ÌWÉ ÌPÀDÉ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀTI IṢẸ́ ÒJÍṢẸ́ ÀWA KRISTẸNI October 2017
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn Jí! lọni àti láti kọ́ni nípa bí a ṣe lè ṣèfẹ́ Ọlọ́run. Lo àbá yìí láti fi kọ ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì Sọ Ìgbà Tí Mèsáyà Máa Dé
Dáníẹ́lì orí 9 sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbà tí Mèsáyà máa dé. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀ Nínú Ìwé Mímọ́
Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀, wàá lè jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò. Àmọ́, ibo ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jèhófà Mọ Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọba
Jèhófà lo wòlí ì Dáníẹ́lì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ilẹ̀ ọba àti àwọn ọba ṣe máa dìde àti bí àwọn mí ì ṣe máa rọ́pò wọn lọ́jọ́ iwájú.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?
Kí ló máa ń mú kéèyàn ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Hóséà àti Gómérì ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ aláìṣòótọ́?
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Fún Jèhófà Ní Ohun Tó Dára Jù Lọ
Inú Jèhófà máa dùn tó o bá fún un ní ohun tó dára jù lọ, ó sì máa ṣe ìwọ náà láǹfààní. Kí ni Jèhófà kà sí ọ̀kan lára ohun tó dára jù lọ?
MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Fi Ayé Rẹ Yin Jèhófà!
Ẹ̀mí ṣeyebíye gan-an. À ń sapá láti fi àwọn ẹ̀bùn wa àti okun wa bọlá fún Jèhófà tó jẹ́ Orísun Ìyè.
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
‘Àwọn Ọmọkùnrin Yín àti Àwọn Ọmọbìnrin Yín Yóò Máa Sọ Tẹ́lẹ̀’
Báwo ni a ṣe lè ti àwọn ẹni àmì òróró lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìsọtẹ́lẹ̀?