Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn Pọn Dandan Ká Tó Lè ní Ìgbàgbọ́?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn Pọn Dandan Ká Tó Lè ní Ìgbàgbọ́?
Lọ́dún 1873, Samuel Manning, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ̀wé nípa ìlú Jerúsálẹ́mù pé: “Bí ìlú náà ṣe fa àwọn èèyàn mọ́ra gan-an ló jẹ́ káwọn tó ń rìnrìn-àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ máa dà gììrì lọ síbẹ̀ láti apá ibi gbogbo lágbàáyé. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ka àwọn ògiri ibẹ̀ tó ti ń ya lulẹ̀, àwọn òpópónà rẹ̀ tó dọ̀tí gan-an, àtàwọn àwókù ìlú náà tó ti ń jẹrà sí nǹkan pàtàkì, tó sì yẹ láti bọlá fún, débi pé, kò tún sí ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé tó ń fa àwọn èèyàn mọ́ra tó bẹ́ẹ̀.”
ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń yán hànhàn láti lọ sí Ilẹ̀ Mímọ́, ó kéré tán látìgbà ayé Kọnsitatáìnì tí í ṣe Olú Ọba Róòmù ni wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. a Fún nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún kan ààbọ̀ [1,500] làwọn arìnrìn-àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ fi ń wá tí wọ́n sì ń lọ. Wọ́n ń ṣe èyí láti lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run àti láti fojú ara wọn rí Ilẹ̀ Mímọ́ náà. Síbẹ̀, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún làwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn arìnrìn-àjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ yìí. Èyí ló wá ṣínà fún ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn nípa Bíbélì—ìyẹn ṣíṣe ìwádìí lórí àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé, àwọn èèyàn, àdúgbò, àtàwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní Ilẹ̀ Mímọ́ láyé ọjọ́un.
Àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ti mú kí òye ọ̀pọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì túbọ̀ yéni sí i. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àkọsílẹ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣe déédéé pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ. Àmọ́, ṣe irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ wá pọn dandan fún Kristẹni kan kó tó lè ní ìgbàgbọ́ ni? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìlú Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ níbi tí wọ́n ti hú ọ̀pọ̀ nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé jáde.
“A Kì Yóò Fi Òkúta Kan Sílẹ̀ Lórí Òkúta Kan”
Níbàámu pẹ̀lú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, ní Nísàn 11, ìyẹn nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù Kristi àtàwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù sílẹ̀, kò sì fẹsẹ̀ tẹ ibẹ̀ mọ́ lẹ́yìn náà. Bí wọ́n ti ń lọ sí orí Òkè Ólífì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà sọ pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé wọ̀nyí mà kàmàmà o!”—Máàkù 13:1.
Àwọn Júù olùṣòtítọ́ yìí nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ tọkàntọkàn. Ohun àmúyangàn ni àwọn ilé kíkàmàmà yìí jẹ́ fún wọn, pa pọ̀ pẹ̀lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn tó ti wà fún ọ̀rúndún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó dá lórí tẹ́ńpìlì náà. Àmọ́ èsì tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu gidigidi, ó sọ pé: “Ṣé ìwọ rí ilé ńlá wọ̀nyí? Lọ́nàkọnà, a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan níhìn-ín tí a kì yóò wó palẹ̀.”—Máàkù 13:2.
Ní báyìí tí Mèsáyà tá a ṣèlérí náà ti dé, báwo ni Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ kí tẹ́ńpìlì rẹ̀ di èyí tí a pa run? Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, díẹ̀díẹ̀ làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wá ń lóye ohun tó ní lọ́kàn ní kíkún. Àmọ́ kí làwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ náà ní í ṣe pẹ̀lú fífi ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn ṣàlàyé Bíbélì?
“Ìlú” Tuntun Kan
Ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, orílẹ̀-èdè Júù pàdánù ipò ojú rere tó ní lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Mátíù 21:43) Èyí ló mú kí Ọlọ́run fi ohun kan tó ga jùyẹn lọ fíìfíì rọ́pò rẹ̀—ìyẹn ìjọba ọ̀run kan tí yóò mú ọ̀pọ̀ ìbùkún wá bá gbogbo aráyé. (Mátíù 10:7) Bí Jésù ṣe sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ló rí, Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ di èyí tí a pa run lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa. Ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn jẹ́rìí sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Síbẹ̀, ní ti àwọn Kristẹni, ìgbàgbọ́ wọn kò sinmi lórí bóyá àwọn awalẹ̀pìtàn rí àwókù tẹ́ńpìlì ìgbàanì náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Jerúsálẹ́mù mìíràn ni wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn kà, àmọ́ èyí jẹ́ oríṣi ìlú mìíràn.
Lọ́dún 96 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Jòhánù, tó gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ sétí, tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì nímùúṣẹ lójú rẹ̀, ni ó rí ìran yìí: “Mo rí ìlú ńlá mímọ́ náà pẹ̀lú, Jerúsálẹ́mù Tuntun, tí ń ti ọ̀run sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Ohùn kan láti ọ̀run wá sọ pé: “Yóò sì máa bá [aráyé] gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”—Ìṣípayá 21:2-4.
Àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ tí yóò jẹ́ ọba pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run ló para pọ̀ jẹ́ “ìlú” yìí. Gbogbo wọn lápapọ̀ ló jẹ́ ìjọba ti ọ̀run—ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run—èyí tí yóò ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò sì mú ìran èèyàn padà wá sí ìjẹ́pípé lákòókò Ẹgbẹ̀rúndún. (Mátíù 6:10; 2 Pétérù 3:13) Àwọn Júù tó jẹ́ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n jẹ́ ara ẹgbẹ́ yẹn mọ̀ pé, kò sí ohunkóhun tí àwọn ní nínú ètò àwọn Júù tó lè jẹ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ àǹfààní ńlá tí wọ́n ní láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run.
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ipò pàtàkì tó ti dì mú rí nínú ìsìn àwọn Júù, ó gbẹnu sọ fún gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi. Họ́wù, ní ti èyíinì, ní tòótọ́ mo ka ohun gbogbo sí àdánù pẹ̀lú ní tìtorí ìníyelórí títayọ lọ́lá ti ìmọ̀ nípa Kristi Jésù Olúwa mi.”—Fílípì 3:7, 8.
Níwọ̀n bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Òfin Ọlọ́run àti ìṣètò tẹ́ńpìlì náà, ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ká wá máa fojú tẹ́ńbẹ́lú ìṣètò tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá yìí. b (Ìṣe 21:20-24) Ńṣe ni Pọ́ọ̀lù wulẹ̀ ń fi hàn pé ìṣètò Kristẹni ní láárí ju ìgbékalẹ̀ àwọn Júù lọ.
Kò sí àní-àní pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ní ọ̀rúndún kìíní mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ètò àwọn Júù. Níwọ̀n bí ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn sì ti tànmọ́lẹ̀ sí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, àwọn Kristẹni náà lè lóye díẹ̀ lára àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yẹn báyìí. Síbẹ̀, kíyè sí apá ibi tí Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà Tímótì pé kó darí àfiyèsí rẹ̀ sí: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí [àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọ Kristẹni]; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tímótì 4:15.
Ó dùn mọ́ni nínú pé, ẹ̀kọ́ ìwalẹ̀pìtàn nípa Bíbélì ti mú kí òye wa nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì lọ́wọ́ gbòòrò sí i. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni mọ̀ pé, kì í ṣe ohun táwọn èèyàn hú jáde látinú ilẹ̀ ni ìgbàgbọ́ àwọn sinmi lé, kàkà bẹ́ẹ̀, orí Bíbélì, tí i ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ni ìgbàgbọ́ sinmi lé.—1 Tẹsalóníkà 2:13; 2 Tímótì 3:16, 17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kọnsitatáìnì àti ìyá rẹ̀, Helena, nífẹ̀ẹ́ láti mọ àwọn ibi mímọ́ tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù. Obìnrin náà fojú ara rẹ̀ rí ìlú Jerúsálẹ́mù. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìgbà náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.
b Fún sáà kan, àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù ní Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní pa oríṣiríṣi ohun tí Òfin Mósè sọ mọ́, bóyá nítorí àwọn ìdí tó tẹ̀ lé e yìí: Àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni Òfin náà ti wá. (Róòmù 7:12, 14) Òfin náà ti di àṣà láàárín àwọn Júù. (Ìṣe 21:20) Òfin yìí ni ìjọba ilẹ̀ náà ń lò, tí wọ́n bá sì ta kò ó, ó lè gbé àtakò tí kò nídìí dìde sí iṣẹ́ táwọn Kristẹni ń jẹ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Òkè: Jerúsálẹ́mù ní ọdún 1920; ẹyọwó àwọn ará Róòmù tí wọ́n ṣe fún ìlò àwọn Júù, ọdún 43 Sànmánì Tiwa; èso pómégíránétì aláwọ̀ funfun mọ́ òféfèé tó yọ òdòdó, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ni wọ́n ti rí i, ọdún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa
[Àwọn Credit Line]
Ojú ìwé 2 àti 14: Ẹyọwó: Fọ́tò © Israel Museum, Jerusalem; nípa ìyọ̀ǹda Israel Antiquities Authority; èso pómégíránétì: Nípa ìyọ̀ǹda Israel Museum, Jerusalem