí wọ́n ṣe ń kẹ́ ara wọn máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè fira wọn ṣọ̀kan bíi tọkọtaya. Ibo lèyí tá à ń sọ yìí ti kàn ẹ́ báyìí?
Ṣó o rí i, tó o bá ti wo ọ̀dọ́bìnrin yìí dáadáa, o lè wá ráwọn ibì kan tó dáa sí. Òun ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ báyìí, ọwọ́ tìẹ ló kù sí kọ́nà yẹn máa bàa dí pa. Ṣùgbọ́n, dípò tí wàá fi kù gìrì kó sínú ìfẹ́sọ́nà yìí, kọ́kọ́ ṣe àwọn nǹkan kan tí ò ní jẹ́ kẹ́yin méjèèjì kábàámọ̀ tó bá yá.
Bó bá ṣe, o lè fẹ́ fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbàlagbà mélòó kan tó mọ obìnrin náà dáadáa. Sọ fóun náà pé kó lọ wádìí lọ́dọ̀ àwọn àgbàlagbà tó mọ̀ ẹ́ dáadáa. Kí kálukú yín béèrè lọ́wọ́ wọn pé ẹ fẹ́ mọ àwọn ìwà ọmọlúwàbí àtàwọn àléébù tẹ́nì kọ̀ọ̀kan yín ní. Ẹ sì tún lè béèrè ojú ìwòye àwọn alàgbà ìjọ. Ó máa dáa kó o mọ̀ bóyá ẹni tó ò ń gbèrò àtifẹ́ yìí lórúkọ rere nínú ìjọ Kristẹni.
O lè fẹ́ béèrè pé, ‘Ṣé dandan ni kéèyàn máa rojọ́ ara ẹ̀ káàkiri ni?’ Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé ṣe la máa ń fi ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n, pàápàá tọ́rọ̀ bá ti dọ̀rọ̀ ara ẹni bí ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà. Ó ṣe tán, Ìwé Mímọ́ pàápàá sọ bẹ́ẹ̀, gbọ́ ohun tí Òwe 15:22 sọ: “Àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.” Kì í ṣe pé àwọn àgbàlagbà tó o fọ̀rọ̀ lọ̀ fẹ́ là lé ẹ lọ́wọ́ o. Ṣùgbọ́n “ìmọ̀ràn ọkàn” tí wọ́n bá fún ẹ lè jẹ́ kójú ẹ là sáwọn nǹkan kan tó ò rí tẹ́lẹ̀ nípa ẹlòmíì kódà ó lè jẹ́ nípa ìwọ alára.—Òwe 27:9.
Ohun tí James tá a fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ṣe nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ti ń dá gbé, síbẹ̀ ó fọ̀rọ̀ Susan lọ àwọn òbí ẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn lòun àti Susan sọ fúnra wọn nípa àwọn àgbàlagbà tó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lọ bá kí wọ́n sì gbọ́ èrò wọn lórí báwọn méjèèjì ṣe ń gbèrò àtidi tọkọtaya. Lẹ́yìn tí wọ́n rí ohun tó dáa gbọ́ nípa ara wọn ni James àti Susan bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà láti lè di tọkọtaya. Bíwọ náà bá lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan náà kí ìfẹ́ tó kó sí ẹ lórí, wàá rí i pé ọkàn ẹ máa balẹ̀ pé ó ti ṣèpinnu tó dáa.
Ju gbogbo ẹ̀ lọ, gbàdúrà sí Jèhófà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìgbéyàwó ni ìfẹ́sọ́nà máa ń yọrí sí, bẹ Jèhófà kó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ìfẹ́sọ́nà ìwọ àti ọ̀dọ́bìnrin náà á lè yọrí sí rere. Èyí tó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé kó o gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí ìpinnu tẹ́ ẹ ṣe lè túbọ̀ mú kẹ́ ẹ sún mọ́ ọn. Nítorí, ìyẹn ló máa jẹ́ kẹ́yin méjèèjì láyọ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àkòrí “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú Jí! November 8, 2004 àti January 8, 2005 jíròrò bí obìnrin ṣe lè sọ fún ọkùnrin pé káwọn máa fẹ́ra.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bó o bá mọ̀ pé o ò ní fi ṣaya, má ṣe nǹkan tó máa jẹ́ kó ṣì ẹ́ lóye