Adìyẹ—Ó Gbajúmọ̀, Ó sì Pọ̀ Rẹpẹtẹ
Adìyẹ—Ó Gbajúmọ̀, Ó sì Pọ̀ Rẹpẹtẹ
LÁTỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KẸ́ŃYÀ
ÀFÀÌMỌ̀ ni adìyẹ kò ní jẹ́ irú ẹyẹ tó tíì pọ̀ jù lọ láyé. Àwọn kan fojú bù ú pé iye rẹ̀ ju bílíọ̀nù mẹ́tàlá lọ! Bákan náà, ẹran rẹ̀ gbajúmọ̀ débi pé, ó lé ní bílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gbọ̀n kìlógíráàmù táwọn èèyàn ń jẹ lọ́dọọdún. Ní àfikún sí i, adìyẹ àgbébọ̀ máa ń yé ẹyin tó tó ẹgbẹ̀ta bílíọ̀nù lọ́dún jákèjádò ayé.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé, adìyẹ pọ̀ yanturu, owó pọ́ọ́kú sì ni wọ́n ń tà wọ́n. Láwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n ṣèlérí fún àwọn olùdìbò Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé, tí wọ́n bá lè dìbò yan ẹnì kan báyìí sípò, kò sẹ́ni tí apá rẹ̀ kò ní ká adìyẹ láti jẹ. Àmọ́ lónìí, adìyẹ kì í tún ṣe oúnjẹ àwọn olówó tàbí pé kìkì ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ lapá wọ́n ká a bíi tìgbà yẹn mọ́. Báwo ni ẹyẹ tó yàtọ̀ nínú gbogbo àwọn tó kù yìí ṣe di èyí tó wọ́pọ̀ gan-an tó sì gbayì bẹ́ẹ̀? Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìyà ń jẹ ń kọ́? Ṣé ọ̀nà kankan wà táwọn náà fi lè pín nínú ọ̀pọ̀ yanturu yìí?
Ìtàn Adìyẹ
Adìyẹ jẹ́ àtọmọdọ́mọ ẹyẹ ẹgàn pupa kan ní Éṣíà. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn ṣàwárí pé adìyẹ á rọrùn láti sìn nínú ilé. Kódà, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn, Jésù Kristi tọ́ka sí bí àgbébọ̀ adìyẹ ṣe máa ń ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀ táá sì pa wọ́n mọ́ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀. (Mátíù 23:37; 26:34) Lílò tó lo irú àpèjúwe bẹ́ẹ̀ fi hàn pé kò sẹ́ni tí kò mọ ẹyẹ yìí dáadáa. Àmọ́ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni mímú adìyẹ àti ẹyin rẹ̀ jáde lọ́pọ̀ yanturu ṣẹ̀ṣẹ̀ di ohun tí wọ́n fi ń ṣòwò.
Lónìí, kò sí ohun abìyẹ́ agbéléjẹ̀ kankan ti ẹran rẹ̀ gbayì tó ẹran adìyẹ. Ọ̀kẹ́ àìmọye ilé ni wọ́n ti ń sin adìyẹ—títí kan àwọn èèyàn tó ń gbé láàárín ìlú—fún jíjẹ àti fún títà. Ká sòótọ́, ṣàṣà ohun ọ̀sìn ló lè ṣọmọọre bíi ti adìyẹ ní oríṣiríṣi àgbègbè tó yàtọ̀ síra. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti ṣàwárí oríṣi àwọn adìyẹ kan pàtó tí wọ́n ń sìn nítorí pé wọ́n bá ojú ọjọ́ wọn àti ohun tí wọ́n nílò mu. Díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí ni: Australorp ti Ọsirélíà; Leghorn tó gbajúgbajà ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àmọ́ tó ṣẹ̀ wá láti Mẹditaréníà; New Hampshire, Plymouth Rock, Rhode Island Red, àti Wyandotte, tí wọ́n ń sin gbogbo
wọn ni Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà; bákan náà tún ni Cornish, Orpington, àti Sussex, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.Àwọn ọ̀nà ìtọ́jú ohun ọ̀sìn tó ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti mú kí iṣẹ́ adìyẹ sísìn jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ àgbẹ̀ tó kẹ́sẹ járí jù lọ. Ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn àgbẹ̀ ní ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bọ́ adìyẹ àti bí wọ́n ṣe ń kó wọn sínú àgò, wọ́n sì ní àwọn ìlànà sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ń lò fún dídènà àrùn. Ọ̀pọ̀ ló ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń lò láti mú kí adìyẹ pọ̀ yanturu yìí pé ó burú. Àmọ́, ìyẹn ò dá àwọn àgbẹ̀ dúró láti máa bá a lọ láti ṣàwárí àwọn ọ̀nà mìíràn tó túbọ̀ gbéṣẹ́ tó máa mú kí àwọn adìyẹ máa pọ̀ sí i. Àwọn ìlànà òde òní ti mú kó ṣeé ṣe báyìí fún ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo láti máa bójú tó adìyẹ tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] sí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000]. Kì í gba àwọn adìyẹ náà ju oṣù mẹ́ta lọ kí wọ́n tóó tóbi tó fún títà lọ́jà. a
Ọbẹ̀ Ni
Bóo bá lọ sí òtẹ́ẹ̀lì èyíkéyìí, ilé àrójẹ tàbí àwọn ibi tí wọ́n ti ń ta oúnjẹ lábúlé, ó ṣọ̀wọ́n kóo máà rí ẹran adìyẹ lára ohun tí wọ́n ní fún títà. Àní, ọ̀pọ̀ ilé àrójẹ tó wà káàkiri ayé ló mọwọ́ sísè rẹ̀. Àwọn àgbègbè kan wà tó jẹ́ pé adìyẹ ṣì ni ààyò wọn lásìkò ayẹyẹ pàtàkì. Wọ́n ti ṣàwárí oríṣiríṣi ọ̀nà fífanimọ́ra tí wọ́n fi ń se adìyẹ láwọn ilẹ̀ kan, irú bí ilẹ̀ Íńdíà. Ọbẹ̀ ata tí wọ́n fi adìyẹ sè, lal murgi; adìyẹ tí wọ́n ya wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, kurgi murgi; àti adìyẹ tí wọ́n rì sínú atalẹ̀, adrak murgi, àjẹpọ́nnulá ni gbogbo wọn!
Kí ló mú kí adìyẹ gbayì bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, ṣàṣà ọbẹ̀ ló ṣeé sè lóríṣiríṣi ọ̀nà bí ọbẹ̀ adìyẹ. Báwo lo ṣe fẹ́ ẹ? Ṣé díndín ni, àyangbẹ, ìmóòyò, tàbí èyí tí wọ́n sè mọ́bẹ̀? Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìwé oúnjẹ sísè tóo máa ṣí tí o ò ní í rí oríṣiríṣi ọ̀nà tóo lè fi se adìyẹ tí wàá fi jẹ ẹ́ ní àjẹpọ́nnulá.
Nítorí pé adìyẹ pọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, kò jẹ́ kí owó rẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ wọ́n. Ọ̀rẹ́ àwọn tó mọ̀ nípa oúnjẹ tó ń ṣara lóore tún ni adìyẹ, nítorí àwọn
èròjà protein, fítámì àti àwọn mineral tó ṣe pàtàkì fún ara tó wà nínú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀rá tó wà lára adìyẹ kò pọ̀ rárá.Bíbọ́ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Gòkè Àgbà
Àmọ́ kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè ló ń rí adìyẹ jẹ lọ́pọ̀kúyọ̀kú o. Èyí kì í ṣe ọ̀ràn kékeré rárá tí a bá wo ìròyìn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe kan fún Àjọ Tó Ń Rí sí Iṣẹ́ Ọ̀gbìn Lọ́nà Ti Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì àti Ti Iṣẹ́ Ẹ̀rọ, èyí tó sọ pé: “Iye àwọn olùgbé ayé ṣeé ṣe kó ròkè kọjá bílíọ̀nù méje àtààbọ̀ tó bá fi máa di ọdún 2020 . . . Síbẹ̀, èyí tó pọ̀ jù lọ (ìpín márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún) lára ìbísí yìí ni wọ́n fojú bù pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.” Ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ wá gbàrònú gan-an nígbà táa bá wò ó pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rin mílíọ̀nù èèyàn ni àìjẹunre-kánú ń yọ lẹ́nu!
Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ògbóǹkangí wòye pé adìyẹ lè ṣe púpọ̀ láti pèsè oúnjẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tébi ń pa yìí kí ó sì pèsè owó táwọn àgbẹ̀ nílò lójú méjèèjì fún wọn. Ìṣòro tó wá wà níbẹ̀ ni pé, sísin adìyẹ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ kò rọrùn rárá fún àwọn àgbẹ̀ tó tálákà. Ìdí kan ni pé, láwọn ilẹ̀ tó tòṣì gan-an, orí ilẹ̀ kékeré tí kò tó nǹkan tàbí lẹ́yìnkùlé ilé ni wọ́n ti sábàá máa ń sin adìyẹ. Ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì rèé, ekukáká ni wọ́n fi máa ń rí ibi kó wọn sí tí jàǹbá ò fi ní í ṣe wọ́n. Tí ilẹ̀ bá mọ́, wọ́n máa ń ṣí àwọn adìyẹ sílẹ̀ láti jẹ̀ lọ kí wọ́n sì wá oúnjẹ kiri, tí wọ́n á sì padà sílé lálẹ́ láti wọ̀, nígbà mìíràn sórí igi tàbí sínú àgò onírin.
Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ adìyẹ tí wọ́n ń sìn lọ́nà yẹn ló máa ń kú dànù—àrùn kọ́ọ́lí máa ń pa àwọn kan, tí èèyàn tàbí ẹranko á sì pa àwọn mìíràn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àgbẹ̀ ni kò mọ bí wọ́n ṣe lè ṣètọ́jú wọn tàbí kí owó máà sí tó láti bọ́ wọn dáadáa, wọ́n lè máà ní ibi tó dára láti kó wọn sí tàbí láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àrùn. Ìdí rèé tí wọ́n fi dá àwọn ètò kan sílẹ̀ láti dá àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lẹ́kọ̀ọ́. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Àjọ Tí Ń Rí sí Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè bẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́dún márùn-ún kan “láti ṣe àwọn òtòṣì tó wà ní àwọn àrọko ilẹ̀ Áfíríkà láǹfààní nípa mímú kí ọ̀sìn adìyẹ túbọ̀ pọ̀ sí i.”
Kò sẹ́ni tó tíì lè sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde irú àwọn ìgbésẹ̀ tí wọ́n fi tinútinú gbé kalẹ̀ yìí. Ó ṣe pàtàkì pé, kí àwọn tó ń gbé láwọn orílẹ̀-èdè tó ti rọ́wọ́ mú ronú lórí kókó náà pé, ekìrí adìyẹ kan tí kò jẹ́ nǹkankan lójú tiwọn lè jẹ́ oúnjẹ àwọn olówó lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ayé. Fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà pé ‘kò sẹ́ni tí apá rẹ̀ kò ní ká adìyẹ láti jẹ’ lè dà bí àlá tí kò dájú pé ó máa ṣẹ ní lọ́wọ́lọ́wọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún ń sin adìyẹ nítorí ẹyin wọn, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ni wọ́n ń sìn fún jíjẹ.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìṣọ́ra Tó Yẹ Ká Lò Bí A Bá Ń Kun Adìyẹ Tútù
“Adìyẹ tí wọn ò tíì sè lè ní àwọn kòkòrò tó lè pani lára nínú, irú bíi bakitéríà kan tó ń jẹ́ salmonella, tó jẹ́ májèlé fún èèyàn. Rí i pé o fọ ọwọ́ rẹ, orí ibi tóo ti ń gé e, pẹ̀lú ọ̀bẹ àti àdá tóo lò nínú omi ọṣẹ tó gbóná kóo tó fọwọ́ kan adìyẹ náà àti lẹ́yìn tóo bá ṣe tán. Ó tún bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa gé e lórí ohun tó máa ṣeé fi omi gbígbóná fọ̀ . . . tó bá sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kìkì gígé ẹran adìyẹ tútù nìkan lèèyàn á máa lò ó fún. Jẹ́ kí adìyẹ tó ti dì yòrò tán pátápátá kóo tó bẹ̀rẹ̀ sí í sè é.”—The Cook’s Kitchen Bible.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀yà adìyẹ tó wà ni “Leghorn” Funfun, Adìyẹ Ẹgàn Aláwọ̀ Eérú, “Orpington,” “Polish,” àti “Sussex” Aláwọ̀ Tó-tòò-tó
[Credit Line]
Gbogbo wọn àyàfi Leghorn Funfun: © Barry Koffler/www.feathersite.com
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Akitiyan ń lọ lọ́wọ́ láti ran àwọn àgbẹ̀ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀sìn adìyẹ túbọ̀ pọ̀ sí i
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìpín àádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún adìyẹ tí wọ́n ń sìn níbẹ̀ ló jẹ́ pé jíjẹ ló wà fún