Bíbélì—Ṣó Yẹ Ká Gba Àwọn Ìtàn Inú Rẹ̀ Gbọ́?
Bíbélì—Ṣó Yẹ Ká Gba Àwọn Ìtàn Inú Rẹ̀ Gbọ́?
WỌ́N bá àwọn alákòóso wí. Wọ́n na àwọn àlùfáà ní patiyẹ ọ̀rọ̀. Àwọn èèyàn gbáàtúù ò sì lọ lọ́fẹ̀ẹ́ fún ìwà ibi tí wọ́n hù. Kódà, wọn kò fi àléébù tiwọn alára àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn bò. Wọ́n wá wọn kiri wọ́n sì ṣenúnibíni sí wọn, wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan lára wọn fún sísọ òtítọ́ àti kíkọ ọ́ sílẹ̀. Àwọn wo tiẹ̀ ni? Àwọn wòlíì inú Bíbélì ni, tí púpọ̀ nínú wọn ní ipa tí wọ́n kó nínú kíkọ Ìwé Mímọ́.—Mátíù 23:35-37.
Nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Historian and History, Page Smith kọ̀wé pé: “Bí wọn [àwọn Hébérù] ò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àwọn tó jẹ́ èèyànkéèyàn láàárín wọn ni wọn ò ṣe fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àwọn tó jẹ́ alágbára nínú wọn, sí ara wọn àtàwọn tó jẹ́ ọ̀tá wọn, nítorí pé Ọlọ́run ń kíyè sí bí wọ́n ti ń ṣe àkọsílẹ̀ náà, dípò kí wọ́n sì jèrè ohun kan tí wọ́n bá fi òtítọ́ pa mọ́, àdánù ńlá gbáà ló máa jẹ́ tiwọn.” Smith tún kọ̀wé pé “láìdàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń súni nípa àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ọba tó jẹ́ jagunjagun ní Síríà tàbí ní Íjíbítì, àkọsílẹ̀ nípa ìpọ́njú àti ìṣẹ́gun àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn . . . jẹ́ ìtàn kan tí ń gbádùn mọ́ni. Ọwọ́ àwọn òpìtàn Hébérù ti ba ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ nínú kíkọ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì sílẹ̀—ìyẹn ni sísọ nípa àwọn èèyàn tó gbé ayé lóòótọ́, pẹ̀lú gbogbo àṣìṣe àti àbààwọ́n tí wọ́n ní.”
Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yìí tún lo ìṣọ́ra gidigidi ní rírí sí i pé ohun tí àwọ́n kọ sílẹ̀ péye. Lẹ́yìn tí òǹkọ̀wé Werner Keller ti fi àlàyé ẹ̀kọ́ ìtàn àti ìwalẹ̀pìtàn ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ Bíbélì, ó sọ nínú ọ̀rọ̀ tó fi ṣíde ìwé rẹ̀ tó pè ní The Bible as History pé: “Lójú ọ̀pọ̀ jaburata ẹ̀rí tó ṣeé gbára lé tó sì jẹ́ ojúlówó tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó báyìí, . . . gbólóhùn kan yìí ṣì máa ń wá sí mi lọ́kàn ṣáá pé: ‘Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Bíbélì tọ̀nà!’”
Ìwé Ìtàn Gbígbéṣẹ́ Tó Ní Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Lágbára
Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ló jẹ́ àwọn ọkùnrin gbáàtúù—àwọn àgbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn, apẹja. Síbẹ̀, ohun tí wọ́n fi nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún kọ ti nípa lórí àwọn èèyàn ju bí ìwé èyíkéyìí mìíràn ti ṣe lọ, ì báà jẹ́ tàtijọ́ tàbí tòde òní. Síwájú sí i, gbogbo ọ̀nà ni wọ́n ti gbógun ti àwọn àkọsílẹ̀ wọn, àmọ́ ìyẹn ò tu irun kan lára rẹ̀. (Aísáyà 40:8; 1 Pétérù 1:25) Lónìí, Bíbélì ni a lè kà bóyá lódindi tàbí lápá kan ní nǹkan bí ẹgbọ̀kànlá [2,200] èdè—ìyẹn ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ! Kí ló mú Bíbélì tayọ lọ́lá tó bẹ́ẹ̀? Àwọn ìtọ́ka tó tẹ̀ lé e yìí á ṣèrànwọ́ láti dáhùn ìbéèrè yẹn.
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
“Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.”—Róòmù 15:4.
“Nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa [Kristẹni] tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.”—1 Kọ́ríńtì 10:11.
Bẹ́ẹ̀ ni o, Bíbélì jẹ́ ìwé táa gbé ga ju gbogbo àwọn ìwé yòókù lọ, nítorí pé ó jẹ́ àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó sì pa mọ́ nípa àwọn èèyàn tó wà láyé
nígbà kan—àwọn kan tó múnú Ọlọ́run dùn àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kì í ṣe ìwé tó jẹ́ pé àwọn òfin ṣe èyí àti má ṣe èyí ló kúnnú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe àkójọ ìtàn dídùn láti dá àwọn ọmọdé lára yá. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn ni Ọlọ́run lò láti kọ ọ́, àmọ́ ńṣe lèyí túbọ̀ fi kún iyì Bíbélì, ó túbọ̀ jẹ́ kó fani mọ́ra, ìyẹn sì ti mú kó wọ àwọn tó ń kà á lọ́kàn láti ìrandíran. William Albright tó jẹ́ awalẹ̀pìtàn sọ pé: “Òye jíjinlẹ̀ nípa ìwà rere àti nípa tẹ̀mí tó wà nínú Bíbélì ṣì jẹ́ òtítọ́ lónìí gẹ́gẹ́ bó ti jẹ́ ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sí mẹ́ta sẹ́yìn, èyí tó wá di ìṣípayá aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọ́run fún ènìyàn nípa lílo ìrírí ẹ̀dá ènìyàn fúnra rẹ̀.”Láti ṣàpèjúwe bí Bíbélì ṣe wúlò ní gbogbo ìgbà, ẹ jẹ́ ká padà lọ sí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn ènìyàn—ibi tó jẹ́ pé Bíbélì nìkan ló lè mú wa débẹ̀—ká sì wá gbé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan yẹ̀ wò látinú ìwé Jẹ́nẹ́sísì.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Tó Bágbà Mu Látinú Ìtàn Ìgbàanì Kan
Lára àwọn ohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣí payá ni bí ìdílé aráyé ṣe bẹ̀rẹ̀—orúkọ wọn, àtàwọn nǹkan mìíràn nípa wọn. Lórí kókó yìí, kò tún sí ìwé ìtàn mìíràn tó tún sọ ojú abẹ níkòó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ o wá lè béèrè pé, ‘àǹfààní wo ló wà nínú mímọ̀ nípa orírun wa?’ Àǹfààní tó ní pọ̀, nítorí Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo ènìyàn—láìka àwọ̀ ara wọn, ẹ̀yà wọn, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí—gbogbo wọn ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí kan, ìwé yẹn tipa bẹ́ẹ̀ mú ìpìlẹ̀ èyíkéyìí tó lè wà fún ẹ̀tanú ẹ̀yà ìran kúrò.—Ìṣe 17:26.
Jẹ́nẹ́sísì tún pèsè ìtọ́sọ́nà lórí ìwà rere. Ó ní àkọsílẹ̀ nípa Sódómù, Gòmórà, àtàwọn ìlú tó yí wọn ká, tí Ọlọ́run pa wọ́n run nítorí ìṣekúṣe lílékenkà àwọn èèyàn tó ń gbé inú wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20–19:29) Jud Ẹsẹ ìkeje ìwé Júúdà nínú Bíbélì sọ pé: “Sódómù àti Gòmórà àti àwọn ìlú ńlá tí ó yí wọn ká, lẹ́yìn tí [wọ́n] . . . ti ṣe àgbèrè lọ́nà tí ó pọ̀ lápọ̀jù, tí wọ́n sì ti jáde tọ ẹran ara lẹ́yìn fún ìlò tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, a gbé wọn ka iwájú wa gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akini-nílọ̀.” Ọlọ́run kò fún àwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà ní òfin kankan lórí ìwà rere; àmọ́ Ọlọ́run fún wọn ni agbára ẹ̀rí ọkàn gẹ́gẹ́ bó ti fún gbogbo ẹ̀dá tó kù. Ìdí rèé tí Ọlọ́run fi lẹ́tọ̀ọ́ láti mú káwọn èèyàn náà jíhìn fún ohun tí wọ́n ṣe. (Róòmù 1:26, 27; 2:14, 15) Bákan náà ni lónìí, Ọlọ́run yóò mú kí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn dáhùn fun ohun tí wọ́n ṣe, yálà wọ́n tẹ́wọ́ gba Bíbélì Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí wọn kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—2 Tẹsalóníkà 1:8, 9.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ìtàn Àwọn Tó Là Á Já
Ère gbígbẹ́ kan tó wà lórí Ọwọ̀n Bìrìkìtì ti Títù ní Róòmù ṣàpèjúwe bí àwọn ọmọ ogun Róòmù ṣe ń kó àwọn ohun èlò mímọ́ jáde nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn ìparun ìlú náà ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Ó lé ní mílíọ̀nù kan àwọn Júù tí wọ́n pa. Bó ti wù kó rí, àwọn Kristẹni tó jẹ́ onígbọràn là á já o, ọpẹ́lọpẹ́ ìkìlọ̀ tí Jésù ti fún wọn ṣáájú pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àárín rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀, kí àwọn tí wọ́n sì wà ní àwọn ibi ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀; nítorí pé ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ọjọ́ fún pípín ìdájọ́ òdodo jáde.”—Lúùkù 21:20-22.
Dípò tí ìpọ́njú tó wá sórí Jerúsálẹ́mù yìí ì bá fi wulẹ̀ jẹ́ apá kan ìtàn lásán, ó jẹ́ ara òjìji ìpọ́njú títóbi jù lọ tó máa bo gbogbo ayé mọ́lẹ̀ pátápátá. Àmọ́ o, bí i ti ìṣáájú, àwọn olùlàájá yóò wà. Àwọn wọ̀nyí ni a pè ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Wọ́n “jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà” nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀—ìyẹn jẹ́ ìgbàgbọ́ kan tó dúró gbọn-in-gbọn-in tí wọn gbé ka àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ti kọjá tí wọ́n rí nínú Bíbélì àti àsọtẹ́lẹ̀.—Ìṣípayá 7:9, 14.
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Ìtàn Tí Kò Ní Padà Ṣẹlẹ̀ Mọ́ Láé
Lónìí, a ń gbé ní àkókò tí Agbára Ayé Gẹ̀ẹ́sì òun Amẹ́ríkà ń ṣàkóso, èyí tó gbẹ̀yìn nínú àwọn agbára ayé tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Nípa yíyẹ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá wò, a rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ti ìṣáájú ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sóun náà, ó gbọ́dọ̀ wá sópin. Àmọ́ lọ́nà wo? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, ó dájú pé ọ̀nà tí agbára ayé yìí máa fi wá sópin kò ní aláfijọ. Ní títọ́ka síwájú sí ọdún 1914 Sànmánì Tiwa, Dáníẹ́lì 2:44 sọ nípa àwọn agbára òṣèlú náà, tàbí àwọn “ìjọba” yẹn pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
Dájúdájú, Ìjọba Ọlọ́run—ìyẹn ìṣàkóso tọ̀run tí Kristi Jésù jẹ́ aṣáájú rẹ̀—yóò mú gbogbo àpá èyíkéyìí ti ìṣàkóso aninilára ẹ̀dá ènìyàn kúrò ní Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn á jẹ́ òtéńté fún “ìpọ́njú ńlá” táa mẹ́nu kàn níṣàájú. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ìjọba yìí ni ‘a kì yóò gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn,’ Sáàmù 72:8.
èyí tó túmọ̀ sí pé a kò ní ṣẹ́gun rẹ̀ láé tàbí mú un kúrò. Àgbègbè ìṣàkóso rẹ̀ yóò jẹ́ “dé òpin ilẹ̀ ayé.”—Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìwà òǹrorò tó máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra nítorí ìjẹgàba ìsìn èké, ètò ìṣèlú agbonimọ́lẹ̀, àti ètò ìṣòwò oníwọra yóò dópin. Sáàmù 72:7 ṣèlérí pé: “Olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.” Ìfẹ́ tó jẹ́ ànímọ́ títayọ tí Ọlọ́run ní ni yóò gba ayé kan, kì í ṣe ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga. (1 Jòhánù 4:8) Jésù sọ pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín.” Nígbà tí òpìtàn Will Durant ń sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó ní: “Àbárèbábọ̀ ohun tí mo rí kọ́ nínú àwọn àlámọ̀rí ènìyàn rí gẹ́lẹ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù. . . . Ìfẹ́ ni ohun tó dára jù lọ nínú ayé.”
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún ẹ̀dá ènìyàn ló sún un láti mí sí kíkọ Bíbélì. Bíbélì nìkan ló tànmọ́lẹ̀ sí ohun to ti ṣẹlẹ̀ kọjá, tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, àti èyí tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Dákun, jọ̀wọ́, tẹ́wọ́ gba ìsọfúnni tí ń fúnni ní ìyè tó wà nínú rẹ̀ nípa wíwá àkókò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí èyí lè ṣeé ṣe, àti ní ìgbọràn sí àṣẹ Jésù, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò wọn. Láìpẹ́, ìhìn rere yìí kò tún ní jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́, yóò di ara ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá.—Mátíù 24:14.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Bíbélì tọ̀nà!”—WERNER KELLER
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
“Òye jíjinlẹ̀ nípa ìwà rere àti nípa tẹ̀mí tó wà nínú Bíbélì . . . ṣì jẹ́ òtítọ́ lónìí gẹ́gẹ́ bó ti jẹ́ ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sí mẹ́ta sẹ́yìn.”—WILLIAM ALBRIGHT TÓ JẸ́ AWALẸ̀PÌTÀN
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Òkúta Móábù: Àkọsílẹ̀ Ọba Méṣà nípa ìjà tó ṣẹlẹ̀ láàárín Móábù àti Ísírẹ́lì wà lára rẹ̀ (2 Àwọn Ọba 3:4-27), ó ní oríṣiríṣi orúkọ àwọn ibi tí Bíbélì dárúkọ, àti orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi lẹ́tà Hébérù ìgbàanì kọ.
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris.
Owó dínárì onífàdákà: Ẹ̀dà rẹ̀ tí wọ́n mú jáde ní ère àti àkọlé Késárì Tìbéríù lára (Máàkù 12:15-17).
Ìwé Ìtàn Nábónídọ́sì: Àkọsílẹ̀ tí wọ́n fín sára òkúta tó ń jẹ́rìí sí ìṣubú Bábílónì sọ́wọ́ Kírúsì lójijì. (Dáníẹ́lì, orí 5)
[Credit Line]
Iléeṣẹ́ British Museum ló fún wa láṣẹ láti ya fọ́tò yìí.
Ẹ̀là òkúta: Ó ní orúkọ Pọ́ńtíù Pílátù ní èdè Látìn.
[Credit Line]
Fọ́tò © Israel Museum, Jerúsálẹ́mù; nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Israel Antiquities Authority.
Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ló wà lẹ́yìn wọn: Àyẹ̀wò àyọkà kan nínú ìwé Aísáyà fi hàn pé ìwé yìí wà digbí láìsí ìyípadà kankan fún ẹgbẹ̀rún ọdún tí wọ́n ti ń fi ọwọ́ ṣe àdàkọ rẹ̀.
[Credit Line]
Shrine of the Book, Israel Museum, Jerúsálẹ́mù.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ère gbígbẹ́ kan tó wà lórí Ọwọ̀n Bìrìkìtì ti Títù jẹ́rìí sí ìparun Jerúsálẹ́mù ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa
[Credit Line]
Soprintendenza Archeologica di Roma