MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
Gbogbo ohun tá a nílò ká lè fara da àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2Ti 3:1, 16, 17) Síbẹ̀, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé a lè má mọ bá a ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, ṣé òbí ni ẹ́, tó o sì ń wá ìmọ̀ràn lórí bó o ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ? Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, tó o sì ń dojú kọ àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò? Ṣé ò ń ṣọ̀fọ̀ ikú ọkọ tàbí ìyàwó rẹ? Lórí Ìkànnì jw.org, wàá rí àwọn ìsọfúnni táá jẹ́ kó o mọ àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ipò yìí àtàwọn ipò míì tó o lè bá ara ẹ.—Owe 2:3-6.
Lórí Ìkànnì jw.org, te apá tá a pè ní Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ. (Wo àwòrán 1.) Nínú àwọn ohun tó gbé wa, yan èyí tó o fẹ́. Tàbí kó o lọ sí apá OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ kó o sì yàn èyí tó o fẹ́. (Wo àwòrán 2.) O tún lè rí àwọn apá yìí lórí JW Library®. * Wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ náà kà ní èyíkéyìí lára àwọn ibi tá a tọ́ka sí yìí. Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o tẹ ohun tó o fẹ́ ṣèwádìí lé lórí sí apá tá a pè ní “wà a” lórí Ìkànnì jw.org.
Tẹ àwọn àkọlé yìí sí apá wá a, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tí wàá fẹ́ kà.
-
Ọmọ títọ́
-
Ìṣòro àwọn ọ̀dọ́
-
Ikú ọkọ tàbí aya
^ Orí jw.org nìkan lo ti lè rí gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan.