MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn Tó Jẹ́ Mímọ́
“Lọ fọ ọwọ́ ẹ̀. Lọ fọ abọ́ tó o fi jẹun. Rí i dájú pé o gbálẹ̀. Lọ dalẹ̀ nù.” Ọ̀pọ̀ òbí máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè fọwọ́ pàtàkì mú ìmọ́tótó. Àmọ́, àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run mímọ́ láwọn ìlànà tó ń jẹ́ ká wà ní mímọ́ ti wá. (Ẹk 30:18-20; Di 23:14; 2Kọ 7:1) Tá a bá ń jẹ́ kí ara wa àtàwọn nǹkan ìní wa wà ní mímọ́, ṣe là ń fògo fún Jèhófà. (1Pe 1:14-16) Ilé wa àti àyíká wa ńkọ́? Kò yẹ ká fìwà jọ àwọn èèyàn tó máa ń ju ìdọ̀tí sójú títì tàbí síbikíbi tí wọ́n bá rí. Dípò bẹ́ẹ̀, àwa Kristẹni máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti mú kí ilẹ̀ ayé tí Jèhófà fi jíǹkí wa wà ní mímọ́. (Sm 115:16; Ifi 11:18) Kódà nínú àwọn nǹkan kéékèèké míì irú bí ibi tá a ju ọ̀rá súìtì sí, agolo ohun mímu tàbí ṣingọ́ọ̀mù lè fi irú ọwọ́ tá a fi mú ìmọ́tótó hàn. Nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa ló ti yẹ ká máa “dámọ̀ràn ara wa bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run.”—2Kọ 6:3, 4.
WO FÍDÍÒ NÁÀ ỌLỌ́RUN NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWỌN ÈÈYÀN TÓ JẸ́ MÍMỌ́, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
-
Àwáwí wo làwọn kan máa ń ṣe tí wọn kì í fi í bójú tó àwọn nǹkan ìní wọn?
-
Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó?
-
Báwo la ṣe lè fògo fún Jèhófà láìsọ ọ̀rọ̀ kan?