Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkúnya Omi Ní—Mòsáńbíìkì Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Bójú Tó Àwọn Tí Àjálù Náà Bá

Àkúnya Omi Ní—Mòsáńbíìkì Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Bójú Tó Àwọn Tí Àjálù Náà Bá

Àkúnya Omi Ní—Mòsáńbíìkì Bí Àwọn Kristẹni Ṣe Bójú Tó Àwọn Tí Àjálù Náà Bá

LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ MÒSÁŃBÍÌKÌ

NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọdún tó kọjá, ó dun àwọn tó ń wo tẹlifíṣọ̀n wọra láti rí àwọn èèyàn Mòsáńbíìkì tí wọ́n dìrọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀ka igi bí àkúnya omi ti ń fẹ́ gbé wọn lọ. Wọ́n rí obìnrin kan tó bímọ lórí igi tí hẹlikóbítà kan sì gbé òun àti ọmọ rẹ̀ lọ síbi tí kò séwu. Àmọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún wà níbẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, táwọn kan tiẹ̀ ń bá ejò gbé kó tó di pé omi náà rọlẹ̀ tàbí kí hẹlikóbítà tó wá gbé wọ́n kúrò níbẹ̀.

Àjálù ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ nígbà tí òjò ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ní Maputo tí í ṣe olú-ìlú Mòsáńbíìkì. Láàárín wákàtí díẹ̀, gbogbo àgbègbè náà ti di alagbalúgbú omi. Àwọn ibì kan wà tí omi kún dé orí àwọn òrùlé. Àwọn ojú pópó yí padà di odò tó ń ta omi lókìtì. Omi ti gbẹ́ kòtò jíjìn káàkiri, bẹ́ẹ̀ ló tún gbá àwọn ilé, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àti ọ̀pọ̀ nǹkan míì lọ. Àṣé ohun tó wà lẹ́yìn ọ̀fà ṣì ju òje lọ.

Òjò yìí rọ̀-rọ̀-rọ̀ kò dáwọ́ dúró o, ó bo gbogbo àgbègbè gúúsù orílẹ̀-èdè náà mọ́lẹ̀ pátápátá. Òjò tún rọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tò wà nítòsí bíi Gúúsù Áfíríkà, Zimbabwe, àti Botswana. Nítorí pé àwọn odò Incomati, Limpopo, àti Zambezi máà ń ṣàn láti àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí wọ́n sì máa ń gba Mòsáńbíìkì kọjá lọ sínú òkun, ọ̀pọ̀ àgbègbè gbígbòòrò ní Mòsáńbíìkì ló bà jẹ́ nígbà táwọn odò náà kún àkúnya. Bí àwọn Kristẹni ṣe bójú tó ara wọn lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ búburú yìí jẹ́ ìtàn tí ń fún ìgbàgbọ́ lókun.

Ṣíṣírò Iye Àdánù Ìbẹ̀rẹ̀

Ní February 9 ọdún tó kọjá, àwọn aṣojú méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Maputo lọ ṣèbẹ̀wò sí àríwá orílẹ̀-èdè náà. Ní nǹkan bí aago mẹ́sàn án òwúrọ̀, wọ́n gba ìlú Xinavane kọjá, níbi tí Odò Incoluane ti kún àkúnya. Ni wọ́n bá pinnu láti máa lọ sí Xai-Xai, tí í ṣe olú ìlú fún ẹkùn Gaza. Àmọ́, wọ́n wòye pé kò sí àmì wàhálà ládùúgbò Chókwè, níbi tí omíyalé tó burú jáì ti máa ń ṣẹlẹ̀ lákòókò ìjì. Nítorí náà, wọ́n pinnu láti padà sí Maputo.

Àmọ́, bí wọ́n ti ń sún mọ́ Xinavane nígbà tí wọ́n ń padà bọ̀, àwọn ọlọ́pàá dá wọn dúró. Àwọn ọlọ́pàá náà kìlọ̀ fún wọn pé: “Àkúnya omi tó ń bọ̀ láti Gúúsù Áfíríkà ti dé, ó sì ti ba títì tó so orílẹ̀-èdè náà pa pọ̀ jẹ́. Kò sí bọ́ọ̀sì tàbí ọkọ̀ akẹ́rù tó lè kọjá.” Ọ̀nà kan náà tí wọ́n gbà kọjá láàárọ̀ lomi ti wá bò mọ́lẹ̀ pátápátá yìí! Níwọ̀n bí àwọn odò tó wà ní apá àríwá ti tún bẹ̀rẹ̀ sí í kún, àgbègbè náà ti ya kúrò lára ìyókù orílẹ̀-èdè náà.

Àwọn arákùnrin méjì náà pinnu láti sùn sí Macia tó wà nítòsí. Nígbà tó dòru ọ̀ràn náà burú sí i. Gbogbo ìlú Xinavane lómi bò pátápátá tàwọn èèyàn sì pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní ráúráú. Wọn ṣètò láti ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè náà lọ́wọ́ láti dé ibi Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Macia, níbi tí wọ́n ṣètò àgọ́ ìsádi fìdí-hẹ sí. Kíá, àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sáwọn ibi ìkóúnjẹsí wọ́n sì ra àwọn ohun tó ṣe kókó bí ìrẹsì, ẹ̀wà, ìyẹ̀fun, àti epo.

Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn nípa àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tó wà ní Chókwè àtàwọn ìlú àgbègbè rẹ̀. Àwọn alábòójútó tó wà nínú àwọn ìjọ ní Chókwè pàdé pọ̀ wọ́n sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa kó gbogbo wọn kúrò. Wọ́n tan ìsọfúnni náà yíká pé: “Ẹ gbéra kíá, ẹ máa lọ sí Macia!” Àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n mọ̀ pé púpọ̀ àwọn tó wà ní Xinavane ni kò tíì dé. Ni wọ́n bá rán àwọn Ẹlẹ́rìí láti lọ wò wọ́n. Wọ́n tún gbọ́ pé Kristẹni alàgbà kan ti kú sómi nínú ilé rẹ̀. Wọn ṣètò ìsìnkú rẹ̀, wọ́n sì wá àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù rí, orí òrùlé làwọn kan wà wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dé Macia.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí àwọn ètò yìí, làwọn aṣojú láti ẹ̀ka náà wá lọ sí Bilene, ìlú kékeré kan tó wà létíkun, níbi tí wọ́n ti háyà ọkọ̀ òfuurufú kan lọ sí Maputo. Gbogbo ibi táwọn arìnrìn àjò náà yíjú sí lómi lọ rẹrẹẹrẹ. Ìròyìn sọ pé lẹ́kùn Gaza nìkan, ó lé ní ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] ènìyàn tí wàhálà náà bá.

Nǹkan Tún Burú Sí I

Láàárín ọjọ́ díẹ̀ tó tẹ̀ lé e, òjò ọ̀hún túbọ̀ ń dà wàràwàrà, gbogbo àwọn ibi pàtàkì ní ẹkùn Mòsáńbíìkì ló sì bà jẹ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ńlá kan tí wọ́n ń pè ní Eline gbára jọ. Ní February 20 ó rọ òjò abàmì kan ní ẹkùn Inhambane, Sofala, àti Manica. Ìyẹn sì tún fa àkúnya, ikú àti òfò púpọ̀ sí i.

Nígbà tí oṣù February ń parí lọ, omi bo ìlú Chókwè àti gbogbo àgbègbè tó yí i ká lọ́nà tí wọn kò tíì rí irú rẹ̀ rí. Ní Saturday, February 26, ni nǹkan bí ọ̀gànjọ́ òru, àkúnya omi rọ́ dé gììrì, gbogbo ohun tó rí ló sì gbá lọ. Luis Chitlango, Ẹlẹ́rìí ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n sọ pé: “Ariwo tí aládùúgbò wa kan ń pa láti ojú fèrèsé ló jí wa.”

Chitlango ṣàlàyé pé: “Báa ṣe bẹ́ kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì, a ń gbọ́ bí omi náà ti ń pariwo gan an. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ejò la rí lọ́nà báa ti ń sá lọ. Láago mẹ́fà òwúrọ̀, a dé ibì kan tó ga sókè díẹ̀, àmọ́ nígbà tó máa fi di ìyálẹ̀ta, tí omíyalé náà sì pọ̀ sí i ní gbogbo àyíká, a ní láti gun orí igi lọ. Àwa èèyàn ogún la wà níbẹ̀.

“Àwọn ọkùnrin ló kọ́kọ́ gun igi. Lẹ́yìn náà làwọn obìnrin gbé àwọn ọmọ fún wọn tí wọ́n sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀ka igi. Àwọn obìnrin gùn ún tẹ̀ lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn. Gbogbo ìgbà la ń sọ̀kalẹ̀ lọ sọ̀kalẹ̀ bọ̀ látorí igi láti wá ẹ̀pà lábẹ́ omi, èyí táa mọ̀ pé wọ́n ń gbìn ní àdúgbò náà.

“Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, a pinnu pé kí gbogbo wa máa fẹsẹ̀ rìn lọ sí Chókwè. Omi mù wá dé àyà, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbì omi ń rọ́ lù wá. Báa ti ń lọ la ń rí àwọn èèyàn lórí igi àti lórí àwọn òrùlé. Lọ́jọ́ kejì, àkúnya omi náà ti rọlẹ̀ débi táwọn ọkọ̀ akẹ́rù fi lè dé ìlú kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn lọ sí Macia.”

Àgọ́ Ìsádi Àwọn Ẹlẹ́rìí

Ní March 4, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà háyà ọkọ̀ òfuurufú kan wọ́n sì gbé àwọn aṣojú lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà ti sá lọ sí Macia, èyí tó ti wá di àgọ́ ńlá fáwọn olùwá-ibi-ìsádi. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wàhálà ìkún omi náà bá ni àrùn gágá, àìjẹunrekánú, ibà, àtàwọn ìpọ́njú mìíràn kọ lù.

Bí ojú ogun ni ìran náà rí. Àwọn hẹlikóbítà tí wọ́n fi ránṣẹ́ láti onírúurú orílẹ̀-èdè kún ojú òfuurufú ìlú náà wọ́n sì balẹ̀ sáwọn ibi tí wọ́n rí láti já àwọn ẹrù tí wọ́n kó wá sílẹ̀. Nígbà táwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó kó nǹkan ìrànwọ́ dé sí Macia, kì í ṣe pé wọ́n kàn ṣètò fífún àwọn èèyàn lóúnjẹ nìkan ni àmọ́ wọ́n tún ṣètò ibi ìtọ́jú aláìsàn kan. Àmọ́ ṣáájú ohunkóhun, wọ́n kọ́kọ́ gba ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ àdúgbò, àwọn yẹn sì yìn wọ́n fún ìdánúṣe wọn.

Ní ibùdó àwọn Ẹlẹ́rìí láràárọ̀, ibùdó tó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn mìíràn nínú, wọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì kan ní aago mẹ́fà ààbọ̀ òròòwúrọ̀. Nígbà tí àwọn Kristẹni arábìnrin bá ti se oúnjẹ tán, wọ́n á pe orúkọ àwọn olórí ìdílé. Ẹnì kọ̀ọ̀kan á sì na ìka sókè láti sọ iye abọ́ oúnjẹ tó fẹ́, wọ́n á wá gbé oúnjẹ náà fún wọn.

Wọ́n ṣètò apá kọ̀ọ̀kan ìgbésí ayé inú àgọ́ náà dáadáa. Wọ́n yan iṣẹ́ oúnjẹ rírà fún àwọn kan; tàwọn mìíràn sì rèé, láti rí sí i pé omi mímú wà ní mímọ́ tónítóní, láti tọ́jú àwọn ilé ìgbọ̀nsẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn aláṣẹ ìjọba ò ṣàì rí ìṣètò dídára yìí o, wọ́n sọ pé: ‘Ó mà dáa kéèyàn wà níbí o. Kò sẹ́ni tí kò róúnjẹ jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aáwọ̀.’ Aláṣẹ àdúgbò kan sọ pé: ‘Gbogbo èèyàn ló yẹ kó yọjú sí àgọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí láti rí bí nǹkan ṣe yẹ kó rí.’

Lọ́jọ́ kan, ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ náà pe àwọn Kristẹni alàgbà jọ wọ́n sì sọ fún wọn pé ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ti ṣètò fún títún àwọn ilé àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ títí kan pípèsè àwọn ohun ṣíṣe kókó fáwọn tó kàgbákò omi náà. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Bíbélì fún ọjọ́ náà, wọ́n ṣe ìfilọ̀ nípa ìṣètò yìí. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má dáwọ́ àtẹ́wọ́ dúró.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aláṣẹ fún wọn ní tẹ́ǹtì méjì, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ibùdó náà ṣì ń sùn ní gbangba ìta. Nítorí náà, wọ́n ṣètò àwùjọ kan lára àwọn tí wàhálà omi náà bá láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ńlá kan sórí ilẹ̀ tó jẹ́ ti ìjọ àdúgbò náà. Esùsú àti páànù ni wọ́n fi kọ́ ọ—èyí jẹ́ lọ́nà ti àwọn ará Mòsáńbíìkì, ó sì gba igba èèyàn. Ọjọ́ méjì péré ni wọ́n fi parí ẹ̀!

Wíwá Àwọn Tó Wà Ní Àdádó Rí

Ní báyìí ná, ní March 5, lẹ́yìn tí omi yẹn ti lọ sílẹ̀ díẹ̀, wọ́n ṣètò àwùjọ aṣèrànwọ́ kan láti lọ sí ìlú Aldeia da Barragem tó wà ní àgbègbè tí àkúnya náà ti kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀. Ó ní ìjọ kan tí nǹkan bí àádọ́rùn-ún Ẹlẹ́rìí wà, wọn ò sì tíì gbúròó wọn rárá.

Níbi tí wọ́n ti ń lọ, àwùjọ ọ̀hún kọjá ní Chihaquelane, àgọ́ ìsádi títóbi kan tó ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn. Ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ọ̀nà náà, tómi ti ru àwọn ibì kan lára ẹ̀ lọ, gbogbo ibi téèyàn lè gbójú sí ládùúgbò yẹn lomi lọ rẹrẹ. Ọ̀kan lára àwọn àwùjọ náà sọ pé: “Nígbà táa dé Chókwè, gbogbo ibẹ̀ ló bà jẹ́. Ọ̀pọ̀ ilé tó wà lábàáwọ ìlú náà lomi ṣì mù dé orí òrùlé. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ilé náà wà lábẹ́ omi. Ilẹ̀ ti ń ṣú, bẹ́ẹ̀ sì rèé a ṣì máa rin kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ká tó dé Aldeia da Barragem.”

Níkẹyìn, ní òru, àwùjọ náà dé ibi tí wọ́n ń lọ. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “A dúró a sì ń ronú ohun táa lè ṣe.” Bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn jáde, tí wọ́n sì ń pariwo: “Ẹ̀yin ará!” bẹ́ẹ̀ lariwo ẹ̀rín ayọ̀ gba ibẹ̀ kan. Bí wọ́n ti rí iná ọkọ̀ méjèèjì náà, kíá làwọn Ẹlẹ́rìí náà ti ronú pé ó lè jẹ́ àwọn arákùnrin wọn ni, wọ́n sì sọ fún àwọn ẹlòmíràn. Orí àwọn tó ń wò wọ́n wú, wọ́n sọ pé: ‘Àwọn èèyàn yìí mà nífẹ̀ẹ́ gan an o. Wọ́n gbé oúnjẹ wá kódà wọ́n tún wá wò wọ́n!’

Pípèsè Ìtọ́jú Tí Kò Dáwọ́ Dúró

Wọ́n ran àwọn arákùnrin tó wá láti Aldeia da Barragem lọ́wọ́ láti dé ibùdó ní Macia, níbi tí wọ́n ti fún wọn lóúnjẹ, ibi tí wọ́n máa gbé, àti ìtọ́jú. Bí àkókò ti ń lọ, ipò nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í le ní Macia. Oúnjẹ, oògùn, àti epo bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́n, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọkọ̀ òfuurufú ni wọ́n fi ń kó wọn wá. Ó wá di kánjúkánjú láti wá ọnà títì tó máa dé Maputo. Wọ́n ṣe èyí ní March 8.

Omi ti bo ìlú ńlá Xai-Xai mọ́lẹ̀ pátápátá. Ohun táwọn ibi kan ní ọ̀gangan ìlú náà fi jìn sábẹ́ omi tó mítà mẹ́ta! Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣètò ìgbìmọ̀ aṣèrànwọ́ kan láti bójú tó àwọn arákùnrin wọn tó wà níbẹ̀. Láfikún sí i, wọ́n dá àwọn ìgbìmọ̀ sílẹ̀ láti bójú tó àwọn tó nílò ìrànwọ́ láwọn ẹkùn Sofala àti Manica.

Ìpèsè ìrànwọ́ tún wá látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn orílẹ̀-èdè míì. Fún àpẹẹrẹ, ẹ̀ka iléeṣẹ́ ní Gúúsù Áfíríkà ṣètò fún kíkó àìmọye aṣọ, bùláńkẹ́ẹ̀tì, àtàwọn ẹrù mìíràn wá. Bẹ́ẹ̀ sì ni oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé ní Brooklyn, New York, gbé owó kalẹ̀ láti fi tọ́jú àwọn tí àjálù náà kàn.

Nígbà tómi náà ti lọ sílẹ̀ dáadáa tí wọ́n sì ti ṣírò iye àwọn tí wọ́n pàdánù ilé wọn, iṣẹ́ títún àwọn ilé àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ bẹ̀rẹ̀. Wọ́n dá ìgbìmọ̀ atúnlékọ́ kan sílẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni sì kọ́wọ́ tì wọ́n, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ní kíákíá. Látìgbà náà wá, wọ́n ti ṣàtúnkọ́ àwọn ilé tó ju àádọ́rin lé rúgba [270] lọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn ún ó kéré tán.

Nígbà tí àwọn ilé táwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn kọ́kọ́ kọ́, bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn, àwọn èèyàn kíyè sí i. Aládùúgbò kan sọ pé: ‘Ọlọ́run tó wà láàyè lẹ̀ ń sìn. Àwọn pásítọ̀ wa ò rántí àwọn àgùntàn wọn tí ìyà ń jẹ. Àmọ́, ẹ̀yín ń rí àwọn ilé tó lẹ́wà wọ̀nyí gbà.’ Ní irú àwọn àdúgbò bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ti ń fetí sí ìhìn Ìjọba táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Mátíù 24:14; Ìṣípayá 21:3, 4.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló pàdánù gbogbo ohun ìní wọn nípa tara, kò sẹ́ni tó pàdánù ìgbàgbọ́ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà Ọlọ́run àti nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kárí ayé túbọ̀ lókun sí i. Wọ́n kún fún ìmoore fún ẹgbẹ́ ará wọn onífẹ̀ẹ́ lágbàáyé, èyí tó dáhùn padà ní kánmọ́ sí àjálù burúkú yìí. Wọ́n ti fúnra wọn rí àbójútó onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà àti ààbò rẹ̀, títí ayé ni wọn yóò sì máa rántí ọ̀rọ̀ Bíbélì náà pé: “Jèhófà tóbi.”—Sáàmù 48:1.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Omi ẹlẹ́rẹ̀ bo ìlú Xai-Xai bámúbámú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Wọ́n fi ọkọ̀ òfuurufú kó àwọn ìpèsè ìrànwọ́ wọlé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwùjọ Ẹlẹ́rìí aṣèrànwọ́ ṣe ibi ìtọ́jú aláìsàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Wọn ò dáwọ́ kíkọ́lé tuntun dúró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àgọ́ ìsádi títóbi jù lọ gba ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] èèyàn