Ohun Tí Kì Í Jẹ́ Kí Àwọn Ọmọdé Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn
Ohun Tí Kì Í Jẹ́ Kí Àwọn Ọmọdé Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn
LỌ́JỌ́ kan tí ojú ọjọ́ ṣú dẹ̀dẹ̀, ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan sáré ṣòòròṣò, ó gbéra ńlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fò. Ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ayẹyẹ pàtàkì kan tí àwọn oníròyìn kò gbẹ́yìn níbẹ̀, tí wọ́n ń fi kámẹ́rà wọn ya fọ́tò ṣáá, tí wọ́n sì ń béèrè onírúurú ìbéèrè tó ń mórí ẹni wú, bákan náà ni wọ́n tún ń kan sáárá sí ẹni pàtàkì ọjọ́ náà. Ta lẹni tó di ìran àpéwò yìí? Kì í ṣe ọ̀jáfáfá awakọ̀ òfuurufú tó wà nínú ọkọ̀ òfuurufú náà, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èrò ọkọ̀ kan ṣoṣo tó wà níbẹ̀, ìyẹn àgbàlagbà ọkùnrin kan—àmọ́, ọmọ ọkùnrin náà ni onítọ̀hún. Ọmọ ọdún méje péré sì ni ọmọdébìnrin ọ̀hún.
Wọ́n ti ṣètò pé ọmọdébìnrin yìí ló máa wa ọkọ̀ òfuurufú náà. Òun ló máa jẹ́ ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jù lọ tó máa kọ́kọ́ wa ọkọ̀ òfuurufú, ó sì ní iye àkókò tí wọ́n fún un láti parí ohun tó fẹ́ ṣe náà. Àwọn oníròyìn á ti máa retí wọn ní pápákọ̀ òfuurufú kejì tó ti máa balẹ̀. Nítorí náà, láìka ojú ọjọ́ tí kò dára sí, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta bọ́ sínú ọkọ̀, ọmọ kékeré náà jókòó sórí tìmùtìmù kan kó lè rí gbogbo àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń wakọ̀, ó sì fi nǹkan tilẹ̀ kí ẹsẹ̀ rẹ̀ lè tó àwọn ẹ̀yà ara ọkọ̀ tí wọ́n ń fẹsẹ̀ tẹ̀ nísàlẹ̀.
Ó ṣeni láàánú pé, ojú ẹsẹ̀ ni ìrìn-àjò náà wá sópin. Ìjì líle kan tó ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ mú kí ọkọ̀ òfuurufú náà yà bàrá sápá kan, nígbà tí kò sì lè fò lọ mọ́, ó já lulẹ̀, ó sì pa àwọn èèyàn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà nínú ọkọ̀ náà. Lójijì làwọn oníròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìkéde ìbànújẹ́ dípò bí wọ́n ṣe ń kan sáárá níṣàájú. Àwọn oníròyìn àtàwọn olóòtú ìwé ìròyìn bíi mélòó kan wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì pé, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé àwọn oníròyìn gan-an dá kún ìṣẹ̀lẹ̀ aburú náà. Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọdé èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ wa ọkọ̀ òfuurufú mọ́. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n ṣe òfin pé kò sí ọmọdé tó gbọ́dọ̀ wa ọkọ̀ òfuurufú. Àmọ́ ohun
tó wà lẹ́yìn ọ̀fà ju òje lọ, torí pé yàtọ̀ sí àṣà pípọ́n nǹkan lé ju bó ṣe yẹ lọ tó ti mọ́ àwọn oníròyìn lára àti òfin tuntun tí ìjọba ṣe, àwọn ìṣòro ńlá mìíràn tó fara sin ṣì wà.Ìṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí mú kí àwọn èèyàn kan ronú jinlẹ̀ lórí àṣà kan tó ń gbilẹ̀ lákòókò wa. Àwọn òbí kì í jẹ́ kí àwọn ọmọdé òde òní fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn, nítorí pé àti kékeré ni wọ́n ti máa ń gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ bàǹtàbanta tó jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà ló tọ́ sí kà wọ́n láyà. Lóòótọ́, àwọn ohun tó ń jẹ́ àbájáde àṣà yìí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbàfiyèsí tàbí kó fa jàǹbá ńlá. Àmọ́ wọ́n lè jẹ́ ìṣòro ńlá fún àwọn ọmọdé, wọ́n sì lè wà pẹ́ títí. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ohun tí kì í jẹ́ kí àwọn ọmọdé lè fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn.
Kíkọ́ Àwọn Ọmọdé Lẹ́kọ̀ọ́ Ní Kánjúkánjú
Kò sóhun tó burú nínú bí àwọn òbí ṣe máa ń yán hànhàn láti rí i pé àwọn ọmọ wọn di èèyàn gidi. Àmọ́ bí ìyánhànhàn àwọn òbí bá wá di àníyàn, wọ́n lè dẹ́rù pa àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n máa mú kí wọ́n ṣe ju agbára wọn lọ. Ńṣe lọ̀pọ̀ àwọn òbí máa ń ronú pé àwọn ń tún ọjọ́ iwájú àwọn ọmọ àwọn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, àṣà kan tó túbọ̀ ń gbilẹ̀ lónìí ni pé kí àwọn òbí máa ṣètò onírúurú ìgbòkègbodò fún àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́, látorí eré ìdárayá títí dórí ẹ̀kọ́ nípa orin kíkọ tàbí ijó jíjó. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n tún máa ń gba olùkọ́ tí yóò máa kọ́ ọmọ nílé.
Ká sòótọ́, kò sóhun tó burú nínú kí òbí máa fún ọmọ níṣìírí pé kó lo ẹ̀bùn àbínibí rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àṣejù wọ̀ ọ́? Láìsí àní-àní, èyí lè rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn ohun tí wọ́n ń gbé ka àwọn ọmọdé kan láyà fẹ́rẹ̀ẹ́ pọ̀ tó ti àwọn àgbàlagbà tí wọ́n ní ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ láti bójú tó. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Àwọn ọmọdé tó jẹ́ pé wọ́n ń gbádùn ìgbà èwe tẹ́lẹ̀ ni ọwọ́ wọn ti ń dí fọ́fọ́ báyìí; àwọn ọmọ tó yẹ kó máa fi okun ìgbà èwe wọn ṣeré ni kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ nítorí àwọn ẹrù iṣẹ́ kíkàmàmà tí wọ́n ń gbé kà wọ́n níwájú.”
Àwọn òbí kan máa ń fẹ́ kí àwọn ọmọ wọn bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ láti di gbajúmọ̀ eléré ìdárayá, akọrin tó lókìkí, tàbí kí wọ́n di ògbóǹkangí nínú iṣẹ́ ọpọlọ kan. Ṣáájú kí àwọn òbí náà tó bí àwọn ọmọ wọn, wọ́n ti máa ń forúkọ wọn sílẹ̀ láwọn ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi, pẹ̀lú ìrètí pé èyí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ ṣàṣeyọrí. Láfikún sí i, àwọn ìyá kan máa ń lọ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ń pè ní “ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ tí wọn kò tíì bí,” níbi tí wọ́n ti máa ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ orin fún àwọn ọmọ tó ṣì wà nínú oyún. Ète tí wọ́n fi ń ṣe èyí ni láti mú kí ọpọlọ wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà sókè túbọ̀ jí pépé.
Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọdé kò tíì ní pé ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti máa ń gbé wọn yẹ̀ wò nípa bí wọ́n ṣe mọ̀wéé kà sí àti bí wọ́n ṣe mọ ìṣirò sí. Irú àwọn àṣà báyìí ti jẹ́ káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó ṣeé ṣe kí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dùn ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ọmọ kan tó bá “fìdí rẹmi” ní ilé ẹ̀kọ́ jẹ́lé-ó-sinmi? David Elkind, ẹni tó kọ ìwé The Hurried Child, sọ pé àwọn ilé ẹ̀kọ́ ti máa ń yara jù láti pinnu pé irú ẹni báyìí lọmọ kan máa yà nígbà tó ṣì kéré gan-an. Ọ̀gbẹ́ni Elkind sọ pé, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti lè mọ irú ọwọ́ tí wọ́n á fi mú ọmọ kan dípò tí wọn ì bá fi fún un ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro.
Ǹjẹ́ àbájáde kankan wà nínú mímú kí àwọn ọmọdé máa ṣe ojúṣe àwọn àgbàlagbà nígbà tí wọn ò tíì dàgbà débì kankan? Lójú ọ̀gbẹ́ni Elkind, kò bójú mu rárá bí ọ̀pọ̀ òbí ṣe ń mú kí àwọn ọmọdé máa ṣe ojúṣe àwọn àgbàlagbà. Ó sọ pé: “Àṣà yìí fi hàn pé ńṣe ni à ń wo fífi ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan dẹ́rù pa àwọn èwe bí ohun tó ‘bójú mu.’” Láìsí àní-àní, ó dà bíi pé ńṣe ni èrò nípa ohun tó bójú mu fún àwọn ọmọdé ń yára yí padà.
Kìràkìtà Láti Gbégbá Orókè
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí máa ń rò pé ó bójú mu tàbí pé ohun tó tiẹ̀ dára gan-an ni pàápàá, láti máa tẹnu mọ́ ọn fún àwọn ọmọ wọn pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbégbá
orókè lọ́nàkọnà—àgàgà nínú eré ìdárayá. Lóde òní, gbígba àmì ẹ̀yẹ Olympic lohun tó ń sún ọ̀pọ̀ àwọn èwe láti ṣe eré ìdárayá. Torí kí àwọn ọmọ lè gba ògo ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, kí wọ́n sì lè rí ohun gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà tí wọ́n bá ń di àgbàlagbà, àwọn òbí kì í jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n gbádùn rẹ̀ rárá.Ronú nípa àwọn obìnrin eléré ìdárayá. Ìgbà tí wọ́n bá ṣì kéré gan-an ni wọ́n ti máa ń bẹ̀rẹ̀, èyí sì máa ń jẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ń tánni lókun púpọ̀ fún ara wọn tí kò tíì gbó. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n máa ń fi múra sílẹ̀ fún ìdíje Olympic, bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn náà ni ọpọlọ wọn á máa ṣiṣẹ́ bí aago. Àmọ́, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló máa borí. Ǹjẹ́ àwọn tó bá fìdí rẹmi lè gbà pé bí àwọn kò ṣe rọ́wọ́ mú yìí tó gbogbo ìrúbọ tí wọ́n ti fi púpọ̀ nínú ìgbà èwe wọn ṣe? Bí àkókò ti ń lọ, kódà àwọn tó bá gbégbá orókè pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì pé, bóyá ni gbogbo ògo tí wọ́n gbà tó ohun tí wọ́n torí ẹ̀ fi ìgbà èwe wọn rúbọ.
Bí àwọn òbí ṣe ń fínná mọ́ àwọn ọmọdébìnrin wọ̀nyí pé wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé wọ́n di gbajúmọ̀ eléré ìdárayá kò ní jẹ́ kí wọ́n ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà èwe wọn. Bákan náà ló jẹ́ pé irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ń tánni lókun bẹ́ẹ̀ lè ṣàkóbá fún ara wọn, torí pé kò ní jẹ́ kí wọ́n dàgbà sókè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin kan ni pé egungun wọn kò ní lágbára tó bó ṣe yẹ. Ó wọ́pọ̀ pé kí irú àwọn ọmọbìnrin bẹ́ẹ̀ ní ìṣòro àìlèjẹun dáadáa. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin kan tètè bàlágà—kódà fún ọ̀pọ̀ ọdún pàápàá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin lóde òní ló jẹ́ pé òdìkejì èyí ni ìṣòro wọn: ìyẹn ni pé wọ́n máa ń tètè bàlágà.—Wo àpótí tó wà lókè.
Àwọn Ọmọ Tó Ń Gbádùn Àwọn Ohun Amáyédẹrùn àmọ́ Tí Wọn Ò Gbádùn Ìgbà Èwe Wọn
Tó o bá lọ gba ohun tí àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn ń sọ gbọ́ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ kí ọmọ gbádùn ìgbà èwe rẹ̀, ńṣe ni wàá rò pé kéèyàn máa fi oríṣiríṣi nǹkan amáyédẹrùn kẹ́ ọmọ ló dára. Àwọn òbí kan máa ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́ láti lè pèsè onírúurú nǹkan ìgbádùn fún àwọn ọmọ wọn, irú bí ilé tó jojú ní gbèsè, onírúurú ohun èlò eré ìnàjú àti àwọn aṣọ olówó ńlá.
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ tí wọ́n tọ́ lọ́nà yìí ló máa ń di ọ̀mùtípara, ajoògùnyó, tàbí kí wọ́n di ẹni tí ayé sú tàbí kí wọ́n máa hùwà tinú-mi-ni-màá-ṣe. Kí nìdí? Ohun tó fa èyí ni pé inú máa ń bí wọn gan-an nítorí pé àwọn òbí wọn pa wọ́n tì. Àwọn ọmọ nílò àwọn òbí tí yóò máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, tó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, tó sì máa bìkítà fún wọn. Àwọn òbí tí ọwọ́ wọn bá dí jù láti gbọ́ ti àwọn ọmọ wọn lè máa rò pé torí kí àwọn ọmọ wọn lè jẹ́ aláyọ̀ làwọn ṣe ń ṣiṣẹ́—àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òdìkejì gan-an lohun tí wọ́n ń ṣe.
Ọ̀mọ̀wé Judith Paphazy sọ pé, àwọn ìdílé tó jẹ́ pé “àwọn òbí méjèèjì ló ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rọ̀ sábà máa ń fi gbogbo nǹkan kẹ́ àwọn ọmọ wọn láìmọ̀ pé bí wọ́n ṣe ń lépa ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ń ṣàkóbá fún ìdílé wọn.” Lójú ọ̀mọ̀wé yìí, ńṣe ni irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ń gbìyànjú láti “fi ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rọ́pò ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí òbí.”
Èyí sábà máa ń mú àbájáde tí kò dára wá fún àwọn ọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lè ní ọ̀pọ̀ nǹkan amáyédẹrùn, wọn kò ní àwọn nǹkan pàtàkì téèyàn fi ń gbádùn ìgbà èwe: ìyẹn ni àkókò òbí àti ìfẹ́ òbí sí ọmọ. Láìsí ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí, kò ní pẹ́ tí wọ́n á fi rí i pé àwọn ní láti ṣe àwọn ìpinnu kan tó ń béèrè ọgbọ́n àgbà, èyí tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ múra sílẹ̀ fún tàbí tí wọn kò tiẹ̀ múra sílẹ̀ fún rárá. Àwọn ìbéèrè bíi, ‘Ṣé ó yẹ kí n máa lo oògùn olóró? Ṣé ó yẹ kí n ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó? Ṣé ó yẹ kí n máa fara ya tí mo bá ń bínú?’ Wọ́n á kúkú rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, bí kò bá jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn á jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n tàbí sinimá. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ohun tó ń jẹ́ àbájáde ìpinnu wọn máa ń ṣàkóbá fún ìgbà èwe wọn tàbí kó tiẹ̀ bà á jẹ́ pátápátá.
Sísọ Ọmọ Di Agbọ̀ràndùn
Nígbà tí ìdílé olóbìí méjì bá ṣàdédé di olóbìí kan, bóyá nítorí ikú, ìpínyà, tàbí ìkọ̀sílẹ̀, èyí sábà máa ń mú kí àwọn ọmọ ní ẹ̀dùn ọkàn. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìdílé olóbìí kan máa ń ṣàṣeyọrí. Àmọ́ àwọn òbí anìkàntọ́mọ kan wà tí kì í jẹ́ kí àwọn ọmọ fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn.
Láìsí àní-àní, òbí kan tó ń dá tọ́mọ lè máa ní ìṣòro ìdánìkanwà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Látàrí èyí àwọn òbí kan máa ń jẹ́ kí ọmọ wọn kan, pàápàá ọmọ tó dàgbà jù, tẹ́rí gba ojúṣe òbí kejì tí kò sí nítòsí. Bóyá nítorí àìrí ọ̀nà mìíràn gbé e gbà, òbí kan lè sọ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ di agbọ̀ràndùn, kó máa gbé àwọn ìṣòro tó lè ka irú ọmọ bẹ́ẹ̀ láyà síwájú rẹ̀. Ńṣe làwọn òbí kan tó ń dá tọ́mọ á tiẹ̀ wá kúkú sọ ọmọ di ẹni tí wọ́n á di gbogbo ẹrù ìṣòro rù.
Àwọn òbí mìíràn máa ń fi gbogbo ojúṣe wọn sílẹ̀ pátápátá, wọ́n á wá máa fipá mú kí ọmọ ṣe ojúṣe òbí. Irú ipò báyìí ni Carmen àti arábìnrin rẹ̀, tá a mẹ́nu kàn níṣàájú, sá fún tí wọ́n fi ń lọ gbé níta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ṣì ni wọ́n, àwọn méjèèjì làwọn òbí wọn fún ní ẹrù iṣẹ́ bíbójútó àwọn àbúrò wọn kékeré. Ọ̀ràn ọ̀hún wá dà bí àtàrí àjànàkú, tó jẹ́ pé ó kọjá ẹrù tọ́mọ kékeré lè gbé.
Láìsí àní-àní, àṣà tó léwu ni ṣíṣàì jẹ́ kí àwọn ọmọdé fara balẹ̀ gbádùn ìgbà èwe wọn, àṣà tó sì yẹ kéèyàn yẹra fún pátápátá bó bá ti lè ṣeé ṣe tó ni. Àmọ́ ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé: Àwọn àgbàlagbà lè gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó gbéṣẹ́ láti rí i pé àwọn ọmọ wọn gbádùn ìgbà èwe wọn. Àwọn ìgbésẹ̀ wo nìyẹn? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìdáhùn kan tí ẹ̀rí fi hàn pé ó gbéṣẹ́.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìṣòro Tó Ń Kojú Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Ń Tètè Bàlágà
Ṣé lóòótọ́ làwọn ọmọbìnrin ń tètè bàlágà lóde òní? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣì ń bára wọn jiyàn lórí ìbéèrè yìí. Àwọn kan sọ pé ní agbedeméjì ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ìgbà tí àwọn ọmọbìnrin bá di ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni wọ́n sábà máa ń bàlágà, àmọ́ lóde òní, wọn kì í pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 1997 ti fi hàn, nínú àwọn ọmọbìnrin tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún tí wọ́n lò fún ìwádìí náà, nǹkan bí ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin aláwọ̀ funfun àti ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin adúláwọ̀ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí fi àmì ìbàlágà hàn ní ọmọ ọdún mẹ́jọ! Àmọ́ ṣá o, àwọn dókítà kò fara mọ́ àwọn àbájáde ìwádìí yìí, wọ́n wá kìlọ̀ fún àwọn òbí pé kí wọ́n má kàn gbà pé bí àwọn ọmọ wọn ṣe tètè ń bàlágà “bójú mu.”
Láìka awuyewuye wọn sí, ọ̀ràn yìí jẹ́ ìṣòro fún àwọn òbí àti fún àwọn ọmọ. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ohun tó tiẹ̀ tún wá burú ju ìyípadà tó ń wáyé nínú ara wọn ni pé, títètè bàlágà yóò nípa lórí ìrònú wọn torí pé á mú kí àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí máa fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀. Àwọn ọmọ tó yẹ kó ṣì máa ka ìwé ìtàn tó wà fáwọn ọmọ kéékèèké á wá di ẹni tí yóò máa wá bí wọn á ṣe dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin tó máa fẹ́ láti fi wọ́n ṣèfà jẹ. . . . Ká sòótọ́, ìgbà ọmọdé kì í pẹ́ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.” Àpilẹ̀kọ náà wá béèrè ìbéèrè amúnironújinlẹ̀ yìí pé: “Bí ara àwọn ọmọdébìnrin bá dà bíi ti àgbàlagbà lójú nígbà tí ọkàn wọn àti ìrònú wọn kò tíì ṣe tán, ìbànújẹ́ wo ló sábà máa ń dorí wọn kodò títí ayé?”
Ìbànújẹ́ tó sábà máa ń dorí wọn kodò ni àìmọ̀kan tó ṣe wọn nígbà tí àwọn ọkùnrin ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú wọn. Ìyá kan sọ ojú abẹ níkòó pé: “Ńṣe làwọn ọmọdébìnrin tó dàgbà lójú ju ọjọ́ orí wọn lọ dà bí eku [sí ológbò]. Ìyẹn ni pé ńṣe làwọn ọkùnrin máa ń lé wọn kiri.” Àbájáde èyí ni pé, wọ́n máa ń mú kí wọ́n ní ìbálòpọ̀ nígbà tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré gan-an. Ọmọdébìnrin kan lè máà níyì lójú ara rẹ̀ mọ́, ó lè máà ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́, kódà ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn, kó sì máa ní ẹ̀dùn ọkàn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣíṣètò ohun tó pọ̀ jù fún àwọn ọmọ láti ṣe lè fa ìṣòro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Títi àwọn ọmọdé láti máa bá àwọn ẹlòmíràn díje lójú méjèèjì kò ní jẹ́ kí wọ́n gbádùn eré ìdárayá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kò lè rọ́pò títọ́ ọmọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ