Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Kún Fún Ìgbàgbọ́ Látinú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Kan
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Kún Fún Ìgbàgbọ́ Látinú Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Kan
Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bẹ àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wò jákèjádò ayé láti ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n fẹ́ fi òótọ́ inú sún mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́. Ó ti lé lógún ọdún tá a ti ń ṣe àṣeyọrí nínú dídarí irú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba tó wà ní Atlanta, Georgia ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá. Bí a ti jẹ́ òjíṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wa, a ti bá àwọn olè afọ́báǹkì, àwọn jáwójáwó, àwọn apààyàn, àwọn tó ń ṣòwò oògùn olóró, àwọn gbájú-ẹ̀, àtàwọn afipábánilòpọ̀ pàdé. Báwo la ṣe ń ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́?
LÁKỌ̀Ọ́KỌ́, o lè fẹ́ mọ ìgbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ wọ inú ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí àti ohun tó gbé wọn débẹ̀. Ọjọ́ kẹrin, oṣù keje, ọdún 1918 ni. Àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ mẹ́jọ tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò ni wọ́n tì gun àtẹ̀gùn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n fi akọ òkúta kọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba yìí. Tó bá jẹ́ pé ohun tí wọ́n sábàá máa ń ṣe fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n nígbà yẹn ni wọ́n ṣe fún wọn, a jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fí ẹ̀wọ̀n dè wọ́n lọ́wọ́ mọ́ ikùn tí wọ́n sì kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀. Àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé yìí jẹ́ àwọn ọkùnrin tó dáńgájíá nípa tẹ̀mí tí wọ́n mú ipò iwájú láàárín àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Kò sí bí àwọn ọkùnrin yẹn ṣe lè ronú pé kò ní pé ọdún kan káwọn èèyàn tó mọ̀ pé yíyí ìdájọ́ òdodo po lọ́nà tó burú jáì ni fífi tí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n náà jẹ́. Ní March 1919, àwọn òjíṣẹ́ mẹ́jọ náà tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tún gba àtẹ̀gùn kan náà sọ̀ kalẹ̀, láìsí ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀ wọn tí wọ́n sì di òmìnira. Lẹ́yìn náà, nígbà táwọn aláṣẹ pinnu láti tú ẹjọ́ náà ká, wọ́n dá wọn láre wọ́n sì tú wọn sílẹ̀ pátápátá. a
Láàárín ìgbà tí wọ́n fi ń ṣẹ̀wọ̀n ní Atlanta, àwọn Kristẹni ọkùnrin wọ̀nyẹn dá àwọn kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀ wọ́n sì ń darí wọn. Ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́jọ náà, A. H. Macmillan, sọ lẹ́yìn náà pé, igbákejì ọ̀gá ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ti kọ́kọ́ ń ṣe gbọ́n-ńkú gbọ́n-ńkú sí wa, àmọ́ níkẹyìn, ó fìtara sọ pé: “Àgbàyanu gbáà mà làwọn ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ ń kọ́ [àwọn ẹlẹ́wọ̀n] yìí o!”
Lónìí, lóhun tó lé ní ọgọ́rin ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń sèso rere ṣì ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn kan náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn aláṣẹ ti dá àwọn mẹ́ńbà wa yà sọ́tọ̀, tí wọ́n gbé wa sáyé tí wọ́n sì fi ẹ̀bùn dá wa lọ́lá. Àṣeyọrí tó ń wá látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe tún jáde nínú ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Volunteer Today tí Ẹ̀ka Ètò Ìdájọ́ àti ti Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìjọba ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ń tẹ̀ jáde.
Ọ̀kan lára àwọn àǹfààní bíbá àwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ìyípadà ńláǹlà tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìwà wọn. Èyí ti mú kí wọ́n dá àwọn kan sílẹ̀ ṣáájú àkókò tí wọ́n dá fún wọn. Àwọn aṣelámèyítọ́ kan lè rò pé kò sóhun méjì tó ń mú àwọn ẹlẹ́wọ̀n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jùyẹn lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú rẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìrírí tá a ti ní lọ́pọ̀ ìgbà ti fi hàn pé ìyẹn kì í ṣòótọ́. Kò sígbà tínú wa kì í dùn tá a bá gbọ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa ṣì ń bá a lọ láti máa hùwà rere Kristẹni lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti dá wọn sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Díẹ̀ rèé lára ọ̀pọ̀ ìrírí tá a ti gbádùn ní ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n àtayébáyé yìí tó ní àwọn ògiri gíga fíofío.
Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Tó Jẹ́ Ọmọ Orílẹ̀-Èdè Mìíràn Rí Ìrètí
Láwọn ọdún 1980, àwa tá a ń wàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta ní àǹfààní láti ran ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́. Mérìíyìírí gbáà ni díẹ̀ lára àwọn ìyípadà tí wọ́n ṣe jẹ́.
Ẹhànnà paraku ni Raoul b nígbà tó máa fi wọ ẹ̀wọ̀n. Òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan tí wọ́n jọ ń ṣẹ̀wọ̀n ìpànìyàn nígbà yẹn kò níṣẹ́ méjì tí wọ́n ń ṣe ju ìwà ọ̀daràn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn alàgbà tó ràn wọ́n lọ́wọ́ sọ, ìwà burúkú ọwọ́ wọn kò lẹ́lẹgbẹ́. Raoul láwọn ọ̀tá kan tí wọn kì í jọ ríra wọn sójú. Ọkùnrin kan ti lérí pé àfi kóun gbẹ̀mí Raoul, Raoul náà sì ti lérí pé òun á gbẹ̀mí onítọ̀hún. Jìnnìjìnnì bo Raoul nígbà tí wọ́n gbé olórí ọ̀tá rẹ̀ yìí wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta. Ó ti dájú pé ọjọ́-kan-á-jọ́kan, àwọn ọ̀tá ayérayé méjì yìí á fojú gán-án-ní ara wọn, bí wọn ò pàdé lójú ọ̀nà wọ́n á pàdé nílé oúnjẹ tàbí ní ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀wọ̀n náà. Àmọ́ o, lẹ́yìn tí Raoul kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣe àwọn ìyípadà tó kàmàmà nínú ìrònú rẹ̀, nínú ìwà rẹ̀ àti nínú ìrísí rẹ̀. Nígbà táwọn ọkùnrin méjì yìí wá rìn pàdé ara wọn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, ọ̀tá Raoul paraku yìí kò tiẹ̀ dá a mọ̀ mọ́! Bẹ́ẹ̀ ni ìjà tí ì bá ti fa ọ̀gbàrá ẹ̀jẹ̀, èyí tó ti dà bí ẹni pé kò sóhun tó lè yẹ̀ ẹ́ ṣe di èyí tí kò wáyé rárá.
Nígbà tí Raoul pinnu láti fi àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi, ó di dandan láti wá ohun kan tó bójú mu tí wọ́n Lúùkù 3:21, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Lónìí, Raoul ti dòmìnira ó sì ń bá a lọ ní jíjẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni onítara.
lè da omi sí. Àlùfáà ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ràn wọ́n lọ́wọ́, ó bá wọn wá pósí dúdú kan tí wọ́n lè da omi ìbatisí sínú rẹ̀. Wọ́n pọn omi kúnnú pósí náà. Àmọ́ ó dà bí pé Raoul ti tóbi jù fún pósí náà. Àwọn alàgbà méjì ní láti pawọ́ pọ̀ rí i pé wọ́n ri Raoul bọ inú omi pátápátá, níbàámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì béèrè. (Òfin kan tó jáde lọ́dún 1987 láti dá ọ̀pọ̀ ẹlẹ́wọ̀n tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè míì padà sí ilẹ̀ wọn fa arukutu nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó yọrí sí bíba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ tí iná sì ń sọ kẹ̀ù káàkiri, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí orílẹ̀-èdè kan tí kò gbé ìròyìn náà. Wọ́n jí àwọn kan gbé pa mọ́. Àmọ́, àwọn èèyàn kan kò ṣàìmọ̀ nípa àwọn ẹlẹ́wọ̀n onígboyà ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan, tí wọ́n fi ẹ̀mí ara wọn wewu nípa kíkọ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀tẹ̀ tó mú ìwà ipá lọ́wọ́ tó sì gbóná girigiri náà. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń wá sí kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ni wọ́n. Àwọn ọkùnrin yìí, tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀, kíá ni wọ́n á ti bẹ̀rẹ̀ ìjà títí tí ẹ̀mí wọn tàbí ti ẹni tí wọ́n ń bá jà á fi bọ́ kò lọ́wọ́ nínú rẹ̀ rárá, wọn ò kópa nínú ìwà ipá àti ìwà ọ̀bàyéjẹ́ náà. Ẹ̀rí tó hàn kedere mà lèyí o nípa agbára tí Bíbélì ní láti yí àwọn ọ̀daràn padà, kódà, àwọn tó jẹ́ òkú òǹrorò pàápàá láti di Kristẹni tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà!—Hébérù 4:12.
Rírí Ìdáríjì
Ìrírí mìíràn tí kò ṣe é gbàgbé ni ti James. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni tẹ́lẹ̀ kó tó sọ ara rẹ̀ di akúrẹtẹ̀ nípa tẹ̀mí. Èròkerò wọnú rẹ̀ ó sì lọ ṣe èrú ní báńkì. Wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni, ìjọba sì sọ pé kó lọ fẹ̀wọ̀n jura ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta. Ó sọ fún wa lẹ́yìn náà pé: “Kò tíì sígbà kan ní ìgbésí ayé mi tinú mi bà jẹ́ tó yẹn rí.”
Ìgbésí ayé nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n le gan-an. James sọ pé: “Ohun tí dídánìkan wà àti wíwà láìsí ìrètí fojú mi rí kì í ṣe kékeré.” Àmọ́ bó ṣe wà nínú yàrá kótópó tó ti ń ṣẹ̀wọ̀n náà jẹ́ kó túnnú ara rẹ̀ rò dáadáa. Ó sọ pé: “Ohun tó dùn mí jù nígbà
tí mo wà lẹ́wọ̀n kì í ṣe ti ara tó ń ni mí, àmọ́ bí mo ṣe já Baba mi ọ̀run kulẹ̀.” Lẹ́yìn tó ti lo bí oṣù mélòó kan, ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn wá bá James, ó sì sọ fún un pé kó wá síbi tí wọ́n ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. James kọ́kọ́ kọ̀ nítorí ìtìjú. Àmọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin yẹn kò fi í lọ́rùn sílẹ̀, nígbà tó sì yá James lọ sí ìpàdé kan tí wọ́n ń ṣe lọ́jọ́ Sunday.Nígbà tó rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń darí kíláàsì náà ṣe fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, orí rẹ̀ wú. Nǹkan kan tún jọ ọ́ lójú lẹ́yìn ìgbà yẹn. Nítorí ohun tí James ti mọ̀ tó máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀, èrò rẹ̀ ni pé ńṣe ni wọ́n ń sanwó fún gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn tó ń yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ́wọ́. Àmọ́ sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, ó rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò ní ìwé kankan tí wọ́n fi ń gba owó, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò gba kọ́bọ̀ fún ohun tí wọ́n ń ṣe náà.—Mátíù 10:8.
Ara James bẹ̀rẹ̀ sí wà lọ́nà láti lọ sáwọn ìpàdé náà. Ó rí i pé àwọn arákùnrin tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ onínúure wọ́n sì ń fúnni níṣìírí. Ọ̀kan wà nínú àwọn alàgbà yẹn tó nífẹ̀ẹ́ sí jù. James sọ pé: “Ńṣe ni mo máa ń wọ̀nà títí tọ́jọ́ tó máa wá yóò fi pé torí ó máa ń mú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe kedere sí mi; irú ẹ̀mí tó ní sì bẹ̀rẹ̀ sí í ràn mí. Ó jẹ́ kí n rí ìdí tó fi yẹ kí n máa ka Bíbélì kínníkínní láti lè rí kókó tó ń sọ gan-an—kí n lè sọ ọ́ di ti ara mi lóòótọ́, àti èyí tó ṣe pàtàkì jù, kí n lè ní irú èrò inú ti Kristi.”
Kò rọrùn rárá fún James láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lè dárí àwọn àṣìṣe rẹ̀ jì í. Kí ló ràn án lọ́wọ́? Ó sọ pé: “Ìdáríjì Ọlọ́run hàn nínú ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tí wọ́n fara wọn rúbọ yìí ń gbà bá wa lò. c Ohun kan ṣe kedere gan-an: Láìka bí ẹ̀ṣẹ̀ mi ṣe burú jáì tó, ìṣesí arákùnrin náà kò fi hàn nígbà kankan rí bó ti wù kó kéré mọ pé Ọlọ́run kò lè dárí jì mí. Jèhófà kò pa mí tì rárá. Ó rí ìrònúpìwàdà àtọkànwá mi àti bí mo ṣe kọ ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu, tó kún fún èrú yẹn sílẹ̀ pátápátá; ó sì ti bù kún mi lọ́pọ̀lọpọ̀.” Àní, James di ẹni tá a gbà padà sínú ìjọ Kristẹni. Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn ni wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, àtìgbà náà ló sì ti jẹ́ onítara tó ń ṣe déédéé. Sí ìdùnnú ìyàwó rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀, ó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí ó sì sọ àsọyé rẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí.
Wíwá Ọ̀nà Rí
Ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 la pàdé Johnny. Ìdílé rẹ̀ ti kọ́kọ́ ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́ nígbà kan, àmọ́ kò séyìí tó jinná dénú nípa tẹ̀mí nínú wọn ní gbogbo ìgbà tí Johnny fi wà lọ́mọdé, tó nílò ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí àti ìwà rere. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Johnny di ẹni tó ń gbé ìgbé ayé ọ̀daràn. Wọ́n dájọ́ fún un pé kó lọ ṣẹ̀wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ìjọba tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Atlanta. Láàárín àkókò tó fi ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀, ó gbọ́ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe níbẹ̀ ó sì pinnu láti wá.
Níbẹ̀rẹ̀, agbára káká ni Johnny fi lè kàwé. Síbẹ̀, ó ní ìtara láti túbọ̀ ní ìmọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi débi pé ó pinnu láti mọ̀wéé kà lọ́nà tó já gaara. (Jòhánù 17:3) Kíláàsì wa sábàá máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n lórí kókó yìí, pàápàá tó bá di ibi kéèyàn lóye ohun tó ń kà tàbí kéèyàn lè kàwé lọ́nà tó já gaara. Johnny kò fi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣeré rárá débi pé ńṣe làwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń wò ó pé àpẹẹrẹ ohun tó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gidi jẹ́ ló jẹ́.
Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, wọ́n gbé Johnny lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba ní Talladega, Alabama, fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n máa ń ṣe lórí oògùn olóró. Bó ṣe débẹ̀, kíá ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe níbẹ̀. Ó ń ṣe déédéé gan-an títí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì dá a sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, Johnny kò fi àkókò ṣòfò, kíá ló wá àwọn Ẹlẹ́rìí rí ní ìlú rẹ̀ kékeré. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi tẹ́wọ́ gbà á tó sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ bẹ́ẹ̀ ló sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.
Ìtara ọkàn àti ìfẹ́ tí Johnny ní fún òtítọ́ Bíbélì tún ti ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa kópa kíkún nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Orísun okun àti ìrànwọ́ gidi ló jẹ́ fún ìyá rẹ̀. Àìpẹ́ yìí ló ṣèrìbọmi láti fi àmì ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn sí Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ń tẹ̀ síwájú ní fífi ìtara kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.
Ọ̀pọ̀ Yanturu Ìkórè
Láàárín ogún ọdún sẹ́yìn, ó ju ogójì àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta lọ tá a ti ràn lọ́wọ́ láti di òjíṣẹ́ tá a batisí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà; àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì tó ju àádọ́rùn-ún lọ tún ti jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n míì ti ṣèrìbọmi lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tàbí lẹ́yìn tí wọ́n gbé wọn lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n mìíràn.
Àwa tá a ń ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àtayébáyé yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó fi òótọ́ inú ronú pìwà dà lọ́wọ́ kún fún ọpẹ́ pé a lè sìn ní apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí. (Ìṣe 3:19; 2 Kọ́ríńtì 7:8-13) Nínú àyíká ọgbà ẹ̀wọ̀n tó kún fún ẹ̀rù yìí pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ lórí odi tàwọn tìbọn wọn lọ́wọ́, àwọn géètì tó ń báná ṣiṣẹ́, àti àwọn wáyà tó kún fún aṣóró, ayọ̀ kúnnú wa gan-an ni, ìyàlẹ́nu ló sì ń jẹ́ fún wa láti rí àwọn ọ̀daràn paraku tí wọ́n ń dẹni tó yí ìgbésí ayé wọn padà pátápátá tí wọ́n sì ń di olóòótọ́ èèyàn láàárín ìlú àti olùjọsìn Ọlọ́run tó dúró ṣinṣin.—1 Kọ́ríńtì 6:9-11—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹjọ́ yẹn, wo ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom (Gèésì), ojú ìwé 647 sí 656, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
b A ti yí orúkọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n padà.
c Ilé Ìṣọ́ April 15, 1991, rọ àwọn Kristẹni alàgbà láti ṣe ìbẹ̀wò aláàánú sí ọ̀pọ̀ àwọn tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Ète irú ìbẹ̀wò bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ láti fún wọn níṣìírí láti padà sọ́dọ̀ Jèhófà.—2 Kọ́ríńtì 2:6-8.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
“Ẹ Ti Ṣe Àwọn Ọ̀rẹ́ Mi Kan Tí Mo Fẹ́ràn Jù Lọ Lálejò Níbí Rí”
NÍ OṢÙ April, 1983, Frederick W. Franz tó wà lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó pẹ́ tó ti ń hára gàgà láti bẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí wò. Bó ṣe wọlé báyìí, ló bá kígbe sókè sí ẹ̀ṣọ́ tó jókòó lẹ́nu ọ̀nà pé: “Mo fẹ́ kó o mọ̀ pé ẹ ti ṣe àwọn ọ̀rẹ́ mi kan tí mo fẹ́ràn jù lọ lálejò níbí rí!” Àsọdùn kọ́ o, gbólóhùn yìí ya ẹ̀ṣọ́ náà lẹ́nu. Kí tiẹ̀ ni Franz ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an?
Ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n láìyẹ fún Joseph F. Rutherford àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ méje fún ẹ̀sùn ìdìtẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Rutherford àti Franz wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n sì jọ ṣiṣẹ́ pọ̀. Báyìí, lóhun tó ti lé ní ogójì ọdún lẹ́yìn ikú Rutherford, tí Franz alára sì ti ń tó ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, inú rẹ̀ dùn láti ṣèbẹ̀wò sí ibi tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ṣẹ̀wọ̀n ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn. Kò sí àní-àní pé ọkàn rẹ̀ á lọ síbi iṣẹ́ tí Rutherford àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti ṣe nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Iṣẹ́ wo ni?
Bí Rutherford àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ti ń wọlé, igbákejì wọ́dà tó wà níbẹ̀ sọ fún wọn pé: “A máa wá iṣẹ́ tẹ́ ẹ máa ṣe fún un yín. Ó yá, irú iṣẹ́ wo lẹ mọ̀ ọ́n ṣe?”
Ni A. H. Macmillan, ọ̀kan lára àwọn mẹ́jọ náà bá dáhùn pé: “Ọ̀gá, mi ò ní iṣẹ́ méjì tí mo ń ṣe láyé mi ju iṣẹ́ ìwàásù lọ. Ṣé ẹ máa ń ṣe irú ẹ̀ níbí?”
“Rárá sà o! Torí iṣẹ́ ìwàásù ni ẹ ṣe di èrò ẹ̀wọ̀n, ẹ sì jẹ́ kí n sọ fún un yín, kò sóhun tó ń jẹ́ pé ẹ ń wàásù níbí.”
Ọ̀sẹ̀ bí i mélòó kan kọjá. Wọ́n ní kí gbogbo ẹlẹ́wọ̀n máa lọ ṣe ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì lọ́jọ́ Sunday, àwọn tó bá wù sì lè dúró fún ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi lẹ́yìn náà. Làwọn ọkùnrin mẹ́jọ yìí bá pinnu láti dá kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiwọn sílẹ̀, èyí tí wọ́n ń pín dídarí rẹ̀ láàárín ara wọn. Rutherford sọ lẹ́yìn ìgbà yẹn pé: “Àwọn kan tó fẹ́ mọ ohun tá a ń ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wá, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn ṣáà ń wá sí i.” Kò pẹ́ kò jìnnà, àwùjọ tó jẹ́ mẹ́jọ péré tẹ́lẹ̀ di àádọ́rùn-ún!
Báwo ni kíláàsì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ṣe rí lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n ọ̀hún? Ẹlẹ́wọ̀n kan sọ pé: “Ọmọ ọdún méjìléláàádọ́rin ni mí, ká ní mi ò wẹ̀wọ̀n ni, ǹ bá máà gbọ́ òtítọ́ yìí. Fún ìdí yìí, inú mi dùn pé mo wá ṣẹ̀wọ̀n lọ́gbà yìí.” Òmíràn sọ pé: “Ó dùn mí pé mo ti ń lọ; ọjọ́ tí wọ́n dá fún mi ti fẹ́ pé . . . Ṣé ẹ lè sọ ibi tí mo ti lè rí àwọn èèyàn bíi tiyín fún mi bí mo bá lọ tán?”
Lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí wọ́n dá àwọn ọkùnrin mẹ́jọ náà sílẹ̀, wọ́n gba lẹ́tà kan tó mórí èèyàn wú látọ̀dọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ti ń wá sí kíláàsì wọn. Ó kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ ti jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ láti di ọkùnrin kan tó máa túbọ̀ wúlò tá á sì túbọ̀ ní láárí, tí irú ẹ̀ bá lè ṣeé ṣe fún òkú èèyàn bíi tèmi yìí. . . . tí ìgbésí ayé ti sọ dìdàkudà. Mo nílò ìrànlọ́wọ́, mo nílò ẹ̀ gan-an ni, èmi nìkan lọ̀rọ̀ yìí yé jù, àmọ́ màá gbìyànjú láti já ara mi gbà tó bá jẹ́ ohun tó gbà nìyẹn, kí n lè so èso irúgbìn tẹ́ ẹ ti gbìn sínú mi ní kíkún, kó lè jẹ́ pé kì í ṣe ara mi nìkan ni màá ràn lọ́wọ́ àmọ́ àtàwọn tó yí mi ká pẹ̀lú. Èyí lè ṣàjèjì létí yín, pé ó wá látọ̀dọ̀ irú èèyàn bí èmi yìí, àmọ́, bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe rí gẹ́lẹ́ nínú mi lọ́hùn-ún ni mo ṣe sọ ọ́.”
Lónìí, tí ọgọ́rin ọdún ti kọjá dáadáa lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń gbin àwọn irúgbìn òtítọ́ Bíbélì ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Atlanta, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń ṣe ní ọ̀pọ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n mìíràn.—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.