Bó o Ṣe Lè Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Ààbò
Bó o Ṣe Lè Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Ààbò
FÍFÒ lókè ní ohun tó fi kìlómítà mọ́kànlá jìn sísàlẹ̀ máa ń kó jìnnìjìnnì bá àwọn kan. Ó lè dà bí ìgbà téèyàn ń tàpá sí òfin ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n bí àwọn ìlànà ààbò ṣe ń múná sí i tí ọkọ̀ òfuurufú wíwọ̀ sì túbọ̀ ń fini lọ́kàn balẹ̀, àwọn ewu tó dà bíi pé ó wà nínú fífò lókè fíofío nínú ọkọ̀ òfuurufú ti dín kù jọjọ. Àmọ́ ṣá o, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ máa ń rán wa létí pé, àjálù lè ṣẹlẹ̀.
Bí O Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ ni pé àjálù lè ṣẹlẹ̀, àtìgbà láéláé ni àwọn ẹ̀dá èèyàn ti nífẹ̀ẹ́ sí àtimáa fò ní òfuurufú. Ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú kí Kristi tó wá sáyé, Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Ì bá ṣe pé mo ní ìyẹ́ apá bí ti àdàbà! Èmi ì bá fò lọ.” (Sáàmù 55:6) Gẹ́gẹ́ bí àwọn àlàyé tá a ṣe ṣáájú ti fi hàn, ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní ti mú kí ìrìn-àjò nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó láàbò tó ga jù lọ láti gbà rìnrìn-àjò. Kì í kúkú ṣe pé àṣìṣe ò lè ṣẹlẹ̀, torí kò sí ohun kankan nínú ayé ìsinsìnyí tó bọ́ lọ́wọ́ ewu pátápátá tàbí téèyàn lè sọ pé báyìí ló ṣe máa rí tó sì máa rí bẹ́ẹ̀.
Á dáa ká máa fi èyí sọ́kàn tá a bá jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fi ìwàǹwara hùwà nígbà
tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀, tí a ò sì sí nípò láti ṣe ohunkóhun. Àwọn èèyàn kan lè máa ronú pé, ‘Tí ọwọ́ mi bá lè tẹ èèkù idà ni, ìbẹ̀rù mi ì bá mọ níwọ̀n.’ Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè ní ìṣòro láwọn ipò tí wọn ò lágbára láti ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀. Wíwọ ọkọ̀ òfuurufú máa ń mú kéèyàn bára rẹ̀ nírú ipò yẹn.Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ akitiyan làwọn tó mọ̀ nípa ọkọ̀ òfuurufú ń ṣe láti mú kí ewu wíwọkọ̀ òfuurufú túbọ̀ dín kù, síbẹ̀ kó yẹ kéèyàn wá máa ronú pé kò sí ìṣòro èyíkéyìí. Àtàwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú o àtàwọn arìnrìn-àjò o, gbogbo wọn ló yẹ kó fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti dín àwọn ohun tó lè fa jàǹbá kù. Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ ọkọ̀ òfuurufú ò yéé kìlọ̀ pé ewu ṣì ń bẹ o. Òwe inú Bíbélì kan tó mọ́gbọ́n dání sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n èèyàn rí ewu tẹ́lẹ̀ ó sì lo ìṣọ́ra.” (Òwe 22:3, New Living Translation) Ó dára láti mọ̀ pé, kò sọ́gbọ́n kí ewu máà sí nínú ohunkóhun téèyàn bá ń ṣe, ì báà tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀. Ohun tá à ń sọ ni pé, máa rántí pé irú ìṣọ́ra kan náà téèyàn nílò láti dáàbò bo ara rẹ̀ nínú àwọn ipò mìíràn náà ló yẹ kéèyàn lò nínú wíwọkọ̀ òfuurufú.
Ó lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣòro fún àwọn tó máa ń wọkọ̀ òfuurufú déédéé láti bójú tó ara wọn láwọn àkókò líle koko tá à ń gbé yìí. Ìdí ni pé, àwọ́n sábà máa ń mọ púpọ̀ nípa pápákọ̀ òfuurufú àti ọkọ̀ òfuurufú fúnra rẹ̀ ju àwọn èrò mìíràn lọ. Ìwọ náà lè mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa wíwọkọ̀ òfuurufú bíi tiwọn, kí ọkàn tìrẹ náà sì máa balẹ̀ bíi tiwọn nípa títẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ rírọrùn tá a ṣàlàyé wọn nínú àwọn àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
Rírìnrìn Àjò Láìsí Ìyọnu
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àǹfààní àwọn èèyàn làwọn ibi àyẹ̀wò tó wà ní pápákọ̀ òfuurufú wà fún, ìyọlẹ́nu làwọn arìnrìn-àjò kan—pàápàá àwọn tójú máa ń kán—máa ń kà á sí. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé ètò ààbò ní ọ̀pọ̀ àwọn pápákọ̀ òfuurufú ti le ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, o dára láti tẹ̀ lé àwọn ìdámọ̀ràn tó wà nísàlẹ̀ yìí kó lè túbọ̀ rọrùn fún ọ láti kọjá láwọn ibi àyẹ̀wò náà:
◼ Tètè dé. Nípa títètè dé sí pápákọ̀ òfuurufú ṣáájú ìgbà tí ọkọ̀ máa gbéra, wàá lè fara balẹ̀, wàá sinmi díẹ̀, wàá sì lè yẹra fún ìnira tó máa ń wáyé tí ohun téèyàn ò rò tẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí àwọn àìfararọ mìíràn bá wáyé.
◼ Nígbà tó o bá ń ṣètò ọkọ̀ òfuurufú tó o máa wọ̀, èyí tó máa ń gbé àwọn oníṣòwò ni kó o máa wọ̀. Àwọ́n ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gbé ẹrù tó pọ̀, wọ́n kì í sì í fẹ́ fi àkókò ṣòfò.
◼ Kó o tó kọjá ní ẹnu ọ̀nà tí wọ́n fi ẹ̀rọ tó máa ń fi àwọn nǹkan onírin hàn, mú àwọn nǹkan tó o mọ̀ pé ó lè jẹ́ kí aago ẹ̀rọ náà dún kúrò lára rẹ. Àwọn nǹkan bíi kọ́kọ́rọ́ ilé, owó wẹ́wẹ́, àwọn ohun ọ̀ṣọ́, àti tẹlifóònù alágbèérìn. Kó wọn fún olùtọ́jú èrò kan bó o ti ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà náà.
◼ To àwọn báàgì àtàwọn ẹrù mìíràn tó o kó sórí bẹ́líìtì tó ń gbé ẹrù dáadáa; bí ẹni tó wà nídìí ẹ̀rọ onítànṣán tí wọ́n fi ń yẹ ẹrù wò bá rí i tí àwọn ẹrù rẹ ṣe hágahàga, ó lè fẹ́ kó o tú u han òun tàbí kó sọ pé kó o tún gbé e kọjá níwájú ẹ̀rọ náà nígbà kejì.
◼ Jẹ́ kí olùtọ́jú èrò mọ̀ ṣáájú nípa ohun èyíkéyìí tó o mọ̀ pé ó lè mú kí aago ẹ̀rọ tó ń yẹ ẹrù wò náà dún, irú bí ohun èèlò kan tó jé onírin tí ìyá rẹ àgbà fún ọ. Bí àlàyé tó bọ́gbọ́n mu tó o ṣe nípa àwòrán tó rí gbágungbàgun tí ẹ̀rọ onítànṣán náà gbé jáde bá ti tẹ́ ẹni tó wà nídìí ẹ̀rọ náà lọ́rùn, kò dájú pé á sọ pé dandan lòún gbọ́dọ̀ tú ẹrù rẹ wò. Bí ojú bá ń kán ọ gidi, o lè ti yọ ohun náà jáde nínú ẹrù rẹ kó o tó dé ibi tí ẹ̀rọ náà wà, kó o sì sọ pé kí wọ́n fọwọ́ yẹ ara rẹ wò.
◼ Bí nǹkan kan lára rẹ bá mú aago ẹ̀rọ náà dún, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ náà kó o sì tètè ṣàlàyé ohun tó fà á. Bí olùtọ́jú èrò náà bá mọ̀ pé ohun kan tó ò tíì mú kúrò lára rẹ ló jẹ́ kí aago náà dún, tí olùtọ́jú èrò mìíràn nítòsí rẹ̀ sì ní ohun èlò ọlọ́wọ́ kan tí wọ́n fi ń yẹ ara èèyàn wò lọ́wọ́, ó lè sọ fún ọ pé kó o lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún àyẹ̀wò.
◼ Ó dájú hán-únhán-ún pé o ò ní í bá ọkọ̀ òfuurufú tó yẹ kó o wọ̀ lọ bó o bá lọ ń fi ọ̀rọ̀ àwọn tó ń já ọkọ̀ òfuurufú gbà dápàárá tàbí kó o máa fi ọ̀rọ̀
bọ́ǹbù ṣàwàdà. Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò á yẹ gbogbo ara rẹ wò fínnífínní, wọ́n lè fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kàn ọ́.Ọkọ̀ Á Gúnlẹ̀ Láyọ̀ O!
Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe láti rí ọkọ̀ òfuurufú tó fini lọ́kàn balẹ̀ wọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣeé ṣe dáadáa. Láìka irú ọkọ̀ òfuurufú tó o yàn láti wọ̀ sí, ohun tó dájú ni pé, o lè débi tí ò ń lọ láìsí ìfarapa kankan. Bó o bá ń ṣiyèméjì nípa bóyá kó o wọ ọkọ̀ òfuurufú tàbí kó o má wọ̀ ọ́, lọ ṣèwádìí lórí àkọsílẹ̀ tí iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú tí ò ń gbèrò láti wọ̀ ní lórí ọ̀ràn ààbò. Máa rántí pé, láìka àwọn jàǹbá tí wọ́n sọ pé ó ń ṣẹlẹ̀ sí, ìrìn-àjò nípasẹ̀ ọkọ̀ òfuurufú ṣì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó láàbò jù lọ láti gbà rìnrìn àjò.
Ní báyìí ná, gbogbo wa lè máa wọ̀nà fún àkókò náà, nígbà tí ìjọba Ọlọ́run yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé, tí ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ yóò wà. Kò ní sí ẹnì kankan tí yóò máa fi ẹ̀mí ẹlòmíràn sínú ewu láàárín ìdílé ẹ̀dá èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tó sì jẹ́ alálàáfíà. Àwọn èèyàn “yóò wà láìséwu, wọn yóò sì rí ààbò kúrò nínú ìbẹ̀rù jàǹbá.”—Òwe 1:33 Holy Bible—Contemporary English Version. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àpilẹ̀kọ tó jíròrò àwọn ohun tó jẹ mọ́ èyí, wo Jí!, February 8, 1990, tó ní àpilẹ̀kọ náà, “Ìbẹ̀rù Ìrìn-àjò-Òfúúrufú—Ó Ha Dè Ọ́ Mọ́lẹ̀ Lápàpàǹdodo Bi?”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]
ÀWỌN ÌSỌFÚNNI DÍẸ̀ TÓ LÈ DÁÀBÒ BÒ Ọ́
Ọkọ̀ òfuurufú tí kì í dúró lọ́nà ni kó o máa wọ̀. Ìgbà tí ọkọ̀ òfuurufú bá ń gbéra nílẹ̀, tó ń lọ sókè, tó ń bọ̀ wálẹ̀ tàbí tó ń balẹ̀ ni ọ̀pọ̀ jù lọ jàǹbá máa ń ṣẹlẹ̀. Tó o bá ń wọ ọkọ̀ òfuurufú tí kì í dúró lọ́nà, èyí á dín jàǹbá kù.
Ọkọ̀ Òfuurufú tó tóbi gan-an ni kó o máa wọ̀. Wọ́n sábà máa ń ṣe àwọn ọkọ̀ òfuurufú tí èrò wọn ju ọgbọ̀n lọ lọ́nà tó ṣeé gbára lé ju àwọn kéékèèké lọ, wọ́n sì máa ń fàṣẹ sí wọn pé wọ́n pegedé. Bákan náà, ká ní jàǹbá ńlá kan lọ ṣẹlẹ̀, ó sábà máa ń ṣeé ṣe fún àwọn tó bá wọ ọkọ̀ òfuurufú tó tóbi gan-an láti yè bọ́ ju àwọn kéékèèké lọ.
Máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí àlàyé tó máa ń wáyé kí ọkọ̀ òfuurufú tó gbéra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìsọfúnni náà máa ń dà bí àsọtúnsọ, àwọn ọ̀nà téèyàn lè tètè gbà sá jáde tí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ lè yàtọ̀ síra, ó sinmi lórí irú ọkọ̀ òfuurufú tó o bá wọ̀ àti apá ibi tó o bá jókòó sí.
Má ṣe kó àwọn ẹrù tó wúwo sí ibi ìkẹ́rùsí tó wà lókè ibi tó o jókòó sí. Àwọn ibi ìkẹ́rùsí tó wà lókè ibi tó o jókòó lè máà tóbi tó láti gba àwọn ẹrù tó bá wúwo gan-an dúró bí ìjì líle bá bẹ̀rẹ̀ sí í mi ọkọ̀ òfuurufú náà jìgìjìgì, nítorí náà, bó o bá ní ẹrù tí kò ní rọrùn fún ọ láti gbé síbi ìkẹ́rùsí náà, jẹ́ kó ti wà lára àwọn ẹrù tí wọ́n máa dì sáyè ẹrù.
Rí i pé o de bẹ́líìtì ìjókòó rẹ le dáadáa tó o bá wà lórí ìjókòó. Jíjẹ́ kí bẹ́líìtì rẹ wà ní dídè nígbà tó o bá wà ní ìjókòó á túbọ̀ pèsè ààbò tó ṣeé ṣe kó o nílò bó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ̀ òfuurufú náà lọ pàdé ìjì líle láìròtẹ́lẹ̀.
Fetí sílẹ̀ sí àwọn olùtọ́jú èrò inú ọkọ̀ òfuurufú. Kò sí ìdí méjì táwọn olùtọ́jú èrò fi máa ń wà nínú ọkọ̀ òfuurufú ju torí ààbò lọ, nítorí náà, bí ọ̀kan nínú wọn bá sọ fún ọ pé kó o ṣe ohun kan, kọ́kọ́ ṣe ohun náà ná kó o tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa béèrè ìbéèrè.
Má ṣe mú ohun eléwu kankan wọnú ọkọ̀ òfuurufú. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn nǹkan tó léwu ló wà tí wọn ò fàyè gbà nínú ọkọ̀ òfuurufú. Àmọ́, ó yẹ kí ìwọ fúnra rẹ mọ̀ pé kò yẹ kó o gbé epo bẹntiróò, àwọn ohun tó lè mú nǹkan dípẹtà, gáàsì olóró àti irú àwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀ wọlé, àyàfi tí àwọn tó ni iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú náà bá ti fàyè gbà á, tí wọ́n sì fúnra wọn gbé e sínú ohun tó bójú mu.
Má ṣe mu ọtí lámujù. Irú ọtí yòówù kó o mu, yóò nípa lórí rẹ tó o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú ju ìgbà tó o bá wà lórí ilẹ̀ lọ. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ló dára nínú gbogbo nǹkan, ìbáà jẹ́ pé èèyàn wà nínú ọkọ̀ òfuurufú tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Rí i pé ò ń wà lójúfò. Tó bá ṣèèṣì ṣẹlẹ̀ pé o bára rẹ nínú ipò pàjáwìrì, irú bíi kí àwọn olùtọ́jú èrò sọ pé kẹ́ ẹ múra láti jáde kíákíá, tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ àti ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ọkọ̀ òfuurufú náà bá ní kẹ́ ẹ ṣe, kó o sì tètè jáde bó bá ti lè yá tó.
[Credit Line]
Ibi tá a ti mú ìsọfúnni: AirSafe.com
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
BÓ O ṢE LÈ FI ÌDÍLÉ RẸ LỌ́KÀN BALẸ̀
Bó o bá ń rìnrìn àjò, àwọn ọ̀nà tó o lè gbà ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù wọn rèé.
Bá ìdílé rẹ sọ̀rọ̀. Kó o tó gbéra ìrìn àjò rẹ, lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ, kó o bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ààbò tìrẹ àti tiwọn náà. Ṣàlàyé àwọn ètò ààbò tuntun táwọn iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe àti bí èyí ṣe máa túbọ̀ fi kún ààbò rẹ lẹ́nu ìrìn àjò náà.
Fún wọn láyè láti sọ ohun tó ń já wọn láyà. Jẹ́ kí ìdílé rẹ sọ ìbẹ̀rù tó wà lọ́kàn wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ, ààbò rẹ sì jẹ wọ́n lógún. Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ohun tí wọ́n ń sọ, má sì ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu, kó o gbà pé gbogbo ohun tí wọ́n sọ pé ó ń ba àwọn lẹ́rù náà ló ṣe pàtàkì.
Fun wọn ní ojúlówó ìdánilójú. Sọ fún wọn nípa bí oríṣiríṣi àwọn àjọ ṣe ń gbìyànjú láti dènà àwọn ìkọlù mìíràn látọ̀dọ̀ àwọn apániláyà lọ́jọ́ iwájú. Lára àwọn akitiyan wọn ni ètò ààbò tó gbópọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láwọn pápákọ̀ òfuurufú àti nígbà téèyàn bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú. Kò dájú pé láburú kankan máa ṣẹlẹ̀ tó o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú.
Jẹ́ kí àwọn aráalé máa gbúròó rẹ. Ṣèlérí fún wọn pé wàá fóònù wọn tó o bá ti dé ibi tó ò ń lọ. Má ṣe dáwọ́ àtimáa bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù dúró ní gbogbo ìgbà tó o bá wà lájò. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí ìdílé rẹ mọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí ọ bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀.
[Credit Line]
A mú un látinú ìsọfúnni tí a pè ní United Behavioral Health lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Múra tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láwọn ibi àyẹ̀wò ààbò ní pápákọ̀ òfuurufú