MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ | JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
Máa Lo Àwọn Ohun Èlò Ìwádìí
Jèhófà ti fún wa láwọn nǹkan tó lè mú ká já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, a ní oríṣiríṣi fídíò, ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ńlá àti Bíbélì tó jẹ́ olórí irinṣẹ́ wa. (2Ti 3:16) Ó tún fún wa láwọn ohun èlò ìwádìí kó lè rọrùn fún wa láti ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, a ni Watchtower Library, JW Library®, Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ti Watchtower), àti Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Wàá máa láyọ̀ tó o bá ń lo àwọn ohun èlò yìí láti túbọ̀ walẹ̀ jìn kó o lè rí àwọn ìṣúra tẹ̀mí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ káwọn náà lè mọ bá a ṣe ń lo àwọn ohun èlò yìí. Ìyẹn á jẹ́ kó rọrùn fáwọn náà láti máa wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọn.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ IṢẸ́ SÍSỌNI DI ỌMỌ Ẹ̀YÌN MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀—MÁA LO ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ PÈSÈ—ÀWỌN OHUN ÈLÒ ÌWÁDÌÍ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Kí ni Jade sọ tó fi hàn pé kò gbà pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan?
-
Ibo ni Neeta ti ṣèwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà?
-
Kí ló jẹ́ kí Neeta mọ ohun tó máa ran Jade lọ́wọ́?
-
Àǹfààní wo ni Neeta rí nígbà tó lo àwọn ohun èlò ìwádìí?