Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ń Mú Nǹkan Mọ́ra Tó?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ń Mú Nǹkan Mọ́ra Tó?
‘BÍ Ó TILẸ̀ JẸ́ PÉ ỌLỌ́RUN NÍ ÌFẸ́ LÁTI FI ÌRUNÚ RẸ̀ HÀN GBANGBA, KÍ Ó SÌ SỌ AGBÁRA RẸ̀ DI MÍMỌ̀, Ó FI Ọ̀PỌ̀ ÌPAMỌ́RA FÀYÈ GBA ÀWỌN OHUN ÈLÒ ÌRUNÚ TÍ A MÚ YẸ FÚN ÌPARUN.’—RÓÒMÙ 9:22.
ÌTÀN látòkèdélẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run ti fara da ìwà búburú tó pọ̀ púpọ̀ àti ìwà ibi tó gogò. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn, Jóòbù figbe bọnu pé: “Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó, tí wọ́n darúgbó, tí wọ́n sì di ẹni tí ó pọ̀ ní ọlà pẹ̀lú? Ọmọ wọn ti fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in pẹ̀lú wọn ní ìṣojú wọn, àti àwọn ọmọ ìran wọn lójú wọn. Ilé wọn wà ní àlàáfíà, láìsí ìbẹ̀rùbojo, ọ̀pá Ọlọ́run kò sì sí lára wọn.” (Jóòbù 21:7-9) Àwọn mìíràn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, bíi Jeremáyà tún fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí bó ṣe dà bí ẹni pé Ọlọ́run kò ṣú já ọ̀ràn àwọn ẹni ibi.—Jeremáyà 12:1, 2.
Kí lèrò tìrẹ? Ṣé o ń ṣe kàyéfì nípa bí Ọlọ́run kò ṣe tíì ṣe nǹkankan sí ìwà ibi? Ṣé ó máa ń dà bí ẹni pé kí Ọlọ́run ṣe pá-pà-pá kó sì palẹ̀ àwọn ẹni ibi mọ́ ráú? Gbé ohun tí Bíbélì sọ yẹ̀ wò nípa ibi tí Ọlọ́run lè gba nǹkan mọ́ra dé àti bó ṣe rí bẹ́ẹ̀.
Kí Ló Mú Kí Ọlọ́run Máa Mú Nǹkan Mọ́ra?
Ohun tó yẹ ká kọ́kọ́ béèrè ni pé: Kí ló dé tí Ọlọ́run tó jẹ́ pé ìlànà òdodo rẹ̀ ló ga jù lọ, fi fàyè gba ìwà búburú gan-an? (Diutarónómì 32:4; Hábákúkù 1:13) Ṣé èyí túmọ̀ sí pé kò sóhun tó kàn án kan ìwà ibi ni? Rárá o! Ronú nípa àkàwé tó wà nísàlẹ̀ yìí: Ká sọ pé oníṣẹ́ abẹ kan wà tí kì í ka àwọn ìlànà tó ṣe kókó nípa ìmọ́tótó sí tó sì tún máa ń kó àwọn aláìsàn sí ìrora tó pọ̀. Ká ní ilé ìwòsàn kan ló ti ń ṣiṣẹ́, ṣé lójú ọgán kọ́ ni wọ́n máa lé e dànù? Àmọ́ àwọn ipò kan wà tó lè máà mú kí wọ́n rinkinkin tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Fún àpẹẹrẹ, bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ bóyá lójú ogun, ṣé kò ní bọ́gbọ́n mu láti fàyè gba oníṣẹ́ abẹ tó ń ṣiṣẹ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe é nígbà àtijọ́, bóyá tó tiẹ̀ ń lo àwọn irinṣẹ́ àtàwọn ohun èèlò iṣẹ́ abẹ táwọn èèyàn ò ní jẹ́ kó lò ká ní kì í ṣe torí ọ̀ràn pàjáwìrì tó ṣẹlẹ̀ ni?
Lọ́nà kan náà lónìí, Ọlọ́run ń fi sùúrù fàyè gba àwọn nǹkan tí kò bá a lára mu rárá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó kórìíra ìwà ibi, ó ń fàyè gbà á kó máa báa lọ fún àkókò díẹ̀. Àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, èyí pèsè àkókò láti mú kí àríyànjiyàn ńlá tí ìwà ọ̀tẹ̀ Sátánì nínú ọgbà Édẹ́nì dá sílẹ̀ yanjú pátápátá. Àríyànjiyàn náà dá lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń ṣàkóso bóyá ó jẹ́ èyí tí ó tọ́, tí Ọlọ́run sì lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Bákan náà, bó ṣe ń rọ́jú fara da ìwà ibi ń fún àwọn tó ń hùwà ibi láyè àti àǹfààní láti yí padà.
Ọlọ́run Tó Láàánú, Tó Tún Ní Sùúrù
Àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Sátánì láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Kò sẹ́ni tó máa yẹ Ọlọ́run lọ́wọ́ wò ká ló pa wọ́n run lójú ẹsẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fi hàn pé òun láàánú Róòmù 5:12; 8:20-22.
òun sì ní sùúrù, nínú ìfẹ́ rẹ̀, ó fún wọn láyè láti bímọ. Àmọ́, inú ẹ̀ṣẹ̀ la gbé bí àwọn ọmọ wọ̀nyí, àti gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tó ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ wọn.—Ọlọ́run pète láti mú ẹ̀dá ènìyàn kúrò nínú ipò ègbé yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Àmọ́, lọ́wọ́ táa ṣì wà yìí, Ọlọ́run ń fi ọ̀pọ̀ àánú àti sùúrù hàn sí wa torí ó mọ bí àìpé táa jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ṣe ń nípa lórí wa. (Sáàmù 51:5; 103:13) Ó “pọ̀ yanturu nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́” ó sì múra tán kódà, ó fẹ́ láti “dárí jì lọ́nà títóbi.”—Sáàmù 86:5, 15; Aísáyà 55:6, 7.
Àmúmọ́ra Ọlọ́run Ní Ààlà
Àmọ́ ṣá o, bí Ọlọ́run bá jẹ́ kí ìwà ibi máa báa lọ títí ayé, kò ní fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní jẹ́ ohun tó bójú mu. Kò sí bàbá onífẹ̀ẹ́ tó máa lajú rẹ̀ sílẹ̀ ṣáá tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ á mọ̀ọ́mọ̀ máa fìyà jẹ àwọn mẹ́ńbà ìdílé tó kù tí kò sì ní ṣe ohunkóhun sí i. Nítorí náà, gbogbo bí Ọlọ́run ṣe ń mú sùúrù yìí, ó tún ní àwọn ànímọ́ mìíràn bí ìfẹ́, ọgbọ́n, àti ìdájọ́ òdodo tó máa fi pẹ̀kún rẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ní gbàrà tó bá mú ète rẹ̀ ṣẹ nípa ohun tó torí rẹ̀ ń ní ìpamọ́ra yìí, àmúmọ́ra náà á dópin.—Róòmù 9:22.
Kedere ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn. Lákòókò kan, ó sọ pé: “Ní àwọn ìran tí ó ti kọjá [Ọlọ́run] gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa bá a lọ ní ọ̀nà wọn.” (Ìṣe 14:16) Lákòókò mìíràn, Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa bí “Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀ bẹ́ẹ̀” dá fún àwọn tó ti ṣàìgbọràn sí òfin àti ìlànà rẹ̀. Pọ́ọ̀lù tún ń bá a lọ pé: “Nísinsìnyí, [Ọlọ́run] ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà.” Èé ṣe? “Nítorí pé ó ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo.”—Ìṣe 17:30, 31.
Jàǹfààní Báyìí Nínú Àmúmọ́ra Ọlọ́run
Nígbà náà, ó dájú pé kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ lérò pé òun lè mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìka òfin Ọlọ́run sí kó sì wá ní kí Ọlọ́run dárí ji òun kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ àbájáde àwọn ohun tó ti ṣe. (Jóṣúà 24:19) Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ọ̀pọ̀ ló ronú pé àwọn lè ṣe bẹ́ẹ̀. Wọn ò yí padà. Wọn kò jàǹfààní látinú ohun tó mú kí Ọlọ́run ní àmúmọ́ra àti sùúrù. Ọlọ́run kò jẹ́ kí ìwà búburú wọn máa báa lọ títí.—Aísáyà 1:16-20.
Bíbélì fi yéni pé bí ẹnì kan bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ ìkẹyìn tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ wá, ó gbọ́dọ̀ “ronú pìwà dà,” ìyẹn ni pé, kó mọ̀ pé aláìpé àti ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun níwájú Ọlọ́run kó sì fi tọkàntọkàn kọ ìwà búburú sílẹ̀. (Ìṣe 3:19-21) Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run á wá dárí jì í lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi. (Ìṣe 2:38; Éfésù 1:6, 7) Tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, ó máa mú gbogbo ohun búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kúrò. ‘Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun’ á wá wà, níbi tí kò ti ní fàyè gba “awọn ohun elo ibinu ti a ṣe fun iparun.” (Ìṣípayá 21:1-5; Róòmù 9:22, Bibeli Mimọ) Ẹ wo nǹkan bàǹtà-banta tó máa wá tìdí àmúmọ́ra Ọlọ́run tó láàlà jáde!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Ọlọ́run gba Ádámù àti Éfà láyè láti bímọ