Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ̀ Pé Ayé Tuntun Ò Ní Pẹ́ Dé!

Jẹ́ Káwọn Èèyàn Mọ̀ Pé Ayé Tuntun Ò Ní Pẹ́ Dé!

Lóṣù November, a máa ṣiṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ káwọn èèyàn lè mọ̀ pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé. (Sm 37:10, 11; Ifi 21:3-5) Ṣètò àkókò ẹ kó o lè kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ yìí. Tó o bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn, o lè pinnu bóyá ọgbọ̀n (30) tàbí àádọ́ta (50) wákàtí ni wàá lò.

Lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti ka ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ayé tuntun fáwọn èèyàn. Tó o bá fẹ́ yan ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà, ronú nípa ohun tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ládùúgbò yín. Tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ, fún un ní Ilé Ìṣọ́ No. 2 2021. Rí i pé o tètè pa dà bá ẹni náà sọ̀rọ̀, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa kéde “ìhìn rere nípa ohun tó sàn”!​—Ais 52:7.

Ẹ WO FÍDÍÒ ORIN NÁÀ AYÉ TUNTUN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn nǹkan wo ni ọmọbìnrin yìí ń fojú sọ́nà fún?

  • Àwọn nǹkan wo lò ń fojú sọ́nà fún nínú ayé tuntun?

  • Tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó o fìtara wàásù nípa ayé tuntun lóṣù November?​—Lk 6:45