Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DÁNÍẸ́LÌ 10-12

Jèhófà Mọ Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọba

Jèhófà Mọ Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọba

11:2

Ọba mẹ́rin máa dìde ní ilẹ̀ Páṣíà. Ọba kẹrin máa “gbé ohun gbogbo dìde lòdì sí ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì.”

  1. Kírúsì Ńlá

  2. Kanbáísísì Kejì

  3. Dáríúsì Kìíní

  4. Sásítà Kìíní (tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé òun ni Ọba Ahasuwérúsì tó fẹ́ Ẹ́sítérì)

11:3

Ọba kan máa dìde ní ilẹ̀ Gíríìsì, àkóso rẹ̀ sì máa dé ibi tó pọ̀ gan-an.

  • Alẹkisáńdà Ńlá

11:4

Àwọn ọ̀gágun Alẹkisáńdà mẹ́rin máa pín àkóso Ilẹ̀ Ọba Gíríìsì láàárín ara wọn.

  1. Kasáńdà

  2. Lisimákù

  3. Sẹ̀lẹ́úkọ́sì Kìíní

  4. Tọ́lẹ́mì Kìíní